ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 4/1 ojú ìwé 27-29
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìṣòro Kárí Ayé Kan
    Jí!—1996
  • Sísan Ohun Ti Kesari Padà fún Kesari
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 4/1 ojú ìwé 27-29

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ni ó yẹ kí Kristẹni kan ṣe nígbà tí a bá pè é fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́?

Ní àwọn ilẹ̀ kan, ètò ìdájọ́ máa ń lo ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tí a yàn láti inú àwọn aráàlú. Níbi tí èyí bá wà, Kristẹni kan gbọ́dọ̀ pinnu bí òun yóò ṣe dáhùn pa dà nígbà tí a bá pàṣẹ pé kí ó wá fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́. Ọ̀pọ̀ Kristẹni ti fi ẹ̀rí ọkàn tí ó tọ́ parí èrò pé, ìlànà Bíbélì kò fagi lé fífarahàn, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò ṣe tẹ̀ lé àṣẹ ìjọba Bábílónì láti fara hàn ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, àti bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù lábẹ́ àṣẹ àwọn aláṣẹ Róòmù. (Dáníẹ́lì 3:1-12; Lúùkù 2:1-4) Ṣùgbọ́n, àwọn kókó abájọ kan wà tí àwọn Kristẹni olóòótọ́ ọkàn ní láti gbé yẹ̀ wò.

Kì í ṣe ibi gbogbo ni a ti ń lo ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́. Ní àwọn ilẹ̀ kan, adájọ́ amọṣẹ́dunjú tàbí àwùjọ àwọn adájọ́ ni wọ́n máa ń pinnu ẹjọ́ tí ó kan ẹ̀tọ́ ẹni àti ti ìwà ọ̀daràn. Níbò míràn, ohun tí a mọ̀ sí òfin àwọn ìdájọ́ àtẹ̀yìnwá ni ó borí, ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ sì jẹ́ apá kan ètò ìdájọ́. Síbẹ̀, èrò oréfèé ni ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ní nípa bí a ṣe ń yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, àti ohun tí wọ́n ń ṣe. Nítorí náà, mímọ kúlẹ̀kúlẹ̀ wọn yóò ṣèrànwọ́ yálà o dojú kọ iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tàbí o kò dojú kọ ọ́.

Àwọn ènìyàn Ọlọ́run mọ̀ pé Jèhófà ni Onídàájọ́ Gíga Jù Lọ. (Aísáyà 33:22) Ní Ísírẹ́lì ìgbàanì, àwọn ọkùnrin onírìírí tí wọ́n jẹ́ adúróṣánṣán, tí wọn kì í sì í ṣe ojúsàájú ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onídàájọ́ láti yanjú aáwọ̀, kí wọ́n sì pinnu àwọn ìbéèrè nípa òfin. (Ẹ́kísódù 18:13-22; Léfítíkù 19:15; Diutarónómì 21:18-21) Nígbà tí Jésù fi wà lórí ilẹ̀ ayé, Sànhẹ́dírìn, kóòtù gíga jù lọ ti àwọn Júù, ni ó ń bójú tó ọ̀ràn ìdájọ́. (Máàkù 15:1; Ìṣe 5:27-34) Kò sí ètò kankan fún gbáàtúù Júù láti kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tí ń rí sí ẹ̀tọ́ ẹni.

Àwọn ilẹ̀ míràn ń lo ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tí àwọn tí ń kópa nínú rẹ̀ jẹ́ aráàlú. Ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹlẹ́ni 501 ni ó gbẹ́jọ́ Socrates. Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Róòmù pẹ̀lú ní ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tí ń gbẹ́jọ́, bí a tilẹ̀ fòpin sí èyí lábẹ́ ìṣàkóso àwọn olú ọba. Lẹ́yìn náà, Ọba Henry Kẹta ti England ṣètò pé kí àwọn aládùúgbò ọ̀daràn kan máa dájọ́ rẹ̀. Èrò náà ni pé, níwọ̀n bí wọ́n ti mọ ọ̀daràn náà, ìdájọ́ wọn yóò dára ju ti ìlànà tí òun yóò ti máa gbìyànjú láti fẹ̀rí hàn pé òun kò mọwọ́ mẹsẹ̀ nípa jíjà tàbí líla àdánwò agbonijìgì kan já. Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ètò ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ yí pa dà di ètò kan tí àwùjọ àwọn aráàlú kan ti ń gbẹ́jọ́, tí wọ́n sì ń dájọ́ lórí ẹ̀rí tí wọ́n bá rí. Adájọ́ amọṣẹ́dunjú kan yóò máa tọ́ wọn sọ́nà lórí àwọn ẹ̀rí tí wọ́n rí.

Ìyàtọ̀ wà nínú oríṣi ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tí ó wà, iye àwọn tí ń kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, àti ohun tí dídórí ìpinnu ìdájọ́ wé mọ́. Fún àpẹẹrẹ, ní United States, ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹlẹ́ni púpọ̀ tí ó ní mẹ́ńbà 12 sí 23 ń pinnu bóyá ẹ̀rí tí ó tó wà láti fẹ̀sùn kan ẹnì kan fún híhu ìwà ọ̀daràn; kì í pinnu bóyá ẹni náà jẹ̀bi tàbí ó jàre. Bákan náà, nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ atẹlẹ̀múyẹ́ (ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tí ń wádìí ọ̀ràn), ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà máa ń yẹ ẹ̀rí wò láti pinnu bóyá ní tòótọ́ ni a hu ìwà ọ̀daràn kan.

Nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn bá ń ronú nípa ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, wọ́n máa ń ní ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni 12 tí wọ́n jẹ́ aráàlú nínú ìgbẹ́jọ́ kan lọ́kàn—yálà aáwọ̀ ti ẹ̀tọ́ ẹni tàbí ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn—tí wọ́n ń gbọ́ ẹ̀rí láti pinnu ẹ̀bi tàbí àre. Ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ alábẹ ṣékélé ní èyí jẹ́, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹlẹ́ni púpọ̀. Ní gbogbogbòò, kóòtù yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n yàn láti inú ìwé orúkọ àwọn olùdìbò, àwọn awakọ̀ tí wọ́n ní ìwé àṣẹ, àti irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, láti fara hàn fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́. A lè já àwọn kan lójú ẹsẹ̀, irú àwọn tí wọ́n ti jẹ̀bi ìwà ọ̀daràn rí àti àwọn tí ọpọlọ wọn kò gbé irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Ó sinmi lórí òfin àdúgbò, àwọn mìíràn—irú bí àwọn dókítà, àlùfáà, amòfin, tàbí àwọn olókòwò kéékèèké—lè sọ pé kí a yọ̀ǹda àwọn. (A lè yọ̀ǹda àwọn kan nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wọn, lọ́nà lílágbára ta ko iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́.) Ṣùgbọ́n, àwọn aláṣẹ túbọ̀ ń dín àwọn ohun tí ó lè mú kí a yọ̀ǹda ẹni kù, kí ó baà lè jẹ́ pé gbogbogbòò ni yóò di dandan fún láti ṣiṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, bóyá léraléra ní ọ̀pọ̀ ọdún.

Kì í ṣe gbogbo àwọn tí ó bá wá fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ni ó máa ń pọn dandan fún láti kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ nínú ìgbẹ́jọ́ kan. Láti inú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí a pè fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, a óò fi ètò èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ yan àwọn díẹ̀ nínú wọn bí àwọn tí ó ṣeé ṣe kí a nílò gẹ́gẹ́ bí olùkópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ nínú ẹjọ́ kan. Lẹ́yìn náà, adájọ́ náà yóò dárúkọ àwọn tí ọ̀ràn kàn àti agbẹjọ́rò wọn, yóò sì sọ bí ẹjọ́ wọ́n ṣe rí. Òun àti àwọn agbẹjọ́rò náà yóò ṣàyẹ̀wò ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó ṣeé ṣe kí ó wà nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà. Àkókò yí ni ẹnì kan lè sọ̀rọ̀, bí ó bá ni ìdí tí ó jẹ mọ́ ti ẹ̀rí ọkàn, tí kò fi ní lè ṣe iṣẹ́ náà, nítorí bí ẹjọ́ náà ti rí.

Ó pọn dandan láti dín àwùjọ náà kù sí iye àwọn tí yóò jókòó gan-an jálẹ̀ àkókò ìgbẹ́jọ́ náà. Adájọ́ náà yóò yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣeé ṣe kí a nàka ṣíṣe ojúsàájú sí kúrò, nítorí ọkàn ìfẹ́ tí ó ṣeé ṣe kí ó ní nínú ẹjọ́ náà. Bákan náà, àwọn agbẹjọ́rò fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ọ̀ràn kàn ní ẹ̀tọ́ láti yọ díẹ̀ lára ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà kúrò. Ẹnikẹ́ni tí a bá yọ kúrò nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ yẹn yóò pa dà sí ara ọ̀pọ̀ àwọn tí ń dúró de yíyàn elétò èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ mìíràn fún àwọn ẹjọ́ mìíràn. Àwọn Kristẹni kan nínú ipò yí ti lo àkókò náà láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́, iṣẹ́ ẹnì kan gẹ́gẹ́ bí olùkópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ yóò parí, yálà ó ti kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ tàbí kò tí ì ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn Kristẹni ń làkàkà ‘láti má ṣe máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn,’ kí wọ́n má sì ṣe máa tojú bọ “ọ̀ràn àwọn ẹlòmíràn.” (Tẹsalóníkà Kíní 4:11; Pétérù Kíní 4:15) Nígbà tí Júù kan ní kí Jésù dájọ́ ọ̀ràn kan nípa ogún, ó fèsì pé: “Ọkùnrin yìí, ta ni yàn mí sípò bí onídàájọ́ tàbí olùfètòpín nǹkan lé yín lórí?” (Lúùkù 12:13, 14) Jésù wá láti polongo ìhìn rere Ìjọba, kì í ṣe láti wá ṣèdájọ́ lórí ọ̀ràn òfin. (Lúùkù 4:18, 43) Èsì Jésù ti lè sún ọkùnrin náà láti lo ọ̀nà ìyanjú-aáwọ̀ tí a là sílẹ̀ nínú Òfin Ọlọ́run. (Diutarónómì 1:16, 17) Bí àwọn kókó wọ̀nyẹn tilẹ̀ jẹ́ òtítọ́, dídáhùnpadà sí àṣẹ láti fara hàn fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ yàtọ̀ sí títojúbọ ọ̀ràn ọlọ́ràn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ bá ọ̀ràn àwọn alábàákẹ́gbẹ́ Dáníẹ́lì mẹ́tẹ̀ẹ̀ta mu. Ìjọba Bábílónì pàṣẹ fún wọn láti wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn kò sì ré Òfin Ọlọ́run kọjá. Ohun tí wọ́n ṣe lẹ́yìn náà jẹ́ ọ̀ràn míràn pátápátá, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti fi hàn.—Dáníẹ́lì 3:16-18.

Lẹ́yìn tí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti kúrò lábẹ́ Òfin Mósè, wọ́n ní láti máa bá àwọn kóòtù ayé tí ó wà ní onírúurú ilẹ̀ lò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ “àwọn ẹni mímọ́” ní Kọ́ríńtì láti yanjú aáwọ̀ wọn láàárín ìjọ. Nígbà tí ó ń tọ́ka sí àwọn onídàájọ́ nínú àwọn kóòtù ayé gẹ́gẹ́ bí “àwọn aláìṣòdodo ènìyàn,” Pọ́ọ̀lù kò sẹ́ pé irú àwọn kóòtù ayé bẹ́ẹ̀ ni ipa yíyẹ tí wọ́n ń kó nínú yíyanjú àwọn àlámọ̀rí tí kì í ṣe ti ìsìn. (Kọ́ríńtì Kíní 6:1) Ó gbèjà ara rẹ̀ nínú ètò ìṣèdájọ́ ti ilẹ̀ Róòmù, àní ní pípẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sọ́dọ̀ Késárì pàápàá. Kì í ṣe pe àwọn kóòtù ayé kò tọ́ rárá.—Ìṣe 24:10; 25:10, 11.

Àwọn kóòtù ayé jẹ́ iṣẹ́ “àwọn aláṣẹ onípò gíga.” Irú àwọn bẹ́ẹ̀ “ni a gbé dúró sí àwọn ipò wọn aláàlà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run,” wọ́n ń ṣe òfin, wọ́n sì ń rí i pé ó múlẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni ó jẹ́ sí ọ fún ire rẹ. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń ṣe ohun tí ó burú, wà nínú ìbẹ̀rù: nítorí kì í ṣe láìsí ète ni ó gbé idà; nítorí òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni, olùgbẹ̀san láti fi ìrunú hàn jáde sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣèwàhù.” Àwọn Kristẹni kì í ‘ta ko aláṣẹ’ bí ó ti ń ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ tí ó jẹ mọ́ òfin, nítorí wọn kò fẹ́ “mú ìdúró kan lòdì sí i,” kí wọ́n sì gba ìdájọ́.—Róòmù 13:1-4; Títù 3:1.

Ní mímú ojú ìwòye wọn wà déédéé, ó yẹ kí àwọn Kristẹni ṣàgbéyẹ̀wò bóyá wọ́n lè juwọ́ sílẹ̀ fún àwọn ohun kan tí Késárì fi dandan béèrè. Pọ́ọ̀lù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi àwọn ohun ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn [àwọn aláṣẹ onípò gíga] fún wọn, fún ẹni tí ó béèrè fún owó orí, owó orí; fún ẹni tí ó béèrè fún owó òde, owó òde; fún ẹni tí ó béèrè fún ìbẹ̀rù, irúfẹ́ ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀.” (Róòmù 13:7) Ìyẹn ṣe tààràtà ní ti owó orí. (Mátíù 22:17-21) Bí Késárì bá sọ pé àwọn aráàlú gbọ́dọ̀ yọ̀ǹda àkókò wọn àti agbára wọn láti tún ojú ọ̀nà ṣe tàbí láti ṣe iṣẹ́ mìíràn tí ó wà lára iṣẹ́ Késárì, Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ pinnu bóyá òun yóò gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 5:41.

Àwọn Kristẹni kan ti wo iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bíi fífi àwọn ohun ti Késárì fún Késárì. (Lúùkù 20:25) Nínú iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, iṣẹ́ wọn ni láti gbọ́ ẹ̀rí, kí wọ́n sì fúnni ní èrò aláìlábòsí ọkàn lórí àwọn òkodoro òtítọ́ tàbí kókó òfin. Fún àpẹẹrẹ, lórí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹlẹ́ni púpọ̀, àwọn tí ń kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà yóò pinnu bóyá ẹ̀rí náà tó láti mú kí a mú ẹnì kan wá fún ìgbẹ́jọ́; wọn kì í pinnu ẹ̀bi. Nínú ìgbẹ́jọ́ gan-an ńkọ́? Nínú ẹjọ́ ti ẹ̀tọ́ ẹni, ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà lè ní kí a sanwó gbà-máà-bínú tàbí owó ìtanràn. Nínú ẹjọ́ ìwà ọ̀daràn, wọ́n ní láti pinnu bóyá ẹ̀rí náà ti ìdájọ́ ẹ̀bi lẹ́yìn. Nígbà míràn, wọ́n máa ń dámọ̀ràn irú ìfìyàjẹni tí òfin là sílẹ̀ tí a lè lò. Lẹ́yìn náà, ìjọba yóò lo ọlá àṣẹ rẹ̀ “láti fi ìrunú hàn jáde sí ẹni tí ń fi ohun tí ó burú ṣèwàhù,” tàbí “láti fi ìyà jẹ àwọn aṣebi.”—Pétérù Kíní 2:14.

Bí Kristẹni kan kò bá rò pé ẹ̀rí ọkàn òun yọ̀ǹda fún òun láti kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ ńkọ́? Bíbélì kò mẹ́nu kan kíkópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, nítorí náà, òun kò lè sọ pé, ‘Ó lòdì sí ìsìn mi láti kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́.’ Ó sinmi lórí ẹjọ́ náà, ó lè sọ pé kíkópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ fún ẹjọ́ kan pàtó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn òun. Ìyẹn lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, bí ẹjọ́ kan bá ní í ṣe pẹ̀lú ìwà ìbálòpọ̀, ìṣẹ́yún, ìṣìkàpànìyàn, tàbí ọ̀ràn míràn tí ìmọ̀ Bíbélì ti tún ojú ìwòye rẹ̀ ṣe, kì í ṣe òfin ti ayé lásán. Ṣùgbọ́n, ní ti gidi, ó ṣeé ṣe ní tòótọ́ pé, kí ìgbẹ́jọ́ tí a yàn án sí máà ní í ṣe pẹ̀lú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.

Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú yóò tún ronú lórí bóyá òun yóò pín nínú ẹ̀bi èyíkéyìí fún ìyà tí àwọn adájọ́ fi jẹni. (Fi wé Jẹ́nẹ́sísì 39:17-20; Tímótì Kíní 5:22.) Bí ìdájọ́ ẹ̀bi kan bá ní àṣìṣe, tí a sì fìyà ikú jẹ ẹni náà, Kristẹni kan tí ó wà lára ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ náà yóò ha pín nínú ẹ̀bi náà bí? (Ẹ́kísódù 22:2; Diutarónómì 21:8; 22:8; Jeremáyà 2:34; Mátíù 23:35; Ìṣe 18:6) Nígbà ìgbẹ́jọ́ Jésù, Pílátù fẹ́ kí ‘ọwọ́ òun mọ́ kúrò nínú ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí.’ Àwọn Júù sọ láìlọ́ tìkọ̀ pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí wa àti sórí àwọn ọmọ wa.”—Mátíù 27:24, 25.

Bí Kristẹni kan bá fara hàn fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ìjọba, ṣùgbọ́n nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀, tí ó kọ̀ láti jókòó fún ẹjọ́ kan láìka ìrinkinkin adájọ́ náà sí, Kristẹni náà ní láti múra tán láti dojú kọ àbájáde rẹ̀—ì báà jẹ́ owó ìtanràn tàbí ìfisẹ́wọ̀n.—Pétérù Kíní 2:19.

Ní àbárèbábọ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan tí ó bá dojú kọ iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ gbọ́dọ̀ pinnu ipa ọ̀nà tí òun yóò tẹ̀ lé, lórí ìmọ̀ rẹ̀ nípa Bíbélì àti ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. Àwọn Kristẹni kan ti fara hàn fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́, wọ́n sì ti kópa nínú ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ mélòó kan. Àwọn mìíràn ti ní láti kọ̀ jálẹ̀ àní lójú ìjìyà pàápàá. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ni yóò fúnra rẹ̀ pinnu ohun tí yóò ṣe, kò sì yẹ kí àwọn mìíràn ṣe lámèyítọ́ ìpinnu rẹ̀.—Gálátíà 6:5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́