ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g00 9/8 ojú ìwé 9-11
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?
  • Jí!—2000
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Èrò Ọlọ́run Nípa Rẹ̀
  • Kí Ló Yẹ Kí N Sọ?
  • Dídènà Àwọn Tó Ń Fẹ́ Báni Tage
  • Bí Wọ́n Bá Fi Ọ̀ranyàn Bá Ọ Tage
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìṣòro Kárí Ayé Kan
    Jí!—1996
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ
    Jí!—1996
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—2000
g00 9/8 ojú ìwé 9-11

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?

“Àwọn ọmọkùnrin máa ń súfèé síni, wọ́n á sì máa kígbe.”—Carla, Ireland.

“Àwọn ọmọbìnrin á máa fóònù ṣáá. Wọ́n á máa gbìyànjú láti mú kí o ṣe tiwọn.”—Jason, United States.

“Á ṣáà máa fọwọ́ kan apá mi, á sì máa gbìyànjú láti di ọwọ́ mi mú.”—Yukiko, Japan.

“Àwọn ọmọbìnrin máa ń sọ ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ sí mi.”—Alexander, Ireland.

“Ọmọkùnrin kan máa ń ké pè mí látinú ọkọ̀ ilé ìwé ní gbogbo ìgbà. Kì í ṣe pé ó fẹ́ fẹ́ mi o. Ó kàn ń bá mi tage ni o.”—Rosilyn, United States.

KÁ MÁA dínjú síni, ká máa fi “ọ̀rọ̀ dídùn pọ́nni” bí oníṣekúṣe, ká máa fi ọ̀rọ̀ rírùn ṣẹ̀fẹ̀, ká máa fọwọ́ kanni bí oníṣekúṣe—bí a bá ń hùwà síni lọ́nà bẹ́ẹ̀, tí kò sì tẹ́ ẹni tí a ń hu ìwà náà sí lọ́rùn, tí a ò sì jáwọ́ nínú híhu ìwà yẹn, irú rẹ̀ la máa ń pè ní fífi ọ̀ranyàn báni tage. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro láti mọ bí ó ti ń ṣẹlẹ̀ tó kárí ayé, ìwádìí fi hàn pé ọ̀pọ̀ àwọn èwe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, tí ọjọ́ orí wọn kò tíì kọjá tọmọ ilé ìwé, ni nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ sí.

Ní ti gidi, kí ni ìbánitage? Ìwé náà, Coping With Sexual Harassment and Gender Bias, tí Dókítà Victoria Shaw, ṣe túmọ̀ rẹ̀ pé ó jẹ́ “dídààmú ẹnì kan nípa fífi ìbálòpọ̀ lọ̀ ọ́ . . . Ó lè jẹ́ lọ́nà tí a lè fojú rí (irú bíi fífi ọwọ́ kan ẹnì kan bí àwọn oníṣekúṣe ti ń ṣe), nípa ọ̀rọ̀ ẹnu (irú bíi sísọ̀rọ̀ nípa ìrísí ẹnì kan, tí ìyẹn kò sì tẹ́ ẹni yẹn lọ́rùn), ó sì lè jẹ́ èyí tí a kò fẹnu sọ.” Nígbà mìíràn, fífi ọ̀ranyàn báni tage máa ń jẹ́ bíbáni sọ̀rọ̀ ìfẹ́ lọ́nà tí kò bójú mu.

Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú títage yìí ní ilé ẹ̀kọ́ sábà máa ń wá látọ̀dọ̀ àwọn ojúgbà rẹ. Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn àgbàlagbà, irú bí àwọn olùkọ́, ló ń hu irú ìwà láìfí bẹ́ẹ̀. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn náà, Redbook, méfò pé iye díẹ̀ lára àwọn olùkọ́ tí a sọ pé wọ́n jẹ̀bi ìwà pálapàla “yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ kíún nínú iye àwọn tó hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ ní ti gidi.”

Àwọn obìnrin—ó sì lè jẹ́ àwọn ọkùnrin nígbà mìíràn—ni wọ́n máa ń hu irú ìwà àìdáa bẹ́ẹ̀ sí, kódà ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì pàápàá. (Jẹ́nẹ́sísì 39:7; Rúùtù 2:8, 9, 15) Bíbélì sì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ohun arínilára yìí yóò ṣẹlẹ̀, ó wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò tó ṣòro yóò wà. Àwọn ènìyàn yóò jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, olójúkòkòrò, agbéraga, onírera; wọ́n á jẹ́ ọ̀yájú . . . ; wọ́n á jẹ́ aláìnínúure, aláìláàánú, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, oníwà-ipá, àti òǹrorò.” (2 Tímótì 3:1-3, Today’s English Version) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe, kódà ó lè ṣẹlẹ̀ pé kí wọ́n fẹ́ fi ọ̀ranyàn bá ọ tage.

Èrò Ọlọ́run Nípa Rẹ̀

A gbà pé kì í ṣe gbogbo èwe ni kò fẹ́ pé kí wọ́n bá àwọn tage. Àwọn kan lè gbádùn rẹ̀—tàbí kí wọ́n kà á sí àpọ́nlé. Ìwádìí kan tí ń dẹ́rù bani tí wọ́n ṣe ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà fi hàn pé lára àwọn tí àwọn kan gbìyànjú láti bá tage, ìpín márùndínlọ́gọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún gbà pé àwọn náà ti gbìyànjú rí láti bá àwọn ẹlòmíràn tage. Àwọn àgbàlagbà kan lè mú kí ìṣòro náà burú sí i nípa fífojú kéré bí ìwà fífi ọ̀ranyàn báni tage ṣe wúwo tó, tí wọ́n á wulẹ̀ wò ó bí erémọdé. Ṣùgbọ́n ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wò ó?

Ní kedere, Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dẹ́bi fún gbogbo onírúurú àṣà fífi ọ̀ranyàn báni tage. Ó sọ fún wa pé kí a má ṣe ‘rakaka lé ẹ̀tọ́’ àwọn ẹlòmíràn nípa kíkọjá ààlà ìfẹ́ ìbálòpọ̀. (1 Tẹsalóníkà 4:3-8) Ní tòótọ́, ó pàṣẹ ní pàtó fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin pé kí wọ́n máa hùwà sí “àwọn ọ̀dọ́bìnrin gẹ́gẹ́ bí arábìnrin pẹ̀lú gbogbo ìwà mímọ́.” (1 Tímótì 5:1, 2) Síwájú sí i, Bíbélì ka “ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn” léèwọ̀. (Éfésù 5:3, 4) Nítorí náà, o lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú, ara rẹ lè kọ̀ ọ́, ọ̀ràn lè tojú sú ọ, kódà o lè nímọ̀lára pé wọ́n fi ọ́ wọ́lẹ̀ bí wọ́n bá gbìyànjú láti fi ọ̀ranyàn bá ọ tage!

Kí Ló Yẹ Kí N Sọ?

Nígbà náà, kí ló yẹ kí o ṣe bí ẹnì kan bá ń dààmú rẹ lọ́nà yìí? Nígbà mìíràn, ṣíṣe wẹ̀dẹ̀wẹ̀dẹ̀ tàbí sísọ̀rọ̀ láìsojú abẹ níkòó wulẹ̀ máa ń jẹ́ kí ẹni tó ń gbìyànjú láti fi ọ̀ranyàn bá ọ tage túbọ̀ tẹra mọ́ ọn ni. Bíbélì sọ fún wa pé nígbà tí aya ọ̀gá Jósẹ́fù fi ọ̀rọ̀ ìfẹ́ lọ̀ ọ́, kì í ṣe pé Jósẹ́fù wulẹ̀ ṣe bí ẹni pé òun kò gbọ́ nǹkan tí obìnrin náà sọ ni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló kọ ìwà pálapàla tí obìnrin náà ń fi lọ̀ ọ́, kò sì fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. (Jẹ́nẹ́sísì 39:8, 9, 12) Lónìí, dídúróṣinṣin, ká sì sọ̀rọ̀ ní tààràtà ṣì jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti yẹra fún àwọn tó máa ń fẹ́ báni tage.

Lóòótọ́, ó lè jẹ́ pé kì í ṣe pé ẹni tó ń dààmú rẹ yẹn fẹ́ mú ọ bínú. Ó lè jẹ́ pé ṣe ni ẹni náà ń gbìyànjú láti fa ojú rẹ mọ́ra, ṣùgbọ́n tí kò ṣe é lọ́nà tó yẹ, tí ó sì wá dà bíi pé ṣe ni ó ń dààmú rẹ. Nítorí náà, má ṣe rò pé ṣe lo gbọ́dọ̀ kan ẹni náà lábùkù kó bàa lè jáwọ́ nínú ìlọ̀kulọ̀ tó fi ń lọ̀ ẹ́. Wíwulẹ̀ sọ̀rọ̀ pé, ‘Mi ò fẹ́ irú ọ̀rọ̀ tí o ń sọ yẹn’ tàbí, ‘Jọ̀wọ́, mú ọwọ́ ẹ kúrò lára mi,’ lè jẹ́ kí ohun tí o ń sọ yé e. Bó ti wù kí o sọ ọ́, má ṣe bíi pé eré lo ń ṣe nígbà tí o bá ń sọ ọ́. Jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́! Ohun tí ọ̀dọ́mọbìnrin Andrea sọ nípa rẹ̀ rèé, ó ní: “Bí o bá sọ ọ́ fún wọn lẹ́rọ̀, tí wọn ò gbọ́, a jẹ́ pé o gbọ́dọ̀ sọ ọ́ fún wọn léle ni. Ó sábà máa ń di dandan pé kí èèyàn sọ ọ́ léle.” Bí o bá sọ ọ́ ní kólekóle pé, ‘Mo ní kóo fi mí sílẹ̀!’ ó lè jẹ́ kí wọ́n ṣe wọ̀ọ̀.

Bí ọ̀ràn ọ̀hún bá wá ń le sí i, má ṣe gbìyànjú láti dá yanjú rẹ̀. Sọ ọ́ fún àwọn òbí rẹ tàbí kí o sọ fún àwọn àgbàlagbà mìíràn tó dàgbà dénú. Wọ́n lè ní àwọn àbá tó gbéṣẹ́ tóo lè fi yanjú ọ̀ràn yẹn. Bó bá wá di kàráǹgídá, wọ́n lè rí i pé ó pọndandan láti jẹ́ kí àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ nípa rẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ojú lè tì ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè jẹ́ kí àwọn tó ń dààmú rẹ jáwọ́ ńbẹ̀.

Dídènà Àwọn Tó Ń Fẹ́ Báni Tage

Dájúdájú, ohun tó dáa jù ni pé kí èèyàn máà jẹ́ kí wọ́n dààmú òun rárá. Kí ló lè ṣèrànwọ́ láti ṣe èyí? Andrea dámọ̀ràn pé: “Má ṣe ṣe bí ẹni pé o nífẹ̀ẹ́ àrà ọ̀tọ̀ sí ẹnì kan. Àwọn yòókù á gbọ́, wọn ò sì ní yéé dààmú rẹ.” Irú aṣọ tí o máa ń wọ̀ lè ṣe ohun púpọ̀ nínú èyí. Ọ̀dọ́mọbìnrin Mara wí pé: “Kì í ṣe pé mo máa ń múra bí arúgbó, ṣùgbọ́n n kì í wọ aṣọ tí yóò pe àfiyèsí sí ara mi.” Kéèyàn máa sọ pé kí wọ́n má fi ìṣekúṣe lọ òun, kóun náà sì máa wọ àwọn aṣọ tí ń rùfẹ́ ìṣekúṣe sókè lè jẹ́ àdàkàdekè. Bíbélì dámọ̀ràn wíwọṣọ “pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú.”—1 Tímótì 2:9.

Irú àwọn ọ̀rẹ́ tí o bá ní tún máa ń ní ipa lórí bí àwọn èèyàn ṣe ń hùwà sí ọ. (Òwe 13:20) Rosilyn wí pé: “Bí àwọn ọmọbìnrin kan lára àwọn tí o ń bá kẹ́gbẹ́ bá fẹ́ kí àwọn ọkùnrin máa bá àwọn ṣeré, àwọn ọkùnrin yẹn lè rò pé gbogbo àwọn ọmọbìnrin tí wọ́n jọ ń kẹ́gbẹ́ yẹn ló fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ohun tí Carla náà sọ nìyẹn, ó ní: “Bí o bá ń bá ẹni tó máa ń gbádùn ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin tàbí tó máa ń fẹ́ kí wọ́n bá òun ṣeré kẹ́gbẹ́, wọ́n á máa dààmú ìwọ náà.”

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Dínà tó bá àwọn ọmọbìnrin Kénáánì kẹ́gbẹ́—níbi tó jẹ́ pé a mọ àwọn obìnrin ibẹ̀ pé wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe. Èyí mú kí wọ́n bá a ṣèṣekúṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 34:1, 2) Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n.” (Éfésù 5:15) Dájúdájú, ṣíṣọ́ra “lójú méjèèjì” nípa bí o ṣe ń múra, nípa bí o ṣe ń sọ̀rọ̀, àti nípa àwọn tí o ń bá kẹ́gbẹ́ lè ṣèrànwọ́ gidigidi láti dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ gbígbìyànjú láti bá ọ tage.

Ṣùgbọ́n, ní ti àwọn Kristẹni ọ̀dọ́, ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ láti dènà ẹni tó lè fẹ́ bá wọn tage jẹ́ nípa jíjẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ ohun tí ẹ̀sìn àwọn fi kọ́ àwọn. Ọ̀dọ́mọkùnrin Timon tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wí pé: “Àwọn ẹlẹgbẹ́ mi mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni mí, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo bí wọn ì bá ṣe fẹ́ máa fi ọ̀ranyàn bá mi tage ni ìyẹn fòpin sí.” Andrea sọ pé: “Bóo bá ti lè sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí ni ẹ́, ọ̀rọ̀ bù ṣe. Wọ́n á mọ̀ pé ohun tóo fi yàtọ̀ sí wọn kò kéré àti pé o kò ní fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn ìwà rere.”—Mátíù 5:15, 16.

Bí Wọ́n Bá Fi Ọ̀ranyàn Bá Ọ Tage

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè gbìyànjú gidigidi, kò sí bí o ṣe lè bọ́ pátápátá lọ́wọ́ àwọn oníláìfí àti oníwà ìbàjẹ́. Ṣùgbọ́n bí ẹnì kan bá gbìyànjú láti fi ọ̀ranyàn bá ọ tage, má ṣe dá ara rẹ lẹ́bi—níwọ̀n ìgbà tó bá ti jẹ́ pé ìwà Kristẹni lo ń hù. (1 Pétérù 3:16, 17) Bí ọ̀ràn ọ̀hún bá ń kó ẹ̀dùn bá ọ, wá ìrànwọ́ nípa bíbá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ tàbí kí o bá àwọn tó dàgbà dénú nínú ìjọ Kristẹni sọ̀rọ̀. Rosilyn gbà pé ó ṣòro kí inú rẹ dùn nígbà tí wọ́n bá gbìyànjú láti fi ọ̀ranyàn bá ọ tage. Ó wí pé: “Níní alábàákẹ́gbẹ́ kan, ẹni tí o lè bá sọ̀rọ̀, ń ṣèrànwọ́ gidigidi.” Rántí pẹ̀lú pé, “Jèhófà ń bẹ nítòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”—Sáàmù 145:18, 19.

Kò máa ń rọrùn láti kọ̀ fún ẹni tó ń gbìyànjú láti fi ọ̀ranyàn báni tage, ṣùgbọ́n ó yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa ọ̀dọ́bìnrin kan láti Ṣúnémù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe pé wọ́n fi ọ̀ranyàn bá a tage lọ́nà tí ọ̀pọ̀ wá gbà lóye ọ̀rọ̀ ọ̀hún lónìí, ṣùgbọ́n Sólómọ́nì, tó jẹ́ ọlọ́lá àti alágbára ọba ní Júdà, fi ìfẹ́ lọ̀ ọ́, ìyẹn kò sì tẹ́ obìnrin náà lọ́rùn. Nítorí pé òun àti ọkùnrin mìíràn ti jọ ń bá ìfẹ́ bọ̀, obìnrin náà kọ ìfẹ́ tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ yẹn. Nítorí náà, obìnrin yìí yangàn nípa ara rẹ̀ pé, “Ògiri ni mí.”—Orin Sólómọ́nì 8:4, 10.

Ìwọ náà fi irú ìwà rere kan náà tó lágbára hàn, kí o sì mú ìpinnu rẹ ṣẹ. Jẹ́ “ògiri” nígbà tí ẹnì kan bá fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́. Jẹ́ kí gbogbo èèyàn tó yí ẹ ká mọ ìdúró rẹ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, o lè máa jẹ́ “aláìlẹ́bi àti ọlọ́wọ́-mímọ́,” kí ọkàn rẹ sì balẹ̀ pé inú Ọlọ́run dùn sí ẹ.—Fílípì 2:15.a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wà á rí ìmọ̀ràn púpọ̀ sí i lórí fífi ọ̀ranyàn báni tage nínú ìtẹ̀jáde Jí!, May 22, 1996; August 22, 1995; àti May 22, 1991.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jíjẹ́ kí àwọn èèyàn mọ àwọn ohun tí o gbà gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni lè dáàbò bò ẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

O lè dènà àwọn tó máa ń fi ọ̀ranyàn báni tage nípa ṣíṣàìkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwùjọ tí kò tọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́