ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 2/15 ojú ìwé 3-4
  • Ọlọrun Ha Ti Pinnu Kádàrá Wa Tẹ́lẹ̀ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọrun Ha Ti Pinnu Kádàrá Wa Tẹ́lẹ̀ Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àyànmọ́—Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Náà
  • Augustine, Bàbá Àyànmọ́
  • Àwọn Olójú-Ìwòye Augustine
  • Àyànmọ́ Tàbí Òmìnira Ìfẹ́-Inú?
  • A Ha Lè Mú Àyànmọ́ Dọ́gba Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọlọrun Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ọjọ́ Ọ̀la Wa Ha Ti Wà Nínú Àkọọ́lẹ̀ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ṣé Ọlọ́run Ti Kádàrá Báyé Ẹ Ṣe Máa Rí?
    Jí!—2007
  • Kí Ló Ti Jẹ́ Àbájáde Ẹ̀kọ́ Ìsìn Calvin Láti Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta Ọdún?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 2/15 ojú ìwé 3-4

Ọlọrun Ha Ti Pinnu Kádàrá Wa Tẹ́lẹ̀ Bí?

“A Ó lé yẹra fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro àfinúrò bí a kò bá lo ọ̀rọ̀ tí a sábà máa ń ṣì lóye náà àyànmọ́ rárá.” O lè ṣe kàyéfì nípa ohun tí gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí, bí ó bá jẹ́ pé o ti lo ọ̀rọ̀ náà “àyànmọ́” tàbí tí o ti gbọ́ tí a lò ó rí.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ French Catholic Théo ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ti sọ, àwa yóò ṣe dáradára láti máṣe lo ọ̀rọ̀ náà “àyànmọ́.” Ìwé mìíràn sọ pé: “Lónìí, ó dàbí ẹni pé, àyànmọ́ kò tún sí lọ́kàn àwọn òjiyàn lórí ọ̀rọ̀ ìsìn mọ́, àní bí ó ti rí fún èyí tí ó pọ̀ jùlọ lára àwọn Protẹstanti.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìbéèrè nípa àyànmọ́ ti kó ìdààmú bá ọ̀pọ̀ ènìyàn jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn. Òun ní ń bẹ láàárín gbùngbùn awuyewuye tí ó súnná sí Ìṣàtúnṣe-Ìsìn, àní láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki pàápàá, ó ti jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn gbígbóná janjan fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í jiyàn lé e lórí púpọ̀ lónìí, síbẹ̀síbẹ̀ ó ṣì jẹ́ ìṣòro. Ta ni kò ní fẹ́ láti mọ̀ bóyá a ti pinnu kádàrá òun ṣáájú?

Àyànmọ́—Ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Náà

Kí ni ọ̀rọ̀ náà “àyànmọ́” túmọ̀ sí nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì? Ìwé Dictionnaire de théologie catholique gbà pé ó jẹ́ “ìpètepèrò àtọ̀runwá láti mú kí àwọn kan, tí a dárúkọ pàtó, ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Èrò gbogbogbòò ni pé àwọn àyànfẹ́, “tí a dárúkọ pàtó,” ni àwọn tí aposteli Paulu ń tọ́ka sí nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Romu, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Ọlọrun ń ṣiṣẹ́ fún rere pẹ̀lú àwọn wọnnì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwọn tí a pè gẹ́gẹ́ bí ète rẹ̀. Nítorí pé àwọn wọnnì tí òun ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ni òun ti yan àyànmọ́ fún láti bá àwòrán Ọmọkùnrin rẹ̀ mu . . . Àwọn wọnnì tí òun sì ti yan àyànmọ́ fún ni òun sì tún pè; àwọn wọnnì tí òun sì pè ni òun tún dáláre; àwọn wọnnì tí òun sì dáláre ni òun tún ṣe lógo.”—Romu 8:28-30, Revised Standard Version.

Àní ṣáájú kí a tó bí wọn, àwọn ènìyàn kan ni a rò pé Ọlọrun ti yàn pẹ̀lú èrò pé wọn yóò nípìn-ín nínú ògo Kristi ní ọ̀run. Èyí yọrí sí ìbéèrè tí a ti ń jiyàn lé lórí fún ìgbà pípẹ́ náà pé: Ọlọrun ha máa ń yan àwọn tí òun fẹ̀ gbàlà bí ó bá ṣe wù ú bí, tàbí àwọn ènìyàn ha ní òmìnira ìfẹ́-inú àti ipa kan láti sà láti lè rí ojúrere Ọlọrun gbà kí wọ́n sì dì í mú bí?

Augustine, Bàbá Àyànmọ́

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Bàbá Ṣọ́ọ̀ṣì mìíràn ti kọ̀wé ṣáájú nípa àyànmọ́, Augustine (354 sí 430 C.E.) ni a gbà ní gbogbogbòò pé ó fi ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ lélẹ̀ fún àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki àti Protẹstanti. Gẹ́gẹ́ bí Augustine ti wí, Ọlọrun ti kádàrá àwọn olódodo láti ìgbà àtayébáyé láti gba ìbùkún ayérayé. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun kò pinnu àyànmọ́ àwọn aláìṣòdodo bí ọ̀rọ̀ náà ti rí ní pàtó, wọ́n níláti gba ìdálẹ́bi, ìjìyà tí ó tọ́ sí wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àlàyé Augustine fi àyè díẹ̀ sílẹ̀ fún òmìnira ìfẹ́-inú, tí ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣí àyè sílẹ̀ fún awuyewuye.

Àwọn Olójú-Ìwòye Augustine

Àríyànjiyàn nípa àyànmọ́ àti òmìnira ìfẹ́-inú ń wáyé déédéé lákòókò Sànmánì Agbedeméjì, ó sì dé ojú ọ̀gbagadè nígbà Ìṣàtúnṣe-Ìsìn. Luther rí àyànmọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ọlọrun lómìnira láti yàn, láìjẹ́ pé Òun ń rí àwọn àǹfààní ọjọ́-ọ̀la tàbí iṣẹ́ rere àwọn àyànfẹ́ náà ṣáájú. Calvin dé ìparí èrò tí ó túbọ̀ yàtọ̀ pátápátá pẹ̀lú ìpìlẹ̀-èrò rẹ̀ nípa àyànmọ́ alápá méjì: Àwọn kan ní àyànmọ́ rírí ìgbàlà ayérayé, àwọn mìíràn sì ní ti ìdálẹ́bi ayérayé. Bí ó ti wù kí ó rí, Calvin pẹ̀lú wo yíyàn Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìpinnu kòdúrógbẹ́jọ́, àní tí ó rúnilójú.

Ọ̀ràn àyànmọ́ àti ìbéèrè tí ó tan mọ́ ọn nípa “oore-ọ̀fẹ́”—ọ̀rọ̀ kan tí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì sábà máa ń lò fún ìgbésẹ̀ tí Ọlọrun ń gbé láti gbanilà àti láti polongo àwọn ènìyàn ní olódodo—di ńlá tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ débi pé ní 1611 Ibùjókòó Ọlá-Àṣẹ Popu ti Katoliki fòfinde títẹ ohunkóhun jáde lórí kókó-ẹ̀kọ́ náà láìjẹ́ pé wọ́n fọwọ́ sí i. Láàárín Ṣọ́ọ̀ṣì Katoliki, àwọn Ọmọlẹ́yìn Jansen ará France ti ọ̀rúndún kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún fún ẹ̀kọ́ Augustine ní ìtìlẹ́yìn tí ó lágbára. Wọ́n ṣalágbàwí irú ìsìn Kristian kan tí ń fi adùn dura rẹ̀ àti èyí tí ó jẹ́ ti àwọn ọ̀tọ̀kùlú wọ́n sì tún ní àwọn tí ń tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láàárín àwọn onípò ọlá. Síbẹ̀, awuyewuye tí ń bẹ lórí ọ̀ràn yìí kò rọlẹ̀. Ọba Louis XIV pàṣẹ pé kí a pa ilé-ìsìn Port-Royal run, ibi tí a ti pilẹ̀ èrò Jansen.

Láàárín àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Alátùn-únṣe Protẹstanti, ìjíròrò náà kò ní ojútùú. Lára àwọn àwùjọ ìsìn mìíràn, àwọn Alákatakítí, tí ń tẹ̀lé Jacobus Arminius, gbàgbọ́ pé ènìyàn ní ipa kan láti sà nínú ìgbàlà ara rẹ̀. Ìpàdé Ìjíròrò Ìlànà ti Dordrecht tí ṣọ́ọ̀ṣì Protẹstanti ṣe (ní 1618 sí 1619) yanjú ìbéèrè náà ráńpẹ́ nígbà tí ó gba èrò ìgbàgbọ́ gíga ti Calvin wọlé. Gẹ́gẹ́ bí ìwé náà L’Aventure de la Réforme—Le monde de Jean Calvin ṣe sọ, ní Germany aáwọ̀ yìí lórí àyànmọ́ àti òmìnira ìfẹ́-inú jálẹ̀ sí sáà gígùn tí ó jẹ́ ti “ìgbìyànjú láti mú ọ̀rọ̀ tọ́ tí kò kẹ́sẹjárí, títí kan ti èébú, ìfinisẹ́wọ̀n, àti lílé àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kúrò láwùjọ.”

Àyànmọ́ Tàbí Òmìnira Ìfẹ́-Inú?

Láti ìbẹ̀rẹ̀, àwọn èrò méjì títakora pátápátá yìí, àyànmọ́ àti òmìnira ìfẹ́-inú, gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtakò gbígbóná janjan dìde. Ó ti jẹ́ ohun tí kó ṣeé ṣe fún Augustine ní tirẹ̀ láti ṣàlàyé àìbáradọ́gba yìí. Calvin pẹ̀lú rí i gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ọlọrun ń gbà fi agbára àjùlọ àti ìfẹ́-inú rẹ̀ hàn tí ó sì wá gbà pé kò ṣeé ṣàlàyé.

Ṣùgbọ́n bí Bibeli ṣe fi àwọn ànímọ́ Ọlọrun àti ìwà rẹ̀ hàn ha ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lọ́nà tí ó túbọ̀ ṣe kedere bí? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀lé e yóò yẹ àwọn kókó wọ̀nyí wò lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Calvin

Luther

Jansen

[Credit Line]

Àwòrán: Bibliothèque Nationale, Paris

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́