ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/22 ojú ìwé 24-27
  • Ṣọ́ra fún ‘Ojú Odò’!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣọ́ra fún ‘Ojú Odò’!
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ojú Odò’ Tí Ń Ṣekú Pani
  • Àwọn Nǹkan Àlùmọ́nì Ń Wu Ìwàláàyè Wọn Léwu
  • A Jádìí Irọ́ Àwọn Àhesọ Ọlọ́jọ́ Pípẹ́ Kan
  • Kì Í Ṣe Kìkì fún Oró Dídá àti Híhùwà Ipá
  • Párì Ọ̀nì
    Jí!—2015
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
  • Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli—Nínú Ọgbà Ẹranko!
    Jí!—1996
  • NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
    Jí!—2015
Jí!—1996
g96 1/22 ojú ìwé 24-27

Ṣọ́ra fún ‘Ojú Odò’!

LÁTI ỌWỌ́ ASỌJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA

ELÉRÉ egéle kan tí ó wà lẹ́nu ìsinmi ń tukọ̀ ọlọ́pọ́n rẹ̀ lọ jẹ́jẹ́ gba odò kan tí ó ṣàn wọ Odò Àlégbà Ìhà Àríwá níbi arabaríbí àbàtà tí ó wà ní Agbègbè Àríwá Australia, ní Ọgbà Ìtura tí Orílẹ̀-Èdè ní Kakadu. Lójijì, ohun tí ó rò pé ó jẹ́ àpólà igi tí ó léfòó lórí omi bẹ̀rẹ̀ sí í taari ọkọ̀ ọlọ́pọ́n rẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún. Ọ̀nì inú omi oníyọ̀ tí gbogbo ènìyàn máa ń bẹ̀rù ni, ó sì ṣẹlẹ̀ pé arìnrìn àjò ìgbafẹ́ náà wà ní agbègbè rẹ̀ tí ó pààlà sí, ní àkókò tí ó léwu jù lọ láàárín ọdún.

Ó jà fitafita láti tukọ̀ ọlọ́pọ́n rẹ̀ lọ sí ibì kan tí àwọn igi pọ̀ sí. Bí ó ti ń gbé ẹsẹ̀ rẹ̀ lé orí ẹ̀ka igi àkọ́kọ́ ni ọ̀nì náà jáde nínú omi, ó fà á padà, ó sì gbé e lógèdèǹgbé nígbà mẹ́ta. Gbogbo ìgbà tí ọ̀nì náà bá fẹ́ tún un gbá mú ni obìnrin náà máa ń gbìyànjú tagbáratagbára láti gun òkè sí etí odò ẹlẹ́rọ̀fọ̀ náà. Ní ìgbà tí ó dán an wò ní ìgbà kẹta, ó yí i mọ́ ọn láti dé òkè odò náà, ó sì ń wọ́ ara rẹ̀ lọ fún nǹkan bíi kìlómítà méjì títí tí aṣọ́gbó kan fi gbọ́ ìbòsí rara tí ń ké fún ìrànwọ́. Láìka pé ó fara pa yánnayànna sí, obìnrin náà yè é bọ́.

Ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ yọrí sí àgbákò yìí ṣẹlẹ̀ ní 1985. Ọdún méjì lẹ́yìn rẹ̀, ọmọ America tí ń rìnrìn àjò ìgbafẹ́ kan ko àgbákò ní tirẹ̀. Ó kọtí ikún sí ìkìlọ̀ tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ fún un, ó sì pinnu láti lúwẹ̀ẹ́ ní Odò Prince Regent tí àwọn ọ̀nì kún fọ́fọ́, ní Ìwọ̀ Oòrùn Australia. Ọ̀nì tí ó máa ń gbé inú omi oníyọ̀ kan kọ lù ú, ó sì pa á. Ìròyìn tí a gbọ́ pé àwọn ọmọ ọ̀nì wà nínú omi náà fi hàn pé, àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ abo ọ̀nì tí ń dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀.

‘Ojú Odò’ Tí Ń Ṣekú Pani

Gbogbo nǹkan tí apẹja níbi ìyalura omi máa ń rí nínú òṣùpá kò ju ìmìlẹ̀gbẹ̀lẹ̀gbẹ̀ omi níbi tí kòkòrò bá bà sí lójú omi tí ń ṣẹ́ lóólóó. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, apẹja tí ó wà ní jìngbunjìngbun ìhà àríwá Australia máa ń wà lójúfò ketekete sí ohun tí kò ṣeé rí—‘ojú odò.’ Bí ó bá fi lè tan tọ́ọ̀ṣì rẹ̀, yóò rí i tí ojú ọ̀nì, tí ó rọra ń yọrí bọ̀ láti inú omi, ń tàn yòò. Ó ti di alátojúbọ̀ ní agbègbè ẹranko panipani àtayébáyé kan.

Àwọn ọ̀nì inú omi oníyọ̀ ní Australia tí ń gbé inú omi oníyọ̀ Australia, tí a tún máa ń rí ní àwọn ibòmíràn, jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀yà ọ̀nì 12 tí ó tóbi jù lọ, tí ó sì léwu jù lọ lágbàáyé. Ó lè gùn tó mítà méje. Ẹni tí kò fura, tí ó bá bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, lè má tètè rí ojú rẹ̀ tí ń kọ mànà láti lè bọ́ lọ́wọ́ ìbẹ́lù gìjà àti ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ aṣekúpani ti gbígbéni lógèdèǹgbé rẹ̀. Ó ti kọlu àwọn ẹran ìjẹ rẹ̀ tí ó tóbi bí ẹfọ̀n, màlúù àti ẹṣin, nígbà tí wọ́n ń pa òùngbẹ wọn létídò.

Àwọn Nǹkan Àlùmọ́nì Ń Wu Ìwàláàyè Wọn Léwu

Ìtàn àròsọ àtijọ́ náà pé, ọ̀nì máa ń sunkún ìbànújẹ́ èké lé ẹran ìjẹ rẹ̀ lórí ti wọnú àṣà òde òní, nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹkún ọ̀nì.” Àmọ́ agbára káká ni àwọn ènìyàn fi tí ì sunkún nítorí ọ̀nì rí. Dípò bẹ́ẹ̀, a ti fi àìláàánú ṣọdẹ àwọn ẹ̀dá afàyàfà tí ó fẹ́ràn omi yìí, nítorí awọ wọn.

Ọ̀pọ̀ ọ̀nì ni a ti fi ṣe ohun ọ̀ṣọ́ aláwọ lọ yan fanda ní àwọn ibi àfihàn ohun ìmúra, nítorí pé àwọn kan ka awọ ọ̀nì sí awọ tí ó dára jù lọ lágbàáyé—èyí tí ó fẹ́lẹ́, tí ó sì lálòpẹ́ jù lọ tí a lè rí. Láìpẹ́ yìí, àpò ìfàlọ́wọ́ obìnrin kan ni à ń tà ní 15,000 dọ́là ní London. A ṣì ka awọ ọ̀nì sí nǹkan tí ó níyelórí gan-an ní ọ̀pọ̀ ibi lórí ilẹ̀ ayé.

Òòfà èrè gọbọi ń wu ìwàláàyè àwọn ọ̀nì tí ń gbé inú omi oníyọ̀ Australia léwu. Láàárín 1945 sí 1971 sì nìyí, nǹkan bíi 113,000 àwọn ẹ̀dá afàyàfà wọ̀nyí ni a pa ní Agbègbè Àríwá nìkan. Láti má baà pa wọ́n run tán, wọ́n fi ààlà sí ọdẹ ọ̀nì ṣíṣe ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé nígbà tí yóò fi di ọdún 1986, iye wọn tí ó wà nínú ìgbẹ́ ti padà lọ sókè. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀nì kò sí nínú ewu mọ́ ní Australia, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn kan ń jiyàn pé ibùgbé rẹ̀ wà nínú ewu.

Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn Ọmọ Onílẹ̀ Australia mọ̀ọ́mọ̀ dáàbò bo àwọn ọ̀nì, tàbí láìmọ̀ọ́mọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀yà kan wà tí wọ́n jẹ́ ògbójú ọdẹ apọ̀nì, àwọn ẹ̀yà míràn ka ṣíṣọdẹ wọn léèwọ̀ nítorí ìsìn.

Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, sísin ọ̀nì àti ìtẹnumọ́ tí à ń gbé ka orí ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ti pa kún ààbò àwọn ọ̀nì. Àwọn tí ń rìnrìn àjò ìgbafẹ́ ń rọ́ lọ sí àwọn oko tí a ti ń sin ọ̀nì nísinsìnyí, èyí sì ń fi hàn pé wọ́n lè mú owó wọlé, nígbà tí ó sì jẹ́ pé àwọn ètò mímú kí wọ́n pamọ máa ń jẹ́ kí ṣíṣaáyan awọ àti ẹran ọ̀nì ṣeé ṣe láìjẹ́ pé à ń pa àwọn ẹranko ìgbẹ́ lára.

Ọmọ Australia kan tí ń sin ọ̀nì gbà gbọ́ pé àwọn ènìyàn máa ń dáàbò bo kìkì àwọn nǹkan tí wọ́n nífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì lóye nìkan, wọ́n sì máa ń fún wọn ní díẹ̀ lára àyè àti àkókò wọn. Ó sọ pé: “Nítorí èyí, àwọn ọ̀nì kò fi bẹ́ẹ̀ rí àyè àtimókè. Àmọ́ ìníyelórí wọn nínú ìbáṣepọ̀ àwọn ohun alààyè sí ara wọn àti sí àyíká wọn dọ́gba pẹ̀lú àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ mèremère.”

Ṣíṣèbẹ̀wò sí oko tí a ti ń sin ọ̀nì máa ń gbádùn mọ́ ènìyàn bí ènìyàn bá sún mọ́ àwọn ẹ̀dá afàyàfà aláwọ paali tí ó ní àwọ̀ pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ náà láti wò wọ́n—àmọ́ ó gbọ́dọ̀ jẹ́ láti ẹ̀yìn irin ọ̀gbà tí a fi ṣààbò. Àwọn lébìrà máa ń gbé ìbẹ̀rù sọnù, tí wọn yóò sì wọlé tọ àwọn ọ̀nì náà lọ nínú ọgbà, tí wọn óò sì máa ké sí wọn láti ṣeré, wọn yóò sì fún wọn ní ẹran adìẹ tútù àti ẹran mìíràn fún ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, lébìrà kan kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tí ó le koko láìpẹ́ yìí pé, ọ̀nì kò ṣeé bá ṣeré. Láìròtẹ́lẹ̀, ọ̀nì náà pa kuuru mọ́ ọn, ó sì fa apá rẹ̀ òsì já pátápátá!

Ẹ̀wẹ̀, gbígbé ọmọ ọ̀nì olóṣù 12 lọ́wọ́ máa ń dùn mọ́ ènìyàn, ó sì máa ń la ènìyàn lóye. Awọ ikùn rẹ̀ fẹ́lẹ́ gan-an ni, ṣùgbọ́n ohun líle, tí à ń pè ní ìpẹ́, tí ó wà lẹ́yìn rẹ̀, dà bí ìhámọ́ra tí omi ń gba orí rẹ̀ lọ. Ní báyìí, a lè lóye ìdí rẹ̀ tí awọ wọn fi wọ́n tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pẹ̀lú “ọmọ rínńdín” yìí. Àní ọmọ ọ̀nì olóṣù 12 pàápàá tí a di èrìgì rẹ̀ pinpin máa ń lágbára ju bí ó ti tóbi tó lọ.

Àwọn ọmọ ọ̀nì tí kò tí ì jáde nínú ẹyin máa dá àwọn ènìyàn lárayá bí wọ́n ti ń gbó jáde láti inú kòròfo ẹyin wọn, tí wọ́n sì ń lu ú jáde síta lójijì pẹ̀lú eyín kan tí ó wà ní ṣóńṣórí ẹnu wọn kékeré fún ìgbà díẹ̀. Ọ̀pọ̀ gbà pé èyí ni yóò jẹ́ ìgbà tí ó kẹ́yìn tí ọ̀nì kan yóò jẹ́ ohun àgbéjó!

A Jádìí Irọ́ Àwọn Àhesọ Ọlọ́jọ́ Pípẹ́ Kan

Níwọ̀n bí àwọn àgbẹ̀ ti ń ṣàkíyèsí ìṣesí àwọn ẹ̀dá afàyàfà tí ń bani lẹ́rù yìí bí wọ́n ti ń dàgbà lábẹ́ àbójútó lóko tí a ti ń sìn wọ́n, wọ́n ti ṣèrànwọ́ láti jádìí irọ́ àwọn àhesọ ọlọ́jọ́ pípẹ́ kan. Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ènìyàn rò pé ọ̀nì máa ń tọpasẹ̀ ẹran ìjẹ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, tàbí ọ̀sẹ̀ pàápàá, kí ó tó sọ ọ́ ṣàkà láìròtẹ́lẹ̀ bí àrá. Bí ó ti wù kí ó rí, àkíyèsí tí a ṣe láìpẹ́ yìí ti fi hàn pé, àwọn ọ̀nì kàn máa ń jẹ́ oníjàgídíjàgan ní ìpínlẹ̀ wọn ni, ní àkókò tí akọ wọ́n bá ń rí abo lọ́wọ́, nígbà tí ọwọ́ òjò le. Tí ẹran ìjẹ kan bá wọ agbègbè rẹ̀ ní àkókò yìí, ọ̀nì náà lè fi ìrunú gbá yá a, nígbà tí ó jẹ́ pé ní àkókò míràn láàárín ọdún, ọ̀nì náà wulẹ̀ lè máa wo ẹranko náà lọ́nà jíjìn láìjá a kúnra.

Nígbà tí a bá rí àwọn ọ̀nì ní àwọn ibi ìtura lónìí, àwọn amọṣẹ́dunjú aṣọdẹ ọ̀nì ni wọ́n máa ń kó wọn lọ sí ibòmíràn. Ara ọgbọ́n tí wọ́n máa ń lò ni pé, wọn yóò fi okùn alátapọ̀ kan so àgbọndò rẹ̀ ìsàlẹ̀, wọn yóò gbé e sókè, tí wọn yóò sì sáre so àgbọndò òkè àti ti ìsàlẹ̀ pa pọ̀. Èyí máa ń sọ àgbọndò ọ̀nì di aláìlágbára pẹ́ẹ̀pẹ́ẹ̀, nítorí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣù ẹran tí ó fi ń pa àgbọndò ìsàlẹ̀ dé lágbára lọ́nà pípabambarì, àwọn ìṣù ẹran tí ó fi ń ṣí i kò lágbára. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ọdẹ kan kò bá ṣọ́ra, ọ̀nì kan lè fi pẹ̀lú ìrọ̀rùn fi ìrù rẹ̀ tí ó lágbára gbé e lulẹ̀.

Kì Í Ṣe Kìkì fún Oró Dídá àti Híhùwà Ipá

Àgbọndò kan náà tí ó lè pani lára tún lè lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún pẹ̀lú ìjáfáfá. Bí ọmọ ọ̀nì kan tí kò tí ì jáde nínú ẹyin kò bá jára nù tó láti jáde kúrò nínú kòròfo ẹyin, ìyá ọ̀nì yóò yí àwọn ẹyin rẹ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, kí ẹyin náà baà lè tètè pa.

A ṣe eyín àwọn ọ̀nì láti di nǹkan mú, kì í ṣe láti gé nǹkan sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́. Bí ẹran ìjẹ náà kò bá tóbi jù, wọn yóò gbé e mì lódindi. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, wọn yóò fà á ya, wọn yóò sì máa jẹ ẹ́ láwẹ́láwẹ́. Àyẹ̀wò tí a ṣe lórí òkú àwọn ẹ̀dá afàyàfà ti fi hàn pé òkúta wà nínú ikùn wọn. Yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ jẹ ẹ́ ni tàbí ó ṣèèṣì, a gbà gbọ́ pé àwọn òkúta wọ̀nyí ń jẹ́ kí wọ́n lóòrìn nínú omi.

Àwọn àlejò sábà máa ń wo àwọn ọ̀nì tí wọ́n ya àwọn àgbọndò hẹ̀ǹlà wọn pàmùgà létí odò. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ rò pé bí wọ́n ti ya ẹnu wọn yìí fi hàn pé wọ́n ń bínú. Bí ó ti wù kí ó rí, kò rí bẹ́ẹ̀, àgbọndò tí ó yà sílẹ̀ ń jẹ́ kí ó lè mú ara bá ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù tí ó wà níta mu. Bíi gbogbo ẹ̀dá afàyàfà yòókù, àwọn ọ̀nì máa ń yí ìgbóná òun ìtutù ara wọn padà léraléra.

Ohun tí ó wá yani lẹ́nu ni pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀nì jẹ́ ẹ̀dá afàyàfà, ó ní ọkàn tí ó ní akoto mẹ́rin, bíi ti àwọn ẹ̀dá afọ́mọlọ́mú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí ọ̀nì kan bá ń mùwẹ̀, ìyípadà máa ń ṣẹlẹ̀, ọkàn náà yóò sì máa ṣiṣẹ́ bí èyí tí ó ní akoto mẹ́ta.

A lè mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀nì tí ń gbé inú omi oníyọ̀ àti àlégbà nípa wíwo ẹnu wọn tí ó rí ṣọnṣọ àti eyín tí ó wà ní èrìgì wọn ìsàlẹ̀ tí ó máa ń hàn síta nígbà tí ó bá pa àgbọndò rẹ̀ dé. A lè rí àwọn ọ̀nì gidi ní Africa, níbi tí àwọn aràrá ọ̀nì ń gbé, títí tí ó fi dé India, àti títí dé ilẹ̀ Asia dé Papua New Guinea. Wọ́n máa ń wà títí dé ìhà gúúsù Australia, wọ́n sì máa ń fẹ́ràn ilẹ̀ títẹ́jú etíkun tí ó bá ní igi ẹ̀gbà àti àwọn àbàtà ilẹ̀ olóoru, nítorí pé wọ́n máa ń kọ́ ìtẹ́ wọn sún mọ́ etí omi. Kìkì àbùkù lọ́nà tí ìṣẹ̀dá tí ó kàn wà níbẹ̀ ni pé, àgbàrá omi máa ń gbé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀nì tí kò tí ì dọmọ lọ lọ́pọ̀ ìgbà. Nítorí àwọn tí ń dọdẹ wọn, irú bí àwọn àgbà ọ̀nì, ẹja barramundi, àti ẹyẹ nankeen, ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún péré lára àwọn ọ̀nì tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde nínú ẹyin ní ń la ọdún àkọ́kọ́ wọn já.

Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, àwọn ọmọ ọ̀nì tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde nínú ẹyin máa ń jáde wá pẹ̀lú oúnjẹ tiwọn. Wọ́n máa ń rí oúnjẹ láti inú àpò inú ẹyin tí ó wà nínú ara wọn fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó àkọ́kọ́ tí wọ́n bá dáyé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbàrà tí ìyá wọn bá ti rọra fi ẹnu gbé wọn, tí ó sì gbé wọn lọ sí etí omi, wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í dán ṣóńṣó ẹnu wọn wò, nípa fífi sọ ohunkóhun tí ó bá wà nítòsí.

Èé ṣe tí èdè ìsọ̀rọ̀ náà, ‘ojú odò,’ fi bá a mu? Nítorí pé bí wọ́n bá tilẹ̀ jẹ́ ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dáyé, ojú wọn tín-íntìn-ìntín máa ń tàn yòò tí ènìyàn bá tanná sí wọn lálẹ́. Ìpele dídán yanranyanran kan tí ó wà lẹ́yìn awọ ọmọlójú wọn máa ń jẹ́ kí wọ́n ríran lálẹ́, ó sì máa ń jẹ́ kí àwọ̀ pupa náà tàn.

Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀nì jẹ́ ẹ̀dá afàyàfà tí ń ru ìmọ̀lára ẹni sókè, ní tòótọ́—àmọ́, a ní láti máa jìnnà sí i nígbà gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí àwọn apẹja sì ti mọ̀ dáadáa, ìgbìyànjú láti mú lefiatani jẹ́ asán.

Ewì Jobu ṣàpèjúwe ọ̀nì lọ́nà tí ó bá a mu gẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí “Lefiatani” pé: “Ìwọ́ lè fi ìwọ̀ fa Lefiatani [ọ̀nì ńlá] jáde, tàbí ìwọ́ lè mú ahọ́n rẹ̀ nínú okùn? Ìwọ́ lè fi ìwọ̀ bọ̀ ọ́ ní imú, tàbí o lè fi ẹ̀gún lù ú ní ẹ̀rẹ̀kẹ́? Òun ó ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí, òun ó ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́? Òun ó ha bá ọ dá májẹ̀mú bí, ìwọ ó ha máa mú un ṣe ìránṣẹ́ láéláé bí? Ìwọ́ ha lè bá a ṣiré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ óò dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ? Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí, wọn óò ha pín in láàárín àwọn oníṣòwò? Ìwọ lè sọ awọ rẹ̀ kún fún irin abetí, tàbí ìwọ óò so orí rẹ̀ kún fún ẹṣín apẹja? Fi ọwọ́ rẹ lé e lára, ìwọ óò rántí ìja náà, ìwọ kì yóò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.”—Jobu 41:1-8.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìṣọ́ra tí ó kún fún ọgbọ́n, tí ń rọ àwọn tí kò fura, tí wọ́n sì fẹ́ ṣe ojúmìító nìyí pé: Ṣọ́ra fún ‘ojú odò’—ọ̀nì alágbára, tí ń bọmọ lẹ́rù!

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 24]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Australian International Public Relations

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Tí a bá tanná sórí omi náà lálẹ́, ọ̀nì ‘ojú odò’ máa ń tàn yòò

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Koorana Crocodile Farm, Rockhampton, Queensland, Australia

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Apá òsì: Ọmọ ọ̀nì kan jáde láti inú ẹyin lójijì

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Koorana Crocodile Farm, Rockhampton, Queensland, Australia

Inú àkámọ́: Ọ̀nì tí o ti dàgbà ń yáàrùn létí Odò Mary tí ó ní ẹrọ̀fọ̀

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Australian International Public Relations

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́