ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 4/15 ojú ìwé 3-4
  • Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ha Ti Wà Nínú Àkọọ́lẹ̀ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ha Ti Wà Nínú Àkọọ́lẹ̀ Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Ha Ti Pinnu Kádàrá Wa Tẹ́lẹ̀ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Wíwádìí Kádàrá Ẹ̀dá
    Jí!—1999
  • Ṣé Àyànmọ́ Ni àbí Àkọsẹ̀bá Lásán?
    Jí!—1999
  • Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Báyé Ẹ Ṣe Máa Rí?
    Jí!—2007
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 4/15 ojú ìwé 3-4

Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ha Ti Wà Nínú Àkọọ́lẹ̀ Bí?

ẸLẸ́SÌN Kristẹni, Mùsùlùmí, Júù, Híńdù, tàbí ẹlẹ́sìn èyíkéyìí mìíràn—gbogbo ẹlẹ́sìn pátá ni ó ń nírìírí ìbànújẹ́, tí wọ́n sì ń kẹ́dùn lórí irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Fún àpẹẹrẹ, ní December 6, 1997, ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan tí ó bùáyà ṣẹlẹ̀ ní Irkutsk, ìlú kan ní Siberia. Ọkọ̀ òfuurufú ràgàjì AN-124, tí a fi ń kẹ́rù, ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéra tán ni nígbà tí méjì nínú àwọn ẹ́ńjìnnì rẹ̀ kọṣẹ́. Ọkọ̀ òfuurufú náà, tí a gba epo kún dẹ́múdẹ́mú, já ṣòòròṣò wọ inú ilé gbígbé alákọ̀ọ́pọ̀ kan. Iná gba ọ̀pọ̀ nínú àwọn ilé gbígbé náà, ó ṣekú pa ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé tí kò sí ohun tí wọ́n lè ṣe, ọ̀pọ̀ sì fara pa yánnayànna, títí kan àwọn ọmọ kéékèèké tí kò mọ ọ̀tún yàtọ̀ sí òsì.

Ó ṣeé ṣe kí àwọn ènìyàn olójú ìwòye ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ìsìn wà ní àgbègbè ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní Siberia. Àwọn kan lè gbà gbọ́ nínú ẹ̀sìn Kristẹni, síbẹ̀ wọ́n ṣì lè rò pé àyànmọ́ ni ó fa ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà. Àwọn àti àwọn mìíràn lè rò pé, ‘Àmúwá Ọlọ́run ni, bí àwọn tí ikú pa kò bá kú lọ́nà yẹn, ikú ì bá pa wọ́n lọ́nà mìíràn—àyànmọ́ wọn ni.’

Irú ìrònú bẹ́ẹ̀, yálà a sọ ọ́ jáde tàbí a kò sọ ọ́ jáde, ń fi èròǹgbà kan tí ó wọ́pọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìsìn yíká ayé hàn—àyànmọ́. Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wa láti ọjọ́ tí a ti bí wa títí di ọjọ́ tí a óò fi kú ti wà nínú àkọọ́lẹ̀.

Ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ pín sí onírúurú ọ̀nà, èyí tí ó mú kí àlàyé tí ó lè kó gbogbo rẹ̀ pọ̀ nira. Àyànmọ́ ní pàtàkì gbé èrò náà yọ pé gbogbo ohun tí ó bá ṣẹlẹ̀, gbogbo ìgbésẹ̀, gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀—yálà rere tàbí búburú—kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀; a ti kádàrá pé kí ó rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, agbára kan tí ó ju ti ẹ̀dá ènìyàn lọ ti pinnu rẹ̀ tẹ́lẹ̀. A lè rí irú èròǹgbà bẹ́ẹ̀ nínú ìmọ̀ ìwòràwọ̀, nínú ẹ̀sìn Híńdù àti kámà ti ẹ̀sìn Búdà, àti ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù ti kádàrá. Ní Babilóníà ìgbàanì, àwọn ènìyàn gbà gbọ́ pé àwọn ọlọ́run ń darí àyànmọ́ àti ọjọ́ ọ̀la nípasẹ̀ àkọọ́lẹ̀. Wọ́n gbà pé, ọlọ́run èyíkéyìí tí ó bá ń darí “àwọn wàláà kádàrá” wọ̀nyí lè pinnu ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn, ìjọba, àti àwọn ọlọ́run pàápàá.

Ọ̀pọ̀ àwọn tí ó gba èyí gbọ́ gbà pé, Ọlọ́run ti fi àṣẹ àtọ̀runwá pinnu gbogbo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn ṣáájú kí a tó bí wọn, títí kan iye ọdún tí wọ́n á lò láyé, yálà wọ́n á jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ọlọ́rọ̀ tàbí òtòṣì, oníròbìnújẹ́ tàbí aláyọ̀. Gbogbo èyí ni wọ́n sọ pé ó wà lọ́kàn Ọlọ́run tàbí ni a ti kọ sínú ìwé kan kí ó tó wá ṣẹlẹ̀. Nípa báyìí, nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, kò ṣàjèjì kí ẹnì kan tí ó gba èrò yìí gbọ́ sọ pé, “mektoub,”—àkọọ́lẹ̀ ni! Wọ́n ronú pé níwọ̀n bí Ọlọ́run ti mọ ohun gbogbo ṣáájú kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀, ó gbọ́dọ̀ pinnu àwọn tí yóò ṣègbọràn sí i àti àwọn tí kò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn tí ó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ yìí gbà pé ṣáájú kí a tó bí ẹnì kan pàápàá, Ọlọ́run ti pinnu yálà a kádàrá rẹ̀ fún ayọ̀ àìnípẹ̀kun nínú Párádísè tàbí yóò gba ègbé àìnípẹ̀kun.

O lè rò pé èyí jọ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ kádàrá tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù kan fi ń kọ́ni. Alátùn-únṣe Ìsìn ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, ọmọ ilẹ̀ Faransé náà, John Calvin, ni òléwájú nínú àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, tí wọ́n jẹ́ alágbàwí kádàrá. Ó túmọ̀ kádàrá sí “àṣẹ ayérayé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí ó fi ń pinnu ohun tí ó fẹ́ ṣe fún ènìyàn kọ̀ọ̀kan. A kò dá gbogbo wa ní ipò kan náà, ṣùgbọ́n a ti yan ìyè ayérayé fún àwọn kan, a sì ti yan ègbé àìnípẹ̀kun fún àwọn mìíràn.” Calvin tún tẹnu mọ́ ọn pé: “Kì í ṣe kìkì pé Ọlọ́run rí i tẹ́lẹ̀ pé ọkùnrin àkọ́kọ́ yóò ṣubú àti pé yóò run àtọmọdọ́mọ rẹ̀; ṣùgbọ́n òun ni ó dìídì ṣètò rẹ̀ bẹ́ẹ̀.”

Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo mẹ́ńbà ìsìn tí ń fi ẹ̀kọ́ kádàrá tàbí àyànmọ́ kọ́ni ni ó gbà á gbọ́. Àwọn kan ń tọ́ka sí i lọ́nà tí ó tọ́ pé, àwọn ìwé ìsìn mẹ́nu kan òmìnira ìfẹ́ inú ènìyàn. Ní tòótọ́, ìgbésẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn ti fa awuyewuye ńláǹlà, ní ti yálà ó jẹ́ àbájáde òmìnira ṣíṣe yíyàn tí ènìyàn ní tàbí yálà Ọlọ́run ni ó kádàrá rẹ̀ bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn kan ti jiyàn pé ènìyàn lómìnira láti yan ohun tí ó bá wù ú, kí ó sì ṣe ohun tí ó bá fẹ́, níwọ̀n bí Ọlọ́run, tí ó jẹ́ aláìṣègbè, yóò ti mú kí ènìyàn jíhìn fún àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀. Àwọn mìíràn ti sọ pé Ọlọ́run ni ó dá àwọn ìwà tí ènìyàn ń hù, ṣùgbọ́n lọ́nà kan ṣáá, ènìyàn “ń mú” wọn “lò,” ó sì di ẹni tí yóò jíhìn nípa ohun tí ó bá ṣe nípa wọn. Ṣùgbọ́n, ní gbogbogbòò, ọ̀pọ̀ gbà pé Ọlọ́run ti kádàrá gbogbo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́, ńlá àti kékeré.

Kí ni ìgbàgbọ́ tìrẹ? Ọlọ́run ha ti pinnu ohun tí ọjọ́ ọ̀la rẹ yóò jẹ́ bí? Àwọn ẹ̀dá ènìyàn ha ní òmìnira ìfẹ́ inú, agbára láti ṣe yíyàn nípa ọjọ́ ọ̀la bí? Títí dé àyè wo ni kádàrá wa fi sinmi lórí ìgbésẹ̀ wa? Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò pèsè ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

SEL/Sipa Press

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́