Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Bíbúmọ́ni—Ewu Wo Ló Wà Níbẹ̀?
‘Gbọ́! Mo wulẹ̀ fi ń mórí yá díẹ̀ ni. Èwo ló wá le lọ títí níbẹ̀? Yàtọ̀ sí ìyẹn, ó yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ fún Ron.’
ÌWỌ lè tóbi, kí o sì lágbára ju àwọn ojúgbà rẹ lọ. Tàbí bóyá o ní làákàyè, ẹnu rẹ mú, o sì ya oníjàgídíjàgan jù wọ́n lọ. Èyí tó wù kó jẹ́, ó jọ pé dídẹ́rùbani, mímúnibínú, tàbí fífinirẹ́rìn-ín, lọ́nà tí ń ba ẹlòmíràn nínú jẹ́, máa ń ṣọwọ́ rẹ.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bíbú mọ́ àwọn ẹlòmíràn lè pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lẹ́rìn-ín, kì í ṣe ọ̀rọ̀ yẹpẹrẹ rárá. Ní ti gidi, àwọn olùwádìí kan ń rí i pé bíbúmọ́ni ń pa òjìyà rẹ̀ lára ju bí àwọn ti ronú kàn nígbà kankan rí lọ. Ìwádìí kan láàárín àwọn èwe tí wọ́n ti tó lọ sílé ẹ̀kọ́ ní United States rí i pé “ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí a bú mọ́ sọ pé àwọn jìyà ìpalára tí a kò rò tẹ́lẹ̀—ìlọsílẹ̀ nínú máàkì wọn, àfikún hílàhílo, ìpàdánù àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ìpàdánù ìgbésí ayé ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.” Ní Japan, ọmọ ọdún 13 kan “pokùn so lẹ́yìn tí ó ti kọ ìwé jàn-ànràn kan, tí ó fi ròyìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúmọ́ni ọlọ́dún mẹ́ta kan, sílẹ̀.”a
Kí ní ń sọ ẹnì kan di abúmọ́ni gan-an? Bí o bá sì ń hùwà bí ọ̀kan fúnra rẹ, báwo ni o ṣe lè yí pa dà?
Kí Ní Ń Jẹ́ Abúmọ́ni?
Bíbélì sọ nípa àwọn abúmọ́ni tí wọ́n gbé ayé ṣáájú Ìkún Omi ọjọ́ Nóà. A pè wọ́n ní Néfílímù—ọ̀rọ̀ kan tí ó túmọ̀ sí “àwọn tí ń fa kí àwọn mìíràn ṣubú lulẹ̀.” Ní àkókò ìṣàkóso ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ wọn, “ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:4, 11, NW.
Bí ó ti wù kí ó rí, kò di ìgbà tí o bá ń lu àwọn ènìyàn tàbí tí o ń tì wọ́n ká kí o tó di abúmọ́ni. Ẹnikẹ́ni tí ń hùwà sí àwọn ènìyàn—ní pàtàkì, àwọn tí kò lágbára tàbí tí kò ní ààbò lọ́wọ́ ìkọlù—lọ́nà òǹrorò tàbí ìfìyàjẹni jẹ́ abúmọ́ni. (Fi wé Oníwàásù 4:1.) Àwọn abúmọ́ni máa ń gbìyànjú láti halẹ̀ mọ́ni, kí wọ́n dẹ́rù bani, kí wọ́n sì ṣàkóso ẹni. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ń lo ẹnu, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ́. Ní gidi, oríṣi ìfìyàjẹni yìí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ni ìbúmọ́ni ní ti èrò ìmọ̀lára. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè ní èébú, ìpẹ̀gàn, ìfiṣẹ̀sín, àti ìpèlórúkọ-yẹ̀yẹ́ nínú.
Àmọ́, nígbà míràn, ìbúmọ́ni lè jẹ́ lọ́nà jíjáfáfá. Bí àpẹẹrẹ, wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Lisa.b Ó dàgbà pẹ̀lú àwùjọ àwọn ọ̀rẹ́bìnrin kan. Àmọ́ nígbà tí ó di ọmọ ọdún 15, nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Lisa di arẹwà gidigidi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gba àfiyèsí púpọ̀. Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ mi bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ mi sílẹ̀, wọ́n sì ń pẹ̀gàn mi lẹ́yìn—tàbí lójú mi pàápàá.” Wọ́n tún tan irọ́ kálẹ̀ nípa rẹ̀, wọ́n ń gbìyànjú láti ba ìfùsì rere rẹ̀ jẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni, owú sún wọn láti bú mọ́ ọn lọ́nà àìgbatẹnirò àti òǹrorò.
Dídi Abúmọ́ni
Ìhùwàsí oníjàgídíjàgan sábà máa ń ní ṣe pẹ̀lú ipò tí ó wà nínú ilé tí ẹnì kan ń gbé. Èwe kan tí ń jẹ́ Scott sọ pé: “Oníjàgídíjàgan ni bàbá mi, nítorí náà, èmi náà jẹ́ oníjàgídíjàgan.” Aaron pẹ̀lú ní ìgbésí ayé ìdílé tí ó ṣòro. Ó rántí pé: “Mo mọ̀ pé àwọn ènìyàn mọ̀ nípa ipò ìdílé mi—pé ó yàtọ̀—n kò sì fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa káàánú mi.” Nítorí náà, nígbàkigbà tí Aaron bá kópa nínú eré ìdíje, ó gbọ́dọ̀ borí ni. Ṣùgbọ́n bíborí nìkan kò tó. Ó gbọ́dọ̀ tẹ́ àwọn abánidíje rẹ̀ lógo—ní pípe àfiyèsí wọn léraléra sí pé òun borí wọn.
Níhà míràn, àwọn òbí olùbẹ̀rù Ọlọ́run ló tọ́ Brent dàgbà. Ṣùgbọ́n ó jẹ́wọ́ pé: “Mo máa ń pa àwọn ènìyàn lẹ́rìn-ín, àmọ́ nígbà míràn, n kì í mọ ìgbà tó yẹ kí n ṣíwọ́, n óò sì pa ìmọ̀lára ẹnì kan lára.” Ìfẹ́ ọkàn Brent láti ṣe nǹkan amóríyá, kí ó sì pe àfiyèsí sí ara rẹ̀, ń mú kí ó ṣàìka ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn sí.—Òwe 12:18.
Ó jọ pé tẹlifíṣọ̀n ń nípa lórí àwọn èwe mìíràn. Àwọn eré oníwà ọ̀daràn ń fògo fún ‘àwọn ẹni líle,’ wọ́n sì ń mú kí ó jọ pé jíjẹ́ onínúure kì í ṣe ìwà akin. Àwọn eré apanilẹ́rìn-ín gbígbajúmọ̀ kún fún ọ̀rọ̀ ìpẹ̀gàn. Àwọn ìròyìn sábà máa ń tẹnu mọ́ ìjà àti àwọn ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí ń lọ nígbà tí a bá ń ṣeré ìdíje. Àwọn ọ̀rẹ́ wa pẹ̀lú lè nípa lórí bí a ṣe ń bá àwọn ẹlòmíràn lò. Nígbà tí àwọn ojúgbà wa bá jẹ́ abúmọ́ni, ó rọrùn fún wa láti wẹgbẹ́ wọn, kí wọ́n má baà fìtínà àwa fúnra wa.
Ohun yòó wù kí ipò náà jẹ́, bí o bá ń lo ọgbọ́n ìbúmọ́ni, nígbà náà, àwọn tí o ń jẹ níyà nìkan kọ́ ni o ń pa lára.
Àwọn Àbájáde Jálẹ̀ Ìgbésí Ayé
Ìwé ìròyìn Psychology Today sọ pé: “Bíbúmọ́ni lè bẹ̀rẹ̀ nígbà ọmọdé, ṣùgbọ́n, ó ń bá a lọ títí di ìgbà àgbàlagbà.” Ìwádìí kan tí a ròyìn nínú ìwé agbéròyìnjáde The Dallas Morning News ṣàwárí pé “ìpín 65 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọkùnrin tí a fi hàn bí abúmọ́ni nígbà tí wọ́n wà ní ìpele ẹ̀kọ́ kejì máa ń jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo nígbà tí wọ́n bá fi pé ọmọ ọdún 24.”
Lóòótọ́, gbogbo abúmọ́ni kọ́ ló ń di ọ̀daràn. Ṣùgbọ́n sísọ ṣíṣàìka ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn sí dàṣà lè dá àwọn ìṣòro gidi sílẹ̀ fún ọ níkẹyìn nínú ìgbésí ayé. Bí àṣà náà bá bá ọ wọ inú ìgbéyàwó, ó lè yọrí sí ìrora ọkàn líle koko fún alábàá-ṣègbéyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ. Níwọ̀n bí àwọn agbanisíṣẹ́ ti máa ń fẹ́ àwọn tí ó mọ bí a ṣeé gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn, ó lè dù ọ́ láǹfààní rírí iṣẹ́ ṣe. A lè fawọ́ àwọn àǹfààní ọjọ́ iwájú nínú ìjọ Kristẹni sẹ́yìn bákan náà. Brent wí pé: “Lọ́jọ́ kan ṣáá, èmi yóò fẹ́ láti tóótun láti ṣiṣẹ́ sìn bí alàgbà, ṣùgbọ́n dádì mi jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn ènìyàn kì yóò mú ìṣòro wọn wá sọ́dọ̀ mi, bí wọ́n bá rò pé mo lè sọ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nípa nǹkan náà.”—Títù 1:7.
Ọ̀nà Láti Yí Pa Dà
A kì í sábà rí àwọn ẹ̀bi ara wa ní kedere. Ìwé Mímọ́ kìlọ̀ fún wa pé ẹnì kan tilẹ̀ lè máa “pọ́n ara rẹ̀ ní ojú ara rẹ̀ títí a óò fi rí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ láti kórìíra.” (Orin Dáfídì 36:2) Nítorí náà, o lè gbìyànjú láti béèrè ohun tí òbí kan, ọ̀rẹ́ tí a gbẹ́kẹ̀ lé kan, tàbí Kristẹni adàgbàdénú kan kíyè sí lọ́wọ́ wọn. Òtítọ́ lè dunni, ṣùgbọ́n ó lè wulẹ̀ ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí àwọn ìyípadà tí ó yẹ kí o ṣe. (Òwe 20:30) Aaron sọ pé: “Mo rò pé ohun títóbi jù lọ tí ó ràn mí lọ́wọ́ ni fífetí sí ìmọ̀ràn. Àwọn tí wọ́n ní òótọ́ ọkàn sọ ibi tí mo ti ń ṣìnà fún mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe ohun tí mo ń fẹ́ gbọ́, ṣùgbọ́n ohun tí mo nílò ní ti gidi ni.”
Èyí ha túmọ̀ sí pé o ní láti ṣe ìyípadà àkópọ̀ ìwà rẹ lọ́nà amúnijígìrì kan bí? Rárá, ó ṣeé ṣe kí ó wulẹ̀ jẹ́ ọ̀ràn ṣíṣe àtúnṣebọ̀sípò ìrònú rẹ àti ọ̀nà ìhùwà rẹ. (Kọ́ríńtì Kejì 13:11) Bí àpẹẹrẹ, bóyá títí di báyìí, o ti rò pé o lọ́lá jù nítorí bí o ṣe tóbi tó, okun tí o ní, àti làákàyè rẹ. Ṣùgbọ́n Bíbélì fúnni níṣìírí láti máa hùwà ‘pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí a máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ.’ (Fílípì 2:3) Mọ̀ pé àwọn ẹlòmíràn—láìka bí wọ́n ṣe tóbi tó tàbí okun tí wọ́n ní sí—ní àwọn ànímọ́ títayọ lọ́lá tí ìwọ kò ní.
O tún lè ní láti gba ara rẹ lọ́wọ́ ìtẹ̀sí jíjẹ́ oníjàgídíjàgan tàbí ajẹgàbaléni. Ṣiṣẹ́ lórí ‘ṣíṣàìmáa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara rẹ nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.’ (Fílípì 2:4) Bí o bá lómìnira láti sọ èrò kan jáde, ṣe bẹ́ẹ̀ láìjẹ́ lọ́nà ìbúni, ìpẹ̀gàn, tàbí ìwọ̀sí.—Éfésù 4:31.
Bí o bá bọ́ sábẹ́ ìdẹwò láti bú mọ́ni, rántí pé Ọlọ́run pa àwọn Néfílímù abúmọ́ni run. (Jẹ́nẹ́sísì 6:4-7; 7:11, 12, 22) Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, ní àwọn ọjọ́ wòlíì Ìsíkẹ́ẹ̀lì, Ọlọ́run sọ ọ̀rọ̀ àìṣètẹ́wọ́gbà gidigidi nípa àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ‘gbígbún’ àti ‘kíkan’ àwọn tí kò lólùrànlọ́wọ́. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:21) Mímọ̀ pé Jèhófà kórìíra ìbúmọ́ni lè jẹ́ ìsúnniṣe lílágbára kan fún ẹnì kan láti ṣe àwọn ìyípadà yíyẹ!
Ó tún ṣàǹfààní láti ṣàṣàrò tàdúràtàdúrà lórí àwọn ìlànà inú Bíbélì. Òfin Oníwúrà náà sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ̀yin bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ̀yin pẹ̀lú gbọ́dọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Nígbà tí o bá wà lábẹ́ ìdẹwò láti dẹ́rù ba ẹnì kan, bi ara rẹ léèrè pé: ‘Èmi ha fẹ́ kí a bú mọ́ mi, kí a dẹ́rù bà mí, tàbí kí a tẹ́ mi lógo bí? Nígbà náà, èé ṣe tí mo fi ń bá àwọn ẹlòmíràn lò lọ́nà bẹ́ẹ̀?’ Bíbélì pàṣẹ fún wa pé kí a ‘di onínúrere sí ara wa lẹ́nìkínní kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.’ (Éfésù 4:32) Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ lọ́nà yí. Bí òun tilẹ̀ lọ́lá ju gbogbo ẹ̀dá ènìyàn míràn lọ, ó fi inú rere, ìgbatẹnirò, àti ọ̀wọ̀ bá ẹni gbogbo lò. (Mátíù 11:28-30) Gbìyànjú láti ṣe bákan náà nígbà tí o bá kojú ẹnì kan tí kò lágbára tó ọ—tàbí ti ó tilẹ̀ ń mú ọ bínú gidigidi.
Àmọ́, bí ìwà jàgídíjàgan rẹ bá jẹ́ nítorí ìmọ̀lára ìbínú lórí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń bá ọ lò nínú ilé ńkọ́? Nínú àwọn ọ̀ràn kan, irú ìbínú bẹ́ẹ̀ lè tọ̀nà. (Fi wé Oníwàásù 7:7.) Síbẹ̀, Bíbélì sọ fún wa pé, a kìlọ̀ fún ọkùnrin olódodo náà, Jóòbù, pé: “Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí tító rẹ má baà tàn ọ́ lọ . . . Máa ṣọ́ra kí ìwọ kí ó máà yí ara rẹ pa dà sí asán.” (Jóòbù 36:18, 21) Kódà bí wọ́n bá ń fìyà jẹ ọ́, o kò ní ẹ̀tọ́ láti fìyà jẹ àwọn ẹlòmíràn. Ọ̀nà kan tí ó sàn jù yóò jẹ́ láti bá àwọn òbí rẹ jíròrò. Bí wọ́n bá ń fìyà jẹ ọ́ lọ́nà rírorò, o lè gba ìrànwọ́ lẹ́yìn òde ìdílé rẹ láti dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ ìpalára síwájú sí i.
Ó lè má rọrùn láti yí pa dà, ṣùgbọ́n ó ṣeé ṣe. Brent wí pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ lójoojúmọ́ ni mo ń gbàdúrà nípa èyí, Jèhófà sì ti ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìmúsunwọ̀n mélòó kan.” Bí ìwọ pẹ̀lú ṣe ń ṣe àwọn ìmúsunwọ̀n bákan náà nínú ọ̀nà tí o gbà ń bá àwọn ènìyàn lò, ó dájú pé, ìwọ yóò rí i pé àwọn ènìyàn yóò túbọ̀ fẹ́ràn rẹ dáradára sí i. Rántí pé àwọn ènìyàn lè máa bẹ̀rù àwọn abúmọ́ni, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tó fẹ́ràn wọn ní ti gidi.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò lórí bí àwọn òjìyà ìbúmọ́ni ṣe lè yẹra fún ìfòòró, wo “Awọn Ọ́dọ́ Beere Pe . . . Kinni Mo Lè Ṣe Nipa Awọn Òṣìkà-abúmọ́ni Ilé-ẹ̀kọ́?,” nínú ìtẹ̀jáde wa ti February 8, 1990.
b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
“Bíbúmọ́ni lè bẹ̀rẹ̀ nígbà ọmọdé, ṣùgbọ́n, ó ń bá a lọ títí di ìgbà àgbàlagbà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Èébú jẹ́ oríṣi ìbúmọ́ni kan