ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/1 ojú ìwé 4-7
  • Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ló Lẹ̀bi?
  • “Ìgbà àti Èèṣì”
  • Àbájáde Búburú Tí Àìpé Ní
  • Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ —Agbára Tí Ń Pani Lára Tí Ó Ní
  • Ó Ha Jẹ́ Ìdènà fún Ipò Ìbátan Wa Pẹ̀lú Ọlọ́run Bí?
  • A Dá A Sílẹ̀ Kúrò Lọ́wọ́ Ìwà Ìkà Agbonimọ́lẹ̀ ti Àyànmọ́
  • Ṣé Àyànmọ́ Ni àbí Àkọsẹ̀bá Lásán?
    Jí!—1999
  • Àyànmọ́ Ha Ni Ó Ń darí Ìgbésí Ayé Rẹ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Jàm̀bá—Àyànmọ́ ni Tabi Ayika Ipo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • A Ha Pinnu Ọjọ-Ọla Rẹ Nipasẹ Àyànmọ́ Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/1 ojú ìwé 4-7

Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí?

ÌFÌWÉBANIJẸ́! ÌFỌ̀RỌ̀BANIJẸ́! Nígbà tí ẹnì kan tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi láwùjọ bá gbà gbọ́ pé a ti fi àkọsílẹ̀ èké bá orúkọ òun tàbí ìfùsì òun jẹ́, ó máa ń di dandan fún un láti mú ọ̀ràn tọ́. Ó tilẹ̀ lè pe àwọn tí wọ́n fìwé bà á jẹ́ náà lẹ́jọ́.

Tóò, ní ti gidi, ẹ̀kọ́ àyànmọ́ jẹ́ fífọ̀rọ̀ ba Ọlọ́run Olódùmarè jẹ́. Àbá èrò orí náà sọ pé, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni okùnfà gbogbo ọ̀ràn ìbànújẹ́ àti àgbákò tí ń pọ́n aráyé lójú. Bí o bá nígbàgbọ́ nínú àyànmọ́, o lè ronú pé Ọba Aláṣẹ Àgbáyé ti ní àkọsílẹ̀ kan, tí ó ní ohun tí ó jọ èyí nínú pé: ‘Lónìí, John yóò fara pa nínú jàm̀bá ọkọ̀, àrùn ibà yóò kọ lu Fatou, ìjì líle yóò ba ilé Mamadou jẹ́’! A ha lè sún ọ ní ti gidi láti ṣiṣẹ́ sin irú Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ bí?

Àwọn onígbàgbọ́ nínú àyànmọ́ béèrè pé: ‘Ṣùgbọ́n bí kì í bá ṣe Ọlọ́run ni okùnfà àwọn àgbákò wa, ta ni okùnfà rẹ̀ nígbà náà?’ Ousmane, fúnra rẹ̀, ọ̀dọ́mọkùnrin tí a mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ ìṣáájú, ṣe kàyéfì nípa èyí. Ṣùgbọ́n òun kò ní láti tànmọ́ọ̀n tàbí méfò kí ó tó mọ òtítọ́. Ó kẹ́kọ̀ọ́ pé nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí a rí nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí a mí sí, Bíbélì, Ọlọ́run ti wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìfọ̀rọ̀banijẹ́ yìí. (Tímótì Kejì 3:16) Nígbà náà, ẹ jẹ́ kí a gbé ohun tí Bíbélì sọ lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí yẹ̀ wò.

Ta Ló Lẹ̀bi?

Omíyalé, ìjì líle, ìmìtìtì ilẹ̀—a sábà máa ń pe irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ ní àmúwá Ọlọ́run. Síbẹ̀, Bíbélì kò fi hàn pé Ọlọ́run ni okùnfà irú àwọn jàm̀bá bẹ́ẹ̀. Ronú lórí ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan ti ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Bíbélì sọ fún wa pé ẹnì kan ṣoṣo tí ó la àjálù náà já ròyìn pé: “Iná ńlá Ọlọ́run [gbólóhùn èdè Hébérù tí ó sábà ń túmọ̀ sí mànàmáná] ti ọ̀run bọ́ sí ilẹ̀, ó sì jó àwọn àgùntàn àti àwọn ìránṣẹ́ ní àjórun.”—Jóòbù 1:16.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin tí jìnnìjìnnì bò yìí ti lè rò pé Ọlọ́run ni okùnfà iná náà, Bíbélì fi hàn pé Òun kọ́ ni ó lẹ̀bi rẹ̀. Ka Jóòbù 1:7-12 fúnra rẹ, ìwọ yóò sì rí i pé, kì í ṣe Ọlọ́run, bí kò ṣe Elénìní rẹ̀—Sátánì Èṣù ni okùnfà mànàmáná náà! Kì í ṣe pé Sátánì ni okùnfà gbogbo àgbákò ní tààràtà. Ṣùgbọ́n, ó ṣe kedere pé, kò sí ìdí kankan láti dá Ọlọ́run lẹ́bi.

Ní tòótọ́, lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ènìyàn ni ó yẹ kí a máa dá lẹ́bi nígbà tí nǹkan bá ṣẹlẹ̀. Ìfìdírẹmi ní ilé ẹ̀kọ́, àìṣàṣeyọrí ní ibi iṣẹ́, tàbí nínú àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà lè jẹ́ ìyọrísí àìsapá àti àìgba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí ó jíire tàbí kí ó jẹ́ nítorí àìgba tẹlòmíràn rò. Bákan náà, àìsàn, jàm̀bá, àti ikú lè jẹ́ ìyọrísí àìbìkítà. Họ́wù, lílo bẹ́líìtì ọkọ̀ lásán nígbà tí a bá ń wakọ̀ ń dín ṣíṣeéṣe kí ẹnì kan kú nínú jàm̀bá ọkọ̀ kù lọ́nà gíga. Ká ní “àyànmọ́” tí kò gbóògùn ni ó ń darí ọ̀ràn ni, bẹ́líìtì ọkọ̀ kì bá lè mú ìyàtọ̀ kankan wá. Ìtọ́jú ìṣègùn tí ó yẹ àti ìmọ́tótó tún ń dín iye àwọn tí ń kú ní rèwerèwe kù lọ́nà gíga lọ́lá. Kódà àwọn jàm̀bá kan tí a sábà ń pè ní “àmúwá Ọlọ́run” ní tòótọ́, jẹ́ àmúwá ènìyàn—ogún ìbànújẹ́ láti inú àṣìlò ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ ènìyàn.—Fi wé Ìṣípayá 11:18.

“Ìgbà àti Èèṣì”

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani nínú jẹ́ ní ń ṣẹlẹ̀ tí a kò mọ okùnfà wọn. Ṣùgbọ́n, ṣàkíyèsí ohun tí Bíbélì sọ nínú Oníwàásù 9:11 pé: “Mo padà, mo sì ri lábẹ́ oòrùn, pé iré ìje kì í ṣe ti ẹni tí ó yára, bẹ́ẹ̀ ni ogun kì í ṣe ti alágbára, bẹ́ẹ̀ ni oúnjẹ kì í ṣe ti ọlọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni ọrọ̀ kì í ṣe ti ẹni òye, bẹ́ẹ̀ ni ojú rere kì í ṣe ti ọlọ́gbọ́n inú; ṣùgbọ́n ìgbà àti [èèṣì, NW] ń ṣe sí gbogbo wọn.” Kò sí ìdí kankan láti gbà gbọ́ nígbà náà pé, Ẹlẹ́dàá ni ó wà lẹ́yìn àwọn jàm̀bá tàbí ni ó ń ṣokùnfà pé kí àwọn tí jàm̀bá ṣẹlẹ̀ sí jìyà lọ́nà kan ṣáá.

Jésù Kristi fúnra rẹ̀ jiyàn lòdì sí ìrònú tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àyànmọ́. Ní títọ́ka sí ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan tí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ mọ́ bí ẹni mowó, Jésù béèrè pé: “Àwọn méjìdínlógún wọnnì tí ilé gogoro tí ń bẹ ní Sílóámù wó lé lórí, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ pa wọ́n, ṣé ẹ̀yin lérò pé a fi wọ́n hàn ní ajigbèsè ju gbogbo àwọn ènìyàn míràn tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù lọ ni? Rárá o, ni mo sọ fún yín.” (Lúùkù 13:4, 5) Jésù fi hàn gbangba pé “ìgbà àti èèṣì” ni ó fa jàm̀bá náà, kì í ṣe Ọlọ́run ni ó lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

Àbájáde Búburú Tí Àìpé Ní

Ṣùgbọ́n, ti ikú àti àìsàn tí a kò mọ̀dí rẹ̀ ńkọ́? Bíbélì sọjú abẹ níkòó lọ́nà tí ó gbà ṣàpèjúwe ipò ẹ̀dá ènìyàn pé: “Gbogbo ènìyàn . . . ń kú nínú Ádámù.” (Kọ́ríńtì Kìíní 15:22) Ikú ti pọ́n aráyé lójú láti ìgbà tí babańlá wa, Ádámù, ti tọ ọ̀nà àìgbọràn. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti kìlọ̀, Ádámù fi ogún ikú sílẹ̀ fún àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:17; Róòmù 5:12) Nítorí náà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a lè tọpasẹ̀ gbogbo àìsàn lọ sọ́dọ̀ babańlá gbogbo wa, Ádámù. Àìlera wa tí a jogún tún ní ohun púpọ̀ ṣe pẹ̀lú ìjákulẹ̀ àti ìkùnà tí a ń nírìírí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé.—Orin Dáfídì 51:5.

Gbé ìṣòro òṣì yẹ̀ wò. Ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ ti fìgbà gbogbo fún àwọn òjìyà níṣìírí láti fara mọ́ ipò ìṣòro wọn. Wọ́n gbà gbọ́ pé: ‘Kádàrá wa ni.’ Ṣùgbọ́n, Bíbélì fi hàn pé, àìpé ẹ̀dá ènìyàn ni ó yẹ kí a dá lẹ́bi, kì í ṣe àyànmọ́. Àwọn kan ń di òtòṣì nígbà tí ‘wọ́n bá ń ká ohun tí wọ́n gbìn’ nípa ṣíṣe ọ̀lẹ tàbí lílo owó nílò àpà. (Gálátíà 6:7; Òwe 6:10, 11) Ọ̀kẹ́ àìmọye ń gbé nínú ipò òṣì nítorí pé àwọn oníwọra tí ń ṣàkóso ń fìyà jẹ wọ́n. (Fi wé Jákọ́bù 2:6.) Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Kò sí ẹ̀rí kankan fún dídi ẹ̀bi gbogbo ipò òṣì ru Ọlọ́run tàbí àyànmọ́.

Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ —Agbára Tí Ń Pani Lára Tí Ó Ní

Iyàn míràn tí ó ṣì ń yíni lérò padà láti lòdì sí àyànmọ́ ní agbára tí àyànmọ́ lè ní lórí àwọn tí ó gbà á gbọ́. Jésù Kristi wí pé: “Gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò níláárí jáde.” (Mátíù 7:17) Ẹ jẹ́ kí a gbé ọ̀kan nínú “èso” ẹ̀kọ́ àyànmọ́ yẹ̀ wò—ọ̀nà tí ó gbà ń ní agbára ìdarí lórí òye àwọn ènìyàn nípa ẹrù iṣẹ́.

Òye yíyè kooro nípa ẹrù iṣẹ́ ẹni ṣe pàtàkì. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun tí ń sún àwọn òbí láti pèsè fún ìdílé wọn, àwọn òṣìṣẹ́ láti fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ wọn, àwọn olùpèsè-ọjà, láti pèsè àwọn ojúlówó ọjà. Ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ lè pa òye yẹn kú. Fún àpẹẹrẹ, finú wòye pé ọ̀pá ìdarí ọkọ̀ ọkùnrin kan yọnu. Bí ó bá ní òye mímúná nípa ẹrù iṣẹ́, yóò tún un ṣe nítorí bí ìwàláàyè tirẹ̀ fúnra rẹ̀ àti ti àwọn èrò rẹ̀ ti ká a lára tó. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹnì kan tí ó gbà gbọ́ nínú àyànmọ́ lè ṣàìka ewu náà sí, ní ríronú pé ọkọ̀ náà lè kọṣẹ́, kìkì bí ó bá ‘wu Ọlọ́run’!

Bẹ́ẹ̀ ni, ó rọrùn fún ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ láti gbe ẹ̀mí àìka-nǹkan-sí, ìwà ọ̀lẹ, ìkùnà láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bi fún ìgbésẹ̀ ẹni, àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ìwà òdì míràn lárugẹ.

Ó Ha Jẹ́ Ìdènà fún Ipò Ìbátan Wa Pẹ̀lú Ọlọ́run Bí?

Èyí tí ó ṣèpalára jù lọ ni pé, ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ lè dín òye ẹrù iṣẹ́ ẹni, tàbí ojúṣe ẹni, sí Ọlọ́run kù. (Oníwàásù 12:13) Onísáàmù náà ń rọ gbogbo aráyé láti ‘tọ́ ọ wò, kí wọ́n sì ri pé rere ni Olúwa.’ (Orin Dáfídì 34:8) Ọlọ́run gbé àwọn ohun àbéèrèfún kan kalẹ̀ fún àwọn tí yóò gbádùn ìwà rere rẹ̀.—Orin Dáfídì 15:1-5.

Ọ̀kan nínú irú ohun àbéèrèfún bẹ́ẹ̀ ni ìrònúpìwàdà. (Ìṣe 3:19; 17:30) Ìyẹn ní títẹ́wọ́ gba àṣìṣe wa àti ṣíṣe ìyípadà tí ó yẹ nínú. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, gbogbo wa ni a ní àṣìṣe púpọ̀ tí ó yẹ kí a ronú pìwà dà lé lórí. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan bá gbà gbọ́ pé òún jẹ́ ẹni tí àyànmọ́ ń fìyà jẹ láìlólùgbèjà, yóò ṣòro fún un láti ronú pé ó yẹ kí òún ronú pìwà dà tàbí kí ó gbà pé òún ṣe àṣìṣe.

Onísáàmù náà sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ìṣeun ìfẹ́ rẹ sàn ju ìyè lọ.” (Orin Dáfídì 63:3) Síbẹ̀, ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ ti mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ni ó ń pọ́n àwọn lójú. Lọ́nà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu, èyí ti mú kí àwọn kan kanra mọ́ ọn, ní kíkọ̀ láti ní ipò ìbátan tímọ́tímọ́ tòótọ́ pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wọn. Ó ṣe tán, báwo ni o ṣe lè nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan tí o kà sí ẹni tí ń ṣokùnfà gbogbo ìṣòro àti àdánwò rẹ? Ẹ̀kọ́ àyànmọ́ tipa bẹ́ẹ̀ gbé ìdènà kan dìde sáàárín Ọlọ́run àti ènìyàn.

A Dá A Sílẹ̀ Kúrò Lọ́wọ́ Ìwà Ìkà Agbonimọ́lẹ̀ ti Àyànmọ́

Ousmane ọ̀dọ́, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, wà ní oko ẹrú ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ tẹ́lẹ̀ rí. Ṣùgbọ́n, nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti fi ìmọ́lẹ̀ Bíbélì yẹ ìrònú rẹ̀ wò, a sún Ousmane láti pa ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú àyànmọ́ tì. Ìyọrísí rẹ̀ ni ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ ti ìtura àti ojú ìwòye tuntun, tí ń fojú sọ́nà fún ohun rere nínú ìgbésí ayé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ti wá mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ‘láàánú, tí ó ní oore ọ̀fẹ́, tí ó ní ìpamọ́ra, tí ó sì pọ̀ ní oore àti òtítọ́.’—Ẹ́kísódù 34:6.

Ousmane ti wa mọ̀ pé Ọlọ́run ní ète kan fún ọjọ́ ọ̀la, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kì í wéwèé gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ìgbésí ayé wa.a Pétérù Kejì 3:13 sọ pé: “Àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun kan wà tí àwa ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú àwọn wọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́wọ́ láti ní ìrètí wíwà láàyè títí láé gẹ́gẹ́ bí apá kan “ilẹ̀ ayé tuntun” tí a ṣèlérí yìí. Wọn yóò fẹ́ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú.

Bí o ṣe ń dàgbà nínú ìmọ̀ pípéye Bíbélì, ìwọ yóò wá lóye pé ọjọ́ ọ̀la rẹ kò sinmi lórí àwọn àyànmọ́ kan tí a ti pinnu tẹ́lẹ̀, tí o kò lè darí. Àwọn ọ̀rọ̀ Mósè sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì ṣeé fi sílò dáradára pé: “Èmi fi ìyè àti ikú, ìbùkún àti ègún síwájú rẹ: nítorí náà yan ìyè, kí ìwọ kí ó lè yè, ìwọ àti irú ọmọ rẹ: Kí ìwọ kí ó lè máa fẹ́ OLÚWA Ọlọ́run rẹ, àti kí ìwọ kí ó lè máa gba ohun rẹ̀ gbọ́, àti kí ìwọ kí ó lè máa fara mọ́ ọn.” (Diutarónómì 30:19, 20) Bẹ́ẹ̀ ni, o ní ohun tí o lè ṣe nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ. Kò sí i lọ́wọ́ àyànmọ́.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìjíròrò kíkúnná nípa ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, wo Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1985, ojú ìwé 3 sí 7.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

Àwọn jàm̀bá wọ̀nyí kì í ṣe ‘àmúwá Ọlọ́run’

[Àwọn Credit Line]

Fọ́tò U.S. Coast Guard

WHO

UN PHOTO 186208 /M. Grafman

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́