Àyè Orin Nínú Ìjọsìn Òde Òní
ORIN kíkọ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gbígbé ohùn wa sókè láti kọrin lè gbádùn mọ́ àwa fúnra wa àti Ẹlẹ́dàá wa. Nípasẹ̀ rẹ̀, a lè sọ èrò ìmọ̀lára wa jáde, ti ìbànújẹ́ àti ti ìdùnnú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a lè sọ ìfẹ́, ìkẹ́, àti ìyìn wa jáde fún Olùpilẹ̀ṣẹ̀ orin, Jèhófà.
Ọ̀pọ̀ jù lọ nínú nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún ìtọ́kasí Bíbélì nípa orin ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà. Orin tún ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú—kì í ṣe ìdùnnú àwọn tí ń kọrin náà nìkan, ṣùgbọ́n ìdùnnú Jèhófà pẹ̀lú. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Jẹ́ kí wọn kí ó . . . kọrin ìyìn sí i. Nítorí tí Olúwa ṣe inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Orin Dáfídì 149:3, 4.
Ṣùgbọ́n, báwo ni orin kíkọ ti ṣe pàtàkì tó nínú ìjọsìn òde òní? Báwo ni àwọn ènìyàn Jèhófà lónìí ṣe lè mú inú rẹ̀ dùn nípa gbígbé ohùn wọn sókè nínú orin kíkọ? Àyè wo ni ó yẹ kí a fi orin sí nínú ìjọsìn tòótọ́? Yíyẹ ìtàn orin wò nínú ìjọsìn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.
Ìtàn Nípa Àyè Orin Nínú Ìjọsìn
Ìtọ́kasí àkọ́kọ́ nínú Bíbélì nípa orin kò ní í ṣe ní pàtó pẹ̀lú ìjọsìn Jèhófà. Nínú Jẹ́nẹ́sísì 4:21, Júbálì ni a sọ pé ó ṣeé ṣe kí ó ti hùmọ̀ ohun èlò orin àkọ́kọ́ tàbí tí ó dá oríṣi iṣẹ́ orin kíkọ kan sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, orin jẹ́ apá kan ìjọsìn Jèhófà àní ṣáájú dídá ẹ̀dá ènìyàn pàápàá. Ọ̀pọ̀ àwọn olùtúmọ̀ Bíbélì ṣàpèjúwe pé àwọn áńgẹ́lì ń kọ́rin. Jóòbù 38:7 sọ nípa àwọn áńgẹ́lì tí ń fi ìdùnnú ké jáde, tí wọ́n sì “ń hó ìhó ayọ̀.” Nípa báyìí, ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wà láti gbà gbọ́ pé kíkọrin nínú ìjọsìn Jèhófà jẹ́ àṣà tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí ènìyàn tó wá sí ojútáyé.
Àwọn òpìtàn kan ti jiyàn pé orin Hébérù ìgbàanì jẹ orin adùnyùngbà látòkè délẹ̀, láìsí àwọn ohùn orin mìíràn tí a fi ń jùmọ̀ kọ ọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá ń ta háápù, ohun èlò kan tí a mẹ́nu kàn lọ́nà títayọ lọ́lá nínú Bíbélì, ó lè mú ju ohùn kan ṣoṣo jáde. Àwọn tí ń ta háápù ti ní láti kíyè sí ohùn orin dídùn tí wọ́n lè mú jáde bí wọ́n bá fi ohun èlò orin náà mú ọ̀pọ̀ ohùn orin jáde pa pọ̀. Kàkà tí yóò fi jẹ́ ti àtijọ́, kò sí iyè méjì pé orin wọn jẹ́ èyí tí ó bá ìgbà mu. Bí a bá sì fi ojú ewì àti ìtàn inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù wò ó, a lè parí èrò sí pé orin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ojúlówó gidi. Dájúdájú, ẹ̀mí tí ń mí sí wọn láti ṣàkójọ orin ga fíìfíì ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó múlé gbè wọ́n lọ.
Ọ̀nà tí a gbà ṣètò tẹ́ńpìlì ìgbàanì mú kí ìṣètò lílo ohun èlò orin àti àwọn ohùn lọ́nà dídíjú nínú ìjọsìn tẹ́ńpìlì ṣeé ṣe. (Kíróníkà Kejì 29:27, 28) A ní ‘àwọn aṣáájú orin,’ “olùkọ́,” “àwọn tí a kọ́,” àti “àwọn olórí àwọn akọrin.” (Kíróníkà Kíní 15:21; 25:7, 8; Nehemáyà 12:46) Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí òye iṣẹ́ jíjáfáfá tí wọ́n ní nípa orin kíkọ, òpìtàn Curt Sachs kọ̀wé pé: “Àwọn elégbè àti àwọn akọrin tí wọ́n wà ní Tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù fi ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga ní ti ìmọ̀ ẹ̀kọ́, òye iṣẹ́, àti ìmọ̀ nípa orin hàn. . . . Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò mọ bí orin ìgbàanì yẹn ṣe dún létí, a ní ẹ̀rí tí ó tó ní ti agbára rẹ̀, ìgbayì, àti ìgbóyeyọ rẹ̀.” (The Rise of Music in the Ancient World: East and West, 1943, ojú ìwé 48, 101 àti 102) Orin Sólómọ́nì jẹ́ àpẹẹrẹ ìgbékalẹ̀ gíga lọ́lá àti ìjójúlówó àkójọ orin Hébérù. Ó jẹ́ ìtàn kan tí a kọ lórin, ó jọ ọ̀rọ̀ orin, tàbí ìwé orin, ti eré orin kan. Nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù a pe orin náà ni “Orin Àwọn Orin,” ìyẹn ni pé, orin tí ó dùn jù lọ. Lójú àwọn Hébérù ìgbàanì, orin kíkọ jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn. Ó sì fàyè gba sísọ èrò ìmọ̀lára dídára tí wọ́n ní jáde nígbà tí wọ́n bá ń yin Jèhófà.
Orin Kíkọ Láàárín Àwọn Kristẹni Ọ̀rúndún Kìíní
Orin ń bá a nìṣó láti jẹ́ apá ṣíṣe déédéé nínú ìjọsìn láàárín àwọn Kristẹni ìjímìjí. Ní àfikún sí níní Orin Dáfídì tí a mí sí, ó dà bí ẹni pé wọ́n ṣàkójọ orin gidi àti àwọn ọ̀rọ̀ orin fún ìjọsìn, ní fífi àwòṣe lélẹ̀ fún ṣíṣàkójọ àwọn orin Kristẹni lóde òní. (Éfésù 5:19) Ìwé náà, The History of Music, láti ọwọ́ Waldo Selden Pratt, ṣàlàyé pé: “Kíkọrin nínú ìjọsìn ní gbangba àti ní ìdákọ́ńkọ́ jẹ́ àṣà àwọn Kristẹni ìjímìjí. Fún àwọn tí a sọ di Júù èyí jẹ́ àṣà inú sínágọ́gù tí ń bá a nìṣó . . . Ní àfikún sí Orin Dáfídì Lédè Hébérù . . . , ìsìn tuntun náà ń ní ìtẹ̀sí nígbà gbogbo láti mú orin ìyìn tuntun jáde, lákọ̀ọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí orin afìmọ̀lárahàn.”a
Ní títẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì orin kíkọ, nígbà tí Jésù dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ orin Hálélì ni òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kọ. (Mátíù 26:26-30) Ìwọ̀nyí jẹ́ orin ìyìn sí Jèhófà tí a kọ sílẹ̀ nínú Orin Dáfídì tí a sì kọ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ayẹyẹ Àjọ Ìrékọjá.—Orin Dáfídì 113 sí 118.
Agbára Ìdarí Tí Ìjọsìn Èké Ní
Nígbà tí yóò fi di ìgbà tí a sábà ń pè ní Sànmánì Ojú Dúdú, a ti sọ orin ìsìn di orin arò. Ní nǹkan bí ọdún 200 Sànmánì Tiwa, Clement ti Alẹkisáńdíríà wí pé: “A nílò ohun èlò orin kan: ọ̀rọ̀ àlàáfíà ti ìjúbà, kì í ṣe háápù tàbí ìlù, tàbí fèrè tàbí ipè.” A gbé òfin kalẹ̀, tí ó fi orin ṣọ́ọ̀ṣì mọ sí orin àfẹnukọ. Àṣà yí ni a mọ̀ sí orin wuuru tàbí orin tí a kò lo ohun èlò orin sí. “Ní ohun tí ó dín ní ogójì ọdún lẹ́yìn tí a ti dá Constantinople sílẹ̀, Ìgbìmọ̀ Laodíkíà (A.D. 367) fòfin de lílo ohun èlò orin pẹ̀lú ohùn ìjọ nínú ààtò ìsìn. Orin ìsìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti jẹ́ àfẹnukọ délẹ̀délẹ̀,” ni ìwé náà, Our Musical Heritage, sọ. (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Àwọn ìkálọ́wọ́kò wọ̀nyí kò ní ìpìlẹ̀ kankan nínú ìsìn Kristẹni ìjímìjí.
Nígbà Sànmánì Ojú Dúdú, àwọn tí kò rọ́wọ́ mú láwùjọ kò láǹfààní láti ní Bíbélì. Àwọn Kristẹni tí wọ́n gbìyànjú láti ní Bíbélì tàbí láti kà á ni a ṣe inúnibíni sí, tí a sì pa pàápàá. Abájọ nígbà náà, tí àṣà kíkọrin ìyìn sí Ọlọ́run fi parẹ́ kíákíá nígbà sáà ojú dúdú yẹn. Ó ṣe tán, bí àwọn tí kò rọ́wọ́ mú láwùjọ kò bá ní àǹfààní láti ní Ìwé Mímọ́, báwo ni wọn yóò ṣe mọ̀ pé ìdá mẹ́wàá Bíbélì látòkè délẹ̀ jẹ́ orin? Ta ni yóò fi tó wọn létí pé Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn olùjọsìn rẹ̀ láti “kọ orin tuntun sí Olúwa, àti ìyìn rẹ̀ nínú ìjọ àwọn ènìyàn mímọ́”?—Orin Dáfídì 149:1.
Dídá Orin Pa Dà sí Àyè Tí Ó Yẹ Ẹ́ Nínú Ìjọsìn
Ètò àjọ Jèhófà ti ṣe gudugudu méje láti dá orin àti orin kíkọ pa dà sí àyè tí ó tọ́ sí wọn nínú ìjọsìn. Fún àpẹẹrẹ, ìtẹ̀jáde Zion’s Watch Tower, February 1, 1896, ní kìkì orin nínú. A pè é ní “Orin Ìdùnnú Síónì Ti Òwúrọ̀.”
A fagi lé kíkọrin ní àwọn ìpàdé ìjọ pátápátá ní 1938. Bí ó ti wù kí ó rí, ọgbọ́n títẹ̀lé àpẹẹrẹ àti ìdarí àwọn àpọ́sítélì borí láìpẹ́. Ní àpéjọpọ̀ àgbègbè 1944, F. W. Franz gbé ọ̀rọ̀ àwíyé náà kalẹ̀, “Orin Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọba.” Ó fi hàn pé, àwọn ẹ̀dá Ọlọ́run tí ń bẹ lókè ọ̀run ti ń kọrin ìyìn sí Jèhófà tipẹ́tipẹ́ kí a tó dá ènìyàn, ó sì wí pé: “Ó jẹ́ ohun yíyẹ tí ó sì dùn mọ́ Ọlọ́run nínú kí àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé gbé ohùn wọn sókè nínú orin gidi.” Lẹ́yìn fífi ọ̀rọ̀ gbe orin kíkọ nínú ìjọsìn lẹ́sẹ̀, ó kéde ìmújáde ìwé náà, Kingdom Service Song Book, fún lílò ní àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.b Lẹ́yìn náà, Informant ti December 1944 (tí a ń pè ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nísinsìnyí) kéde pé àwọn ìpàdé yòó kù pẹ̀lú yóò máa ní orin ìbẹ̀rẹ̀ àti orin ìparí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, kíkọrin tún di apá kan ìjọsìn Jèhófà.
‘Kíkọrin sí Jèhófà Láti Inú Ọkàn Àyà Wa’
Àwọn ará wa ní Ìlà Oòrùn Europe àti Áfíríkà tí wọ́n ti nírìírí ọ̀pọ̀ ọdún hílàhílo àti inúnibíni fi ìjẹ́pàtàkì orin kíkọ látọkànwá hàn. Lothar Wagner lo ọdún méje ní àgọ́ àdádó. Báwo ni ó ṣe fara dà á? “Fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ mo pọkàn pọ̀ sórí rírántí àwọn orin Ìjọba. Nígbà tí n kò bá mọ ọ̀rọ̀ orin náà dáradára n óò hùmọ̀ ẹsẹ orin kan tàbí méjì. . . . Ẹ wo irú ọ̀pọ̀ jaburata èrò tí ń fúnni níṣìírí, tí ó sì ń gbéni ró, tí ó wà nínú àwọn orin Ìjọba wa!”—1974 Yearbook of Jehovah’s Witnesses, ojú ìwé 226 sí 228.
Ní ọdún márùn-ún tí ó fi wà ní àgọ́ àdádó nítorí ìdúró ìṣòtítọ́ rẹ̀, Harold King rí ìtùnú nínú ṣíṣàkójọ orin àti kíkọ orin láti fi yin Jèhófà. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn orin tí ó ṣàkójọ rẹ̀ ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò nísinsìnyí nínú ìjọsìn wọn. Ìdùnnú tí ó so mọ́ kíkọrin jẹ́ èyí tí ń múni dúró. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí a dúró di ìgbà tí inúnibíni bá dé kí a tó mọyì fífi orin yin Ọlọ́run.
Gbogbo ènìyàn Jèhófà lè rí ìdùnnú nínú orin. Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè má rọgbọ fún wa láti sọ ìmọ̀lára wa jáde lọ́rọ̀ ẹnu, a lè sọ ìmọ̀lára wa jáde fùn Jèhófà nígbà tí a bá kọ wọ́n lórin. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi bí a ṣe lè rí ìdùnnú nínú kíkọ orin ìyìn hàn, nígbà tí ó ṣí àwọn Kristẹni létí láti ‘máa fi àwọn sáàmù àti ìyìn sí Ọlọ́run àti àwọn orin ẹ̀mí bá ara wọn sọ̀rọ̀, kí wọ́n máa kọrin kí wọ́n sì máa fi ohùn orin gbè é nínú ọkàn àyà wọn sí Jèhófà.’ (Éfésù 5:19) Nígbà tí ọkàn àyà wa bá kún fún ohun tẹ̀mí, a ń rí àwọn ọ̀rọ̀ lílágbára tí ó wà nínú orin. Nítorí náà àṣírí bí a ṣe lè sunwọ̀n sí i nínú orin kíkọ ni ọkàn àyà tí ó tọ́.
Níní ipò ìbátan tí ó dára pẹ̀lú Jèhófà ń fi kún ẹ̀mí onídùnnú, ó ń sún wa láti sọ̀rọ̀, láti kọrin, àti kígbe ìyìn sí Jèhófà. (Orin Dáfídì 146:2, 5) Tọkàntọkàn ni a fi ń kọrin nípa ohun tí ó gbádùn mọ́ wa. Bí a bá sì nífẹ̀ẹ́ orin náà tàbí èrò ìmọ̀lára tí ń bẹ nínú orin náà, kò sí iyè méjì pé a óò fi ìmọ̀lára gidi kọ ọ́.
Kò dìgbà tí ẹnì kan bá kọrin sókè kí ó tó fi ìmọ̀lára kọ ọ́. Orin kíkọ sókè kò fi gbogbo ìgbà jẹ́ ohun kan náà pẹ̀lú kíkọrin lọ́nà tí ó dùn mọ́ni; bẹ́ẹ̀ sì ni kíkọrin láìgbóhùn sókè kì í ṣe ohun kan náà pẹ̀lú kíkọrin lọ́nà tí ó gbádùn mọ́ni. Àwọn ohùn kan tí wọ́n ní adùn àdánidá lè yàtọ̀ bí wọ́n tilẹ̀ ń kọrin náà lábẹ́lẹ̀. Apá kan ìpèníjà kíkọrin lọ́nà dídán mọ́nrán pẹ̀lú àwùjọ ni, kíkọ́ bí orin wa yóò ṣe ṣù mọ́ ti àwọn yòó kù. Yálà o ń kọrin láàárín àwọn tí ń lo onírúurú ohùn tàbí oríṣi ohùn kan náà, mímú kí ohùn rẹ̀ má bo tí àwọn tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ mọ́lẹ̀ ń mú kí ó tuni lára, ó sì ń mú kí orin ṣù mọ́ra. Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì Kristẹni àti títẹ́tísílẹ̀ ń ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti jèrè ìwàdéédéé ní ti fífi ìtara kọrin síbẹ̀ kí a máà gbóhùn sókè ju bí ó ti yẹ lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ń kọrin lọ́nà jíjáfáfá tàbí tí wọ́n ní ohùn dídùn lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kò ní láti rẹ̀ wẹ̀sì láé láti kọrin jáde. Ohùn dídùn kan lè pèsè ìtìlẹ́yìn tí ó lágbára fún orin ìyìn tí ìjọ kan ń kọ sí Jèhófà.
Kíkọrin ní àwọn ìpàdé wa tún ń pèsè ọ̀nà yíyẹ fún fífi ohùn kọrin pa pọ̀ bí ohùn orin adùnyùngbà tí ń lọ lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n lè fi etí dá àwọn ohùn orin mọ̀ tàbí tí wọ́n lè ka àwọn ìlà ohùn orin nínú ìwé orin kí wọ́n sì kọ wọ́n jáde ni a ń fún níṣìírí láti mú kí ohùn wọn ṣù mọ́ tí àwọn yòó kù nígbà tí wọ́n bá ń kọrin, kí wọ́n sì fi kún adùn orin náà.c
Àwọn kan lè sọ pé, ‘N kò lè gbé ohùn orin’ tàbí ‘ohùn mi kò dára; ó máa ń há bí mo bá ń lo ohùn òkè.’ Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń lọ́ tìkọ̀ nígbà tí wọ́n bá ń kọrin, àní nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba pàápàá. Òtítọ́ náà ni pé, kò sí ohùn tí a gbé sókè láti fi yin Jèhófà tí “kò dára” lójú ìwòye tirẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe lè tún ohùn ẹni ṣe pẹ̀lú fífi kọ́ra àti nípa títẹ̀lé àwọn àbá arannilọ́wọ́ tí a ń fúnni ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ náà ni a ṣe lè mú ọ̀nà ìkọrin ẹni sunwọ̀n sí i. Àwọn kan ti mú ohùn wọn sunwọ̀n sí i nípa wíwulẹ̀ kùn yunmuyunmu nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Kíkùn yunmun ń ṣèrànwọ́ láti mú kí ohùn ẹni là. Ní àwọn ìgbà tí ó bá sì yẹ, tí a bá dá wà tàbí tí a ń ṣiṣẹ́ níbi tí a kì yóò ti dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́, kíkọ àwọn orin adùnyùngbà ti Ìjọba jẹ́ eré ìdárayá gbígbámúṣé fún ohùn àti ọ̀nà kan láti múnú ará ẹni dùn, kí ọkàn ẹni sì fúyẹ́.
A tún lè fún kíkọ díẹ̀ nínú àwọn orin Ìjọba níṣìírí ní àwọn àpèjọ ìgbafẹ́. Irú orin kíkọ bẹ́ẹ̀, tí a lo ohùn èlò orin pẹ̀lú, irú bíi gìtá tàbí dùùrù olóhùn gooro tàbí dùùrù olóhùn gooro tí Society ti gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀, ń mú kí àpéjọ ìgbafẹ́ wa ní agbára ìdarí tẹ̀mí. Ó tún ń pèsè ìrànwọ́ fún kíkọ́ orin àti kíkọrin lọ́nà tí ó dán mọ́nrán ní àwọn ìpàdé ìjọ.
Láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ìjọ láti lè máa fi ìtara kọrin nínú ìpàdé, Society ti pèsè àwọn ohun èlò orin tí a gba ohùn wọn sílẹ̀. Nígbà tí a bá ń lò wọ́n, ẹni tí ń bójú tó ohun èlò orin gbọ́dọ̀ kíyè sí ohùn orin náà. Bí orin náà kò bá lọ sókè tó, ìjọ lè máa lọ́ tìkọ̀ láti kọrin jáde. Bí arákùnrin tí ń bójú tó ohun èlò orin ti ń bá ìjọ kọrin, yóò lè ṣeé ṣe fún un láti pinnu yálà orin náà ń ṣáájú lọ́nà tí ń ranni lọ́wọ́ tàbí kò ṣe bẹ́ẹ̀.
Kọrin Dídùnyùngbà sí Jèhófà
Orin kíkọ ń fún wa láǹfààní láti sọ ìmọ̀lára wa jáde fún Ẹlẹ́dàá wa. (Orin Dáfídì 149:1, 3) Kì í ṣe ìbújáde èrò ìmọ̀lára lásán, ṣùgbọ́n fífi ìdùnnú fi ìyìn wa hàn, lọ́nà tí a lè ṣàkóso, tí ó sì lọ́gbọ́n nínú. Títú ọkàn àyà wa jáde nínú kíkọrin pẹ̀lú ìjọ lè múra ọkàn àyà àti èrò inú wa sílẹ̀ fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí yóò tẹ̀ lé e, ó sì lè sún wa láti nípìn-ín púpọ̀ sí i nínú ìjọsìn Jèhófà. Bí orin kíkọ tilẹ̀ ń ní ipa lórí èrò ìmọ̀lára, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú lè fún wa nítọ̀ọ́ni. Ní títipa báyìí sọ ìmọ̀lára wa jáde pa pọ̀, tí a sì ń fi ìṣọ̀kan sọ ọ́, a ń fi inú tútù àti ìrẹ̀lẹ̀ múra ọkàn àyà wa sílẹ̀ kí a baà lè kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí a kó jọ.—Fi wé Orin Dáfídì 10:17.
Orin kíkọ yóò máa fìgbà gbogbo jẹ́ apá kan ìjọsìn Jèhófà. Nítorí náà, a ní ìfojúsọ́nà ti ṣíṣàjọpín èrò ìmọ̀lára onísáàmù náà títí láé pé: “Èmi óò yin Jèhófà nígbà tí mo wà láàyè. Èmi yóò kọrin dídùnyùngbà sí Ọlọ́run mi níwọ̀n ìgbà tí mo ba ń bẹ.”—Orin Dáfídì 146:2, NW.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orin afìmọ̀lárahàn jẹ́ oríṣi orin kan tí a fi òmìnira ọ̀rọ̀ dá apá kọ̀ọ̀kan rẹ̀ mọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà orin afìmọ̀lárahàn máa ń gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tàbí akọni ẹ̀dá ga.
b Kọ́ríńtì Kíní 14:15 dà bí ẹni fi hàn pé orin kíkọ jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní.
c Díẹ̀ nínú àwọn orin wa ti inú ìwé orin tí a ń lò lọ́wọ́, Kọrin Ìyìn sí Jehofah, ní ohùn orin alápá mẹ́rin fún àǹfààní àwọn tí wọ́n gbádùn kíkọrin pẹ̀lú onírúurú ohùn. Bí ó ti wù kí ó rí, a ti ṣètò ọ̀pọ̀ àwọn orin náà fún fífi dùùrù olóhùn gooro kọ ọ́, a sì ti ṣètò wọn lọ́nà tí a óò fi lè pa bí a ṣe mọ àwọn ohùn náà sí káàkiri ayé mọ́. Ṣíṣe àgbélẹ̀rọ àwọn ohùn orin fún àwọn orin tí a kọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọn kò ní àwọn ohùn orin alápá mẹ́rin tí ó wà gẹ́gẹ́ bí ìlànà lè túbọ̀ mú kí kíkọrin ní àwọn ìpàdé wa gbádùn mọ́ni.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn Àbá Díẹ̀ fún Kíkọrin Lọ́nà Tí Ó Sunwọ̀n Sí I
1. Di ìwé orin mú ṣánṣán níwájú rẹ̀ nígbà tí o bá ń kọrin. Èyí ń ranni lọ́wọ́ láti lè mí lọ́nà tí ó túbọ̀ rọrùn.
2. Mí kanlẹ̀ dáradára ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹsẹ orin kọ̀ọ̀kan.
3. Yíya ẹnu ju bí o ti fẹ́ lọ lákọ̀ọ́kọ́ yóò mú kí ohùn rẹ̀ lọ sókè sí i, yóò sì mú kí ohùn rẹ dùn sí i tìrọ̀rùntìrọ̀rùn.
4. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, fiyè sí èrò ìmọ̀lára orin tí a ń kọ.