ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Kò Lè Sọ Àsọtẹ́lẹ Ìmìtìtì Ilẹ̀
  • Líla Ìrìbọmi Nínú Omi Tútù Já
  • Eré Ìdárayá àti Ẹ̀mí Gígùn
  • Sísọ Òtítọ́ Kì Í Ṣe Ọ̀ràn-anyàn
  • Àwọn Ohun Tuntun Tí Ó Jẹ́ Pàtàkì
  • Ẹ̀wádún Aláìlérè
  • Lílo Ìgbójú Fi Ìbọn Jalè
  • Ìròyìn Nípa Ọ̀ni
  • Ìdààmú Ọkàn Tí Ń Pọ̀ Sí I
  • Àìdọ́gba Ipò Ìlera
  • Ṣọ́ra fún ‘Ojú Odò’!
    Jí!—1996
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Tẹ́lẹ̀ Nípa Àwọn Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Lágbára?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Bí Ilẹ̀ Sísẹ̀ Àti Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Ṣe Kàn Ọ́
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 3/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

A Kò Lè Sọ Àsọtẹ́lẹ Ìmìtìtì Ilẹ̀

Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ rò pé ó yẹ kí ó ṣeé ṣe láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìmìtìtì ilẹ̀. Wọ́n wo ìpele omi, sísún díẹ̀díẹ̀ ìtẹ́jú ilẹ̀ ayé, gáàsì olóró tí ń jáde láti inú àwọn kànga, àti àwọn àmì tí ó ṣeé fojú rí mìíràn. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ògúnná gbòǹgbò onímọ̀ nípa ìmìtìtì ilẹ̀ ń ronú nísinsìnyí pé ó dà bí ẹni pé ìmìtìtì ènìyàn kò lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìmìtìtì ilẹ̀. Wọ́n sọ pé ó dà bí ẹni pé gbogbo ìwádìí láti wá ọ̀nà láti lè kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn ní ọjọ́, wákàtí àti ìṣẹ́jú bí mélòó kan kí ìmìtìtì ilẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ jẹ́ òtúbáńtẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ kan máa ń ní àwọn àmì àṣeṣíwájú tí ó máa ń jẹ́ ìyírapadà ìtẹ́jú ilẹ̀ ayé, àwọn àmì yẹn kéré púpọ̀, wọn kò ṣe kedere tó, wọ́n kì í sì wà ní ojútòó dèbi tí rírí wọn ní ti gidi gan-an fi lè máà ṣeé ṣe.” Àwọn ènìyàn kan ti ń ké sí ìjọba nísinsìnyí láti ṣíwọ́ nínáwò sórí ṣíṣèwádìí lórí ìmìtìtì ilẹ̀, kí wọ́n sì lo owó náà lórí dídín àwọn ìjàm̀bá tí ó ń fà kúrò. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà pé ó yẹ kí a mọ bí ilẹ̀ ṣe ń sún àti ohun tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ilé nígbà ìmìtìtì ilẹ̀.

Líla Ìrìbọmi Nínú Omi Tútù Já

Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ń ṣèwádìí nípa ohun tí ń fà á tí àwọn ènìyàn tí wọ́n bá já sómi tútù bíi yìnyín ṣe máa ń tètè kú ti ṣàwárí pé bí Ọlọrun ti dá a pé kí ara máa ṣe bí ó bá rí òtútù lójijì ni kí ènìyàn máa mí ju bí ó ti yẹ lọ. Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé: “Bí ènìyàn ti ń yára mí lójijì ni omi yóò máa tara rọ́ wọlé—ènìyàn yóò sì rì sómi.” Ènìyàn kò lè ṣàkóso yíyára mí. Nítorí náà, ènìyàn gbọ́dọ̀ gbórí sókè omi títí tí òòfà láti máa mí sínú yóò fi rọlẹ̀, èyí tí ó sábà máa ń jẹ́ láàárín ìṣẹ́jú méjì sí mẹ́ta, bí ènìyàn bá fẹ́ là á já.

Eré Ìdárayá àti Ẹ̀mí Gígùn

Àwọn ará Germany ń ná iye tí ó tó bílíọ̀nù 25 dọ́là lórí eré ìdárayá lọ́dún, tàbí ohun tí ó ju 300 dọ́là lọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ìwé agbéròyìnjáde Nassauische Neue Presse sọ pé, wọ́n ń ná owó yìí lórí “aṣọ, ohun èèlò, ìdánilẹ́kọ̀ọ́, híháyà ibi ìṣeré, àti owó ẹgbẹ́.” Ohun tí ó ju mílíọ̀nù mẹ́ta àwọn ènìyàn ní ń ṣeré ìmárale ní àwọn ilé ìṣeré ìmárale, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló sì ń sáré kúṣẹ́kúṣẹ́. Ó ha ṣeé ṣe nígbà náà kí ó jẹ́ pé ẹ̀mí àwọn olùfẹ́ eré ìdárayá lè máa gùn jù, tàbí kí ìgbésí ayé wọn tilẹ̀ dára ju tí àwọn ajókòórẹkẹtẹ-sójú-kan lọ? Kò pọn dandan kí ó rí bẹ́ẹ̀. Ìwé Physiologie des Menschen (Ìbáṣepọ̀ Ìgbòkègbodo Ìgbésí Ayé àti Ìṣiṣẹ́ Ara Ènìyàn) sọ pé: “Ó dájú pé, kò tọ̀nà láti fi gbogbo ẹnu sọ pé eré ìdárayá ni oògùn tí ó dára jù lọ.” Èé ṣe? Nítorí pé ó lé ní mílíọ̀nù 1.5 àwọn ará Germany tí ń lọ sọ́dọ̀ dókítà lọ́dọọdún nítorí àwọn ìfarapa tí wọ́n ń rí nídìí eré ìdárayá nígbà tí wọ́n ń ṣe eré ìtura ní òpin ọ̀sẹ̀ àti nígbà ìsinmi. Ìwé náà gba àwọn ènìyàn nímọ̀ràn pé, eré ìmárale àti eré ìdárayá dára fún ìlera kìkì “bí jàm̀bá tàbí ọṣẹ́ eré ìdárayá kì í bá ṣe ohun tí ń pa ìlera ènìyàn lára.”

Sísọ Òtítọ́ Kì Í Ṣe Ọ̀ràn-anyàn

Àwọn ẹjọ́ tí à ń ṣe ní àwọn ilé ẹjọ́ United States lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti fa ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lágbàáyé mọ́ra, ó sì ń ya àwọn òǹwòran lẹ́nu. Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ọ̀ràn-anyàn fún àwọn olùpẹ̀jọ́ láti sọ bí ọ̀rọ̀ bá ti rí, àwọn agbẹjọ́rò ń lépa ohun tí ó yàtọ̀. . . .Iṣẹ́ agbẹjọ́rò olùjẹ́jọ́ ni láti gba àre fún ẹni tí wọ́n ń gbẹjọ́ rò fún, kí wọ́n kó rọwọ́rọwọ́ bọ ìgbìmọ̀ agbọ̀ràndùn lọ́wọ́ (nípa gbígbin iyè méjì tí ó pọ̀ díẹ̀ sọ́kàn ẹnì kan lára ìgbìmọ̀ agbọ̀ràndùn) tàbí kí wọ́n bu bí ẹ̀sùn náà ti rinlẹ̀ tó kù.” Stephen Gillers, olùkọ́ nípa ìlànà ìwà híhù lọ́nà òfin ní ilé ẹ̀kọ́ òfin ti Yunifásítì New York, sọ pé: “Kì í ṣe ọ̀ràn-anyàn fún wọn láti rí i dájú pé ìdájọ́ kan tí a ti dá ẹnì kan láre tọ́. . . . A máa ń sọ fún àwọn ìgbìmọ̀ agbọ̀ràndùn pé ẹjọ́ náà jẹ́ láti wá òtítọ́ rí, a kò jẹ́ sọ fún wọn pé ọ̀ràn-anyàn ló jẹ́ fún àwọn agbẹjọ́rò láti tú wọn jẹ.” Ìwé agbéròyìnjáde Times náà sọ pé, nígbà tí “àwọn agbẹjọ́rò bá dojú kọ àwọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ tí ó lè kó bá ẹni tí wọ́n ń gbẹjò rò fún, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n gbọ́dọ̀ wá ìtàn sọ, tí ìgbìmọ̀ àwọn adájọ́ yóò máa yiiri wò, kí wọ́n baà lè gbójú fo àwọn òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà, kí wọ́n sì dá ẹni náà láre.” Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ bí àwọn agbẹjọ́rò bá mọ̀ pé ẹni tí àwọn ń gbẹjọ́ rò fún jẹ̀bi, àmọ́ tí ẹni tí wọ́n ń gbẹjọ́rò fún ṣì takú pé àwọn yóò dán an wò lọ́dọ̀ àwọn ìgbìmọ̀ agbọ̀ràndùn? Gillers sọ pé: “Nígbà yẹn ni àwọn agbẹjọ́rò yóò ṣe bí Uriah Heep aláàánúkù lọ sí ilé ẹ̀jọ́, wọn yóò ṣe bí onírẹ̀lẹ̀, wọn yóò sì sọ nípa ìgbàgbọ́ jíjinlẹ̀ tí wọ́n ní nínú òtítọ́ ìtàn tí ẹni tí wọ́n ń gbẹjọ́ rò fún sọ, nígbà tí wọ́n mọ̀ pé gbogbo rẹ̀ porogodo ló jẹ́ irọ funfun.”

Àwọn Ohun Tuntun Tí Ó Jẹ́ Pàtàkì

Ohun tí ó ṣe pàtàkì fún àwọn èwe ilẹ̀ Rọ́ṣíà àti gbogbo àwùjọ àwọn ènìyàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà lápapọ̀ tí ń yí padà. Ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan, Sankt-Peterburgskiye Vyedomosti, ròyìn pé, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní àìpẹ́ yìí ní St. Petersburg, Rọ́ṣíà, ṣàwárí pé ìṣarasíhùwà àwọn èwe ń tẹnu mọ́ “àwọn ohun tí ó jẹ́ pàtàkì sí ẹ̀dá ènìyàn—ìyẹn ni, ìlera, ìwàláàyè, ìdílé, àti ìfẹ́, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ohun tí ó jẹ́ pàtàkì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan, irú bí àṣeyọrí, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ìtura, àti ìrọ̀ṣọ̀mù nǹkan tí ara.” Àwọn ohun tí ó jẹ́ pàtàkì míràn dá lórí àwọn òbí, owó, ìwàlálàáfíà, ayọ̀, dídọ́rẹ̀ẹ́, àti ìmọ̀. Ó wọni lọ́kàn pé, níní orúkọ rere àti gbígbádùn òmìnira ẹni gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ló gba méjì nínú àwọn àyè tí ó kẹ́yìn lọ́kàn àwọn èwe. Kí ló gba àyè tí ó kẹ́yìn? Ìṣòtítọ́. Ìròyìn náà parí ọ̀rọ̀ pé: “Bí irọ́ bá rọ̀gbà yí wọn ká báyìí, nígbà náà, [ìṣòtítọ́] kò lè jẹ́ ohun tí ó ṣe pàtàkì lọ́kàn àwọn ìran tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dàgbà yìí.”

Ẹ̀wádún Aláìlérè

Àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ Britain sọ ẹ̀wádún tí a wà yìí ní “Ẹ̀wádún Ìjíhìnrere.” Nísinsìnyí tí a ti dé ìdajì ẹ̀wádún náà, kí ni wọ́n ti ṣàṣeyọrí rẹ̀? Agbẹnusọ kan, Michael Green, sọ nínú ìwé agbéròyìnjáde Church Times pé: “A kò tilẹ̀ tí ì bẹ̀rẹ̀ sí í mú ìròyìn rere náà bá ìbéèrè tí àwọn ènìyàn gbáàtúù ń béèrè mu. N kò rí àmí pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣiṣẹ́ kọjá ẹnu ọ̀nà wọn, kí wọ́n sì jáde lọ pẹ̀lú ìhìn rere náà sọ́dọ̀ àwùjọ ènìyàn. . . . Agbára káká ni a fi tí ì bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdarí kankan lórí àwọn èwe ìwòyí tí wọn kì í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì jẹ́ nǹkan bí ìpín 86 nínú ọgọ́rún-ún lára gbogbo àwọn ọ̀dọ́ tí ó wà ní orílẹ̀-èdè wa.” Kí ló dé tí wọn kò láṣeyọrí? Green sọ pé: “À ń tan ara wa jẹ pé ọ̀nà tí à ń gbà gbé ìgbésí ayé wa lásán ti tó láti sọ ìhìn rere náà láìjẹ́ pé a lanu sọ̀rọ̀. Ẹ̀rù ń bà wá pé kí a máà mú àwọn ẹlòmíràn bínu.”

Lílo Ìgbójú Fi Ìbọn Jalè

Ní Kánádà, ìdá 1 nínú 7 àwọn ilé ìfowópamọ̀ ni àwọn olè fọ́ ní ọdún 1994—ohun tí ó ju iye tí wọ́n ń jà lólè ní àwọn ẹ̀ka ilé ìfowópamọ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ní Itali, níbi tí wọ́n ti ń fọ́ ìdá 1 nínú 13 ilé ìfowópamọ́ ẹ̀ka wọn, ó jọ bí ẹni pé àwọn olè náà gbójú ju àwọn ti ibòmíràn lọ. Àwọn olè tí ń fọ́ ilé ìfowópamọ́ ní Itali tí ń tagọ̀ bojú, tàbí tí ń lo ohun ìjà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Àwọn kan kàn wulẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ àwọn agbowókà ilé ìfowópamọ́ ni, wọ́n sì ń gba owó lọ́wọ́ wọn. Ìwé agbéròyìnjáde The Economist ròyìn pé, àwọn olè kan tilẹ̀ ti lo ọ̀nà ìmúnimúyè. Àwọn olè ilé ìfowópamọ́ Itali tún máa ń tẹpẹlẹ mọ nǹkan: ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀ka ilé ìfowopamọ́ 165 ni wọ́n fọ́ lẹ́ẹ̀mejì, wọ́n fọ́ 27 ní ẹ̀mẹta, 9 sì jẹ́ ní ẹ̀ẹ̀mẹrin kí ọdún náà tó parí. Èló wá ni ìpíndọ́gba owó tí wọ́n kó nígbà ìdigunjalè yìí ní ọdún 1994? Mílíọ̀nù 61 owó lire (37,803 dọ́là United States), iye tí ó tí ì lọ sílẹ̀ jù lọ láti ọdún 1987.

Ìròyìn Nípa Ọ̀ni

Ìwé ìròyìn Nature ròyìn pé, àkẹ̀kù àgbọndò ọ̀ni ìgbà láéláé kan tí wọ́n hú jáde láìpẹ́ yìí “lè jẹ́ àkọ́kọ́ lára àwọn ẹranko jewéjewé tí a tí ì rí rí” tí ó jẹ́ ìbátan ọ̀ni. Dípò eyín ṣómúṣómú, gígùn tí àwọn ọ̀ni òde òní ní, tí àwọn ènìyàn máa ń bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ lónìí, baba ẹranko tí ó ti wà ní ìgbàanì yìí ní eyín tí ó rí pẹrẹsẹ tí wọ́n ròyìn pé ó wà fún jíjẹ koríko. Ó fara hàn pé, ẹ̀dá yìí—tí àwọn olùṣèwádìí ará China àti Kánádà ní Agbègbè Hupeh ní China rí ní orí òkè kan ní ìhà gúúsù etí Odò Yangtze—tún jẹ́ olùgbé orí ilẹ̀, kì í ṣe jomijòkè. Ó ti tóbi tó? Ó gùn tó nǹkan bíi mítà kan.

Ìdààmú Ọkàn Tí Ń Pọ̀ Sí I

Ìwé ìròyìn Veja ròyìn pé ìwádìí kan tí wọn ṣe láìpẹ́ yìí ní Rio de Janeiro, Brazil, fi hàn pé ohun tí ó ju ìdá 35 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí ń wá ìtọ́jú ìṣègùn ni ó ní onírúurú ìdààmú ọpọlọ. Ìwé ìròyìn náà bèèrè lọ́wọ́ Dókítà Jorge Alberto Costa e Silva, tí ó jẹ́ olùdarí ẹ̀ka ìwàdéédéé ọpọlọ fún Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO), pé: “Kí ni a lè sọ pé ó fa iye tí ń lọ sókè yìí? Ṣe ayé ti burú sí i ni, àbí àwọn ènìyàn ti ń di aláìlera ní ti ọpọlọ ni?” Ó fèsì pé: “À ń gbé ní àkókò tí gbogbo nǹkan ń yára yí padà ní kánmọ́kánmọ́, èyí tí ó máa ń yọrí sí àníyàn ṣíṣe àti ìdààmú ọkàn ní ìwọ̀n tí a kò tí ì rí rí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn.” Ó sọ pé, ọ̀kan nínú okùnfa tí ó wọ́pọ̀ fún ìdààmú ọkàn ni ìwà ipa tí ó gbalẹ̀ kan ní Rio de Janeiro.  Èyí lọ́pọ̀ ìgbà máa ń fa ìdààmú ọpọlọ tí ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìrírí apániláyà, èyí tí ó ṣàlàyé nípa rẹ̀ pé, “ó ń nípa lórí àwọn ènìyàn nígbà tí wọ́n bá bọ́ sínú ipò tí ń wu ìwàláàyè wọn léwu lọ́nà kan tàbí òmíràn. Ní ojúmọmọ, wọ́n máa ń nímọ̀lára àìláàbò nípa gbogbo nǹkan. Ní alẹ́, wọ́n máa ń lálàá burúkú tí yóò jẹ́ kí ìrírí tí wọ́n ní tí ó fi ìwàláàyè wọn sínú ewu tún wá sójútáyé lẹ́ẹ̀kan sí i.”

Àìdọ́gba Ipò Ìlera

Ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ àti àwọn tí ó tòṣì ń pọ̀ sí i. Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ṣírò rẹ̀ pé ìpíndọ́gba gígùn ìwàláàyè àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà, tí a sì bí wọn sí ibẹ̀ jẹ́ ọdún 76—tí a bá fi wéra pẹ̀lú ọdún 54 ti àwọn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tí ì fí bẹ́ẹ̀ gòkè àgbà. Ní ọdún 1950, iye àwọn ọmọ ọwọ́ tí ń kú ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tòṣì fi ìlọ́po mẹ́ta ju tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ lọ; ní báyìí, o ti fi ìlọpo 15 pọ̀ jù ú lọ. Nígbà tí yóò fi di apá ìparí àwọn ọdún 1980, iye àwọn tí ń kú nítorí àwọn ìṣòro ìgbà ìbímọ fi ìgbà 100 ju ti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó lọ́rọ̀ lọ. Ètò àjọ WHO sọ pé, ohun tí ó tún wá pa kún ìṣòro náà ni pé, ohun tí kò tó ìlàjì lára àwọn ènìyàn tí ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó tòṣì ló ń rí omi tí ó mọ́ àti ètò ìmọ́tótó. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ, iye “àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ dàgbà sókè” ti lọ sókè láti 27 ní ọdún 1975 sí 48 ní ọdún 1995. Jákèjado ayé, bílíọ̀nù 1.3 àwọn òtòṣì ló wà, iye wọ́n sì ń pọ̀ sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́