ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 5/22 ojú ìwé 6-10
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwà Yíyẹ fún Àwọn Ọkùnrin
  • Bíbẹ́gi Dínà Ìfòòró
  • Bí A Bá Fòòró Rẹ
  • Òpin Ìfòòró
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?
    Jí!—2000
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìṣòro Kárí Ayé Kan
    Jí!—1996
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Mi Lọ́wọ́ Àwọn Tó Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Fi Ìṣekúṣe Lọ̀ Mí?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 5/22 ojú ìwé 6-10

Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ

OLÙYẸ̀WÒṢÀTÚNṢE ìwé ìròyìn kan, Gretchen Morgenson, sọ pé: “Obìnrin kankan kò ní láti máa kojú ìfìbálòpọ̀lọni lójoojúmọ́, ṣùgbọ́n kì yóò lọ́gbọ́n nínú fún àwọn obìnrin láti fojú sọ́nà fún àyíká iṣẹ́ tí ó bọ́ lọ́wọ́ ìwà àìlajú.” Lọ́nà tí ó gbayì, ìsapá àwọn agbanisíṣẹ́ àti àwọn ilé ẹjọ́ láti mú kí ibi iṣẹ́ túbọ̀ fọkàn balẹ̀ ń ní ìyọrísí rere díẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ewu pípe ẹjọ́ ti sún àwọn agbanisíṣẹ́ àti àwọn òṣìṣẹ́ kárí ayé láti gbìyànjú láti mú kí àyíká iṣẹ́ túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ti ṣètò àwọn ìgbésẹ̀ abẹ́lé láti bójú tó ìfìbálòpọ̀ lọni níbi iṣẹ́. Àwọn ìpàdé àti àpérò ń wáyé láti dá àwọn òṣìṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́ lórí ìwà yíyẹ níbi iṣẹ́.

Dájúdájú, ó wulẹ̀ bọ́gbọ́n mu láti mọ àwọn ìlànà ètò ilé iṣẹ́ àti àwọn òfin àdúgbò, kí a sì tẹ̀ lé wọn. (Romu 13:1; Titu 2:9) Àwọn Kristian tún ti rí i pé lílo àwọn ìlànà Bibeli ń ṣèrànwọ́. Títẹ̀ lé àwọn ìtọ́sọ́nà onímìísí wọ̀nyí nínú ìbálò rẹ pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ púpọ̀ láti yẹra fún dídi òjìyà ìpalára fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni—tàbí ẹni tí ń ṣe é gan-an.

Ìwà Yíyẹ fún Àwọn Ọkùnrin

Yẹ ọ̀ràn bí ó ṣe yẹ kí àwọn ọkùnrin máa bá àwọn obìnrin lò wò. Ọ̀pọ̀ ògbógi ti kìlọ̀ lòdì sí fífọwọ́ kan ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà kejì. Wọ́n kìlọ̀ pé a lè fìrọ̀rùn ṣi wíwulẹ̀ fọwọ́ gbáni lẹ́yìn bí ọ̀rẹ́ lóye. Amòfin ọ̀ràn iṣẹ́ kan, Frank Harty, ṣàkíyèsí pé: “Àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ elétí gbáròyé kì í fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú fífọwọ́ tọ́ni.” Kí ni ó dámọ̀ràn? “Bí ó bá ju wíwulẹ̀ bọwọ́ lọ, má ṣe é.” Òtítọ́ ni pé Bibeli funra rẹ̀ kò gbé òfin tí ó dárúkọ gbogbo ipò ọ̀ràn yìí kalẹ̀.a Ṣùgbọ́n lójú ìwòye ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ ní ti ọ̀ràn òfin àti ìwà híhù, ó gba ìṣọ́ra—ní pàtàkì fún àwọn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí fífọwọ́ tọ́ni láìròtì nígbà tí wọ́n bá ń báni sọ̀rọ̀.

A gbà pé irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ kò rọrùn láti tẹ̀ lé. Fún àpẹẹrẹ, Glen wá láti inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Spain. Ó sọ pé: “Níbi tí mo ti wá, àwọn ènìyàn wulẹ̀ nítẹ̀sí láti rọ̀ mọ́ ọ ju níhìn-ín ní United States lọ. Nínú ìdílé mi, a sábà máa ń kí àwọn ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ìfẹnukonu, ṣùgbọ́n níbí, a ń kìlọ̀ fún wa láti má ṣe yára ṣe bẹ́ẹ̀.” Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìlànà Bibeli wúlò nínú ọ̀ràn yìí. Aposteli Paulu sọ fún ọ̀dọ́kùnrin Timoteu pé: “Máa bá àwọn ọ̀dọ́kùnrin lò bí arákùnrin, àwọn àgbàbìnrin bí ìyá, àti àwọn ọ̀dọ́bìnrin bí arábìnrin, pẹ̀lú ìwà mímọ́ pátápátá.” (1 Timoteu 5:1, 2, New International Version) Ìyẹn kì yóò ha fagi lé ìfọwọ́kàn tajátẹran, tí ń dẹni wò, tàbí tí a kò fẹ́?

A lè lo ìlànà kan náà yẹn fún ọ̀rọ̀ sísọ. Ó bá a mu pé Bibeli sọ pé: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nukan àgbèrè ati ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo tabi ìwà ìwọra láàárín yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ awọn ènìyàn mímọ́; bẹ́ẹ̀ naa ni ìwà tí ń tinilójú tabi ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tabi ìṣẹ̀fẹ̀ rírùn akóninírìíra, awọn ohun tí kò yẹ.” (Efesu 5:3, 4) Kathy Chinoy tí ó jẹ́ amòfin ọ̀ràn fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹní dábàá pé, kí o tó sọ̀rọ̀, gbé ìbéèrè kan yẹ̀ wò pé: “Ìwọ yóò ha fẹ́ kí ìyẹ́n ṣẹlẹ̀ sí ìyá rẹ, arábìnrin rẹ, tàbí ọmọbìnrin rẹ bí?” Ọ̀rọ̀ àlùfààṣá, tí ń múni ro ìròkurò ń tàbùkù ẹni tí ń sọ ọ́ àti ẹni tí ń gbọ́ ọ.

Bíbẹ́gi Dínà Ìfòòró

Báwo ni ẹnì kan ṣe lè gbìyànjú láti yẹra fún dídi ẹni tí a fòòró? Bóyá ìmọ̀ràn tí Jesu fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó rán wọn jáde lọ nínú iṣẹ́ àyànfúnni ìwàásù wọn àkọ́kọ́ lè ṣeé mú lò nínú ọ̀ràn yìí pé: “Wò ó! Mo ń rán yín jáde gẹ́gẹ́ bí àgùtàn sáàárín awọn ìkookò; nitori naa ẹ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùnmímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.” (Matteu 10:16) Bí ó ti wù kí ó rí, Kristian kan kò ṣàìnírànwọ́. Bibeli fi dá wa lójú pé: “Nígbà tí ọgbọ́n bá wọ inú rẹ lọ . . . , ìmòye yóò pa ọ́ mọ́, òye yóò sì máa ṣọ́ ọ.” (Owe 2:10, 11) Nítorí náà, jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà Bibeli díẹ̀ tí ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti dáàbò bo ara rẹ.

1. Ṣọ́ àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ. Èyí kò túmọ̀ sí pé kí o má ṣe yára mọ́ni tàbí kí o máa kanra, nítorí Bibeli rọ̀ wá láti “máa lépa àlàáfíà pẹlu gbogbo ènìyàn.” (Heberu 12:14; Romu 12:18) Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí Bibeli ti rọ àwọn Kristian láti “máa bá a lọ ní rírìn ninu ọgbọ́n sí awọn wọnnì tí ń bẹ ní òde,” ó bọ́gbọ́n mu láti máa ní ìwà ṣíṣe iṣẹ́ bí iṣẹ́, ní pàtàkì nígbà tí a bá ń bá àwọn ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà kejì lò. (Kolosse 4:5) Ìwé Talking Back to Sexual Pressure, tí Elizabeth Powell kọ, rọ àwọn òṣìṣẹ́ “láti mọ ààlà pàtó láàárín ìṣarasíhùwà ọlọ́yàyà tí ó yẹ ipa iṣẹ́ wọn àti irú jíjẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́ tí ó lè dọ́gbọ́n túmọ̀ sí ìfọkànfẹ́ ìbálòpọ̀.”

2. Múra níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ohun tí o wọ̀ ń sọ ohun kan fún àwọn ẹlòmíràn. Lẹ́yìn lọ́hùn-ún nígbà tí a ń kọ Bibeli, wíwọ irú àwọn aṣọ kan ń fi ẹnì kan hàn bí oníwà pálapàla tàbí oníṣekúṣe. (Owe 7:10) Ohun kan náà sábà máa ń jẹ́ òtítọ́ lónìí; wíwọ àwọn aṣọ fífún, tí ń tàn yòyò, tàbí tí ń fìhòòhò hàn lè fa oríṣi àfiyèsí òdì. Òtítọ́ ni pé àwọn kan lè rò pé àwọ́n ní ẹ̀tọ́ láti wọ ohun tí àwọ́n bá fẹ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé Elizabeth Powell ṣe sọ ọ́, “bí o bá ń ṣiṣẹ́ láàárín àwọn tí wọ́n gbà pé jíjí owó gbé dára, èmi yóò gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kí o má fi ìdì owó rẹ síbi tí ọwọ́ wọ́n ti lè tó o. . . . O gbọ́dọ̀ mọ ibi tí àìlera wà nínú . . . ìhùwàsí àwùjọ, kí o sì gbìyànjú láti dáàbò bo ara rẹ kí wọ́n má baà fi ọ́ ṣe ìjẹ.” Ìmọ̀ràn Bibeli náà tipa báyìí bágbà mu. Ó ṣí àwọn obìnrin létí láti “máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹlu ìmẹ̀tọ́mọ̀wà ati ìyèkooro èrò inú.” (1 Timoteu 2:9) Múra níwọ̀ntúnwọ̀nsì, o sì lè ṣàìdi ohun àfojúsùn fún ọ̀rọ̀ àti ìhùwà atẹ́nilógo.

3. Ṣọ́ irú ẹgbẹ́ tí o ń kó! Bibeli sọ fún wa nípa ọ̀dọ́bìnrin kan tí ń jẹ́ Dina, tí ó di òjìyà ìfipábánilòpọ̀. Ó ṣe kedere pé ó fa àfiyèsí olùgbákò rẹ̀ mọ́ra nítorí tí ó máa ń “jáde lọ láti wo àwọn ọmọbìnrin ìlú náà” ní Kenaani—àwọn obìnrin tí a mọ̀ mọ ìṣekúṣe! (Genesisi 34:1, 2) Bákan náà lónìí, bí o bá ń fọ̀rọ̀ wérọ̀—tàbí fetí sí—àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ tí a mọ̀ mọ jíjíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè, àwọn kán lè parí èrò sí pé o fọkàn fẹ́ ìfìbálòpọ̀lọni.

Èyí kò túmọ̀ sí pé kí o ṣá àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ tì. Ṣùgbọ́n bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà bá di èyí tí kò tọ́, o kò ṣe rọra pasẹ̀ dà? Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti rí i pé jíjẹ́ ẹni tí a mọ̀ mọ ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere gíga máa ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìfòòró.—1 Peteru 2:12.

4. Yẹra fún àwọn ipò tí ń súnni juwọ́ sílẹ̀. Bibeli sọ bí ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ Amnoni ṣe dọ́gbọ́n àrékérekè láti dá wà pẹ̀lú ọ̀dọ́bìnrin kan tí ń jẹ́ Tamari, kí ó lè kó o nífà ìbálòpọ̀. (2 Samueli 13:1-14) Àwọn afòòró ẹni lóde òní lè hùwà lọ́nà jíjọra, bóyá ní kíké sí ọmọ abẹ́ wọn láti nípìn-ín nínú mímu ọtí líle pẹ̀lú wọn tàbí láti dúró lẹ́yìn iṣẹ́ láìsí ìdí kan tí ó ṣe kedere. Ṣọ́ra fún irú ìkésíni bẹ́ẹ̀! Bibeli sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó sì pa ara rẹ̀ mọ́.”—Owe 22:3.

Bí A Bá Fòòró Rẹ

Ó dájú pé àwọn ọkùnrin kan yóò fìlọ̀kulọ̀ lọni, àní nígbà tí obìnrin kan bá tilẹ̀ ń hùwà láìlálèébù. Báwo ni ó ṣe yẹ kí o hùwà padà bí a bá dojú irú ìfilọni bẹ́ẹ̀ kọ ọ́? Àwọn kan ti dábàá wíwulẹ̀ kojú rẹ̀ láìfi ìbínú hàn! Obìnrin kan sọ pé, ‘Ìbálòpọ̀ níbi iṣẹ́ jẹ́ ohun amáyédùn!’ Bí ó ti wù kí ó rí, dípò wíwo irú àfiyèsí tí kò yẹ bẹ́ẹ̀ bí àwàdà tàbí àpọ́nlé, ó kó àwọn Kristian tòótọ́ nírìíra. Wọ́n “fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ohun burúkú,” wọ́n sì mọ̀ pé ète irú ìfilọni bẹ́ẹ̀ sábà máa ń jẹ́ láti tanni sí ìwà pálapàla takọtabo. (Romu 12:9; fi wé 2 Timoteu 3:6.) Ó kéré pin, ìwà àìlajú náà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí ipò iyì jíjẹ́ Kristian wọn. (Fi wé 1 Tessalonika 4:7, 8.) Báwo ni o ṣe lè bójú tó irú ipò bẹ́ẹ̀?

1. Jẹ́ onípinnu! Bibeli sọ fún wa nípa bí ọkùnrin olùbẹ̀rù Ọlọrun kan, tí ń jẹ́ Josefu, ṣe hùwà padà sí ìfilọni ìwà pálapàla pé: “Ó sì ṣe lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni aya olúwa rẹ̀ gbójú lé Josefu; ó sì wí pé, Bá mi ṣe.” Josefu ha wulẹ̀ ṣàìka ìwà àṣejù obìnrin náà sí, ní ríretí pé ìṣòro náà yóò kásẹ̀ nílẹ̀ fúnra rẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ kọ rárá! Bibeli sọ pé ó fi tìgboyàtìgboyà kọ ìfilọni rẹ̀, ní wíwí pé: “Ǹjẹ́ èmi ó ha ti ṣe hu ìwà búburú ńlá yìí, kí èmí sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?”—Genesisi 39:7-9.

Ìṣarasíhùwà Josefu fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fún tọkùnrin-tobìnrin. Ṣíṣàìka ọ̀rọ̀ rírùn tàbí ìwà jàgídíjàgan sí—tàbí èyí tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ, dídi ẹni tí a fi dẹ́rù bà—kì í jẹ́ kí ó tán nílẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù tàbí àìdára-ẹni-lójú lè mú kí ó máa le sí i! Olùgbaninímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìfipábánilòpọ̀, Martha Langelan, kìlọ̀ pé àwọn tí ń fipá báni lò pọ̀ sábà máa ń lo fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni bí “ọ̀nà kan láti díwọ̀n ṣíṣeé ṣe pé obìnrin kan yóò jà padà bí a bá kọ lù ú; bí ó bá dákẹ́ tí ó sì tijú nígbà tí wọ́n fòòró rẹ̀, wọ́n gbà pé yóò dákẹ́, yóò sì bẹ̀rù bí wọ́n bá kọ lù ú.” Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí o jẹ́ onípinnu nígbà tí o bá ti rí àmì ìfòòró nígbà àkọ́kọ́. Gẹ́gẹ́ bí òǹkọ̀wé kan ṣe sọ, “sísọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láìṣe mẹinmẹin ti tó lọ́pọ̀ ìgbà láti mú kí afòòró ẹni náà ṣíwọ́ ìwà tí ń múni bínú náà.”

2. Jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́! Jesu sọ ìyẹn nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè. (Matteu 5:37) Gbólóhùn rẹ̀ yìí bá àwọn ipò wọ̀nyí mu, níwọ̀n bí àwọn afòòró ẹni ti máa ń tẹpẹlẹ mọ́ nǹkan gan-an. Báwo gan-an ni ó ṣe yẹ kí o dúró gbọnyin tó? Ìyẹ́n sinmi lórí àyíká ipò náà àti ìhùwàpadà afòòró ẹni náà. Lo ìwọ̀n ìdúrógbọnyin èyíkéyìí tí ó bá pọn dandan láti mú un lóye ìdúró rẹ. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, gbólóhùn tààrà, tí ó rọrùn, tí a sì fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ ti tó. Wò ó lójú kòrókòró. Àwọn ògbógi dá àwọn àbá wọ̀nyí: (a) Sọ ìmọ̀lára rẹ jáde. (“N kò nífẹ̀ẹ́ sí i rárá nígbà tí o . . .”) (b) Dárúkọ ìwà tí ń múni bínú náà ṣàkó. (“. . . nígbà tí o bá ń lo èdè àìlajú, rírùn . . .”) (d) Jẹ́ kí ohun tí o fẹ́ kí ẹni náà ṣe hàn kedere. (“Mo fẹ́ kí o ṣíwọ́ sísọ̀rọ̀ sí mi bẹ́ẹ̀!”)

Langelan kìlọ̀ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, lábẹ́ ipòkípò, ìkonilójú kò gbọdọ̀ di ìkóguntini. Ìhùwàpadà oníkòóguntini (lílo ìwọ̀sí, ìhalẹ̀mọ́ni, àti ìfìyàjẹni ọlọ́rọ̀ ẹnu, líluni ní ìkúùkù, títutọ́ sí afòòró ẹni lójú) kì í sèso rere. Ìwà ipá ọlọ́rọ̀ ẹnú léwu, kò sì sí ìdí láti lo ìwà ipá gidi bí kò bá jẹ́ pé ìkọlù gidi tí ń béèrè fún ìgbèjà ara ẹní ṣẹlẹ̀.” Irú ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ bẹ́ẹ̀ bára mu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Bibeli ní Romu 12:17 pé: “Ẹ máṣe fi ibi san ibi fún ẹni kankan.”

Bí ìfòòró ẹni náà bá ń bá a lọ láìka ìsapá dídára jù lọ rẹ láti dá a dúró sí ńkọ́? Àwọn ilé iṣẹ́ kan ti lànà àwọn ìgbésẹ̀ fún bíbójú tó fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni. Lọ́pọ̀ ìgbà, kìkì ìhàlẹ̀ láti fẹjọ́ sun ilé iṣẹ́ yóò mú kí ẹni tí ń fòòró rẹ fi ọ́ sílẹ̀ jẹ́ẹ́. Síbẹ̀ náà, ó lè ṣàìrí bẹ́ẹ̀. Ó dunni pé, rírí alábòójútó tí ń gba tẹni rò kì í fìgbà gbogbo rọrùn fún ì báà jẹ́ obìnrin tàbí ọkùnrin. Glen, tí ó sọ pé obìnrin òṣìṣẹ́ kan ń fòòró òún gbìyànjú láti fẹjọ́ sùn. Ó rántí pé: “Nígbà tí mo sọ fún ọ̀gá náà nípa rẹ̀, n kò rí ìrànlọ́wọ́ kankan gbà. Ní gidi, ó rò pé ọ̀rọ̀ ìpanilẹ́rìn-ín lásán ni. Mo wulẹ̀ ní láti máa ṣọ́ obìnrin náà, kí n sì sapá lákànṣe láti yẹra fún un.”

Àwọn kan ti gbìyànjú pípẹjọ́. Ṣùgbọ́n àwọn àgbàyanu ìdájọ́ tí o ń kà nínú ìwé agbéròyìnjáde kì í ṣe àpẹẹrẹ ohun tí ń fìgbà gbogbo ṣẹlẹ̀. Láfikún sí i, ìwé Talking Back to Sexual Pressure kìlọ̀ pé: “Fifi ọ̀ràn òfin yanjú ìfòòró ń gba okun èrò ìmọ̀lára àti àkókò jaburata; ó máa ń yọrí sí másùnmáwo ara ìyára àti ti ọpọlọ.” Pẹ̀lú ìdí rere, Bibeli kìlọ̀ pé: “Ma ṣe fi ìwàǹwára lọ ṣe ẹjọ́ òfin.” (Owe 25:8, NW) Lẹ́yìn ṣíṣírò ohun tí pípẹjọ́ yóò ná wọn ní ti èrò ìmọ̀lára àti tẹ̀mí, àwọn kan ti yàn láti wá iṣẹ́ mìíràn.

Òpin Ìfòòró

Fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni kì í ṣe ohun tuntun. Ó kárí ayé bí ọkàn-àyà oníwọra ẹ̀dá ènìyàn aláìpé, tí ń pète ibi. Àwọn ẹjọ́ níwájú ìgbìmọ̀ àti nílé ẹjọ́ kì yóò gba àwùjọ ènìyàn lọ́wọ́ fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni. Kíkásẹ̀ fífi ìbálòpọ̀ fòòró ẹni nílẹ̀ ń béèrè fún ìyípadà ọkàn-àyà nínú àwọn ènìyàn.

Lónìí, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti ẹ̀mí rẹ̀ ń ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ènìyàn kárí ayé. Ńṣe ni ó dà bíi kí àwọn ìkookò àti kìnnìún máa kọ́ láti hùwà bí ọ̀dọ́ àgùntàn àti ọmọ màlúù, bí wòlíì Isaiah ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gan-an. (Isaiah 11:6-9) Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú àwọn ènìyàn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ran ẹgbẹẹgbẹ̀rún ‘àwọn ìkookò’ tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ lọ́dọọdún láti ṣé ìyípadà pípẹ́ títí, tí ó jinlẹ̀, nínú àkópọ̀ ìwà wọn. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń ṣègbọràn sí àṣẹ Ìwé Mímọ́ láti “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ èyí tí ó bá ìlà ipa-ọ̀nà ìwà yín àtijọ́ ṣe déédéé” àti láti gbé “àkópọ̀ ìwà titun wọ̀ èyí tí a dá ní ìbámu pẹlu ìfẹ́-inú Ọlọrun ninu òdodo tòótọ́ ati ìdúróṣinṣin” rọ́pò rẹ̀.—Efesu 4:22-24.

Lọ́jọ́ kan, ilẹ̀ ayé yóò kún fún àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n Bibeli. Àwọn ènìyàn olùbẹ̀rù Ọlọrun ń fi ìháragàgà dúró de ọjọ́ yẹn, nígbà tí òpin yóò dé bá gbogbo ìbálò àìtọ́. Títí di ìgbà náà, wọ́n ń kojú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òde òní tí kò bójú mu bí wọ́n ti lè ṣe tó.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó hàn gbangba pé ìkìlọ̀ Paulu nínú 1 Korinti 7:1 láti “máṣe fọwọ́kan obìnrin” ń tọ́ka sí ìfarakanra ìbálòpọ̀, kì í ṣe fífọwọ́ tọ́ lásán. (Fi wé Owe 6:29.) Nínú àyíká ọ̀rọ̀ náà, Paulu ń fún wíwà ní àpọ́n níṣìírí, ó sì ń kìlọ̀ lòdì sí ìwà pálapàla takọtabo.—Wo “Ibere lati Ọwọ Awọn Onkawe Wa” nínú Ile-Iṣọ Na, February 1, 1974.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 7]

“Ìwọ yóò ha fẹ́ kí ìyẹ́n ṣẹlẹ̀ sí ìyá rẹ, arábìnrin rẹ, tàbí ọmọbìnrin rẹ bí?”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ìhùwàsí ṣíṣe iṣẹ́ bí iṣẹ́ àti ìmúra oníwọ̀ntunwọ̀nsì lè dáàbò boni lọ́wọ́ ìfòòró

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn Kristian tòótọ́ lónìí ń kọ́ láti báni lò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́