ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 5/8 ojú ìwé 5-6
  • Ohun Tó Máa Ń mú Kí Wọ́n Dájú Sọni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó Máa Ń mú Kí Wọ́n Dájú Sọni
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbára Ẹni Ṣiṣẹ́ Láìjà Láìta
  • Irú Ẹni Tí Wọ́n Máa Ń Dájú Sọ
  • Ibi Iṣẹ́ Àbí Ojú Ogun?
    Jí!—2004
  • Wíwà Ní Ìrẹ́pọ̀ Níbi Iṣẹ́
    Jí!—2004
  • Fífi Ìbálòpọ̀ Fòòró Ẹni—Ìṣòro Kárí Ayé Kan
    Jí!—1996
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Tó Máa Ń Fi Ọ̀ranyàn Báni Tage?
    Jí!—2000
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 5/8 ojú ìwé 5-6

Ohun Tó Máa Ń mú Kí Wọ́n Dájú Sọni

Kété tí Monika jáde ilé ẹ̀kọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé tó ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nípa iṣẹ́ amòfin. Èrò Monika ni pé bí ẹní fi ẹran jẹ̀kọ ló máa rí fóun láti ti ilé ẹ̀kọ́ bọ́ sẹ́nu iṣẹ́.

Oníṣègùn òyìnbó ni Horst, ó sì ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún dáadáa. Ó ti fẹ́yàwó ó sì ti bímọ, kò sì sí ohun tó lè mú kéèyàn rò pé kò ní dépò gíga lẹ́nu iṣẹ́ kówó ńlá sì máa wọlé fún un.

Àti Monika àti Horst ni wọ́n dẹni tí wọ́n ń fòòró lẹ́nu iṣẹ́.

A RÍ ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́ lára ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Monika àti Horst, òun ni pé: Kò sẹ́ni tí wọn ò lè hàn léèmọ̀ lẹ́nu iṣẹ́. Àní, ẹni yòówù tó bá wà lẹ́nu iṣẹ́ èyíkéyìí ló lè dẹni à ń fòòró. Nígbà náà, báwo lo ṣe lè dáàbò bo ara rẹ? Lára ohun tó o lè ṣe ni pé kó o mọ bó o ṣe lè máa wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn níbi iṣẹ́, àní pẹ̀lú àwọn tó ṣòroó bá ṣiṣẹ́ pàápàá.

Bíbára Ẹni Ṣiṣẹ́ Láìjà Láìta

Ohun tí níníṣẹ́ lọ́wọ́ túmọ̀ sí fún ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ láìjà láìta pẹ̀lú àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn kí wọ́n sì ran àwùjọ òṣìṣẹ́ yẹn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀. Báwọn òṣìṣẹ́ bá jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ láìjà láìta, iṣẹ́ á máa lọ déédéé. Àmọ́, bọ́ràn ò bá rí bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ á máa wọ́lẹ̀, wọ́n sì tún lè tètè bẹ̀rẹ̀ sí fòòró ẹni.

Kí ló lè ba àjọṣe dídán mọ́rán tó wà láàárín àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́ jẹ́? Ọ̀kan lára ohun tó lè fà á ni kí wọ́n máa pààrọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ lemọ́lemọ́. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kì í rọrùn fáwọn òṣìṣẹ́ láti dọ̀rẹ́ ara wọn. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà síṣẹ́ ò tíì mọ nípa iṣẹ́ náà dáadáa, èyí á sì má fawọ́ aago iṣẹ́ ará yòókù sẹ́yìn. Bí iṣẹ́ bá ń pọ̀ sí i, á di pé kó máa wọ àwọn òṣìṣẹ́ náà lọ́rùn ní gbogbo ìgbà.

Síwájú sí i, báwọn òṣìṣẹ́ ò bá ní àfojúsùn kan pàtó, wọn ò ní lè wà ní ìṣọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀rọ̀ lè rí báyìí nígbà tí ọ̀gá kan tí ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀ bá ń fi èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò rẹ̀ jìjàdù kí ipò ọ̀gá máà bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́ dípò tí ì bá fi máa darí iṣẹ́. Ó tiẹ̀ lè máa rúná lábẹ́lẹ̀ tá sì máa forí àwọn òṣìṣẹ́ gbára torí kó lè ráyè máa darí wọn. Èyí tó tún lè bọ̀ràn jẹ́ ni pé àwọn òṣìṣẹ́ náà lè má mọ àyè ara wọn, àwọn kan lára wọn ò sì ní mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe àtèyí tí ò yẹ kí wọ́n ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìjàngbọ̀n lè sọ nígbà táwọn òṣìṣẹ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá ronú pé iṣẹ́ àwọn ni láti máa buwọ́ lu ìwé ọjà.

Bọ́ràn bá ti dà bẹ́ẹ̀, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ níbi iṣẹ́ ò ní lọ déédéé mọ́, àwọn òṣìṣẹ́ á sì máa di ara wọn sínú. Ó di kí wọ́n máa jowú ara wọn, kóníkálùkù sì máa wá bí òun á ṣe rí ojúure ọ̀gá. Wọ́n á máa sọ ọ̀rọ̀ kékeré di ńlá. Wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ máa sọ ohun tí ò tó nǹkan di bàbàrà. Bí fífòòró ẹni ṣe ń bẹ̀rẹ̀ nìyẹn o.

Irú Ẹni Tí Wọ́n Máa Ń Dájú Sọ

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n dá òṣìṣẹ́ kan yàn sọjú. Ta ló ṣeé ṣe kí wọ́n yàn sọjú bẹ́ẹ̀? Ó lè jẹ́ ẹnì kan tó dá yàtọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó lè jẹ́ ọkùnrin kan ṣoṣo tó ń ṣiṣẹ́ láàárín àwọn obìnrin, ó sì lè jẹ́ òṣìṣẹ́ obìnrin láàárín àwọn ọkùnrin. Wọ́n lè ka ẹnì kan sí oníjàgídíjàgan nítorí pé ó jẹ́ onígboyà, wọ́n sì lè sọ pé ẹlẹ̀tàn lẹnì kan nítorí pé kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀. Ẹni tó ṣeé ṣe kí wọ́n dájú sọ tún lè yàtọ̀ ní ti pé láàárín àwọn yòókù ó lè jẹ́ pé òun ló dàgbà jù tàbí kó kéré ju gbogbo wọn lọ, ó sì lè jẹ́ ohun ló tóótun jù lọ fún iṣẹ́ náà.

Ẹnì yòówù kí wọ́n wá pàpà dájú sọ, ìwé ìròyìn ìṣègùn ilẹ̀ Jámánì náà, mta, sọ pé àwọn òṣìṣẹ́ yòókù “á máa fìwọ̀sí lọ ẹni tí wọ́n bá dájú sọ, wọ́n á máa mú un gùn, wọ́n á sì máa fìkanra ohun tó ń ṣe wọ́n mọ́ ọn.” Ohun yòówù kó ṣe láti yanjú ọ̀ràn náà lè má tu irun kan lára wọn, ó sì lè mú kí ọ̀ràn náà burú sí i pàápàá. Bí ìdáyàfoni náà bá ṣe ń wáyé lemọ́lemọ́ tí ò sì dáwọ́ dúró, kò ní pẹ́ tí ẹni tí wọ́n dájú sọ náà á fi dẹni àpatì. Bó bá ti dà bẹ́ẹ̀, ó lè máà rọrùn fẹ́ni tí wọ́n dájú sọ láti dá kojú ìṣòro náà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibi iṣẹ́ ni àyè ti máa ń gba àwọn èèyàn láti ṣe òṣìṣẹ́ bíi tiwọn bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú; ọ̀pọ̀ ṣì lè rántí ìgbà kan táwọn òṣìṣẹ́ ò jẹ́ fọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ bíi tiwọn ṣeré rárá. Agbára káká la fi lè rírú ẹ̀ látijọ́. Àmọ́, bí ọdún ti ń gorí ọdún, ọ̀ràn náà ti di ohun tí dókítà kan ṣàpèjúwe rẹ̀ bí “ẹ̀mí àìfìmọ̀ṣọ̀kan tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, àti ìwà àìlójútì tó ń gbilẹ̀ sí i ṣáá.” Àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ rí ohun tó burú nínú bíbá ara wọn fà á lẹ́nu iṣẹ́ mọ́.

Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo òṣìṣẹ́ pátá ló ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè bí èyí: Ǹjẹ́ ohun tá a lè ṣe wà kí wọ́n má bàa fòòró ẹni? Báwo la ṣe lè máa wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn níbi iṣẹ́?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Nítorí àtidẹ́yẹ sáwọn èèyàn ni wọ́n ṣe máa ń fẹ́ láti fòòró wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́