ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 9/15 ojú ìwé 16
  • Párì Ọ̀nì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Párì Ọ̀nì
  • Jí!—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣọ́ra fún ‘Ojú Odò’!
    Jí!—1996
  • NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
    Jí!—2015
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
  • Sísọ̀rọ̀ Ketekete
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Jí!—2015
g 9/15 ojú ìwé 16
Abo ọ̀nì rọra fẹnu gbé ọmọ rẹ̀

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Párì Ọ̀nì

KÒ SÍ ẹranko mí ì láyé yìí tó lè fagbára deyín mọ́ nǹkan tó ọ̀nì. Bí àpẹẹrẹ, agbára tí àwọn ọ̀nì tó wà lágbègbè Ọsirélíà fi ń deyín mọ́ nǹkan fi ìlọ́po mẹ́ta ju agbára tí kìnnìún àti ẹkùn fi ń deyín mọ́ nǹkan lọ. Síbẹ̀, ọ̀nì máa ń tètè nímọ̀lára tí nǹkan bá kan párì rẹ̀, kódà, ó máa ń yára mọ nǹkan lára ju àwa èèyàn lọ. Báwo ni ọ̀nì tí awọ ara rẹ̀ yi bí irin ṣe lè tètè máa mọ nǹkan lára?

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn sẹ́ẹ̀lì tíntìntín tó ń gbé ìsọfúnni lọ sínú ọpọlọ ló wà ní párì ọ̀nì. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Duncan Leitch sọ pé: “Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fọ́nrán iṣan tó so kọ́ àwọn sẹ́ẹ̀lì yìí ló gba inú àwọn ihò ­tíntìntín tó wà nínú agbárí ọ̀nì.” Ihò agbárí yìí máa ń dáàbò bo àwọn fọ́nrán iṣan yẹn, lẹ́sẹ̀ kan náà, ó máa ń jẹ́ kó yára gba ìsọfúnni, èyí ló fà á tí ọ̀nì fi máa ń tètè mọ nǹkan lára. Fún ìdí yìí, ọ̀nì tètè máa ń mọ̀ ìyàtọ̀ láàárín oúnjẹ àti ohun tí kì í ṣe oúnjẹ tó bá wà ní ẹnu rẹ̀. Bákan náà, ọ̀nì tún lè kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí ẹnu láìjẹ́ pé ó máa ṣèèṣì deyín mọ́ wọn. Ká sòótọ́, ohun àrà gbáà ni páárì ọ̀nì jẹ́ torí pé, bó ṣe lágbára tó, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe tètè máa ń mọ̀ nǹkan lára.

Kí lèrò rẹ? Ṣé párì ọ̀nì kàn ṣàdédé wà bẹ́ẹ̀ ni, àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́