ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ypq ìbéèrè 5 ojú ìwé 15-17
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Níléèwé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Níléèwé?
  • Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jíja Àjàbọ́ Lọ́wọ́ Ìfòòró Ẹni
    Jí!—2003
  • Fífòòró Ẹni—Díẹ̀ Lára Ohun Tó Ń Fà Á Àtàwọn Ohun Tó Ń Yọrí Sí
    Jí!—2003
  • Fífòòró Ẹni—Ìṣòro Tó Kárí Ayé
    Jí!—2003
  • Bíbúmọ́ni—Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè 10 Táwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè
ypq ìbéèrè 5 ojú ìwé 15-17
Ẹnì kan nínú kíláàsì ń halẹ̀ mọ́ ọmọ kan níṣojú àwọn ọmọ kíláàsì yòókù

ÌBÉÈRÈ 5

Kí Ni Mo Lè Ṣe tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Mi Níléèwé?

ÌDÍ TỌ́RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Ohun tó o bá ṣe tí wọ́n bá halẹ̀ mọ́ ẹ lé mú kí wọ́n fi ẹ́ sílẹ̀ tàbí kí wọ́n túbọ̀ fínná mọ́ ẹ.

KÍ LO MÁA ṢE?

Fojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí: Thomas ò fẹ́ lọ sí ilé ìwé lónìí. Ó lè má lọ lọ́la pàápàá. Kò tiẹ̀ fẹ́ lọ mọ́. Ní oṣù mẹ́ta sẹ́yìn, àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í rojọ́ ẹ̀ kiri. Wọ́n tún ń pè é lórúkọ burúkú. Nígbà míì, ẹnì kan lè fọwọ́ gbá ìwé Thomas dà nù lọ́wọ́ ẹ̀, á wá ṣe bíi pé òun ò mọ̀ọ́mọ̀ tàbí kí ẹnì kan láàárín èrò ṣàdédé fọwọ́ tì í látẹ̀yìn, kó sì tó wẹ̀yìn, onítọ̀hún á ti ṣojú fúrú. Lánàá, ohun míì tún ṣẹlẹ̀ tó mú kí ọ̀rọ̀ ọ̀hún tún burú sí i. Ṣe làwọn kan halẹ̀ mọ́ Thomas látorí íńtánẹ́ẹ̀tì . . .

Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni Thomas, kí lo máa ṣe?

RÒ Ó WÒ NÁ!

Má rò pé kò sóhun tó o lè ṣe! Ṣó o fẹ́ gbọ́, o lè borí ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ láìbá a jà. Báwo lo ṣe lè ṣe é?

  • MÁA WÒ Ó NÍRAN. Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ni arìndìn ń tú jáde, ṣùgbọ́n ẹni tí ó gbọ́n a máa mú kí ó pa rọ́rọ́ títí dé ìkẹyìn.” (Òwe 29:11) Tó ò bá fún wọn lésì, tó ò sì jẹ́ kí wọn rí i lójú ẹ pé ó dùn ẹ́, àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ lè fi ẹ́ sílẹ̀.

  • MÁ GBẸ̀SAN. Bíbélì sọ pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:17) Tó o bá gbẹ̀san, ṣe lo máa dá kún ọ̀ràn náà.

  • SÁ FÚN OHUN TÓ LÈ KÓ Ẹ SÍ WÀHÁLÀ. Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́.” (Òwe 22:⁠3) Máa yẹra fún àwọn tó lè dá wàhálà sílẹ̀ débi tó o bá lè ṣe é dé, má sì lọ síbi tí wọ́n ti lè halẹ̀ mọ́ ẹ.

  • SỌ OHUN TÍ WỌN Ò RETÍ. Bíbélì sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” (Òwe 15:⁠1) O tiẹ̀ lè dàá sí àwàdà. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹnì kan bá ń bú ẹ pé o ti sanra jù, o lè fakọ sí i, kó o sọ pé, “Tí mo bá tiẹ̀ lè jò díẹ̀ sí i, màá yọ̀!”

  • KÚRÒ NÍBẸ̀. Nora, tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], sọ pé: “Tó o bá dákẹ́, tó ò fún ẹni tó ń halẹ̀ mó ẹ lésì, ńṣe ló fi hàn pé o níwà àgbà, o sì lágbára ju ẹni yẹn lọ. Ó tún fi hàn pé o lè kó ara ẹ níjàánu, ohun tẹ́ni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ ò lè ṣe.”​—2 Tímótì 2:⁠24.

  • MÁ ṢE JẸ́ KÍ Ẹ̀RÙ MÁA BÀ Ẹ́. Àwọn tó máa ń halẹ̀ mọ́ni máa ń mọ̀ tẹ́rù bá ń ba ẹnì kan, tí kò sì ní lè gbèjà ara ẹ̀. Àmọ́, tí wọ́n bá ti rí i pé àwọn ò lágbára lórí ẹ, wọ́n á fi ẹ́ sílẹ̀.

  • WÁ ẸNÌ KAN SỌ FÚN. Ẹnì kan tó ti ṣiṣẹ́ olùkọ́ rí sọ pé: “Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ, má bò ó mọ́ra, ṣe ni kó o sọ̀rọ̀ síta. Ohun tó yẹ kó o ṣe nìyẹn, ìyẹn á jẹ́ ká wá nǹkan ṣe sí i, wọn ò sì ní tún lè halẹ̀ mọ́ ẹlòmíì.”

Ọ̀dọ́kùnrin kan ò bẹ̀rù ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ọn

Tó ò bá bẹ̀rù, wàá lágbára ju ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bá lu èèyàn nìkan ni wọ́n tó halẹ̀ mọ́ ọn, ó tún kan:

  • Ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ni lè dà bí iná

    Èébú. Celine, tó jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún sọ pé: “Mi ò jẹ́ gbàgbé àwọn orúkọ burúkú tí wọ́n ń pè mí àtàwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ sí mi. Wọ́n máa ń jẹ́ kí n rí ara mí bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, tí ò ṣeé rí mọ́ọ̀yàn, tí kò sì wúlò. Ó sàn kí wọ́n lù mí ju kí wọ́n sọ̀rọ̀ sí mi lọ.”

  • Ọ̀dọ́kùnrin kan dá jókòó torí àwọn ojúgbà rẹ̀ pa á tì

    Kí wọ́n pani tì. Haley, tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé: “Àwọn ọmọ kíláàsì mi ò kí ń fẹ́ dá sí mi. Wọ́n kì í fẹ́ kí n jókòó tì wọ́n tá a bá fẹ́ jẹun ọ̀sán, wọ́n á wá gba gbogbo ààyè. Odindi ọdún kan ni mo fi dá jẹun, tí mo sì máa ń sunkún.”

  • Ọ̀dọ́bìnrin kan kúrò nídìí kọ̀ǹpútà nígbà tí wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì

    Bíba èèyàn lórúkọ jẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Daniel, tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14], sọ pé: “Wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan ba èèyàn lórúkọ jẹ́ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n tiẹ̀ lè fi ba ayé onítọ̀hún jẹ́ pátápátá. Ọ̀rọ̀ yìí lè dà bí àsọdùn, àmọ́ ó lè ṣẹlẹ̀ dáadáa!”

ÌBÉÈRÈ NÍPA ÀWỌN TÓ Ń HALẸ̀ MỌ́NI

BẸ́Ẹ̀ NI ÀBÍ BẸ́Ẹ̀ KỌ́

ÌDÁHÙN

1 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ti ń halẹ̀ mọ́ni.

1 Bẹ́ẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ̀rọ̀ àwọn Néfílímù tí orúkọ wọn túmọ̀ sí “Àwọn Tó Ń Bini Ṣubú.”​—Jẹ́nẹ́sísì 6:⁠4.

2 Tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ọ̀yàn, wọ́n kàn ń bá a ṣeré ni. Kì í ṣe nǹkan tó le.

2 Bẹ́ẹ̀ kọ́. Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ ló ti pa ara wọn.

3 Ohun tó dáa jù tó o lè ṣe tí wọn ò fi ní halẹ̀ mọ́ ẹ mọ́ ni pé kó o ṣe tìẹ pa dà.

3 Bẹ́ẹ̀ kọ́. Àwọn tó máa ń halẹ̀ mọ́ni sábà máa ń lágbára ju àwọn tí wọ́n ń halẹ̀ mọ́ lọ, apá ẹ ò lè ká wọn tó o bá lọ ń bá wọn jà.

4 Tó o bá rí i pé wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ẹnì kan, á dáa kó o ṣe bí i pé o ò rí i.

4 Bẹ́ẹ̀ kọ́. Nínú ọ̀ràn yìí, kò yẹ kéèyàn kàn jẹ́ òǹwòran lásán. Tó o bá rí i pé wọ́n ń halẹ̀ mọ́ ẹnì kan, tó ò sì sọ nǹkan kan nípa ẹ̀, ńṣe lò ń dá kún ìṣòrò rẹ̀ dípò kó o bá a yanjú ẹ̀.

5 Àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ni kàn ń halẹ̀ ni, ọkàn tiwọn náà ò balẹ̀.

5 Bẹ́ẹ̀ ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ni máa ń gbéra ga, ọ̀pọ̀ nínú wọn lọkàn wọn ò bàlẹ̀, ṣe ni wọ́n ń halẹ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíì kí wọ́n lè múnú ara wọn dùn.

6 Àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ni lè yíwà pa dà.

6 Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn tó bá ń halẹ̀ mọ́ni lè yíwà pa dà tí wọ́n bá rẹ́ni ràn wọ́n lọ́wọ́.

OHUN TÍ MÀÁ ṢE

  • Kí ni màá sọ tàbí tí màá ṣe tí ẹnì kan bá halẹ̀ mọ́ mi?

MO PÚPỌ̀ SÍ I!

O Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láìbá A Jà

Wo eré ojú pátákó náà, Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láì Bá A Jà lórí ìkànnì www.jw.org/⁠yo. (Wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́