Jàm̀bá—Àyànmọ́ ni Tabi Ayika Ipo?
BI Cristina, ọ̀dọ́ òrékelẹ́wà afìmúra-ọ̀ṣọ́ polowo kan, ṣe sọdá oju popo Nove de Julho tí ọkọ̀ ìrìnnà pọ si ni São Paulo, Brazil, oun kò rí bọ́ọ̀sì ti nbọ. Awakọ naa fi ìgbékútà gbiyanju lati dá ọkọ̀ rẹ̀ duro, ṣugbọn ẹ̀pa kò bóró mọ́. Cristina ni ọkọ̀ gùn lori ti o si kú.
Jàm̀bá apanilẹkun yii gba irohin oju-ewe iwaju ninu iwe irohin Brazil naa O Estado de S. Paulo. (July 29, 1990) Sibẹ ó wulẹ jẹ́ ọkan lara 50,000 iku mọto ti nṣẹlẹ lọdọọdun ni Brazil ni. Nigba ti a sì nsọ ẹgbẹẹgbẹrun pupọ sii di alaabọ ara nipa iru awọn jàm̀bá bẹẹ, awọn miiran laaja laifarapa. Eeṣe, nigba naa, ti ọdọmọbinrin yii kò fi laaja? A ha yàn án mọ́ ọn lati kú ni ọjọ yẹn ni bi?
Aimọye awọn eniyan ni yoo jiyan pe bayii ni ọran rí. Wọn gbagbọ ninu kádàrá, pe awọn iṣẹlẹ pataki, iru bii akoko iku ẹnikan, ni a ti pinnu ṣaaju. Igbagbọ yii ti ṣokunfa iru awọn ọrọ bii “Ayanmọ kò gbóògùn,” “Ọjọ rẹ̀ ló pé,” tabi “Ohun ti ó bá maa ṣeni kò lee ṣai ṣeni dandan.” Otitọ kankan ha wà ninu awọn ọrọ ti ó wọ́pọ̀ bi iwọnyi bi? Awa ha wulẹ jẹ ẹrú kádàrá bi?
Igbagbọ ninu kádàrá, tabi ero naa pe gbogbo iṣẹlẹ ni a ti pinnu ṣaaju, wọ́pọ̀ laaarin awọn ara Gíríìsì ati Roomu igbaani. Ani lonii paapaa ero naa ṣì lagbara sibẹ ninu ọpọlọpọ isin. Fun apẹẹrẹ, Islam di awọn ọrọ Kurani naa mú pe: “Ọkàn kankan kò le kú lae ayafi nipasẹ iyọọda Allah ati ni akoko ti a ti yàn.” Igbagbọ ninu kádàrá tun wọpọ ninu Kristẹndọmu a sì ti fun un lokun nipasẹ ẹkọ igbagbọ àkọmọ́ ti a fi kọni lati ọwọ John Calvin. Nitori naa, ó wọpọ fun awọn alufaa lati sọ fun awọn ibatan ti nbanujẹ pe irú jàm̀bá kan jẹ “ifẹ inu Ọlọrun.”
Bi o ti wu ki o ri, oju-iwoye naa pe jàm̀bá jẹ́ iyọrisi kádàrá, lodisi làákàyè, iriri, ati ọgbọn ironu. Fun ohun kan, awọn jàm̀bá ọkọ ni ko le jẹ́ iyọrisi ìlọ́wọ́sí atọrunwa, niwọn bi iwadii kulẹkulẹ lọpọ igba yoo ti ṣipaya okunfa ti o ba ọgbọn ironu mu lọna pipe ni ọpọlọpọ igba. Siwaju sii, awọn isọfunni oniṣiro fihan kedere pe lilo iṣọra ti o ba ọgbọn mu—bii dide bẹ́líìtì ijokoo—a maa din ṣiṣeeṣe jàm̀bá aṣekupani kan kù lọna ti o ga. Awọn ohun eelo aabo eyikeyii ha le dá ifẹ inu Ọlọrun ti a ti pinnu ṣaaju duro niti gidi bi?
Bi o ti wu ki o ri, igbagbọ ninu kádàrá a maa nipa lori ẹni ti o gba a gbọ lọna buburu. Ko ha fun awọn igbesẹ alaibikita niṣiiri bi, iru bii gbigbojufo ààlà iwọn iyara sare ati awọn àmì oju popo dá tabi wiwakọ labẹ agbara idari ọti líle tabi oogun? Eyi ti o buru ju, igbagbọ ninu kádàrá sun awọn kan lati dẹbi fun Ọlọrun nigba ti jàm̀bá kan bá kàn wọn. Pẹlu imọlara ibinu ati ainiranwọ, ati nini idaniloju pe Ọlọrun kò bikita, wọn tilẹ le sọ igbagbọ nù paapaa. Rẹgi ni ohun ti akewi naa Emerson sọ pe: “Okunfa apanilẹkun ti o buru julọ ninu igbesi-aye ni igbagbọ ninu Kádàrá tabi Àyànmọ́ ti ko mọ́gbọ́ndání.”
Ṣugbọn ki ni Bibeli sọ nipa awọn àjálù ati jàm̀bá? O ha kọni pe iwọnyi jẹ iṣẹ ọwọ kádàrá bi? Ni afikun, ki ni o sọ nipa awọn ifojusọna wa fun igbala? A ha ni yiyan eyikeyii rárá ninu ọran naa bi?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
“Okunfa apanilẹkun ti o buru julọ ninu igbesi-aye ni igbagbọ ninu Kádàrá tabi Àyànmọ́ ti ko mọ́gbọ́ndání.”—Ralph Waldo Emerson