ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 4/15 ojú ìwé 27
  • Ìwọ Ha Rántí Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Rántí Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ákúílà àti Pírísílà Tọkọtaya Àwòfiṣàpẹẹrẹ
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Wàásù Láti Sọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Àyè Orin Nínú Ìjọsìn Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 4/15 ojú ìwé 27

Ìwọ Ha Rántí Bí?

Ìwọ ha ti ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò rí i pé, ó ń gbádùn mọ́ni láti rántí àwọn ohun tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí:

◻ Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya lónìí ṣe tẹ̀ lé àpẹẹrẹ títayọ lọ́lá tí Ákúílà àti Pírísílà fi lélẹ̀?

Ákúílà àti Pírísílà ṣiṣẹ́ sìn nínú àwọn ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bíi mélòó kan. Bíi tiwọn, ọ̀pọ̀ Kristẹni onítara lónìí ti mú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti lọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀. Wọ́n tún ti gbádùn ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn láti inú rírí ire Ìjọba tí ń dàgbà, àti láti inú mímú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ Kristẹni ṣíṣeyebíye dàgbà.—12/15, ojú ìwé 24.

◻ Kí ni ojú ìwòye Bíbélì nípa ọtí líle?

Ojú ìwòye Bíbélì nípa ọtí líle wà déédéé. Ní ọwọ́ kan, Bíbélì sọ pé, wáìnì jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. (Orin Dáfídì 104:1, 15) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ó dẹ́bi fún ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́. (Lúùkù 21:34; Tímótì Kíní 3:8; Títù 2:3; Pétérù Kíní 4:3)—12/15, ojú ìwé 27.

◻ Apá pàtàkì wo ni ó fani mọ́ra nípa ìwé Hágáì inú Bíbélì?

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ 38 péré ni ìwé Hágáì ní, a lo orúkọ Ọlọ́run ní ìgbà 35. Irú àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ kì í mọ́yán lórí mọ́ nígbà tí a bá ti fi orúkọ oyè náà, “Olúwa,” rọ́pò orúkọ náà, Jèhófà.—1/1, ojú ìwé 6.

◻ Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni a lè rí kọ́ lára ẹ̀ṣẹ̀ tí Dáfídì àti Mánásè ṣẹ̀?

Láìka dídá tí Jèhófà dárí ji Dáfídì àti Mánásè sí, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí—àti Ísírẹ́lì pẹ̀lú wọn—ní láti nírìírí àbájáde ìgbésẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. (Sámúẹ́lì Kejì 12:11, 12; Jeremáyà 15:3-5) Lọ́nà kan náà, nígbà tí ó jẹ́ pé Jèhófà ń dárí ji àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n ronú pìwà dà lónìí, àwọn àbájáde ìgbésẹ̀ wọn lè wà tí kò ní ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.—1/1, ojú ìwé 27.

◻ Ní ọ̀nà wo ni ‘ẹsẹ̀ àwọn wọnnì tí ń polongo ìhìn rere’ Ìjọba Ọlọ́run fi “dára”? (Aísáyà 52:7)

Ní ti gidi, ẹsẹ̀ ni ènìyàn fi ń rìn káàkiri bí ó ti ń wàásù fún àwọn ẹlòmíràn. Láìsí tàbí-tàbí, irú ẹsẹ̀ bẹ́ẹ̀ dúró fún ẹni náà gan-an. Nítorí náà, lójú ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbọ́, tí wọ́n sì dáhùn pa dà lọ́nà rere sí ìhìn rere Ìjọba náà, irú ẹsẹ̀ àwọn ońṣẹ́ bẹ́ẹ̀ rẹwà gidigidi ní tòótọ́.—1/15, ojú ìwé 13.

◻ Iṣẹ́ alápá méjì wo ni ‘pípolongo ìhìn rere’ ní nínú? (Kọ́ríńtì Kíní 9:16)

Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ pòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà. Apá kejì tí iṣẹ́ yìí ní kan kíkọ́ àwọn tí wọ́n dáhùn pa dà lọ́nà rere sí ìpòkìkí Ìjọba náà lẹ́kọ̀ọ́.—1/15, ojú ìwé 23.

◻ Àǹfààní wo ni kíkọ orin Ìjọba ní àwọn ìpàdé ìjọ ń mú wá fún wa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan?

Orin kíkọ ń fún wa láǹfààní láti sọ ìmọ̀lára wa jáde fún Ẹlẹ́dàá wa. (Orin Dáfídì 149:1, 3) Nígbà tí a bá tú ọkàn àyà wa jáde nínú kíkọrin pẹ̀lú ìjọ, ó lè múra ọkàn àyà àti èrò inú wa sílẹ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí yóò tẹ̀ lé e. Ó lè sún wa láti nípìn-ín púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Jèhófà.—2/1, ojú ìwé 28.

◻ Nígbà wo ni ọjọ́ ikú dára ju ọjọ́ ìbí lọ? (Oníwàásù 7:1)

Ọjọ́ ikú lè dára ju ọjọ́ tí a bí ẹnì kan lọ, bí ẹni náà ṣáájú ìgbà yẹn bá ti ṣe orúkọ rere pẹ̀lú Jèhófà, tí ó lè jí àwọn olùṣòtítọ́ tí ó ti kú dìde. (Jòhánù 11:25)—2/15, ojú ìwé 12.

◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ìwé Oníwàásù ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?

Ó lè ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ láti mú ojú ìwòye wa nípa ìgbésí ayé àti ohun tí a darí àfiyèsí wa sí tọ́. (Oníwàásù 7:2; Tímótì Kejì 3:16, 17)—2/15, ojú ìwé 16.

◻ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ha jẹ́ arinkinkin-mọ́lànà bí?

Rárá o. Bí wọ́n tilẹ̀ ní ìdánilójú lílágbára ní ti ìsìn, wọn kì í ṣe arinkinkin-mọ́lànà ní ti ọ̀nà tí a ti gbà lo ọ̀rọ̀ náà. Wọn kì í yíjú sí ìwọ́de àti ìwà ipá lòdì sí àwọn tí wọn kò bá jọ fohùn ṣọ̀kan. Wọ́ ń fara wé Aṣáájú wọn, Jésù Kristi.—3/1, ojú ìwé 6.

◻ Ipa wo ni ṣíṣàìmọ àkókò náà gan-an tí Jésù yóò wá láti mú ẹ̀san Ọlọ́run ṣẹ ń ní lórí àwọn Kristẹni?

Èyí ń mú kí àwọn Kristẹni wà lójúfò, ó sì ń fún wọn ní àǹfààní ojoojúmọ́ láti fi hàn pé wọ́n ń fi ẹ̀mí àìmọtara-ẹni-nìkan ṣiṣẹ́ sin Jèhófà.—3/1, ojú ìwé 13.

◻ Kí ni ó yẹ kí a gbé yẹ̀ wò ṣáájú fífi ẹsẹ̀ òfin tọ ọ̀ràn arákùnrin kan tí ó lù wá ní jìbìtì?

Ó yẹ kí a ronú lórí ìyọrísí tí ó ṣeé ṣe kí ó ní lórí wa, lórí àwọn ẹlòmíràn tí ọ̀ràn kàn, lórí ìjọ, àti lórí àwọn ará ìta. (Kọ́ríńtì Kíní 6:7)—3/15, ojú ìwé 22.

◻ Báwo ni a ṣe lè ní ayọ̀ tòótọ́?

Ayọ̀ tòótọ́ jẹ́ ipò ọkàn àyà, tí a gbé karí ojúlówó ìgbàgbọ́ àti ipò ìbátan rere pẹ̀lú Jèhófà. (Mátíù 5:3)—3/15, ojú ìwé 23.

◻ Kí ni ó yẹ kí Kristẹni kan ṣe nígbà tí a bá pè é fún iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́?

Kristẹni kọ̀ọ̀kan tí ó bá dojú kọ iṣẹ́ ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ gbọ́dọ̀ pinnu ipa ọ̀nà tí òun yóò tẹ̀ lé, lórí ìmọ̀ rẹ̀ nípa Bíbélì àti ẹ̀rí ọkàn rẹ̀. (Gálátíà 6:5)—4/1, ojú ìwé 29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́