Wíwádìí Kádàrá Ẹ̀dá
ÈÉ ṢE tí ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ fi gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀? Jálẹ̀ gbogbo sànmánì ni èèyàn ti ń fẹ́ rídìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, kí wọ́n sì mọ ìdí abájọ. Òpìtàn, Helmer Ringgren ṣàlàyé pé: “Ìhín yìí ni ọ̀ràn ‘ọlọ́run’, ‘kádàrá’, àti ‘àkọsẹ̀bá’ ti yọjú, ó sì sinmi lórí okùnfà àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bóyá nípasẹ̀ agbára ẹ̀dá kan ni, tàbí nípasẹ̀ ìṣètò tó kọjá agbára ẹ̀dá, tàbí ìṣètò tí kò tilẹ̀ sí rárá.” Ìtàn kún fún ìgbàgbọ́, ìtàn àtẹnudẹ́nu, àti ìtàn àròsọ tó jẹ mọ́ àyànmọ́ àti kádàrá.
Jean Bottéro, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa ìtàn Ásíríà àti Bábílónì ìgbàanì sọ pé: “Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Mesopotámíà ló kó apá tó pọ̀ jù lọ nínú gbogbo àṣà ìbílẹ̀ wa,” ó wá fi kún un pé Mesopotámíà tàbí Babilóníà ìgbàanì la ti rí “àwọn ìṣarasíhùwà àti èròǹgbà tó pẹ́ jù lọ tí aráyé ní nípa àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, èyí sì ni ètò ẹ̀sìn tó tíì pẹ́ jù lọ tí a mọ̀.” Ìhín sì ni àyànmọ́ ti pilẹ̀.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ẹ̀kọ́ Àyànmọ́
Àárín àwókù Mesopotámíà ìgbàanì, tó wà ní Iraq báyìí, ni àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí àwọn ọ̀nà ìkọ̀wé tó pẹ́ jù lọ nínú ìtàn ènìyàn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún wàláà táa kọ lọ́nà ìkọ̀wé cuneiform ṣàlàyé kínníkínní fún wa nípa ìgbé-ayé ní sànmánì àwọn Sumer àti Akkad àti ní Bábílónì, ìlú olókìkí. Gẹ́gẹ́ bí awalẹ̀pìtàn nì, Samuel N. Kramer ti wí, àwọn ará Sumer “dààmú gidigidi nípa ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá ènìyàn, pàápàá jù lọ nítorí àìmọ ohun tó ń fà á.” Wíwá tí wọ́n ń wá ojútùú rẹ̀ kiri ló sún wọn dédìí ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́.
Nínú ìwé rẹ̀ Babylon, awalẹ̀pìtàn náà Joan Oates sọ pé, “olúkúlùkù ará Bábílónì ló ní ọlọ́run àti abo ọlọ́run tirẹ̀.” Àwọn ará Bábílónì gbà gbọ́ pé àwọn ọlọ́run “ló ń yan kádàrá ẹ̀dá, ti ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ti gbogbo gbòò.” Gẹ́gẹ́ bí Kramer ti wí, àwọn ará Sumer gbà gbọ́ pé “àwọn ọlọ́run tí ń darí ayé ló pète, tí wọ́n sì dá ìwà ibi, èké ṣíṣe àti ìwà ipá sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ara ọ̀làjú.” Ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ gbilẹ̀ láàárín wọn, wọ́n sì gbé e gẹ̀gẹ̀.
Àwọn ará Bábílónì rò pé ó ṣeé ṣe láti ṣàwárí ìwéwèé àwọn ọlọ́run nípa wíwoṣẹ́—èyí tí wọ́n kà sí “ọ̀nà àtibá àwọn ọlọ́run sọ̀rọ̀.” Wíwoṣẹ́ wé mọ́ gbígbìyànjú láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la nípa wíwo àwọn nǹkan àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, mímòye wọn, àti títúmọ̀ wọn. Àwọn ohun tí wọ́n máa ń gbé yẹ̀ wò ni àlá, ìṣesí ẹranko, àti ìfun tàbí ẹ̀dọ̀ ẹranko. (Fi wé Ìsíkíẹ́lì 21:21; Dáníẹ́lì 2:1-4.) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kàyéfì tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀, tí wọ́n sọ pé ó ń fi ọjọ́ ọ̀la hàn, ni wọ́n máa ń kọ sára wàláà amọ̀.
Édouard Dhorme ọmọ ilẹ̀ Faransé, tí í ṣe ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nípa àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ìgbàanì, sọ pé, “bí a ti túbọ̀ ń tọsẹ̀ ìtàn Mesopotámíà ni a ń rí i pé àwọn oníṣẹ́ àfọ̀ṣẹ àti ọ̀ràn lílọ woṣẹ́ gbilẹ̀ níbẹ̀.” Wíwoṣẹ́ jẹ́ apá pàtàkì nínú ìgbésí ayé wọn. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bottéro tilẹ̀ sọ pé, “kò sí nǹkan tí wọn ò lè gbé kalẹ̀ fún àyẹ̀wò, kí wọ́n sì fi woṣẹ́ . . . Wọ́n ka ohun gbogbo tó wà lágbàáyé sóhun tó lè sọ nǹkan kan fún wọn nípa ọjọ́ ọ̀la, bí wọ́n bá yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Mesopotámíà gbówọ́ nídìí lílo ìwòràwọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà àtimọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la.—Fi wé Aísáyà 47:13.
Ní àfikún sí i, àwọn ará Bábílónì ń fi ọmọ ayò tàbí kèké woṣẹ́. Deborah Bennett ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀ Randomness pé èyí jẹ́ láti “yọwọ́ ọmọ aráyé kúrò nínú ọ̀ràn náà, kí ọ̀nà lè là peregede fáwọn ọlọ́run láti sọ ìfẹ́ inú wọn.” Ṣùgbọ́n o, wọ́n gbà pé ìpinnu àwọn ọlọ́run ṣeé yí padà. Àgbákò ṣeé yẹra fún, bí wọ́n bá tu àwọn ọlọ́run lójú.
Àyànmọ́ ní Íjíbítì Ìgbàanì
Ní ọ̀rúndún kẹẹ̀ẹ́dógún ṣááju Sànmánì Tiwa, ọwọ́ Babilóníà àti Íjíbítì wọ ọwọ́ gan-an. Àwọn ìgbàgbọ́ tó wé mọ́ àyànmọ́ wà lára àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí wọ́n ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ̀. Èé ṣe táwọn ará Íjíbítì fi tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́? John R. Baines, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn Íjíbítì ní Yunifásítì Oxford, sọ pé, “ọ̀pọ̀ nǹkan nínú ẹ̀sìn [àwọn ará Íjíbítì] dá lé ìsapá láti lóye àwọn àgbákò tó ṣàdédé ṣẹlẹ̀, kí wọ́n sì wá nǹkan ṣe sí i.”
Lára ọ̀pọ̀ ọlọ́run Íjíbítì, Isis ni wọ́n pè ní “ìyálóde ìwàláàyè, alákòóso àyànmọ́ àti kádàrá.” Àwọn ará Íjíbítì pẹ̀lú lọ́wọ́ nínú wíwoṣẹ́ àti wíwòràwọ̀. (Fi wé Aísáyà 19:3.) Òpìtàn kan sọ pé: “Wọ́n mọ gbogbo àpadé-àludé tó wà nínú wíwádìí ọ̀ràn lọ́wọ́ àwọn ọlọ́run.” Àmọ́ ṣá o, àwọn ará Íjíbítì nìkan kọ́ ló tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ Bábílónì nípa àyànmọ́.
Ilẹ̀ Gíríìsì àti Róòmù
Jean Bottéro sọ pé, tó bá dọ̀ràn ẹ̀sìn, “ilẹ̀ Gíríìsì ìgbàanì kò bọ́ lọ́wọ́ agbára Bábílónì tó rìn jìnnà tó sì rinlẹ̀.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Peter Green ṣàlàyé ìdí tí ìgbàgbọ́ nínú kádàrá fi gbajúmọ̀ gan-an ní ilẹ̀ Gíríìsì, ó ní: “Nínú ayé àìdánilójú, níbi táwọn èèyàn ti túbọ̀ ń yẹrí fún jíjíhìn fún iṣẹ́ ọwọ́ wọn, tí wọ́n sì gbà pé àwọn ò kúkú yàtọ̀ sí ère bọrọgidi, táwọn òfin Àyànmọ́ àwámáridìí, tí kò gbóògùn, ń tì gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kiri, àyànmọ́ yìí táwọn ọlọ́run ti yàn tẹ́lẹ̀ láìdúrógbẹ́jọ́, ni wọ́n sọ pé ó ti pinnu ọjọ́ ọ̀la kalẹ̀. Ohun tí Àyànmọ́ ti pinnu ṣeé mọ̀, téèyàn bá gbówọ́. Ó lè máà jẹ́ ohun téèyàn ń retí àtigbọ́ o; àmọ́ tóo bá ti gbọ́ ọ, ogun àgbọ́tẹ́lẹ̀ ni, tí kì í parọ tó bá gbọ́n.”
Yàtọ̀ sí pé àyànmọ́ ń fọkàn àwọn èèyàn balẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la wọn, ó tún ń ṣe àwọn iṣẹ́ burúkú mí-ìn. Ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ mú kí wọ́n tẹ àwọn gbáàtúù lórí ba, gẹ́gẹ́ bí òpìtàn F. H. Sandbach sì ti wí, ìyẹn ló fà á “tí ìgbàgbọ́ pé Olú Ọ̀run nìkan ló ń ṣàkóso ayé yóò fi dùn mọ́ ẹgbẹ́ àwọn aláṣẹ tí ń ṣàkóso nínú.”
Èé ṣe? Ọ̀jọ̀gbọ́n Green ṣàlàyé pé ìgbàgbọ́ yìí jẹ́ “ìdáláre tó fẹsẹ̀ rinlẹ̀—ní ti ọ̀nà ìwà híhù, ní ti ẹ̀kọ́ ìsìn, ní ti ìtumọ̀ ọ̀rọ̀—fún ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà àti ìṣèlú tó lòde: ìgbàgbọ́ yìí táwọn aláṣẹ Hélénì hùmọ̀ ni ọgbọ́n tó ga jù lọ, tó sì jáfáfá jù lọ láti fi jókòó pa sórí àlééfà. Èyí wá já sí pé kò sóhun tó lè ṣẹlẹ̀ láìní ọwọ́ kádàrá nínú; níwọ̀n bí ọba adẹ́dàá sì ti yọ́nú sí ẹ̀dá, kò sí ni, ire ni kádàrá tó wà lákọọ́lẹ̀ yóò já sí.” Àní, ó tilẹ̀ “dá ìwà anìkànjọpọ́n láre.”
Àwọn ìwé lítíréṣọ̀ Gíríìkì mú un ṣe kedere pé tẹrútọmọ ló gbà pé àyànmọ́ wà. Ara àwọn ọ̀nà tí wọ́n pín lítíréṣọ̀ ìgbàanì sí ni ìtàn akọni, ìtàn àtẹnudẹ́nu, àti eré àjálù—èyí tí àyànmọ́ kópa pàtàkì nínú rẹ̀. Nínú ìtàn àròsọ Gíríìkì, abo ọlọ́run mẹ́ta táa ń pè ní Moirai, ló dúró fún kádàrá ẹ̀dá. Clotho ló ń rànwú ìwàláàyè, Lachesis ló ń pinnu gígùn ìwàláàyè, Atropos ló sì máa ń gé okùn ìwàláàyè nígbà tí ọjọ́ tí a kọọ́lẹ̀ fún ẹnì kan bá pé. Àwọn ará Róòmù ní irú ọlọ́run mẹ́talọ́kan bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Parcae.
Àwọn ará Róòmù àti Gíríìkì máa ń hára gàgà láti mọ kádàrá wọn. Fún ìdí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lo ọ̀nà ìwòràwọ̀ àti iṣẹ́ wíwò ti Bábílónì, wọ́n sì mú un bóde mu. Ohun táwọn ará Róòmù ń pe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ń lò láti fi mọ ọjọ́ ọ̀la ní portenta, tàbí àmì. Ohun tí wọ́n ń pe iṣẹ́ tí àmì wọ̀nyí ń jẹ́ ni omina. Nígbà tó di ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, ìwòràwọ̀ ti gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ Gíríìsì, ọdún 62 ṣááju Sànmánì Tiwa la gbọ́ pé àwọn Gíríìkì kọ́kọ́ gbé àwòrán ìwòràwọ̀ jáde. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Gilbert Murray ti wí, àwọn Gíríìkì fẹ́ràn ìwòràwọ̀ púpọ̀, wọ́n fẹ́ràn rẹ̀ débi pé ìwòràwọ̀ “kó wọnú àwọn Hélénì bí àrùn tuntun tí ń jà ràn-ìn láàárín àwọn èèyàn erékùṣù àdádó.”
Nínú ìsapá wọn láti mọ ọjọ́ ọ̀la, àwọn Gíríìkì àti àwọn ará Róòmù ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ adáhunṣe àti abẹ́mìílò. Wọ́n ní àwọn wọ̀nyí làwọn ọlọ́run ń fiṣẹ́ rán séèyàn. (Fi wé Ìṣe 16:16-19.) Kí ni ipa tí ìgbàgbọ́ wọ̀nyí ní? Onímọ̀ ọgbọ́n orí nì, Bertrand Russell, sọ pé: “Ìbẹ̀rù rọ́pò ìrètí; ète ìgbésí ayé kò sì ju sísá fún àgbákò, dípò kéèyàn ṣe nǹkan rere láyé ẹ̀.” Irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí di kókó ìjiyàn lé lórí nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù pẹ̀lú.
“Àwọn Kristẹni” Ń Jiyàn Nípa Àyànmọ́
Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ń gbé láwùjọ tí èròǹgbà Gíríìkì àti Róòmù nípa kádàrá àti àyànmọ́ ti kó sí lórí. Fún àpẹẹrẹ, ìwé àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì bí Aristotle àti Plato, làwọn Baba Ìsàlẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì fi ṣe ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ wọn. Ìṣòro kan tí wọ́n gbìyànjú láti wá ojútùú sí ni, Báwo ni Ọlọ́run arínúróde, alágbára gbogbo, “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin,” ṣe tún lè jẹ́ Ọlọ́run ìfẹ́? (Aísáyà 46:10; 1 Jòhánù 4:8) Èrò wọn ni pé, bí Ọlọ́run bá ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ mọ òpin, ó dájú nígbà náà pé ó mọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú ènìyàn sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àwọn ohun burúkú tí yóò tìdí ẹ̀ yọ.
Origen, ọ̀kan lára àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, tó tún jẹ́ akọ̀wé-kọwúrà, sọ pé ọ̀kan lára àwọn kókó pàtàkì tó yẹ ká fi sọ́kàn ni èròǹgbà òmìnira ènìyàn láti ṣe ohun tó bá fẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Àní, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ẹsẹ ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé ènìyàn lómìnira láti ṣe ohun tó bá fẹ́.”
Origen sọ pé sísọ pé agbára àtọ̀húnrìnwá kan ló tì wá ṣe nǹkan kan “kì í ṣe òótọ́, kò sì bọ́gbọ́n mu, ṣùgbọ́n àwọn tó fẹ́ ta jàǹbá fún èròǹgbà òmìnira ènìyàn láti ṣe ohun tó bá fẹ́ ló máa ń sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ jáde lẹ́nu.” Origen jiyàn pé bí Ọlọ́run tilẹ̀ mọ ìtòtẹ̀léra ìṣẹ̀lẹ̀ kí wọ́n tó ṣẹ̀, èyí ò wá túmọ̀ sí pé òun ló mú kí nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tàbí pé dandan ni kí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan ò gbà.
Ìlúmọ̀ọ́ká nì, Augustine (ọdún 354 sí 430 Sànmánì Tiwa), tó jẹ́ Baba Ìsàlẹ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì, ló wá dojú ọ̀ràn rú pátá, nígbà tó sọ pé òmìnira láti ṣe ohun téèyàn fẹ́ kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára lórí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀. Augustine yìí ló sọ kádàrá di ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Àwọn ìwé rẹ̀, pàápàá jù lọ De libero arbitrio, làwọn èèyàn gbé ìjíròrò wọn kà ní Sànmánì Ìbẹ̀rẹ̀ Ọ̀làjú. Ìjiyàn náà wá dé òtéńté rẹ̀ nígbà Àtúnṣe Ẹ̀sìn, nígbà tí ọ̀ràn kádàrá pín Kirisẹ́ńdọ̀mù yẹ́lẹyẹ̀lẹ.a
Ìgbàgbọ́ Tó Tàn Kálẹ̀
Ṣùgbọ́n ṣá o, èròǹgbà nípa àyànmọ́ kò mọ sí Ìwọ̀ Oòrùn ayé nìkan. Ọ̀pọ̀ àwọn Mùsùlùmí ló nígbàgbọ́ nínú kádàrá, torí pé àwọn náà máa ń sọ pé, “mektoub”—tó túmọ̀ sí ó ti wà lákọọ́lẹ̀—tí àjálù bá já lù wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn àwọn ará Ìlà Oòrùn máa ń tẹnu mọ́ ipa tí ọ̀ràn àfọwọ́fà ń kó nínú kádàrá kálukú, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ àyànmọ́ ṣì ń ta sánsán nínú àwọn ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni.
Fún àpẹẹrẹ, òfin Kámà nínú ẹ̀sìn Híńdù àti Búdà ni kádàrá tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nítorí àwọn ohun téèyàn ṣe láyé àkọ́wá. Ní China, ara ìkarawun alábawun tí wọ́n fi ń woṣẹ́ ni wọ́n kọ àwọn ìkọ̀wé àkọ́kọ́ táa ṣàwárí sí. Àyànmọ́ tún jẹ́ apá kan ìgbàgbọ́ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Aztec ṣe àwọn kàlẹ́ńdà ìwoṣẹ́ tí wọ́n ń lo láti fi kádàrá kálukú hàn. Àwọn ìgbàgbọ́ tó jẹ mọ́ àyànmọ́ wọ́pọ̀ pẹ̀lú ní ilẹ̀ Áfíríkà.
Gbígbà táwọn èèyàn níbi gbogbo gba ẹ̀kọ́ àyànmọ́ fi hàn ní tòótọ́ pé kòṣeémánìí ló jẹ́ fún ènìyàn láti nígbàgbọ́ nínú agbára kan tó ga ju ti ẹ̀dá lọ. Nínú ìwé Man’s Religions tí John B. Noss kọ, ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Ohun tí gbogbo ẹ̀sìn ń sọ lédè kan tàbí lédè mìíràn ni pé ènìyàn kò dá dúró, kò sì lè dá dúró. Ó ní àjọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú agbára Ọba Adẹ́dàá àti ti Ẹgbẹ́ òun Ọ̀gbà tó yí i ká, àwọn ló sì gbára lé. Yálà ó yé e yékéyéké tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó mọ̀ pé òun kì í ṣe orísun agbára tó dá dúró láyé.”
Ní àfikún sí ìjẹ́pàtàkì gbígba Ọlọ́run gbọ́, ó tún ṣe pàtàkì fún wa láti mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ láyìíká wa. Àmọ́, ìyàtọ̀ wà láàárín gbígbà pé Ẹlẹ́dàá alágbára gbogbo wà àti gbígbàgbọ́ pé ó ti kọ kádàrá wa sílẹ̀ láìṣeé yí padà. Ǹjẹ́ ipa kankan tilẹ̀ wà tí a ń kó nínú kádàrá wa? Ipa wo ni Ọlọ́run kó?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé ìròyìn wa kejì, Ilé Ìṣọ́nà, ti February 15, 1995, ojú ìwé 3 àti 4.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Kàlẹ́ńdà ìwòràwọ̀ àwọn ará Bábílónì, ní ẹgbẹ̀rún ọdún ṣááju Sànmánì Tiwa
[Credit Line]
Musée du Louvre, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Gíríìkì àti àwọn ará Róòmù gbà gbọ́ pé àwọn abo ọlọ́run mẹ́ta ló ń pinnu kádàrá ẹ̀dá
[Credit Line]
Musée du Louvre, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Isis ti Íjíbítì, ni “alákòóso àyànmọ́ àti kádàrá”
[Credit Line]
Musée du Louvre, Paris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn ìkọ̀wé èdè Chinese tó pẹ́ jù lọ, tí wọ́n kọ sára ìkarawun alábawun, ni wọ́n fi ń woṣẹ́
[Credit Line]
Institute of History and Philology, Academia Sinica, Taipei
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn àmì sódíákì fara hàn lára àpótí yìí láti Páṣíà
[Credit Line]
British Museum ló fún wa láṣẹ láti ya fọ́tò yìí