ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/22 ojú ìwé 3-6
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìṣòro Kárí Ayé Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìṣòro Kárí Ayé Kan
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àṣìlò Agbára
  • Báwo Ni Ó Ṣe Gbilẹ̀ Tó?
  • Àmì Àwọn Àkókò
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?
    Jí!—2000
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ
    Jí!—1996
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ibi Iṣẹ́ Àbí Ojú Ogun?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/22 ojú ìwé 3-6

Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìṣòro Kárí Ayé Kan

IṢẸ́ ti di ohun tí ń kó jìnnìjìnnì bá ọ̀dọ́ akọ̀wé kan tí ń jẹ́ Rena Weeks. Òtítọ́ ni pé ilé iṣẹ́ agbẹjọ́rò tó gbà á síṣẹ́ ní orúkọ tí ó yááyì àti ọ̀pọ ọ́fíìsì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lé ní 24. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀, ó ń ṣiṣẹ́ fún ọkùnrin kan tí ó máa ń fẹ́ láti gbá a mú tàbí fọwọ́ kàn án. Ó máa ń fi ọ̀rọ̀ àìnítìjú, amúniròròkurò, kún ìwà atẹ́nilógo náà.

Ní àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn obìnrin tí ó bá wà ní irú ipò yìí kò ní ọ̀nà àbáyọ kankan—yàtọ̀ sí bóyá kí wọ́n fiṣẹ́ sílẹ̀. Àwọn alábòójútó ilé iṣẹ́ ì bá ti wulẹ̀ parí ọ̀rọ̀ sí pé ‘kò sí ẹlẹ́rìí.’ Àní àwọn tí ọ̀rọ̀ obìnrin náà bá tilẹ̀ fẹ́ wọ̀ létí pàápàá ì bá ti gbọ̀n ọ́n nù ní sísọ pé, ‘Èwo ni ojú ò rí rí nínú ìyẹn?’ Ṣùgbọ́n ìgbà ti yí padà. Rena Weeks ṣe ju wíwulẹ̀ bínú fiṣẹ́ sílẹ̀ lọ. Ó pẹjọ́.

Ìgbìmọ̀ elétí gbáròyé kan ní United States dájọ́ pé kí ọ̀gá rẹ̀ àtijọ́ san 50,000 dọ́là fún un nítorí wàhálà tí ó kó bá èrò ìmọ̀lára rẹ̀, kí ó sì san 225,000 dọ́là bí owó ìtánràn. Lẹ́yìn náà, nínú ìgbésẹ̀ kan tí ó jọ gbogbo ilé iṣẹ́ okòwò àti ilé iṣẹ́ òfin kárí ayé lójú, ìgbìmọ̀ náà pàṣẹ pé kí ilé iṣẹ́ òfin náà san gbankọgbì iye owó tí ó jẹ́ 6.9 mílíọ̀nù dọ́là bí ìtánràn nítorí pé ó kùnà láti ṣàtúnṣe ìṣòro náà!

Ẹjọ́ Weeks kì í ṣe aláìláfijọ lọ́nàkọnà. Ìpẹ̀jọ́ mìíràn láìpẹ́ yìí kan ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìtajà ẹ̀dínwó orílẹ̀-èdè United States. Òṣìṣẹ́ kan tí ń jẹ́ Peggy Kimzey sọ pé alábòójútó iṣẹ́ òún ti bá òun sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ aṣa nípa ìbálòpọ̀. Ní 1993, Peggy Kimzey kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀, ó sì pẹjọ́. Wọ́n fún un ní 35,000 dọ́là nítorí ìtẹ́lógo àti làásìgbò èrò orí, pa pọ̀ pẹ̀lú dọ́là 1 àfiṣàpẹẹrẹ fún owó ọ̀yà tí ó ti pàdánù. Ìgbìmọ̀ elétí gbáròyé náà tún pinnu pé agbanisíṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́ ti dá àyíká iṣẹ́ tí kò fara rọ sílẹ̀ nípa fífàyè gba ìfòòró náà. Ìjìyà rẹ̀? Àádọ́ta mílíọ̀nù dọ́là owó ìtánràn!

Ìwé ìròyìn Men’s Health sọ pé: “Àwọn ẹjọ́ ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹni ti ń gbilẹ̀ bíi bakitéríà. Ní 1990, àjọ EEOC [Àjọ Àǹfààní Ìgbanisíṣẹ́ Dídọ́gba] bójú tó 6,127 irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀; nígbà tí ó fi di èṣín [1993] iye náà lọ́dọọdún ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po méjì, ó jẹ́ 11,908.”

Àṣìlò Agbára

Nígbà tí ìròyìn iye owo rẹpẹtẹ tí ń múni kọ háà, tí àwọn ìgbìmọ̀ elétí gbáròyé ń bù fúnni, ń gba ojú ìwé ìròyìn, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, iye ẹjọ́ díẹ̀ ní ń délé ẹjọ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn òjìyà ń fara da ìtẹ́nilógo láìpariwo—wọ́n di ọmọ ayò nínú eré ayò agbára àti ìkójìnnìjìnnìbáni tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọ́fíìsì, ní òpópó, nínú ọkọ̀, nílé oúnjẹ, àti nílé iṣẹ́. Nígbà míràn, a ń fipá múni ní tààràtà láti ní ìbálòpọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà púpọ̀ jù lọ, ìfìbálòpọ̀ lọni náà máa ń wá lọ́nà ìṣe ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, síbẹ̀, tí ń fi àìnítìjú hàn: ìfọwọ́kàn tí kò tọ́ tàbí tí a kò fẹ́, ọ̀rọ̀ rírùn, sísejú síni.

Òtítọ́ ni pé àwọn kan kò fara mọ́ pípe irú ìwà bẹ́ẹ̀ ní ìfòòró, pẹ̀lú àlàyé pé ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà ìgbìyànjú àwọn ọkùnrin kan láti jèrè àfiyèsí ẹ̀yà òdì kejì lọ́nà tí kò wọ́pọ̀ ni. Ṣùgbọ́n bíi ti òǹkọ̀wé Martha Langelan, ọ̀pọ̀ kò fara mọ́ irú ìgbìdánwò láti wá àwáwí fún ìwà ìmúnibínú bẹ́ẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Kì í ṣe ìfẹ́sọ́nà àìlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, tàbí ìfẹ́sọ́nà àìlajú, tàbí ìfẹ́sọ́nà aláwàdà, tàbí ìfẹ́sọ́nà ‘àṣìlóye.’ Kì í ṣe pẹ̀lú ète wíwu obìnrin; ìwà tí ń ṣiṣẹ́ fún ète ọ̀tọ̀ pátápátá gbáà ni. Bíi ti ìfipábánilòpọ̀, a ṣètò fífìbálòpọ̀ fòòró ẹni láti fipá mú obìnrin, kì í ṣe láti wú wọn lórí. . . . [Ó] jẹ́ àfihàn agbára.” Bẹ́ẹ̀ ni, lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìbálò tí kò tọ́ bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ ọ̀nà òǹrorò míràn nípa èyí tí “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.”—Oniwasu 8:9; fi wé Oniwasu 4:1.

Àwọn obìnrin kì í hùwà padà sí ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹni pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìmọ̀lára tí ó bẹ̀rẹ̀ láti orí ìríra àti ìbínú sí ìtẹ̀lóríba àti ìtẹ́lógo. Ẹnì kan tí ó ṣẹlẹ̀ sí rí rántí pé: “Ipò náà bà mí jẹ́. Mo pàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé mi, ìgbọ́kànlé mi, ọ̀wọ̀ ara ẹni mi, àti ìlépa iṣẹ́ ìgbé ayé mi. Irú ẹni tí mo jẹ́ yí padà lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Mo ti jẹ́ ẹni tí ń fìgbà gbogbo túra ká tẹ́lẹ̀. Mo wá di oníbìínú, ẹni tí kì í yára mọ́ni, àti onítìjú.” Nígbà tí ẹni tí ń ṣe é síni bá sì wá jẹ́ agbanisíṣẹ́ tàbí ẹlòmíràn tí ó wà nípò agbára, ìfòòró túbọ̀ máa ń dani lọ́kàn rú.

Kò yani lẹ́nu nígbà náà pé, àwọn ilé ẹjọ́ ti bẹ̀rẹ̀ sí í fìyà jẹ àwọn tí ń fìbálòpọ̀ fòòró ẹni, tí wọ́n sì ń sanwó gbà máà bínú fún àwọn òjìyà ìpalára. Láti ìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ United States ti gbà pé irú ìfìyàjẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú, a ti ń béèrè pé kí àwọn agbanisíṣẹ́ máa jẹ́ kí ibi iṣẹ́ wọ́n jẹ́ èyí tí kì í “nini lára tàbí múni bínú.”

Àwọn ilé iṣẹ́ tí ó bá fàyè gba fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni lè fara gbá ìwà àìtọ́ àwọn òṣìṣẹ́, pípa ibi iṣẹ́ jẹ gan-an, ìlọsílẹ̀ àṣeyọrí iṣẹ́, àti iye ìfiṣẹ́sílẹ̀ gíga—kí a má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àgbákò ìnáwó, bí àwọn òjìyà ìpalára bá pinnu láti pẹjọ́.

Báwo Ni Ó Ṣe Gbilẹ̀ Tó?

Báwo gan-an ni fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni ṣe gbilẹ̀ tó? Ìwádìí fi hàn pé, ó ti ṣẹlẹ̀ sí iye tí ó ju ìdajì lára àwọn obìnrin tí ń ṣiṣẹ́ ní United States lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwé kan wí pé: “Ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹní jẹ́ ìṣòro kan tí ó gbilẹ̀. Ó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn obìnrin ní gbogbo ibi iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe, bẹ̀rẹ̀ láti orí àwọn agbóúnjẹfúnni dé orí àwọn ọ̀gá pátápátá lẹ́nu iṣẹ́. Ó ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìpele ètò iṣẹ́ àti ní gbogbo onírúurú okòwò àti iṣẹ́ àmúṣe.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìṣòro náà kò mọ sí United States nìkan. Ìwé Shockwaves: The Global Impact of Sexual Harassment, tí Susan L. Webb kọ, mẹ́nu ba àkọsílẹ̀ oníṣirò tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:a

KÁNÁDÀ: “Ìwádìí kan fi hàn pé ìpín 4 nínú 10 àwọn obìnrin sọ pé wọ́n ń fìbálòpọ̀ fòòró àwọn níbi iṣẹ́.”

JAPAN: “Ìwádìí kan tí a ṣe ní August 1991 fi hàn pé ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ti nírìírí” ìfòòró lẹ́nu iṣẹ́. “Ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé wọ́n fìbálòpọ̀ fòòró àwọn lọ́nà ibi iṣẹ́.”

AUSTRIA: “Ìwádìí 1986 kan fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 31 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí wọ́n ròyìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìfòòró lílé kenkà.”

ILẸ̀ FARANSÉ: “Ìwádìí kan ní 1991 . . . ṣàwárí pé ìpín 21 nínú ọgọ́rùn-ún lára 1,300 obìnrin tí a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò sọ pé àwọn fúnra àwọ́n ti fojú winá ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹni.”

NETHERLANDS: Ìwádìí kan fi hàn pé “ìpín 58 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí ó lóhùn [sí ìwádìí náà] sọ pé àwọn fúnra àwọ́n ti fojú winá ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹni.”

Àmì Àwọn Àkókò

Ó dájú pé ìfìbálòpọ̀ lọni àti ìfòòró ẹni níbi iṣẹ́ kì í ṣe ohun tuntun. Àwọn obìnrin—àti àwọn ọkùnrin nígbà míràn—máa ń bá ara wọn nínú ìjẹniníyà bẹ́ẹ̀, àní ní àwọn àkókò tí a ń kọ Bibeli. (Genesisi 39:7, 8; Rutu 2:8, 9, 15) Ṣùgbọ́n ó jọ pé irú ìṣìwàhù bẹ́ẹ̀ gbòde kan lónìí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ó ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Ìdí kan ni pé àwọn obìnrin ti kó sẹ́nu iṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu. Nípa bẹ́ẹ̀, obìnrin púpọ̀ sí i wà nínú ipò tí irú ìfìyàjẹni bẹ́ẹ̀ ti lè ṣẹlẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí tí ó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ ni ohun tí Bibeli sọ tẹ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn pé: “Rántí èyí! Àwọn àkókò ìnira yóò wà ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àwọn ènìyàn yóò mọ ti ara wọn nìkan, wọn yóò jẹ́ oníwọra, afúnnu, àti ajọra-ẹni-lójú; wọn yóò máa búni . . . ; wọn yóò jẹ́ aláìnínúure, aláìláàánú, afọ̀rọ̀ èké bani jẹ́, oníwà ipá, àti òǹrorò.” (2 Timoteu 3:1-3, Today’s English Version) Ìgbòdekan ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹní wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀rí tí ń ṣẹlẹ̀ kan pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ń ní ìmúṣẹ lóde òní. Ó dùn mọ́ni pé ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Men’s Health sọ pé “ìbísí nínú ẹjọ́ fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹní ti kẹ́gbẹ́ rìn pẹ̀lú ìwólulẹ̀ ìmọ̀wàáhù lápapọ̀. Àìmọ̀wàáhù wà níbi gbogbo.”

Ìgbòdekan ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹni tún ń fi “ọ̀nà ìhùwà tuntun,” tí ó yára gbilẹ̀ ní àwọn ọdún 1960, hàn. Ìbìṣubú àwọn ààlà ìwà híhù tí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ ti mú àìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àti ìmọ̀lára àwọn mìíràn lọ́nà gígadabú lọ́wọ́. Ohun yòówù kí ó fà á, fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹní jẹ́ òtítọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò ríbi yẹ̀ ẹ́ sí níbi iṣẹ́. Kí ni tọkùnrin-tobìnrín lè ṣe láti dáàbò bo ara wọn? Ìgbà kankan yóò ha wà tí ìfòòró ẹni kì yóò sí níbi iṣẹ́ mọ́ bí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò máa ń yàtọ̀ síra, nítorí pé àwọn olùwádìí máa ń lo ọ̀nà ìwádìí àti ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ìfìbálòpọ̀ fòòró ẹni.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìyàtọ̀ Àròsọ àti Òkodoro Òtítọ́

Àròsọ: A ti ń ròyìn fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni jù. Àṣà ìgbàlódé mìíràn lásán ni, tí àṣejù ìpolongo àti èrò ìmọ̀lára ilé iṣẹ́ ìròyìn mú jáde.

Òkodoro Òtítọ́: Ní gbogbogbòò, ríròyìn ìjìyà ìpalára kò ṣe obìnrin kan láǹfààní lọ títí. Ní ti gidi, ìwọ̀n kéréje àwọn obìnrin (ìpín 22 nínú ọgọ́rùn-ún gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan ṣe fi hàn) ní ń sọ fún ẹnì kankan pé a fòòró àwọn. Ìbẹ̀rù, ìmójútìbáni, ìdára ẹni lẹ́bi, ìdàrú ọkàn, àti àìmọ̀kan nípa ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin ń pa ọ̀pọ̀ obìnrin lẹ́nu mọ́. Ọ̀pọ̀ amọṣẹ́dunjú tipa báyìí gbà pé, a kò ròyìn fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni tó!

Àròsọ: Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn obìnrin ń gbádùn àfiyèsí náà. Àwọn tí ìmọ̀lára wọ́n gbóná jù lásán ní ń ròyìn pé a fòòró àwọn.

Òkodoro Òtítọ́: Ìwádìí fi hàn léraléra pé àwọn obìnrin ń bínú sí irú ìbálò àìlajú bẹ́ẹ̀. Nínú ìwádìí kan, “ó lé ní ìpín méjì nínú márùn-ún àwọn obìnrin náà tí wọ́n sọ pé ó kó àwọn nírìíra tí nǹkan bí ìdá mẹ́ta sì sọ pé ó bí àwọn nínú.” Àwọn mìíràn ròyìn pé àwọ́n nímọ̀lára ìdàníyàn, ìṣeléṣe, àti ìmúninípá.

Àròsọ: Àti ọkùnrin àti obìnrin ń fojú winá rẹ̀ bákan náà.

Òkodoro Òtítọ́: Àwọn olùwádìí fún Ẹgbẹ́ Àpapọ̀ Àwọn Obìnrin Lẹ́nu Iṣẹ́ (ní United States) ròyìn pé “a díwọ̀n rẹ̀ pé ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún ọ̀ràn ìfòòró kan àwọn ọkùnrin tí wọ́n fòòró obìnrin, ìpín 9 nínú ọgọ́rùn-ún jẹ́ láàárín ẹ̀yà kan náà . . . , ìpín 1 péré nínú ọgọ́rùn-ún sì jẹ́ ti àwọn obìnrin tí ń fòòró ọkùnrin.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni kì í ṣe ọ̀ràn ìbálòpọ̀ nìkan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́