ORÍ 14
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Níléèwé?
Fàmì Sí Bẹ́ẹ̀ Ni Tàbí Rárá Nínú Àwọn Gbólóhùn Tó Wà Nísàlẹ̀ Yìí:
1. Ìgbà táwọn ọmọléèwé bá ṣèèyàn léṣe la tó lè sọ pé wọ́n ń fòòró ẹ̀mí onítọ̀hún.
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
2. Ó dìgbà táwọn ọmọ iléèwé bá bẹ̀rẹ̀ sí fọwọ́ pani lára ká tó lè sọ pé wọ́n ń fìṣekúṣe lọni.
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
3. Àwọn obìnrin náà lè fòòró ẹ̀mí èèyàn kódà wọ́n lè fi ìlọ̀kulọ̀ lọni.
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
4. Táwọn ọmọléèwé bá ń fòòró ẹ̀mí ẹ tí wọ́n sì ń fìṣekúṣe lọ̀ ẹ́, kò sóhun tó o lè ṣe sí i.
□ Bẹ́ẹ̀ ni
□ Rárá
OJOOJÚMỌ́ lẹ̀rù máa ń ba ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ níléèwé. Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ryan sọ pé: “Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tí mo máa ń lò nínú ọkọ̀ iléèwé wá dà bí ọ̀pọ̀ wákàtí téèyàn fi ń jìyà, torí àwọn tó ń fòòró ẹ̀mí mi ò yéé pin mí lẹ́mìí, tí wọ́n bá bú mi tí ò tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n á tún bẹ̀rẹ̀ sí í lù mí.” Ìṣekúṣe ni wọ́n fi ń lọ àwọn ọ̀dọ́ míì. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Anita sọ pé: “Ọmọkùnrin kan tó gbajúmọ̀ níléèwé wa ká mi mọ́ ojú ọ̀nà tá a máa ń gbà lọ sí kíláàsì ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ pa mí lára. Mo rọra sọ fún un pé kó gbọ́wọ́ ẹ̀ kúrò lára mi, àmọ́ kò dáhùn. Bóyá ó rò pé mò ń ṣeré ni.”
Àwọn ọ̀dọ́ kan tí ò tiẹ̀ tíì tó ọmọ ogún ọdún pàápàá máa ń fòkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn ọmọ kíláàsì wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ṣáwọn ọmọ iléèwé ẹ ti halẹ̀ mọ́ ẹ tàbí kí wọ́n sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí ẹ rí? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe sí ìṣòro náà? Ohun tó o lè ṣe pọ̀ lọ jàra! Àmọ́, jẹ́ ká lo àwọn gbólóhùn tá a fi bẹ̀rẹ̀ orí yìí láti fìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ìhalẹ̀mọ́ni jẹ́ àti ohun tí kò jẹ́.
1. Rárá. Ẹnu lọ̀pọ̀ àwọn tó ń fòòró ẹ̀mí èèyàn máa ń lò, wọn kì í gbáni lẹ́ṣẹ̀ẹ́. Ìhalẹ̀mọ́ni, èébú, ọ̀rọ̀ kòbákùngbé àti òkò ọ̀rọ̀ ni wọ́n fi ń fòòró àwọn èèyàn.
2. Rárá. Àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́nlé táwọn èèyàn bá sọ lọ́nà tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ, àpárá tí ò dáa tàbí sísejú síni pàápàá lè túmọ̀ sí fífi ìṣekúṣe lọni.
3. Bẹ́ẹ̀ ni. Tọkùnrin tobìnrin ló lè fòòró èèyàn.
4. Rárá. Ohun tó o lè ṣe wà láti dẹ́kun ìhalẹ̀mọ́ni. Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ṣe é.
Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Fòòró Ẹ Láì Bá A Jà
Àwọn kan lára àwọn tó ń fòòró ẹni máa ń mọ̀ọ́mọ̀ tọ́jà èèyàn, torí wọ́n fẹ́ mọ nǹkan téèyàn máa ṣe. Àmọ́ Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya.” (Oníwàásù 7:9) Òótọ́ pọ́ńbélé kan ni pé téèyàn bá fi ibi san ibi, ó lè dá kún ọ̀ràn tó wà nílẹ̀, ìṣòro yẹn sì lè túbọ̀ pọ̀ sí i. (Róòmù 12:17) Báwo lo wá ṣe lè borí ẹni tó ń fòòró ẹ láì bá a jà?
Má sọ ọ́ dariwo. Bó bá jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n fẹ́ fọ̀rọ̀ kan dá yẹ̀yẹ́ ẹ sílẹ̀, ńṣe ni kíwọ náà bá wọn rẹ́rìn-ín, má fi ṣèbínú. Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Eliu sọ pé: “Nígbà míì, gbogbo nǹkan téèyàn kàn máa ṣe ò ju pé kó má ka ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ fi múnú bí i sí bàbàrà.” Bí ẹni tó ń fòòró ẹ̀mí ẹ bá rí i pé gbogbo ọ̀rọ̀ òun ò tu irun kankan lára ẹ, ó lè fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀.
Má gbé e gbóná fún un. Bíbélì sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” (Òwe 15:1) Àwọn tó ń fòòró ẹ̀mí èèyàn kì í retí pé kó o sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, tó o bá wá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè bomi tútù sí wọn lọ́kàn. Ká sòótọ́, ó gba ìkóra-ẹni-níjàánu kéèyàn tó lè hùwà pẹ̀lẹ́ nígbà tí wọ́n bá ń kó gìrìgìrì báni. Àmọ́, ìyẹn gan-an ló dáa jù. Òwe 29:11 sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” Ẹ̀yìn onísùúrù ni Ọlọrun wà. Nǹkan kì í tètè sú ẹni tó bá ń hùwà pẹ̀lẹ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, àyà àwọn tó ń fòòró ẹ̀mí èèyàn kì í ki tó bẹ́ẹ̀, nǹkan sì máa ń tètè tojú sú wọn. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.”—Òwe 16:32.
Dáàbò bo ara ẹ. Bó o bá rí i pé agbára ẹ ò ká a mọ́, yáa wábi sá gbà. Ìwé Òwe 17:14 sọ pé: “Kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” Torí náà bó o bá ti rí i pé ìjà fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, tètè rìn kúrò níbẹ̀ tàbí kó o sáré pàápàá. Bó o bá sì rí i pé kò síbi tó o lè sá gbà, sa gbogbo agbára rẹ láti gba ara ẹ sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwà ipá.
Fẹjọ́ sùn. Ó yẹ káwọn òbí ẹ mọ nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀. Àwọn náà lè fún ẹ nímọ̀ràn tó gbéṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè ní kó o lọ fẹjọ́ sun àwọn ọ̀gá iléèwé yín, irú bí agbaninímọ̀ràn iléèwé. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé àwọn òbí àtàwọn ọ̀gá iléèwé lè fọgbọ́n yanjú ìṣòro tó wà nílẹ̀ láìtún kó ẹ sí wàhálà kankan.
Òótọ́ kan tí ò ṣeé já ní koro ni pé, ẹni tó ń fòòró ẹ̀mí ẹ ò lè borí ẹ tó ò bá gbà fún un. Torí náà, máà jẹ́ kí gbogbo gànràngànràn ẹ̀ dẹ́rù bà ẹ́ lọ́nàkọnà. Kàkà bẹ́ẹ̀, lo gbogbo àbá tá a ti jíròrò láti bójú tó ọ̀ràn náà.
Bó O Ṣe Lè Borí Àwọn Tó Bá Ń Fìṣekúṣe Lọ̀ Ẹ́
O lẹ́tọ̀ọ́ láti bínú táwọn èèyàn bá ń fìṣekúṣe lọ̀ ẹ́! Àmọ́, ìbéèrè náà ni pé, Kí lo lè ṣe láti gbara ẹ lọ́wọ́ wọn? Ọ̀pọ̀ nǹkan wà tó o lè ṣe! Àwọn àbá díẹ̀ rèé.
Fi gbogbo ara sọ pé o ò gbà. Bó ò bá fi ìdánilójú sọ pé o ò gbà, àwọn tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ lè rò pé táwọn ò bá fi ẹ́ lọ́rùn sílẹ̀, o ṣì máa gbà fáwọn. Torí náà fi gbogbo ara sọ pé o ò gbà, kó o sì jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́. (Mátíù 5:37) Bó o bá lọ ń ṣojú mẹin-mẹin tó o sì ń gúnpá bí ọmọdé, bóyá torí o ò fẹ́ kó dójú tì ẹ́, ìyẹn lè jẹ́ kí ẹni tó ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ rò pé o nífẹ̀ẹ́ sóhun tó fẹ́ ṣe. Torí náà, jẹ́ kó hàn nínú ohùn ẹ àti bó o ṣe ń hùwà pé o ò gbà. Ìyẹn gan-an lo lè fi gbara ẹ sílẹ̀!
Yarí. Anita sọ ohun tó ṣe fún ẹni tó ń fìṣekúṣe lọ̀ ọ́, ó ní: “Mo yarí fún un lójú àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀, mo pariwo mọ́ ọn pé kó MÁ ṢE fọwọ́ kàn mí bẹ́ẹ̀ yẹn mọ́!” Kí nìyẹn wá yọrí sí? Anita sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ fi ṣe yẹ̀yẹ́, ojú sì tì í gan-an. Ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà ló wá bẹ̀ mí, àtìgbà yẹn ló sì ti máa ń gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó bá ń dà mí láàmú.”
Tọ́rọ̀ ẹnu ò bá gbà ẹ́ sílẹ̀, fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Ohun tó tún máa dáa jù ni pé kó o sá lọ. Bí kò bá sì sí ibi tó o lè gbà sá lọ, o lè ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti gbèjà ara ẹ. (Diutarónómì 22:25-27) Ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé: “Nígbà tí ọmọkùnrin kan fẹ́ kì mí mọ́lẹ̀, mo fi gbogbo agbára mi gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́, mo sì sá lọ!”
Wá ẹni sọ fún. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16] kan tó ń jẹ́ Adrienne sọ pé: “Ohun tí mo pàpà ṣe nìyẹn. Mo sọ fáwọn òbí mi, mo sì ní kí wọ́n gbà mí nímọ̀ràn nígbà tí ọmọkùnrin kan tí mo kà sí ọ̀rẹ́ gidi ò fẹ́ fi mí lọ́rùn sílẹ̀. Bí mo ṣe ń sọ fún un pé mi ò ṣe ni eegun ẹ̀ túbọ̀ ń le sí i, àfi bíi pé eré ayò là ń ta.” Àwọn òbí Adrienne fún un láwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́, ìyẹn sì ràn án lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro ọ̀hún. Kò sí àní-àní pé àwọn òbí tìẹ náà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Kò rọrùn láti borí ìhalẹ̀mọ́ni àti fífi ìṣekúṣe lọni. Àmọ́ ohun kan tó ò gbọ́dọ̀ gbàgbé nìyí: Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ò ní láti di sùẹ̀gbẹ̀ fáwọn tó ń fòòró ẹ̀mí wọn, wọn ò sì gbọ́dọ̀ gbà fáwọn tó ń fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ wọ́n. Bó o bá tẹ̀ lé àwọn àbá tá a ti jíròrò, ó dájú pé wàá borí.
KA PÚPỌ̀ SÍ I NÍPA ÀKÒRÍ YÌÍ NÍ ORÍ 19, NÍNÚ APÁ KÌÍNÍ ÌWÉ YÌÍ
Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe wà lára àwọn ìṣòro tó lágbára jù lọ tó o gbọ́dọ̀ kojú. Kọ́ bó o ṣe lè fìgboyà dojú kọ ọ́.
ÀWỌN ẸSẸ ÌWÉ MÍMỌ́
“Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.
ÌMỌ̀RÀN
Bẹ́nì kan bá dójú sọ ẹ́ láti halẹ̀ mọ́ ẹ, má bẹ̀rù àmọ́ má ṣe gbé e gbóná fún un. Sọ fún un pé kó jáwọ́, kó o sì fibẹ̀ sílẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́. Bí kò bá jáwọ́, fẹjọ́ ẹ̀ sùn.
ṢÓ O MỌ̀ PÉ . . . ?
Bó o bá lọ wọ aṣọ tó fàwọ̀ jọ tàwọn ẹgbẹ́ kan tàbí tó o lo nǹkan ẹ̀ṣọ́ wọn, o lè rí ìyà he. Ọmọkùnrin kan tó ti fìgbà kan wà nínú irú ẹgbẹ́ bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá múra bíi tiwa, tí kì í sì í ṣara wa, a máa ń dájú sọ irú wọn ni. Ohun tó sì máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀ ni pé kó dara pọ̀ mọ́ wa tàbí kó jẹ àjẹkún ìyà.”
OHUN TÍ MÀÁ ṢE!
Bẹ́nì kan bá fẹ́ bú mi tàbí tó fẹ́ múnú bí mi, màá ․․․․․
Kí n má bàa kó sínú ìjàngbọ̀n, ohun tí màá ṣe rèé ․․․․․
Ohun tí màá béèrè lọ́wọ́ Dádì tàbí Mọ́mì nípa ọ̀rọ̀ yìí ni ․․․․․
KÍ LÈRÒ Ẹ?
● Báwo lo ṣe lè túbọ̀ fi hàn pé o nígboyà, pé o ò sì lágbaja, káwọn ọmọléèwé ẹ má bàa rí ẹ bí ẹni tó yẹ káwọn wá halẹ̀ mọ́?
● Kí lo lè ṣe tí wọ́n bá fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́? (Ronú lórí àwọn ohun tó lè ṣẹlẹ̀ gan-an àti bó o ṣe lè fèsì.)
● Kí nìdí tó fi yẹ kó o fọwọ́ tó le mú ọ̀ràn fífi ìṣekúṣe lọni?
[Ìsọfúnni tó wà ní ojú ìwé 123]
“Bó o bá ti mọ̀ pé ìjà máa tó bẹ́ sílẹ̀, máà bá wọn dá sí i, ilé ni kó o gbà lọ. Àwọn kan máa ń ṣojúmìító, ìyẹn sì máa ń kó wọn sí wàhálà.”—Jairo
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 125]
Bó O Ṣe Lè Dáàbò Bora Ẹ Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fìṣekúṣe Lọni
Má ṣe bá wọn tage. Bó o bá ń bá wọn tage, ńṣe lò ń pè wọ́n pé kí wọ́n wá fi ìṣekúṣe lọ̀ ẹ́. Bíbélì béèrè pé: “Ṣé [èèyàn] kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná?” (Òwe 6:27) Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tó o bá ń bá àwọn ọmọléèwé ẹ tage, ńṣe lò ń finá ṣeré.
Yan àwọn tí wàá máa bá rìn. Wọ́n ṣáà máa ń sọ pé: “Fi ọ̀rẹ́ rẹ hàn mí, kí n lè sọ irú ẹni tó o jẹ́.” Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Carla sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé àwọn tó fẹ́ràn ìṣekúṣe lò ń bá rìn, kò sí bí wọn ò ṣe ní fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ ẹ́.”—1 Kọ́ríńtì 15:33.
Máa ṣọ́ irú aṣọ tó ò ń wọ̀. Bó o bá ń wọṣọ tí kò bá tọmọlúwàbí mu, ńṣe lò ń sọ fún wọn pé o nífẹ̀ẹ́ sí ìṣekúṣe, wàá sì rí nǹkan tó ò ń wá.—Gálátíà 6:7.
Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́. Bó ò bá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ́, wọn ò ní mọ ohun tó fà á tó o fi ń fàwọn ìlànà Kristẹni ṣèwà hù.—Mátíù 5:15, 16.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 124]
Bí ìgbà téèyàn bá ń tú epo síná ló ṣe máa rí béèyàn bá ń rọ̀jò èébú lé ẹni tó ń fòòró ẹni lórí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127]
Sọ fẹ́ni tó ń fìṣekúṣe lọ̀ ẹ́ pé kó wábi gbà!