Ojú Ìwòye Bíbélì
Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Báyé Ẹ Ṣe Máa Rí?
Lówùúrọ̀ ọjọ́ kan, àwọn ọkùnrin méjì kan ń wakọ̀ lọ síbi iṣẹ́, wọ́n wá pinnu pé káwọn kúkú gba àdúgbò tí ọ̀kan nínú wọn ń gbé tẹ́lẹ̀ kọjá nítorí pé ibẹ̀ máa yá. Bí wọ́n ṣe ń wakọ̀ gba àdúgbò náà lọ, wọ́n rí i tí èéfín ń rú jáde látojú wíńdò tó wà lára ilé kan báyìí. Wọ́n dúró, wọ́n gbé àkàbà jáde látinú ọkọ̀ wọn, wọ́n gòkè lọ sínú ilé tí iná ti ń jó náà, wọ́n sì dóòlà ẹ̀mí ìyá kan àtàwọn ọmọ ẹ̀ márùn-ún. Ìwé ìròyìn kan tó sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà sọ pé: “Ó lè jẹ́ kádàrá tiwọn nìyẹn.”
Ọ̀PỌ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé kóhun rere tàbí ohun búburú yòówù tóó ṣẹlẹ̀ sáwọn, agbára tó ju agbára lọ kan ti ní láti kádàrá ẹ̀ pé bó ṣe máa rí fáwọn nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀gbẹ́ni John Calvin tó jẹ́ Alátùn-únṣe ẹ̀sìn, kọ̀wé pé: “Àwa pe kádàrá ní àkọọ́lẹ̀ látọwọ́ Ọlọ́run, nínú èyí tó ti ń pinnu ibi tóun fẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan já sí. Nítorí pé kò dá gbogbo wọn bákan náà, àmọ́ ó kádàrá pé káwọn kan jogún ìyè ayérayé, káwọn míì sì lọ sínú ìparun àìnípẹ̀kun.”
Ṣóòótọ́ ni pé Ọlọ́run ti máa ń kọ àkọọ́lẹ̀ nípa bí ìgbésí ayé ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan á ṣe rí àti ibi tọ́rọ̀ ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan máa já sí? Kí ni Bíbélì sọ sí ọ̀rọ̀ náà?
Ọgbọ́n Táwọn Kan Sọ Pó Wà Nínú Kádàrá
Báwọn kan tó gbà gbọ́ nínú kádàrá ṣe sábà máa ń ronú nípa ọ̀ràn náà rèé: Arínúróde ni Ọlọ́run. Ó mọ ohun gbogbo, títí kan àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó mọ bí olúkúlùkù á ṣe gbé ìgbé ayé ẹ̀, ó sì mọ àkókò pàtó tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa kú àti irú ikú tó máa pa á. Nítorí náà, lérò tiwọn, bí àkókò bá tó fún olúkúlùkù láti pinnu ohun tó fẹ́, ìpinnu ọ̀hún ò lè kọjá ohun tí Ọlọ́run ti rí tẹ́lẹ̀ tó sì ti wà lákọọ́lẹ̀ fún un; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a jẹ́ pé Ọlọ́run kì í ṣe arínúróde nìyẹn. Ṣé irú ìrònú yìí mọ́gbọ́n dání lójú ẹ? Bọ́rọ̀ bá wá rí bẹ́ẹ̀, wá wo bí nǹkan á ṣe rí o.
Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni agbára àràmàǹdà kan ti kádàrá bí ọjọ́ iwájú ẹ ṣe máa rí, a jẹ́ pé kò sídìí tí wàá fi máa gbìyànjú láti bójú tó ara ẹ nìyẹn. Yálà o mu sìgá tàbí o ò mu sìgá, ìyẹn ò ní ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìlera ẹ àti ìlera àwọn ọmọ ẹ. Béèyàn bá lo bẹ́líìtì nígbà tó wà nínú ọkọ̀ tàbí bí ò bá lò ó, ìyẹn ò ní kó fara pa tàbí kó má fara pa. Ẹ ò wá rí i pé ọgbọ́n tí kò yè kooro lèyí bí. Nínú ìwádìí tí wọ́n ṣe, ìṣirò fi hàn pé àwọn èèyàn tó bá ń ṣọ́ra kì í sábàá kàgbákò. Béèyàn ò bá máa ṣọ́ra ẹ̀, dandan ni kó kó síyọnu.
Ìwọ tún ro ọ̀rọ̀ náà wò lọ́nà yìí. Bí Ọlọ́run bá yàn láti máa mọ gbogbo nǹkan tẹ́lẹ̀, nígbà náà ó ti ní láti jẹ́ pé kó tó dá Ádámù àti Éfà lá á ti mọ̀ pé wọ́n á ṣàìgbọràn sí òun. Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú “igi ìmọ̀ rere àti búburú” bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ó máa kú, ṣé Ọlọ́run ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé Ádámù á jẹ nínú ẹ̀ ni? (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Nígbà tí Ọlọ́run sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀, kí ẹ sì máa jọba lórí ẹja òkun àti àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti olúkúlùkù ẹ̀dá alààyè tí ń rìn lórí ilẹ̀ ayé,” ṣó ti mọ̀ pé kò ní ṣeé ṣe fún wọn láti gbé títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé ni? Ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.
Bó bá sì wá jẹ́ pé kò sí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá tí Ọlọ́run ò ti pinnu pé kó rí bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, ohun tó máa túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run ló jẹ̀bi gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá, ìyẹn àwọn bí ogun, ìrẹ́nijẹ àti ìjìyà. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí lóòótọ́? Ìdáhùn tó ṣe kedere wà nínú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nípa ara rẹ̀.
‘Ṣe Yíyàn’
Ìwé Mímọ́ sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” àti pé ó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo.” Ìgbà gbogbo ló máa ń rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n “kórìíra ohun búburú” kí wọ́n sì “nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (1 Jòhánù 4:8; Sáàmù 37:28; Ámósì 5:15) Lọ́pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run ti rọ àwọn adúróṣinṣin pé kí wọ́n yàn láti máa rìn ní ọ̀nà òdodo. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà dá májẹ̀mú pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, ó tipasẹ̀ Mósè sọ fún wọn pé: “Èmi ń fi ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí yín lónìí, pé èmi ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ìfiré; kí o sì yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè nìṣó, ìwọ àti ọmọ rẹ.” (Diutarónómì 30:19) Ṣé Ọlọ́run ti kádàrá ohun táwọn èèyàn yẹn máa yàn mọ́ wọn? Ó dájú gbangba pé kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Jóṣúà, tó jẹ aṣáájú àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, gba àwọn ará ìlú ẹ̀ níyànjú pé: “Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín . . . ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” (Jóṣúà 24:15) Bákan náà, Jeremáyà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run tún rọ àwọn èèyàn ìgbà tiẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà nínú ohun tí mo ń sọ fún ọ, nǹkan yóò lọ dáadáa fún ọ, ọkàn rẹ yóò sì máa wà láàyè nìṣó.” (Jeremáyà 38:20) Ǹjẹ́ Ọlọ́run òdodo àti onífẹ̀ẹ́ á rọ àwọn èèyàn láti máa ṣe ohun tó tọ́ kí wọ́n bàa lè máa retí àtirí èrè gbà bó bá ti mọ̀ pé ìsapá wọn máa forí ṣánpọ́n gbẹ̀yìn náà ni? Ó tì o. Ìwà àgàbàgebè ló hù yẹn bó bá ṣe bẹ́ẹ̀.
Nítorí náà, bí ohun rere tàbí aburú bá ń ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé ẹ, kì í ṣe nítorí pé Ọlọ́run ti kádàrá ẹ̀ ni o. Lọ́pọ̀ ìgbà táwọn ‘ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀’ bá wáyé, ó sábà máa ń jẹ́ àbájáde ìpinnu táwọn ẹlòmíràn ṣe, yálà ìpinnu náà mọ́gbọ́n dání tàbí kò mọ́gbọ́n dání. (Oníwàásù 9:11) Àní sẹ́, kò sẹ́ni tó kádàrá báyé ẹ ṣe máa rí, àmọ́ ìpinnu tó o bá ṣe fúnra ẹ ló máa sọ bí ọjọ́ ọ̀la ayérayé ẹ ṣe máa rí.
KÍ LÈRÒ Ẹ?
◼ Ṣé Ọlọ́run ti pinnu tẹ́lẹ̀ pé Ádámù àti Éfà máa dẹ́ṣẹ̀?—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:16, 17.
◼ Àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run ní wo ni ò ní jẹ́ kó máa kádàrá àwọn èèyàn?—Sáàmù 37:28; 1 Jòhánù 4:8.
◼ Kí ni ojúṣe rẹ?—Jóṣúà 24:15.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Ìwádìí fi hàn pé àwọn èèyàn tó bá ń ṣọ́ra kì í sábàá kàgbákò