ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 5/8 ojú ìwé 7-9
  • Wíwà Ní Ìrẹ́pọ̀ Níbi Iṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwà Ní Ìrẹ́pọ̀ Níbi Iṣẹ́
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Yíyanjú Aáwọ̀
  • “Ẹ Jẹ́ Kí Ìfòyebánilò Yín Di Mímọ̀”
  • Wá Ẹni Tá Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
  • Ìṣòro Náà Ò Ṣeé Yanjú Pátápátá
  • Ohun Tó Máa Ń mú Kí Wọ́n Dájú Sọni
    Jí!—2004
  • Ibi Iṣẹ́ Àbí Ojú Ogun?
    Jí!—2004
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?
    Jí!—2000
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Bí O Ṣe Lè Dáàbò Bo Ara Rẹ
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 5/8 ojú ìwé 7-9

Wíwà Ní Ìrẹ́pọ̀ Níbi Iṣẹ́

KÍ LÓ fà á táwọn kan fi máa ń fòòró àwọn ẹlòmíì? Bíbélì jẹ́ ká lóye ọ̀ràn náà yékéyéké. Ó ṣàlàyé pé à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí, àti pé ìyẹn ló fà á tá a fi bára wa nínú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga.” (2 Tímótì 3:1-5) Láwọn àkókò onírúkèrúdò yìí, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kárí ayé, híhanni léèmọ̀ sì jẹ́ ọ̀kan lára èso búburú tó ń so. Nígbà náà, báwo lo ṣe lè máa wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́?

Yíyanjú Aáwọ̀

Ibi aáwọ̀ tí wọn kò yanjú láàárín àwọn òṣìṣẹ́ ni ìfòòró ẹni ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Nítorí náà, láìtojú bọ ọ̀ràn ọlọ́ràn, yáa tètè yanjú èdèkòyédè tó o bá ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Fi ọ̀wọ̀ àti ọgbọ́n bomi paná ìbínú. Máa bá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lò bí ẹnì kọ̀ọ̀kan, kì í ṣe bí àwùjọ èèyàn kan. Bí ẹnì kan bá sọ pé o ṣẹ òun, ẹ tètè yanjú ọ̀rọ̀ náà kó sì tán síbẹ̀. Fi ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù sọ́kàn pé: “Bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá pẹ̀lú ẹni tí ń fi ọ́ sùn.”—Mátíù 5:25.

Síwájú sí i, gbogbo òṣìṣẹ́ ló máa jàǹfààní ẹ̀ bí gbogbo wọ́n bá ń bára wọn sọ̀rọ̀ pọ̀. Nígbà náà, rí i pé ò ń bá ọ̀gá rẹ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti lọ́nà tí kò fi ní rò pé ò ń wá ojúure òun. Tún rántí pé bíbá àwọn ẹgbẹ́ rẹ àtàwọn tó kéré sí ọ lẹ́nu iṣẹ́ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára kò ní jẹ́ kí ohunkóhun máa kó ọ láyà sókè. Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Àwọn ìwéwèé máa ń já sí pàbó níbi tí kò bá ti sí ọ̀rọ̀ ìfinúkonú, ṣùgbọ́n àṣeparí ń bẹ nínú ògìdìgbó àwọn agbani-nímọ̀ràn.”—Òwe 15:22.

Nítorí náà, sapá gidigidi láti máa bá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lò bí ọ̀rẹ́. Èyí ò túmọ̀ sí pé kó o sọ ara ẹ di “ẹni tó ń ṣojú ayé,” kó jẹ́ pé gbogbo ohun táwọn èèyàn bá ṣáà ti sọ náà ni wàá máa gbà láìjanpata, láìsí ìlànà kan pàtó tí ò ń tẹ̀ lé mọ́ nítorí àtiwà ní ìrẹ́pọ̀. Ṣùgbọ́n jíjẹ́ ọlọ́yàyà àti híhùwà bí ọ̀rẹ́ lè pẹ̀tù sí ohun tí ì bá dá wàhálà sílẹ̀. Kì í ṣe ohun tó ò ń sọ sáwọn èèyàn nìkan ló gba ìṣọ́ra o, ọ̀nà tó ò ń gbà sọ ọ́ pàápàá ṣe kókó. Bíbélì tún pèsè àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n nígbà tó sọ pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà.” (Òwe 15:1) “Ìparọ́rọ́ ahọ́n jẹ́ igi ìyè.” (Òwe 15:4) “Sùúrù ni a fi ń rọ aláṣẹ lọ́kàn.” (Òwe 25:15) “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Kólósè 4:6.

“Ẹ Jẹ́ Kí Ìfòyebánilò Yín Di Mímọ̀”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Fílípì nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn.” (Fílípì 4:5) Nípa títẹ̀lé ìlànà yìí, mọ bí wàá ṣe máa fòye báwọn èèyàn lò. Má ṣe dára ẹ lójú jù, má sì ṣe máa tijú akika. Báwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ bá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, má ṣe wọ́nà àtigbẹ̀san o. Kò sí èrè kankan nínú ṣíṣe burúkú ṣe rere. Ọ̀wọ̀ àti àpọ́nlé ni kó o máa fi bá àwọn ẹlòmíràn lò, ó sì dájú pé àwọn náà á fọ̀wọ̀ tìẹ wọ̀ ẹ́.

Kì í ṣe ìwà tó ò ń hù nìkan ni wàá máa ṣọ́ o, o tún ní láti máa ṣọ́ aṣọ tó ò ń wọ̀ pẹ̀lú. Bi ara rẹ pé: ‘Kí ni àwọn aṣọ mi ń sọ fáwọn ẹlòmíràn nípa mi? Ṣé aṣọ tó ń polówó ara ni mò ń wọ̀? Ṣé ìmúra mi máa ń rí wúruwùru? Ǹjẹ́ kò ní dára kí n kúkú ní irú aṣọ tó bójú mu tí màá máa wọ̀ lọ síbi iṣẹ́?’

Nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, ọ̀wọ̀ tó ga ni wọ́n máa ń fún àwọn òṣìṣẹ́ aláápọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn. Nítorí náà, gbìyànjú láti jẹ́ káwọn èèyàn máa fọ̀wọ̀ wọ̀ ẹ́ nípa ṣíṣe iṣẹ́ tó pójú owó. Jẹ́ ẹni tó ṣeé gbára lé, tí wọ́n sì lè gbẹ̀rí ẹ̀ jẹ́. Èyí ò túmọ̀ sí pé wàá di adára-má-kù-síbì-kan o. Obìnrin kan tí wọ́n fòòró, wá gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé òun gan-an lòun fọwọ́ ara òun fà á. Ó sọ pé: “Mi ò fẹ́ kú síbì kankan.” Ó wá yé e nígbà tó yá pé èèyàn ò lè dára títí kó má kù síbì kan. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Òṣìṣẹ́ tó dára ni mí, ṣùgbọ́n ìyẹn ò ní kí n mọ gbogbo nǹkan ṣe láìkù síbì kan.”

Má ṣe jẹ́ kí ara máa ta ọ́ jù bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí ọ. Kì í ṣe gbogbo ìgbà táwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ tó kù díẹ̀ káàtó sí wa náà ló jẹ́ pé wọ́n ń fòòró wa ni. Nínú Bíbélì, Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya . . . Pẹ̀lúpẹ̀lù, má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ, . . . nítorí ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ mọ̀ dáadáa, àní ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé ìwọ, àní ìwọ, ti pe ibi wá sórí àwọn ẹlòmíràn.”—Oníwàásù 7:9, 21, 22.

A gbà pé fífi irú ìlànà gbígbéṣẹ́ bẹ́ẹ̀ sílò kì í ṣe ẹ̀rí pé ẹnikẹ́ni ò ní fòòró rẹ láé. Bó ti wù kó o sapá tó, àwọn kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ ṣì lè fòòró rẹ. Kí lo lè ṣe bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀?

Wá Ẹni Tá Ràn Ọ́ Lọ́wọ́

Gregory sọ pé: “Nígbà táwọn èèyàn bá dẹ́yẹ sí mi fún ọ̀pọ̀ oṣù, ìdààmú ọkàn tó máa ń fún mi kì í ṣe kékeré.” Ohun tó ṣe é yìí ló sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tí wọ́n ń fòòró, tí ọ̀pọ̀ nǹkan sì máa ń fa ìdààmú ọkàn fún, irú bí ìbínú, ìdálẹ́bi ọkàn, ojútì, àìmọ-èwo-ni-ṣíṣe àti bó ṣe máa ń ṣe wọ́n bí ẹni pé wọn ò já mọ́ nǹkan kan. Ẹ̀rù tí ríronú pé wọ́n lè fòòró ẹni máa ń dá bani lè mú kí ẹni tó ní àmúmọ́ra pàápàá sọ ìrètí nù. Kódà, Bíbélì sọ pé “ìnilára pàápàá lè mú kí ọlọ́gbọ́n ṣe bí ayírí.” (Oníwàásù 7:7) Nítorí náà, èwo ni ṣíṣe o?

Ìwádìí fi hàn pé ohun tó dáa jù lọ ni pé kó o má ṣe gbìyànjú láti dá yanjú ìṣòro ìfòòró ẹni. Níbo lẹni tí wọ́n ń fòòró lè wá ìrànlọ́wọ́ lọ? Àwọn iléeṣẹ́ aládàá-ńlá kan ti ṣètò ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣèrànwọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ wọn táwọn míì ń fòòró. Irú àwọn iléeṣẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé fún àǹfààní iléeṣẹ́ tàwọn ni báwọn bá fòpin sí ìfòòró ẹni. Nínú ìṣirò kan tí wọ́n ṣe, wọ́n fojú bù ú pé, láàárín wákàtí mẹ́wàá, ó máa ń tó wákàtí kan tí ọkàn àwọn òṣìṣẹ́ tó máa ń fòòró àwọn ẹlòmíràn fi ń pínyà. Níbi tírú ìṣètò bẹ́ẹ̀ bá wà, ẹni tí wọ́n ń fòòró lè wá ìrànlọ́wọ́. Agbaninímọ̀ràn kan tí kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, yálà èyí tó wà níbi iṣẹ́ náà tàbí èyí tó wá láti ìta, lè wá bí gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn á ṣe jíròrò ọ̀ràn náà, kí wọ́n sì gbé ìlànà kan kalẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí kálùkù máa ṣe lẹ́nu iṣẹ́.

Ìṣòro Náà Ò Ṣeé Yanjú Pátápátá

Àmọ́ ṣá o, a ò lè fọwọ́ sọ̀yà ẹ̀ pé ohun kan wà tí yóò kásẹ̀ ìfòòró ẹni nílẹ̀. Kódà, àwọn tó ń lo ìlànà Bíbélì tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí lè rí i pé fífojú ẹni rí màbo lẹ́nu iṣẹ́ ṣì ń bá a nìṣó. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè rí i dájú pé ìfaradà àti ìsapá àwọn láti fi ànímọ́ rere bá àwọn èèyàn lò lábẹ́ ipò tó nira ni Jèhófà Ọlọ́run kò ní gbójú fò dá.—2 Kíróníkà 16:9; Jeremáyà 17:10.

Àwọn míì tí wọ́n ń fòòró máa ń wáṣẹ́ síbòmíràn ni bó bá dà bíi pé fífojú ẹni rí màbo náà ti wá ń pọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ tó sì ń wáyé lemọ́lemọ́. Àwọn míì sì wà tí ò rọrùn fún láti tètè ríṣẹ́, nítorí pé iṣẹ́ lè má pọ̀ níta, ibi tí wọ́n sì ti lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà lè má fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Monika, tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, rí i pé, bí àkókò ti ń lọ, ìṣòro náà kásẹ̀ nílẹ̀ nígbà tí ẹni tó ń fòòró ẹni náà fiṣẹ́ sílẹ̀. Nítorí èyí, afẹ́fẹ́ àlàáfíà bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ níbi iṣẹ́ náà, ó sì wá ṣeé ṣe fún un láti parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ kó tó pinnu láti wáṣẹ́ síbòmíràn.

Ní ti Peter, tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́, ó rí ìtura tó ń fẹ́ gbà nígbà tó fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ ṣáájú àkókò tó yẹ kó fẹ̀yìn tì. Àmọ́ ṣá o, nígbà tí wọ́n ń fòòró Peter, ìtìlẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ fún un ràn án lọ́wọ́ gidigidi. Ó sọ pé: “Ó mọ ohun tó ń bá mi fínra, odi agbára ló sì jẹ́ fún mi.” Nígbà tí wọ́n ń fara da àdánwò tó bá wọn, Monika àti Peter rí ìtùnú pàtàkì gbà látinú ìgbàgbọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ìtagbangba ti fún wọn lókun sí i láti máa fojú iyì wo ara wọn, ìbákẹ́gbẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn ará sì ti mú un dá wọn lójú pé àwọn lè ní ọ̀rẹ́ tí okùn ìfẹ́ rẹ̀ yi.

Ipò yòówù kó o wà, ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ bá gbé láti ní àjọṣe rere pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ jọ wà lẹ́nu iṣẹ́. Bí wọ́n bá fòòró rẹ, sapá láti ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe gbani níyànjú pé: “Má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. . . . Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:17-21.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Jíjẹ́ ọlọ́yàyà lè pẹ̀tù sí ohun tí ì bá dá wàhálà sílẹ̀

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

“Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—RÓÒMÙ 12:18

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Tètè yanjú èdèkòyédè tó o bá ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́