ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 9
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo ni wọ́n ṣe máa ń fi ìṣekúṣe lọni?
  • Kí ni mo lè ṣe tí wọ́n bá ti fi ìṣekúṣe lọ̀ mí?
  • Kí ni mo lè ṣe tí ẹnì kan bá fẹ́ fi ìṣekúṣe lọ̀ mí?
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?
    Jí!—2000
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìfipá-Báni-Lòpọ̀?
    Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Níléèwé?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 9

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí ni mo lè ṣe tí wọ́n bá ń fi ìṣekúṣe lọ̀ mí?

  • Báwo ni wọ́n ṣe máa ń fi ìṣekúṣe lọni?

  • Kí ni mo lè ṣe tí wọ́n bá ti fi ìṣekúṣe lọ̀ mí?

  • Kí ni mo lè ṣe tí ẹnì kan bá fẹ́ fi ìṣekúṣe lọ̀ mí?

Báwo ni wọ́n ṣe máa ń fi ìṣekúṣe lọni?

Àwọn nǹkan téèyàn ò fẹ́ làwọn tó ń fi ìṣekúṣe lọni máa ń ṣe, irú bíi kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ tàbí ṣe ohun tó fi hàn pé wọ́n fẹ́ bá ẹnì kan ṣe ìṣekúṣe. Wọ́n lè máa fọwọ́ pa ẹlòmíì lára tàbí kí wọ́n máa sọ ọ̀rọ̀ rírùn sí i. Àmọ́ nígbà míì, èèyàn lè má mọ ìyàtọ̀ láàárín fífi ẹnì kan ṣe yẹ̀yẹ́, títage àti kí wọ́n fi ìṣekúṣe lọni.

Ǹjẹ́ o mọ ìyàtọ̀ láàárín wọn? Wàá mọ̀ ọ́n tó o bá dáhùn àwọn ìbéèrè nípa fífi ìṣekúṣe lọni tó wà nísàlẹ̀!

Àmọ́ o, kì í ṣe ìgbà tó o bá wà níléèwé nìkan ni wọ́n lè fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́. Torí náà, tó o bá ní ìgboyà, tó o sì mọ ohun tó o lè ṣe tí wọ́n bá fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́, kò ní ṣòro fún ẹ láti kojú rẹ̀ tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ nígbà tó o bá ti ń ṣiṣẹ́. Ó sì lè jẹ́ ohun tó o bá ṣe ló máa fòpin sí bí ẹni náà ṣe ń fi ìṣekúṣe lọ àwọn ẹlòmíì!

Olivia

“Ìwọ lo máa gba ara ẹ lọ́wọ́ wọn. Wọn ò ní yéé yọ ẹ́ lẹ́nu àfi tó o bá sọ fún wọn pé o kò nífẹ̀ẹ́ sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ìwọ ṣáà sọ fún wọn pé, ‘Rárá, mi ò fẹ́ bẹ́ẹ̀!’ Tí wọn ò bá sì gbọ́, fi ọ̀rọ̀ náà lọ ẹnì kan!”

Tanisha

“Má ṣe bá wọn ṣe àwàdà rírùn tàbí kó o bá wọn dá sí àwọn ọ̀rọ̀ rírùn tí wọ́n ń sọ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí tí ò ń bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ rìn, ṣe làwọn èèyàn máa rò pé irú kan náà ni gbogbo yín.”

Kí ni mo lè ṣe tí wọ́n bá ti fi ìṣekúṣe lọ̀ mí?

O lè fòpin sí bí wọ́n ṣe ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ tó o bá mọ ohun tó jẹ́ àti ohun tó o lè ṣe tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ sí ẹ! Gbé àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta yìí yẹ̀ wò, kó o sì wo ohun tó o lè ṣe tó bá jẹ́ pé ìwọ ló ṣẹlẹ̀ sí.

ÀPẸẸRẸ:

“Àwọn ọkùnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n jù mí lọ dáadáa máa ń sọ fún mi pé mo rẹwà gan-an, pé ó máa ń ṣe àwọn bíi pé káwọn pa dà di ọmọ ọgbọ́n [30] ọdún. Kódà ọ̀kan nínú wọn wá sẹ́yìn mi lọ́jọ́ kan, ó sì gbóòórùn irun mi!”​—Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Tabitha, ọmọ ogún [20] ọdún.

Tabitha lè ronú pé: ‘Tí mi ò bá kà á sí, tí mo sì ń fara dàá, ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin náà má ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.’

Ìdí tó fi léwu láti ronú bẹ́ẹ̀: Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé tí wọ́n bá ń fi ìṣekúṣe lọ ẹnì kan, tí kò sì kà á sí, ọ̀rọ̀ náà sábà máa ń le sí i ni.

Gbìyànjú èyí wò: Fi ìgboyà sọ̀rọ̀, má pariwo mọ́ ẹni náà, jẹ́ kó mọ̀ pé o kò fara mọ́ ọ̀rọ̀ rírùn tó ń sọ tàbí bó ṣe ń ṣe sí ẹ. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Taryn, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlélógún [22] sọ pé: “Tí ẹnì kan bá fọwọ́ kan mi lọ́nà tí mi ò fẹ́, ńṣe ni màá kọjú sí i, tí màá sì sọ fún un pé kó má tún fọwọ́ kàn mí bẹ́ẹ̀ mọ́ láé. Tí mo bá sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí, ó sábà máa ń bá ẹni náà lójijì.” Tí ẹni náà bá ṣì ń yọ ẹ́ lẹ́nu, má ṣe jẹ́ kó sú ẹ, ṣì dúró lórí ìpinnu rẹ. Tá a bá fẹ́ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run, Bíbélì gbà wá níyànjú pé: ‘Kí ẹ̀yin dúró ní pípé àti ní kíkún.’​—Kólósè 4:​12, Bíbélì Mímọ́.

Tí ẹni tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ bá sọ pé òun máa ṣe ẹ́ ní jàǹbá ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe sọ pé kò tó bẹ́ẹ̀ o! Tètè kúrò níbẹ̀ kíá, kó o sì ní kí àgbàlagbà kan tó o fọkàn tán ràn ẹ́ lọ́wọ́.

ÀPẸẸRẸ:

“Nígbà tí mo wà ní kíláàsì kẹfà, àwọn ọmọbìnrin méjì kan wá fà mí láàárín ọ̀ọ̀dẹ̀ ilé-ìwé wa lọ́jọ́ kan. Obìnrin tó ń bá obìnrin lò pọ̀ ni ọ̀kan lára wọn, ó sì fẹ́ ká jọ máa ṣèṣekúṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò gbà fún un, ojoojúmọ́ làwọn méjèèjì máa ń yọ mí lẹ́nu tí mo bá ń lọ láti kíláàsì kan sí ìkejì. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí wọ́n tì mí lu ògiri!”​—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Victoria, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].

Victoria lè ronú pé: ‘Tí mo bá fẹjọ́ wọn sùn, àwọn èèyàn á pè mí ní ojo tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ gbà mí gbọ́.’

Ìdí tó fi léwu láti ronú bẹ́ẹ̀: Tó o bá kọ̀ tó ò sọ fún ẹnì kankan, ẹni tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ lè ṣì máa yọ ẹ́ lẹ́nu, ó sì tún lè máa ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn ẹlòmíì pàápàá.​—Oníwàásù 8:11.

Gbìyànjú èyí wò: Ní kí wọ́n ràn ẹ́ lọ́wọ́. Àwọn òbí rẹ àtàwọn olùkọ́ rẹ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí. Àmọ́, tí àwọn tó o fọ̀rọ̀ lọ̀ kò bá ka ọ̀rọ̀ náà kún, kí lo lè ṣe? Gbìyànjú èyí wò: Máa kọ ohun tó ṣẹlẹ̀ àti bó ṣe ṣẹlẹ̀ sínú ìwé kan ní gbogbo ìgbà tí ẹnì kan bá fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́. Kọ ọjọ́ tó ṣẹlẹ̀, aago tó ṣẹlẹ̀, ibi tó ti ṣẹlẹ̀ àti ohun tí ẹni náà sọ. Kó o wá fún àwọn òbí rẹ tàbí olùkọ́ rẹ ní ẹ̀dà kan. Àwọn èèyàn sábà máa ń fi ọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sùn tí ẹnì kan kọ sínú ìwé ju èyí téèyàn fẹnu sọ lọ.

ÀPẸẸRẸ:

“Ẹ̀rù ọmọkùnrin kan ní ilé ẹ̀kọ́ mi tó wà nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan máa ń bà mí gan-an. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ẹsẹ̀ bàtà méje, ìwọ̀n rẹ̀ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àpò sìmẹ́ǹtì mẹ́ta (135 kìlógíráàmù)! Ó máa ń ronú pé òun ṣì máa ‘bá mi lò pọ̀.’ Ojoojúmọ́ ló máa ń yọ mí lẹ́nu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọdún kan gbáko. Lọ́jọ́ kan, èmi àti ẹ̀ nìkan la wà nínú kíláàsì, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀ lọ́dọ̀ mi. Ńṣe ni mo tètè gba ẹnu ọ̀nà sá bọ́ síta.”​—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Julieta, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18].

Julieta lè ronú pé: ‘Bí àwọn ọkùnrin ṣe máa ń ṣe nìyẹn.’

Ìdí tó fi léwu láti ronú bẹ́ẹ̀: Ẹni tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu yìí lè má jáwọ́ tí àwọn èèyàn bá rò pé kò sí ohun tó burú nínú ìwà tó ń hù yẹn.

Gbìyànjú èyí wò: Má ṣe fi ọ̀rọ̀ náà ṣeré rárá tàbí kó o fi ṣàwàdà. Kàkà bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ẹni tó ń yọ ẹ́ lẹ́nu mọ̀ pé o kò fara mọ́ ohun tó ń ṣe sí ẹ, ó sì gbọ́dọ̀ hàn lójú àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ pé o kò fẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀.

Kí ni mo lè ṣe tí ẹnì kan bá fẹ́ fi ìṣekúṣe lọ̀ mí?

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN:

“Mo máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn. Kódà tí àwọn ọkùnrin bá ń fi ìṣekúṣe lọ̀ mí, ńṣe ni màá kàn sọ fún wọn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ pé mi ò fẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohùn mi kì í le tí n bá sọ ọ́. Wọ́n wá rò pé mo kàn ń díbọ́n ni.”—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tabitha.

  • Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Tabitha, kí lo máa ṣe fún àwọn tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ yẹn? Kí nìdí tí wàá fi ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Kí ló lè mú kí ẹni tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ rò pé ọ̀rọ̀ náà ò ka ẹ lára?

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN:

“Ìsọkúsọ ni àwọn ọ̀dọ́kùnrin kan ní kíláàsì mi fi bẹ̀rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà wá túbọ̀ le sí i lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mélòó kan torí pé mi ò ka ohun tí wọ́n ń sọ yẹn sí. Nígbà tó yá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jókòó sí ẹ̀gbẹ́ mi, wọ́n á sì fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn. Mo máa ń tì wọ́n dànù, àmọ́ wọn ò jáwọ́. Lọ́jọ́ kan, ọ̀kan lára wọn fún mi ní bébà kan tó kọ ọ̀rọ̀ rírùn sí. Mo fún olùkọ́ mi. Wọ́n sì lé e kúrò ní ilé ìwé. Mo wá rí i pé ìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mi lẹ́nu ni mi ò bá ti lọ fẹjọ́ wọn sùn!”—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Sabina.

  • Kí lo rò pé ó mú kí Sabina má fẹ́ lọ fi ẹjọ́ àwọn ọmọ náà sun olùkọ́ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yọ ọ́ lẹ́nu? Ṣé ohun tí Sabina ṣe dáa? Kí nìdí tó o fi sọ pé ó dáa? Kí nìdí tó o fi sọ pé kò dáa?

OHUN TÓ ṢẸLẸ̀ SÍ ẸNÌ KAN:

“Ọmọkùnrin kan wá bá àbúrò mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Greg nínú balùwẹ̀ lọ́jọ́ kan. Ó sún mọ́ Greg, ó sì sọ fún un pé, ‘Fi ẹnu kò mí lẹ́nu.’ Greg sọ fún un pé rárá òun ò ṣe, àmọ́ ọmọ náà ò kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Ìgbà tí Greg tì í dànù ló tó jáwọ́.”—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Suzanne, ọmọ ogún [20] ọdún.

  • Ǹjẹ́ o rò pé ọmọ náà fẹ́ bá Greg ṣe ìṣekúṣe? Kí nìdí tó o fi sọ pé bẹ́ẹ̀ ni? Kí nìdí tó o fi sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́?

  • Kí ni kì í jẹ́ kí àwọn ọmọ kan sọ̀rọ̀ tí àwọn ọkùnrin bíi tiwọn bá fi ìṣekúṣe lọ̀ wọ́n?

  • Ṣé o gbà pé ohun tó tọ́ ni Greg ṣe yẹn? Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni, kí ni wàá ṣe?

Ìbéèrè nípa fífi ìṣekúṣe lọni

“Ní ilé ìwé wa, àwọn ọmọkùnrin máa ń wá fa bùrèsíà mi látẹ̀yìn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ rírùn sí mi létí. Wọ́n lè máa sọ nípa bí màá ṣe gbádùn ẹ̀ tó tí n bá gbà pé káwọn bá mi sùn.”—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Coretta.

Kí lo rò pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹn ń ṣe?

  1. A Wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́

  2. B Wọ́n ń bá a tage

  3. D Wọ́n ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́

“A wà nínú mọ́tò lọ́jọ́ kan, ni ọmọkùnrin kan bá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ rírún sí mi, ó sì tún dì mí mú. Mo já ọwọ́ ẹ̀ kúrò lára mi, mo sì ní kó kúrò níwájú mi. Ó yà á lẹ́nu, ó wá ń wò mí.”—Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Candice, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17]..

Kí lo rò pé ọmọ yẹn ń ṣe fún Candice?

  1. A Ó ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́

  2. B Ó ń bá a tage

  3. D Ó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́

“Lọ́dún tó kọjá, ọmọkùnrin kan sọ fún mi lọ́pọ̀ ìgbà pé òun fẹ́ràn mi, pé òun fẹ́ ká jọ máa ṣèṣekúṣe. Mo máa ń sọ fún un pé rárá mi ò ṣe. Ó máa ń fi ọwọ́ rẹ̀ pa ọwọ́ mi nígbà míì. Kì í dá mi lóhùn tí mo bá sọ fún un pé kó má fi ọwọ́ kàn mí mọ́. Lọ́jọ́ kan, ó gbá mi nídìí bí mo ṣe ń de okùn bàtà mi.”​— Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Bethany, ọmọ ọdún mẹ́tàlá.

Kí lo rò pé ọmọkùnrin yìí ń ṣe?

  1. A Ó ń bá a tage

  2. B Ó ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́

  3. D Ó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́

D ni ìdáhùn gbogbo ìbéèrè náà.

Kí ni ìyàtọ̀ láàárín fífi ìṣekúṣe lọni, títage àti fífi ẹnì kan ṣe yẹ̀yẹ́? Ọ̀dọ́bìnrin ọmọ ogún ọdún kan tó ń jẹ́ Eve sọ pé: “Ọ̀rọ̀ fífi ìṣekúṣe lọni lágbára gan-an. Ẹni tó ń fi ìṣekúṣe lọni kì í jáwọ́ kódà lẹ́yìn tó o bá sọ pé o kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó ń ṣe.” Ọ̀rọ̀ ńlá lọ̀rọ̀ fífi ìṣekúṣe lọni. Yàtọ̀ sí pé ó lè ṣe àkóbá fún ìlera rẹ tàbí kó má jẹ́ kó o ṣe dáadáa lẹ́nu ẹ̀kọ́ rẹ, ó tún lè yọrí sí ìfipá báni lò pọ̀.

Mọ púpọ̀ sí i: Wo orí 32 tó ní àkòrí náà, “Báwo Ni Mi Ò Ṣe Ní Kó Sọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fipá Báni Lò Pọ̀?” nínú ìwé náà Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́