ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g99 8/8 ojú ìwé 3
  • Ṣé Àyànmọ́ Ni àbí Àkọsẹ̀bá Lásán?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Àyànmọ́ Ni àbí Àkọsẹ̀bá Lásán?
  • Jí!—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwá Àlàyé Kiri
  • Títúmọ̀ Àyànmọ́
  • Ohun Tí Ń Pinnu
  • Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Wíwádìí Kádàrá Ẹ̀dá
    Jí!—1999
  • Jàm̀bá—Àyànmọ́ ni Tabi Ayika Ipo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ohun Gbogbo Làkókò Wà Fún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
Àwọn Míì
Jí!—1999
g99 8/8 ojú ìwé 3

Ṣé Àyànmọ́ Ni àbí Àkọsẹ̀bá Lásán?

ÌWÉ ìròyìn International Herald Tribune polongo pé: “Àyànmọ́ gba ẹ̀mí àwọn kan, ó sì dá tàwọn mìíràn sí.” Ní èṣí, àwọn apániláyà tó kọ lu àwọn iléeṣẹ́ táa ti ń gbàwé àṣẹ àtiwọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà, èyí tó wà ní Kẹ́ńyà àti Tanzania, pa nǹkan bí igba èèyàn, ọgọ́rọ̀ọ̀rún sì fara pa. Ṣùgbọ́n ìwé ìròyìn náà sọ pé “àkókò tí wàhálà ọ̀hún ṣẹlẹ̀ ló kó àwọn lọ́gàálọ́gàá iléeṣẹ́ náà yọ.”

Wọ́n mórí bọ́ nítorí pé wọ́n wà nínú ìpàdé kan lágbègbè ilé náà tó jìnnà síbi tí bọ́ǹbù náà ti bú gbàmù. Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà, tó yẹ kó wà níbi ìpàdé náà ṣùgbọ́n tí kò lọ, wà lágbègbè tó sún mọ́ ibi tí bọ́ǹbù náà ti bú, bọ́ǹbù náà sì pa á.

Ìwé ìròyìn náà sọ pé: “Àyànmọ́ tún ṣọwọ́ òdì sí Arlene Kirk.” Nígbà tí Arlene ń padà sí Kẹ́ńyà lẹ́yìn ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, ó yọ̀ǹda àyè rẹ̀ nínú ọkọ̀ òfuurufú fẹ́lòmíràn, nítorí pé èrò léélẹ̀. Àmọ́, àwọn èrò mí-ìn tó fẹ́ bá ọkọ̀ òfuurufú náà lọ tẹ́lẹ̀ ti ṣáájú rẹ̀ yọ̀ǹda àyè tiwọn, èyí wá jẹ́ kí àyè wà fún un. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ó padà sẹ́nu iṣẹ́ lọ́jọ́ tí bọ́ǹbù náà bú, bó ṣe kú nìyẹn o.

Àjálù kì í ṣe nǹkan tuntun fáráyé. Ṣùgbọ́n, àlàyé rẹ̀ ṣòroó ṣe. Kárí ayé, léraléra ló máa ń jẹ́ pé nígbà tí jàǹbá àti nǹkan burúkú bá ṣẹlẹ̀, àwọn kan á kú, àwọn mìíràn á là á já. Àmọ́ o, kì í ṣe ìgbà àjálù nìkan làwọn kan máa ń sọ pé, ‘Ó ṣe jẹ́ èmi nirú èyí ṣẹlẹ̀ sí?’ Kódà, bó jẹ́ ọ̀ràn kí nǹkan ṣẹnuure yìí náà ni, ó jọ pé àwọn kan máa ń rìnnà kore ju àwọn mí-ìn lọ. Nígbà tó ṣe pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi gbogbo ọjọ́ ayé wọn sáré kòókòó jàn-án jàn-án kiri, ó jọ pé wẹ́rẹ́ ni nǹkan kàn máa ń bọ́ sí i fún àwọn mìíràn. Àbí bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nìyẹn ni? Èyí lè wá sún ẹ béèrè pé, ‘Ó ha lè jẹ́ pé gbogbo rẹ̀ ló wà lákọọ́lẹ̀ bí? Ṣé àyànmọ́ ló ń darí ayé mi ni?’

Wíwá Àlàyé Kiri

Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn, ọlọgbọ́n ọba kan rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó ṣe é ní kàyéfì. Ọ̀rọ̀ tó sọ rèé nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Nígbà mí-ìn, ohun tí a ò retí ló máa ń ṣẹlẹ̀. Kò sì sí béèyàn ṣe lè rí i tẹ́lẹ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé, ì báà jẹ́ rere ì báà jẹ́ búburú, sábà máa ń jẹ́ ọ̀ràn àkókò tó bọ́ sí.

Ṣùgbọ́n o lè ní ojú ìwòye táwọn kan ní pé, dípò kó jẹ́ pé àkọsẹ̀bá làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, lójú tiwọn kò lè jẹ́ ojú lásán—àyànmọ́ ni. Ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ tàbí kádàrá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbàgbọ́ tí ẹ̀dá ní, tó pẹ́ jù lọ, tó sì gbilẹ̀ jù lọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n François Jouan, gíwá Iléeṣẹ́ Ìwádìí Ìtàn Ìwáṣẹ̀ ní Yunifásítì Paris, sọ pé: “Kò sí sáà tàbí sànmánì táwọn èèyàn ò nígbàgbọ́ nínú ọlọ́run àyànmọ́ . . . láti lè ṣàlàyé gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò ṣeé ṣàlàyé nínú ìgbésí ayé wa.” Ìdí nìyẹn táa fi ń gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ pé: “Ó fọjọ́ ọlọ́jọ́ lọ ni” tàbí, “Bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.” Ṣùgbọ́n kí ni àyànmọ́?

Títúmọ̀ Àyànmọ́

Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà “fate” [àyànmọ́], wá láti inú èdè Látìn náà fatum, tó túmọ̀ sí “ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀, ọ̀rọ̀ awo, ìpinnu àtọ̀runwá.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà mí-ìn, a máa ń rò pé agbára àtọ̀húnrìnwá kan ló ń pinnu ọjọ́ iwájú lọ́nà kan tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, tí kò sì ṣeé ṣàlàyé, ọlọ́run kan làwọn èèyàn máa ń pe agbára yìí.

Òpìtàn nípa ẹ̀sìn, Helmer Ringgren ṣàlàyé pé: “Kókó pàtàkì kan tó jẹ mọ́ ojú ìwòye ẹ̀sìn ni ìmọ̀lára náà pé àyànmọ́ ẹ̀dá bọ́gbọ́n mu, pé kì í sì í ṣọ̀ràn àkọsẹ̀bá, ṣùgbọ́n pé agbára kan tó ní ète àti góńgó ló ń pinnu rẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ìyípadà díẹ̀-dìẹ̀-díẹ̀ lè dé sí kádàrá, síbẹ̀ wọ́n rí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí a kàn ń tì kiri, tó ti tàn sóko òǹdè. Bí wọ́n ṣe ‘há sọ́wọ́ àyànmọ́ tiwọn’ nìyẹn.

Tipẹ́tipẹ́ làwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn àti àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ti ń ṣe atótónu lórí ìtumọ̀ àyànmọ́. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopedia of Religion sọ pé: “Bó ti wù kí ohun táwọn èèyàn ń pè láyànmọ́ yàtọ̀ síra tó, tàbí kí òye wọn nípa rẹ̀ yàtọ̀ síra tó, àdììtú ṣì ni títí di báa ti ń wí yìí.” Ṣùgbọ́n o, ojú ìwòye kan wà tó fara hàn nínú gbogbo ọ̀kan-ò-jọ̀kan èròǹgbà wọ̀nyí, ojú ìwòye ọ̀hún ni pé agbára kan tó ga ju ẹ̀dá ló ń darí ìgbòkègbodò ẹ̀dá. Wọ́n ní agbára yìí ló ń pinnu ìgbésí ayé olúkúlùkù ènìyàn àti tàwọn orílẹ̀-èdè kí wọ́n tó délé ayé, wọ́n ní ọjọ́ iwájú wọn kò ṣeé yí padà, àfi bí ẹni pé ó ti ṣẹlẹ̀ kọjá ni.

Ohun Tí Ń Pinnu

Ǹjẹ́ ìyàtọ̀ kankan wà nínú bóyá o nígbàgbọ́ nínú àyànmọ́ tàbí oò ní? Onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Bertrand Russell, kọ̀wé pé: “Ipò tó yí ìgbésí ayé ẹ̀dá ká máa ń ṣe púpọ̀ nínú pípinnu ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lápapọ̀, táa bá tún gba ibòmíràn wò ó, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ tún máa ń ṣe púpọ̀ láti pinnu ipò tó yí wọn ká.”

Ká sòótọ́, ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́—ìyẹn báyànmọ́ bá wà lóòótọ́—lè pinnu ìṣesí wa. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbà pé ìfẹ́ àwọn ọlọ́run ni, ní ipòkípò tí wọ́n bá wà, ṣe ni wọ́n á gba kámú—láìka bí ipò ọ̀hún ti burú tó, tó sì nira tó—wọ́n á ní àyànmọ́ tàwọn nìyẹn, àyànmọ́ ò sì gbóògùn. Nípa báyìí, ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ ta ko èrò jíjèrè iṣẹ́ ọwọ́ ẹni.

Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, ìgbàgbọ́ nínú kádàrá ti sún àwọn kan ṣe ohun tó jẹ́ òdìkejì èyí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn òpìtàn ti tọsẹ̀ àwọn kókó pàtàkì kan tó fa ìdàgbàsókè ìṣòwò bòńbàtà àti ìyípadà tó dé bá ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ. Lára àwọn kókó ọ̀hún ni ìgbàgbọ́ nínú àkọọ́lẹ̀. Àwọn ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì kan fi kọ́ni pé Ọlọ́run ti yan àwọn kan tẹ́lẹ̀ fún ìgbàlà. Ará Jámánì náà, Max Weber, onímọ̀ àjọṣepọ̀ ẹ̀dá, sọ pé: “Ìbéèrè náà, Ǹjẹ́ mo wà lára àwọn àyànfẹ́? yóò ti dìde lọ́kàn olúkúlùkù onígbàgbọ́, bó pẹ́ bó yá.” Kálukú ń wá ọ̀nà láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run ti bù kún òun, tó sì ti tipa bẹ́ẹ̀ kọ kádàrá òun sílẹ̀ pé òun yóò rí ìgbàlà. Ọ̀gbẹ́ni Weber sọ pé wọ́n ń fi “iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́” wọn díwọ̀n èyí. Wọ́n kà á sí pé ojú rere Ọlọ́run ló mú kí iṣẹ́ òwò wọn kẹ́sẹ járí, kí wọ́n sì rí towó ṣe.

Ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ ń sún àwọn kan láti ṣàṣerégèé. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn awakọ̀ òfuurufú ọmọ ogun Japan tó pa ara wọn mọ́ ọ̀tá, nígbàgbọ́ nínú ìjì kamikaze, tàbí “ẹ̀fúùfù látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Èròǹgbà náà pé àwọn ọlọ́run ní ète kan àti pé ó ṣeé ṣe láti lọ́wọ́ nínú ète yẹn, mú ọ̀ràn ẹ̀sìn wọ ikú oró tí wọ́n kú. Ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé, òkìkí àwọn oníbọ́ǹbù apara-ẹni-mọ́-ọ̀tá àti ìpakúpa tí wọ́n pa àwọn èèyàn kàn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé ẹ̀kọ́ àyànmọ́ kó ipa pàtàkì nínú àwọn “rògbòdìyàn tí àwọn apara-ẹni-mọ́-ọ̀tá nítorí ọ̀ràn ẹ̀sìn dá sílẹ̀.”

Ṣùgbọ́n èé ṣe tí ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ fi gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Wíwo ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ fìrí yóò dáhùn ìbéèrè yẹn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́