Ibi Iṣẹ́ Àbí Ojú Ogun?
LÁTỌWỌ́ ÒǸKỌ̀WÉ JÍ! NÍ JÁMÁNÌ
“Ara mi ò gbà á mọ́. Ó lé lọ́gbọ̀n ọdún tí mo fi bá ilé iṣẹ́ náà ṣiṣẹ́. Mo ti dépò alábòójútó. Bí wọ́n ṣe gbé ọ̀gá tuntun dé nìyẹn o. Ọ̀dọ́ ni, ó já fáfá, ọgbọ́n sì kún agbárí ẹ̀. Ńṣe ló wò mí bí ẹni tó ń fawọ́ aago ilé iṣẹ́ yẹn sẹ́yìn, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí fòòró mi nìyẹn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù tó fi ń fìwọ̀sí lọ̀ mí, tó ń purọ́ mọ́ mi, tó sì ń rí mi fín, mo sún kan ògiri. Nígbà tí ilé iṣẹ́ náà sọ pé àwọn lè sanwó ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ fún mi, mo gbà láti fiṣẹ́ wọn sílẹ̀.”—Peter.a
WỌ́N máa ń fòòró Peter lẹ́nu iṣẹ́. Bá a bá ní ká lo ọ̀rọ̀ mìíràn tí wọ́n sábà máa ń lò nílẹ̀ Yúróòpù, a óò kúkú sọ pé wọ́n ń “jùmọ̀ hàn” án “léèmọ̀.” Lórílẹ̀-èdè Jámánì, níbi tí Peter ń gbé, àwọn èèyàn tí wọ́n fojú bù pé wọ́n tó ọgọ́ta ọ̀kẹ́ ni wọ́n ń hàn léèmọ̀ lẹ́nu iṣẹ́. Lórílẹ̀-èdè Netherlands, nínú èèyàn mẹ́rin, a óò rí ẹnì kan tí wọ́n máa hàn léèmọ̀ nígbà kan ṣá lẹ́nu iṣẹ́. Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Àwọn Òṣìṣẹ́ Lágbàáyé sì fi tóni létí pé ìṣòro tó ń ga bí òkè lọ̀ràn à ń hanni léèmọ̀ ní Ọsirélíà, Austria, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Denmark, Sweden àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Kí tiẹ̀ ló ń jẹ́ jíjùmọ̀ hanni léèmọ̀?
“Ogun Tó Ń Dáni Lágara”
Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ilẹ̀ Jámánì náà, Focus, ṣe sọ, jíjùmọ̀ hanni léèmọ̀ jẹ́ “dídọ́gbọ́n fòòró ẹni lemọ́lemọ́ àti léraléra.” Ó kọjá ohun tá a lè pè ní fífiniṣeyẹ̀yẹ́ lẹ́nu iṣẹ́, lára èyí tí fífi ọ̀rọ̀ gúnni lára, ṣíṣe àríwísí, títọ́ni níjà àti àpárá líle wà, mímọ̀ọ́mọ̀ yọ ayé lẹ́mìí ẹni gbáà ló jẹ́. Gbogbo ohun tó sì dá lé lórí ò ju kí wọ́n lè sọ ẹni tí wọ́n ń hàn léèmọ̀ náà dí ẹni ìtanù.b
Onírúurú ọ̀nà ni wọ́n ń gbà fòòró ẹni, wọ́n lè tani láyà, wọ́n sì lè ṣeni léṣe tààrà. Wọ́n lè ba ẹni tí wọ́n dójú sọ náà lórúkọ jẹ́, wọ́n lè bú u bí ẹní láyin, wọ́n lè máa wá ìjà ẹ̀, tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ sú já a mọ́. Wọ́n á mọ̀ọ́mọ̀ fi iṣẹ́ pá àwọn míì lórí tàbí kí wọ́n máa yàn wọ́n nígbà gbogbo pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ tí kò gbádùn mọ́ni táwọn mìí máa ń sá fún. Àwọn tó jẹ́ alábàáṣiṣẹ́ ẹni tí wọ́n ń fòòró náà sì lè máa ba iṣẹ́ jẹ́ mọ́ ọn lọ́wọ́, bóyá nípa fífi àwọn ìsọfúnni kan tó nílò pa mọ́. Láwọn ìgbà míì, àwọn tó ń hanni léèmọ̀ ti fọ́ táyà ẹni tí wọ́n ń fòòró tàbí kí wọ́n tọwọ́ bọ kọ̀ǹpútà rẹ̀ lójú.
Ẹnì kan ṣoṣo ló máa ń dá àwọn kan tí wọ́n ń fòòró sọjú. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, àgbájọ àwọn òṣìṣẹ́ ló máa ń sòpàǹpá láti fòòró ẹlòmíì. Ìdí tí ọ̀rọ̀ náà, ‘jíjùmọ̀ hanni léèmọ̀’ fi bá a mu nìyẹn, níwọ̀n bó ti túmọ̀ sí pé àwùjọ àwọn èèyàn ń máye nira fún ẹnì kan ṣoṣo nípa mímọ̀ọ́mọ̀ mú un bínú tàbí nípa gbígbéjà kò ó.
Èyí tó tiẹ̀ wá yani lẹ́nu jù níbẹ̀ ni pé lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀gá iṣẹ́ máa ń mọ̀ sí ìfòòró ẹni náà. Nínú àwọn ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nílẹ̀ Yúróòpù, alábòójútó iṣẹ́ gan-an ló múpò iwájú nínú ìdajì ìfòòró ẹni tó wáyé, lọ́pọ̀ ìgbà sì rèé, òun náà gan-an lẹnì kan ṣoṣo tó ń fòòró ẹlòmíì. Gbogbo èyí wá sọ ibi iṣẹ́ di ohun tí ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ ti ilẹ̀ Jámánì náà, Frankfurter Allgemeine Zeitung, pè ní “ogun tó ń dá ara lágara tá à ń fi gbogbo ọjọ́ jà, tó sì ń mú kó rẹni.”
Ọṣẹ́ Tó Ń Ṣe Ò Mọ Síbi Iṣẹ́
Lọ́pọ̀ ìgbà, ọṣẹ́ tí ìfòòró ẹni ń ṣe ò mọ síbi iṣẹ́ o. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ń fòòró ni ìlera wọn máa ń jagọ̀ tàbí kí ìwà ìkà tí wọ́n ń hù sí wọn di àìsàn sí wọn lára. Àárẹ̀ ọkàn, àìróorunsùntó àti ìbẹ̀rù pé wọ́n á hanni léèmọ̀ wà lára àwọn ohun tó máa ń tẹ̀yìn ìfòòró ẹni yọ. Peter, tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ńkọ́? Kò tiẹ̀ wá já mọ́ nǹkankan lójú ara ẹ̀ mọ́. Dókítà Margaret, obìnrin kan tóun náà jẹ́ ará Jámánì, gbà á níyànjú pé kó lọ gbàtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn tó ń tọ́jú ọpọlọ. Kí nìdí? Wọ́n ń fòòró ẹ̀ níbi iṣẹ́. Híhanni léèmọ̀ tún lè kó bá ìgbéyàwó ẹni tàbí àwọn tó wà lọ́ọ̀dẹ̀ ẹni.
Ní Jámánì, fífòòró ẹni níbi iṣẹ́ ti wọ́pọ̀ débi pé ilé iṣẹ́ abánigbófò ìlera kan ní nọ́ńbà tẹlifóònù táwọn tí wọ́n ń fòòró fi lè ké sí wọn bí wọ́n bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́. Ilé iṣẹ́ náà rí i pé ó ju ìdajì lọ lára àwọn tó ké sí wọn tí kò lè ṣiṣẹ́ fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, ìdámẹ́ta lára wọn ò lè ṣiṣẹ́ fún bí oṣù mẹ́ta, ó sì ju oṣù mẹ́ta lọ tí èyí tó ju ìdá mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún lọ lára wọn ò fi lè ṣiṣẹ́. Ìwé ìròyìn ìṣègùn kan nílẹ̀ Jámánì ṣírò rẹ̀ pé “a óò rí ẹnì kan nínú ẹni márùn-ún lára àwọn tó para wọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé wọ́n hàn wọ́n léèmọ̀.”
Ó ṣe kedere nígbà náà pé fífòòró ẹni lè sọ iṣẹ́ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ mọ́ni lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ọ̀nà kan wà tá a lè gbà kòòré ìṣòro yìí? Báwo la ṣe lè máa wà ní ìrẹ́pọ̀ lẹ́nu iṣẹ́?
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí padà.
b Ìsọfúnni oníṣirò fi hàn pé àwọn obìnrin tí wọ́n ń fòòró lẹ́nu iṣẹ́ pọ̀ ju ọkùnrin lọ, àmọ́, ó lè jẹ́ ohun tó fa èyí ni pé àwọn obìnrin kì í sábà fi ohun tó ń ṣe wọ́n pa mọ́, wọ́n sì tètè máa ń wá ìrànlọ́wọ́.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Fífòòró ẹni lè sọ iṣẹ́ di ogun tó ń dáni lágara