ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 9/1 ojú ìwé 3-4
  • Àyànmọ́ Ha Ni Ó Ń darí Ìgbésí Ayé Rẹ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àyànmọ́ Ha Ni Ó Ń darí Ìgbésí Ayé Rẹ Bí?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Ha Fi Ìgbàgbọ́ Nínú Àyànmọ́ Kọ́ni Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ṣé Àyànmọ́ Ni àbí Àkọsẹ̀bá Lásán?
    Jí!—1999
  • Wíwádìí Kádàrá Ẹ̀dá
    Jí!—1999
  • Jàm̀bá—Àyànmọ́ ni Tabi Ayika Ipo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 9/1 ojú ìwé 3-4

Àyànmọ́ Ha Ni Ó Ń darí Ìgbésí Ayé Rẹ Bí?

“ALA NÒ DON.” Ní èdè Bambara ti Mali, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, gbólóhùn yìí túmọ̀ sí, “Iṣẹ́ Ọlọ́run ni.” Àwọn ọ̀rọ̀ apàfiyèsí bí èyí wọ́pọ̀ gidigidi ní apá ibí yìí nínú ayé. Ní èdè Wolof, wọ́n máa ń sọ pé, “Yallah mo ko def” (Ọlọ́run ló ṣe é). Àti ní èdè ìbílẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti àwọn Dogon, wọ́n máa ń wí pé, “Ama biray” (Àmúwá Ọlọ́run ni).

Àwọn gbólóhùn wọ̀nyí ní àwọn aláfijọ wọn ní àwọn ilẹ̀ míràn. A sábà máa ń gbọ́ àwọn gbólóhùn bíi, “Àkókò rẹ̀ ló tó” àti, “Ó wu Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni” nígbàkigbà tí ẹnì kan bá kú tàbí tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan bá ṣẹlẹ̀. Ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, a sábà máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ apàfiyèsí bíi “Rírò ni ti ènìyàn, ṣíṣe ni ti Ọlọ́run” sí ará ọkọ̀ akérò, a sì máa ń lẹ̀ ẹ́ mára àwọn ilé ìtajà gẹ́gẹ́ bí àkọlé. Lójú ọ̀pọ̀lọpọ̀, àkànlò èdè ayàwòrán lásán ni wọ́n jẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń gbé ìgbàgbọ́ àyànmọ́ tí ó wọni lọ́kàn ṣinṣin yọ.

Kí tilẹ̀ ni ẹ̀kọ́ àyànmọ́? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The World Book Encyclopedia, túmọ̀ rẹ̀ sí “ìgbàgbọ́ náà pé àwọn ipá ajẹ̀dálọ ní ń pinnu àwọn ìṣẹ̀lẹ̀.” Kí ni “àwọn ipá” wọ̀nyí? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, àwọn ará Bábílónì gbà gbọ́ pé, ìrísí àwọn ìràwọ̀ nígbà ìbí máa ń ní agbára ìdarí ńláǹlà lórí àyànmọ́ olúkúlùkù. (Fi wé Aísáyà 47:13.) Àwọn ará Gíríìkì gbà gbọ́ pé, ọwọ́ àwọn abo-ọlọ́run mẹ́ta tí ń rànwú, tí ń wọ̀n ọ́n, tí ó sì ń gé òwú ìwàláàyè ni àyànmọ́ wà. Ṣùgbọ́n, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ni wọ́n mú èrò náà wá pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni ó ń pinnu àyànmọ́ ẹni!

Fún àpẹẹrẹ, Augustine “Mímọ́” kọ “èrò èké, tí ń ní agbára ìdarí búburú lórí ìṣarasíhùwà ẹni” tí àwọn awòràwọ̀ gbé lárugẹ sílẹ̀. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó jiyàn pé “láti sọ pé Ọlọ́run ń bẹ, kí a sì tún sẹ́ lọ́wọ́ kan náà pé Òún mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ọ̀la, ni ìwà òmùgọ̀ tí ó hàn gbangba jù lọ.” Ó sọ pé kí Ọlọ́run tó lè jẹ́ Olódùmarè ní ti gidi, ó gbọ́dọ̀ “mọ ohun gbogbo kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀” láìsí “ohun kan tí kò ti pinnu rẹ̀ tẹ́lẹ̀.” Síbẹ̀, Augustine fi ìgbónára jiyàn pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti mọ̀ nípa ohun gbogbo tí ń ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí ó tó ṣẹlẹ̀, ẹ̀dá ènìyàn ṣì ní òmìnira ìfẹ́ inú.—The City of God, Ìwé V, Orí 7 sí 9.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Pùròtẹ́sítáǹtì náà, John Calvin, túbọ̀ pa èrò náà láró, ní jíjiyàn pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan wà “tí [Ọlọ́run] ti kádàrá pé kí wọ́n jẹ́ ọmọ àti ajogún ìjọba ọ̀run,” ó kádàrá àwọn mìíràn láti jẹ́ “àwọn tí yóò fara gbá ìbínú rẹ̀”!

Lónìí, a fọwọ́ dan-in dan-in mú ìgbàgbọ́ nínú àyànmọ́ ní ibi púpọ̀ lágbàáyé. Gbé ìrírí Ousmane, ọ̀dọ́mọkùnrin kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, yẹ̀ wò. Ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó já fáfá jù lọ ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe ìdánwò àṣejáde rẹ̀, ó fìdí rẹmi! Kì í ṣe pé ó tún ìdánwò náà ṣe nìkan ni, ṣùgbọ́n àwọn ìdílé àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ tún ń dá ṣíọ̀ rẹ̀. Ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan gbìyànjú láti tù ú nínú nípa sísọ pé, ó wu Ọlọ́run bẹ́ẹ̀ ni. Ìyá Ousmane pẹ̀lú dá àyànmọ́ lẹ́bi fún bí ọmọ rẹ̀ ṣe fìdí rẹmi.

Lákọ̀ọ́kọ́, Ousmane láyọ̀ nítorí bí wọ́n ṣe gbìyànjú láti tù ú nínú. Ó ṣe tán, bí ó bá kúkú jẹ́ pé ó wu Ọlọ́run pé kí ó fìdí rẹmi ni lóòótọ́, kò sí ohun tí òun ì bá lè ṣe láti yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n bàbá rẹ̀ ní èrò tí ó yàtọ̀. Ó sọ fun Ousmane pé òun ni ó jẹ̀bi bí ó ṣe fìdí rẹmi—kì í ṣe Ọlọ́run. Ousmane fìdí rẹmi nítorí pé ó ń fi ẹ̀kọ́ rẹ̀ ṣeré.

Ní rírí i pé ìgbàgbọ́ òun nínú àyànmọ́ ń mì, Ousmane pinnu láti fúnra rẹ̀ wádìí ọ̀ràn náà. A ké sí ọ nísinsìnyí láti ṣe ohun kan náà, nípa gbígbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yẹ̀ wò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́