A Ha Lè Mú Àyànmọ́ Dọ́gba Pẹ̀lú Ìfẹ́ Ọlọrun Bí?
“ATÚMỌ̀ àyànmọ́ sí ohun tí Ọlọrun ti wéwèé láti àtayébáyé, nípa èyí tí òun fi pinnu ohun tí òun fẹ́ ṣe pẹ̀lú ènìyàn kọ̀ọ̀kan. Nítorí òun kò dá gbogbo wọn bákan náà, ṣùgbọ́n ó yan àwọn kan ṣáájú fún ìyè àìnípẹ̀kun àti àwọn mìíràn fún ìjìyà ayérayé.”
Bí Alátùn-únṣe ìsìn Protẹstanti John Calvin ṣe túmọ̀ ìpìlẹ̀-èrò rẹ̀ nípa àyànmọ́ nìyẹn nínú ìwé Institutes of the Christian Religion. A gbé ìpìlẹ̀-èrò yìí ka orí èrò náà pé Ọlọrun jẹ́ ọlọ́gbọ́n gbogbo àti pé ìgbésẹ̀ àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀ kò lè gbé ìbéèrè dìde sí àwọn ète rẹ̀ tàbí kí wọ́n kàn án nípá fún un láti ṣe àwọn ìyípadà.
Ṣùgbọ́n níti tòótọ́ ohun tí Bibeli ń sọ nípa Ọlọrun ha nìyí bí? Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni pé, ǹjẹ́ irú àlàyé bẹ́ẹ̀ bá àwọn ànímọ́ Ọlọrun mu, ní pàtàkì ànímọ́ rẹ̀ tí ó tayọ jùlọ—ìfẹ́?
Ọlọrun Tí Ó Tóótun Láti Sàsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́-Ọ̀la
Ó ṣeé ṣe fún Ọlọrun láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́-ọ̀la. Ó ṣàpèjúwe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Ẹni tí ń sọ òpin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wá, àti nǹkan tí kò tí ì ṣe láti ìgbàanì wá, wí pé, Ìmọ̀ mi yóò dúró, èmi ó sì ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.” (Isaiah 46:10) Jálẹ̀ ọ̀rọ̀-ìtàn ẹ̀dá ènìyàn, Ọlọrun ti mú kí a kọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ láti fi hàn pé òun lè lo òye ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kí ó sì sọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó wáyé.
Nípa báyìí, ní àwọn ọjọ́ Belṣassari, ọba Babiloni, nígbà tí wòlíì Danieli lá àlá nípa àwọn ẹranko ẹhànnà méjì, tí ọ̀kan ń fèrú gbapò lọ́wọ́ èkejì, Jehofa fún un ní ìtumọ̀ rẹ̀ pé: “Àgbò náà tí ìwọ rí tí ó ní ìwo méjì nì, àwọn ọba Media àti Persia ni wọ́n. Òbúkọ onírun nì ni ọba [Griki, NW].” (Danieli 8:20, 21) Ó hàn gbangba pé, Ọlọrun lo òye ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ láti ṣí ìtòtẹ̀léra àwọn agbára ayé payá. Ilẹ̀-Ọba Babiloni tí ó gbilẹ̀ nígbà yẹn ni Medo-Persia yóò gbapò rẹ̀ lẹ́yìn náà sì ni Griki yóò tẹ̀lé e.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tún lè níí ṣe pẹ̀lú ẹnìkọ̀ọ̀kan. Fún àpẹẹrẹ, wòlíì Mika polongo pé Messia náà ni a óò bí ní Betlehemu. (Mika 5:2) Lẹ́ẹ̀kan síi, nínú ọ̀ràn yìí Ọlọrun lo òye ìsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, a kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí pẹ̀lú ète pàtàkì kan lọ́kàn—dídá Messia náà mọ̀ yàtọ̀. Àpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò pèsè ìdáláre fún èrò ìgbàgbọ́ nípa àyànmọ́ gbogbogbòò tí kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀.
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, Ìwé Mímọ́ fi hàn pé àwọn ìpò kan wà nínú èyí tí Ọlọrun ti máa ń yàn láti máṣe mọ ohun tí yóò jẹ́ àbájáde. Gẹ́rẹ́ ṣáájú ìparun Sodomu àti Gomora, ó polongo pé: “Èmi ó sọ̀kalẹ̀ lọ nísinsìnyí, kí n rí bí wọ́n tilẹ̀ ṣe, gẹ́gẹ́ bí òkìkí igbe rẹ̀, tí ó dé ọ̀dọ̀ mi; bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, èmi ó mọ̀.” (Genesisi 18:21) Ẹsẹ ìwé mímọ́ yìí fi hàn pé Ọlọrun kò mọ bí ìwà ìbàjẹ́ ṣe gbilẹ̀ tó ní àwọn ìlú-ńlá wọ̀nyẹn ṣáájú kí ó tó wádìí-ọ̀ràn.
Lótìítọ́, Ọlọrun lè rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣáájú, ṣùgbọ́n nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀ràn, òun ti yàn láti máṣe lo òye rẹ̀ láti mọ nǹkan ṣáájú. Nítorí pé Ọlọrun ni olodumare, òun lómìnira láti lo agbára-ìṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé bá ṣe fẹ́.
Ọlọrun Tí Ó Lè Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́
Gẹ́gẹ́ bí Calvin ti sọ, àwọn kan sọ pé Ọlọrun ti pinnu ìṣubú ènìyàn ṣáájú ṣíṣẹ̀dá rẹ̀ àti pé ó ti pinnu àyànmọ́ ‘àwọn àyànfẹ́’ ṣáájú ìṣubú yẹn. Ṣùgbọ́n bí èyí bá jẹ́ òtítọ́, kì yóò ha jẹ́ ìwà àgàbàgebè fún Ọlọrun láti nawọ́ ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun sí Adamu àti Efa, nígbà tí ó sì mọ̀ dájú pé wọn kò ní lè jèrè rẹ̀? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ìwé Mímọ́ kò sẹ́ níbikíbi pé tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ni a fún ní yíyàn kan: yálà láti tẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá kí wọ́n sì wàláàyè títíláé tàbí kí wọ́n kọ̀ wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n sì kú.—Genesisi, orí 2.
Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Adamu àti Efa ha ké ète Ọlọrun nígbèrí nítòótọ́ bí? Rárá, nítorí pé kété lẹ́yìn tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, Ọlọrun kéde pé òun yóò gbé “irú-ọmọ” kan dìde láti pa Satani àti àwọn aṣojú rẹ̀ run àti pé òun yóò tún mú àwọn ọ̀ràn tọ́ lórí ilẹ̀-ayé. Gan-an gẹ́gẹ́ bí kòkòrò díẹ̀ kò ti lè dá àgbẹ̀ kan dúró láti máṣe mú èso yanturu jáde, bẹ́ẹ̀ náà ni àìgbọràn Adamu àti Efa kò lè dí Ọlọrun lọ́wọ́ láti sọ ilẹ̀-ayé di paradise.—Genesisi, orí 3.
Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn Ọlọrun ṣí i payá pé Ìjọba àkóso kan yóò wà tí a ó fi lè àtọmọdọ́mọ Ọba Dafidi lọ́wọ́ àti pé àwọn mìíràn yóò darapọ̀ mọ́ Ìjọba yìí. Àwọn mìíràn yìí ni a pè ní “àwọn ènìyàn mímọ́ ti Ọ̀gá-ògo jùlọ.”—Danieli 7:18; 2 Samueli 7:12; 1 Kronika 17:11.a
Láti Sọtẹ́lẹ̀ Kì í Ṣe Láti Pinnu Àyànmọ́
Òtítọ́ náà pé Ọlọrun kò yàn láti mọ ipa-ọ̀nà tí ìran ènìyàn yóò tọ̀ kò dí i lọ́wọ́ láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóò jẹ́ àbájáde ìwà rere tàbí búburú tí ènìyàn kan bá hù. Atọ́kọ̀ṣe kan tí ó kìlọ̀ fún awakọ̀ kan nípa bí ọkọ̀ rẹ̀ ṣe bàjẹ́ tó ni a kò lè dá lẹ́bi bí jàm̀bá bá ṣẹlẹ̀ tàbí kí a fẹ̀sùn kàn án fún pípinnu àyànmọ́ onítọ̀hún. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a kò lè fẹ̀sùn kan Ọlọrun fún yíyan àyànmọ́ àbájáde oníbànújẹ́ tí ìgbésẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan ń mú wa.
Ohun kan náà ni ó jẹ́ òtítọ́ nípa àtọmọdọ́mọ tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́. Ṣáájú kí Kaini tó pa arákùnrin rẹ̀, Jehofa gbé yíyàn kan ka iwájú Kaini. Òun yóò ha ṣẹ́pá ẹ̀ṣẹ̀, tàbí yóò ha jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ́pá òun bí? Kò sí ohunkóhun nínú àkọsílẹ̀ náà tí ó fi hàn pé Jehofa ti pinnu ṣáájú pé Kaini yóò ṣe yíyàn bíburú náà kí ó sì pa arákùnrin rẹ̀.—Genesisi 4:3-7.
Lẹ́yìn náà, Òfin Mose kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Israeli nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ Jehofa, fún àpẹẹrẹ, nípa fífẹ́ aya láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kèfèrí. Ohun tí a sọtẹ́lẹ̀ wáyé níti gidi. Èyí ni a lè rí láti inú àpẹẹrẹ ti Ọba Solomoni, ẹni tí àwọn aya rẹ̀ àjèjì nípa ìdarí lé lórí nígbẹ̀yìn ayé rẹ̀ láti bọ̀rìṣà. (1 Ọba 11:7, 8) Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọrun kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n òun kò pinnu àyànmọ́ ohun tí ìgbésẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóò jẹ́.
A fún àwọn Kristian tí a yàn, tàbí àwọn àyànfẹ́, ní ìṣírí láti máa faradà á bí wọn kò bá fẹ́ kí a fi èrè tí a ṣèlérí níti ṣíṣàkóso pẹ̀lú Kristi ní ọ̀run dù wọ́n. (2 Peteru 1:10; Ìṣípayá 2:5, 10, 16; 3:11) Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ní ìgbàanì ti béèrè, Èéṣe tí a fi fúnni ní irú ìránnilétí bẹ́ẹ̀ bí ìpè àwọn àyànfẹ́ kò bá ṣeé yípadà?
Àyànmọ́ àti Ìfẹ́ Ọlọrun
A fún ènìyàn ní òmìnira ìfẹ́-inú, níti pé a dá a “ní àwòrán Ọlọrun.” (Genesisi 1:27) Òmìnira ìfẹ́-inú kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn bí ìfẹ́ yóò bá mú kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn bọlá fún Ọlọrun, kí ìfẹ́ sì sún wọn láti sìn ín, kì í ṣe bíi ti àwọn ẹ̀rọ àgbélẹ̀rọ aṣe-bí-ènìyàn tí a ti pinnu gbogbo ìgbésẹ̀ wọn ṣáájú. Ìfẹ́ tí àwọn ẹ̀dá olómìnira, tí wọ́n sì tún jẹ́ ọlọ́gbọ́nlóye fi hàn yóò mú kí Ọlọrun fi hàn pé èké ni àwọn ẹ̀sùn tí kò lẹ́sẹ̀nílẹ̀ tí wọ́n fi kàn án. Ó wí pé: “Ọmọ mi, kí ìwọ kí ó gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn; kí èmi kí ó lè dá ẹni tí ń gàn mí lóhùn.”—Owe 27:11.
Bí a bá ti pinnu àyànmọ́ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ni—tàbí tí a ti ṣe ìwéwèé wọn, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀—a kò ha lè gbé ìbéèrè dìde sí ìjójúlówó ìfẹ́ wọn fún Ẹlẹ́dàá wọn bí? Àti pé, ṣíṣe ìpinnu àyàntẹ́lẹ̀ nípa àwọn tí a ti kádàrá fún ògo àti ayọ̀ ṣáájú láìka ohun tí ó tọ́ sí ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sí kò ha ní tako àìkì í ṣe ojúsàájú Ọlọrun bí? Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí àwọn kan bá rí irú ìbálò dídára jù bẹ́ẹ̀ gbà, ti a sì kádàrá ìyà ayérayé fún àwọn yòókù, ekukáká ni èyí fi lè ru ìmọ̀lára ìmoore àtọkànwá sókè nínú “àwọn tí a yàn,” tàbí “àwọn àyànfẹ́.”—Genesisi 1:27; Jobu 1:8; Iṣe 10:34, 35.
Ní àkótán, Kristi sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti wàásù ìhìnrere fún gbogbo aráyé. Bí ó bá jẹ́ pé Ọlọrun ti yan àwọn wọnnì tí òun yóò gbàlà, èyí kò ha ní bomi paná ìtara tí àwọn Kristian ń fi hàn nínú iṣẹ́ ajíhìnrere bí? Kò ha ní mú kí iṣẹ́ ìwàásù náà di èyí tí kò ní ète kankan nínú bí?
Ìfẹ́ tí kò ní ojúsàájú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ipa tí ó lágbára jùlọ tí ó lè sún àwọn ènìyàn láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ padà. Ọ̀nà títóbi jù tí Ọlọrun gbà fi ìfẹ́ hàn ni láti fi Ọmọkùnrin rẹ̀ rúbọ nítorí aráyé aláìpé, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Òye tí Ọlọrun ti ní nípa Ọmọkùnrin rẹ̀ ṣáájú jẹ́ ọ̀ràn kan tí ó yàtọ̀, ṣùgbọ́n ó mú un dá wa lójú pé àwọn ìlérí ìmúpadàbọ̀sípò tí ó sinmi lórí Jesu yóò ní ìmúṣẹ níti tòótọ́. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọkùnrin yẹn kí a sì súnmọ́ Ọlọrun. Ẹ jẹ́ kí a fi ìmọrírì wa hàn nípa títẹ́wọ́gba ìkésíni Ọlọrun láti wá sínú ipò-ìbátan tí ó dára pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Lónìí, Ọlọrun nawọ́ ìkésíni yìí sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ láti lo òmìnira ìfẹ́-inú kí wọ́n sì fi ìfẹ́ wọn hàn sí i.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Jesu ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà tí a ti múrasílẹ̀ “lati ìgbà pípilẹ̀ ayé” (Matteu 25:34), òun ti níláti máa tọ́ka sí àkókò kan lẹ́yìn ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́. Luku 11:50, 51 so “ìgbà pípilẹ̀ ayé,” tàbí ìgbà pípilẹ̀ ìran ènìyàn tí ó ṣeé rà padà nípasẹ̀ ìràpadà, pọ̀ mọ́ ìgbà Abeli.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
A PINNU ÀYÀNMỌ́ WỌN GẸ́GẸ́ BÍ ẸGBẸ́ KAN
“Àwọn wọnnì tí Ọlọrun ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ ni òun tún pinnu àyànmọ́ wọn kí wọ́n lè bá ìrísí Ọmọkùnrin rẹ̀ mu, kí òun baà lè jẹ́ àkọ́bí láàárín ọ̀pọ̀lọpọ̀ arákùnrin. Àwọn wọnnì tí òun sì pinnu àyànmọ́ wọn, ni òun tún pè; àwọn wọnnì tí òun pè, ni òun sì tún dáláre; àwọn wọnnì tí òun dáláre, ni òun sì tún ṣe lógo.” (Romu 8:29, 30, New International Version) Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lóye èdè ọ̀rọ̀ náà “pinnu àyànmọ́” tí Paulu lò nínú àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?
Èrò Paulu níhìn-ín kì í ṣe ìjiyàn olójú-ìwòye-tèmi-lọ̀gá tí ó faramọ́ pípinnu àyànmọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún wa, ìwé Dictionnaire de théologie catholique ṣàlàyé ìjiyàn Paulu (Romu, orí 9 sí 11) lọ́nà yìí: “Lọ́nà tí ń ga síi, èrò tí ó gbilẹ̀ láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ Katoliki ni pé ìpìlẹ̀-èrò náà gan-an nípa pípinnu àyànmọ́ fún ìyè ayérayé ni a kò tí ì fi lélẹ̀.” Iṣẹ́ ìtọ́ka sí kan náà fa ọ̀rọ̀ M. Lagrange yọ ní sísọ pé: “Ìbéèrè náà tí Paulu gbé dìde ní ìbẹ̀rẹ̀ kì í ṣe ti pípinnu àyànmọ́ tàbí ti pípinnu ìjìyà ṣáájú bíkòṣe ti pípè tí a pe àwọn Kèfèrí sínú oore-ọ̀fẹ́ ti ìsìn Kristian, ọ̀nà tí ó gbà sọ ọ́ jẹ́ nítorí àìnígbàgbọ́ àwọn Júù. . . . Ó níí ṣe pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ, àwọn Kèfèrí, àwọn Júù, kì í sì í ṣe àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan ní pàtó.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.
Láìpẹ́ yìí, The Jerusalem Bible fúnni ní ìparí èrò kan náà nípa àwọn orí wọ̀nyí (9 sí 11), ní sísọ pé: “Nítorí náà, kókó ẹ̀kọ́ inú orí wọ̀nyí kì í ṣe ìṣòro pípinnu àyànmọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún ògo, tàbí fún ìgbàgbọ́ pàápàá, bíkòṣe ipa tí Israeli ń kó nínú mímú ọ̀rọ̀-ìtàn nípa ìgbàlà gbèrú, ìṣòro kanṣoṣo tí àwọn ọ̀rọ̀ inú M[ájẹ̀mú] L[áéláé] gbé dìde.”
Àwọn ẹsẹ tí ó kẹ́yìn nínú Romu orí 8 parapọ̀ jẹ́ àyíká ọ̀rọ̀ kan náà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ẹsẹ wọ̀nyí wulẹ̀ lè rán wa létí pé Ọlọrun rí i ṣáájú pé ẹgbẹ́ kan, tàbí àwùjọ kan wà, láti inú gbogbo aráyé tí a óò késí láti ṣàkóso pẹ̀lú Kristi, ó sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti kúnjú òṣùwọ̀n àwọn ohun àbéèrè-fún tí wọ́n níláti kúnjú òṣùwọ̀n rẹ̀—a sì ṣe èyí láì jẹ́ pé a ti ya àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan pàtó sọ́tọ̀ tí a óò yàn ṣáájú ìgbà náà, nítorí pé ìyẹn yóò tako ìfẹ́ àti ìdájọ́-òdodo rẹ̀.