ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 2 ojú ìwé 86-ojú ìwé 88 ìpínrọ̀ 3
  • Sísọ̀rọ̀ Ketekete

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sísọ̀rọ̀ Ketekete
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • “Ìbáramu Ìṣètò Àkókò Lọ́nà Kíkọyọyọ”
    Jí!—1997
  • Ṣé Ọ̀rọ̀ Ẹnu Ẹ Máa Ń Tu Àwọn Èèyàn Lára?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 2 ojú ìwé 86-ojú ìwé 88 ìpínrọ̀ 3

Ẹ̀KỌ́ 2

Sísọ̀rọ̀ Ketekete

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o sọ̀rọ̀ lọ́nà tí yóò lè tètè yé àwọn tó ń gbọ́ ẹ. Èyí wé mọ́ (1) lílo àwọn ẹ̀yà ara tá à ń lò fún ọ̀rọ̀ sísọ bó ṣe tọ́, àti (2) mímọ òfin ẹ̀hun gbólóhùn.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Bí o bá sọ̀rọ̀ ketekete, ohun tí ò ń sọ á lè yé àwọn èèyàn. Bí ọ̀rọ̀ bá dá ṣáká lẹ́nu ẹni, ọwọ́ pàtàkì làwọn èèyàn sábà máa ń fi mú un.

IBÍ O bá ń fẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ ẹ yé nígbà tí o bá ń bá wọn sọ̀rọ̀, o ní láti sọ̀rọ̀ ketekete. Ó lè jẹ́ ohun tó fani mọ́ra lo fẹ́ sọ, àní ohun tó ṣe pàtàkì pàápàá, ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ rẹ kò bá fi bẹ́ẹ̀ yéni, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú rẹ̀ làwọn èèyàn yóò pàdánù.

Ọ̀rọ̀ tí kò bá fi bẹ́ẹ̀ yé àwọn èèyàn kì í ta wọ́n jí. Èèyàn ì báà lè sọ̀rọ̀ lóhùn rara kí àwọn èèyàn sì gbóhùn rẹ̀ dáadáa, bó bá ń rún ọ̀rọ̀ pọ̀ mọ́ra, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní sún àwọn èèyàn ṣe ohun tó fẹ́ kí wọ́n ṣe. Ńṣe ni yóò dà bí ìgbà tó ń sọ èdè àjèjì, ohun tó ń sọ kò sì ní yé àwọn olùgbọ́ rẹ. (Jer. 5:15) Bíbélì rán wa létí pé: “Bí kàkàkí bá mú ìpè tí kò dún ketekete jáde, ta ni yóò gbára dì fún ìjà ogun? Lọ́nà kan náà pẹ̀lú, láìjẹ́ pé ẹ sọ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn láti lóye jáde nípasẹ̀ ahọ́n, báwo ni a ó ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Ní ti tòótọ́, ẹ óò máa sọ̀rọ̀ sínú afẹ́fẹ́.”—1 Kọ́r. 14:8, 9.

Kí Ni Kì Í Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹni Dún Jáde Ketekete? Ó lè jẹ́ nítorí pé onítọ̀hún kì í la ẹnu dáadáa nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀. Bí iṣan àgbọ̀n ẹni bá le tantan, tí ètè ẹni ò sì fi bẹ́ẹ̀ mì dáadáa, ńṣe lèèyàn á máa ránu sọ̀rọ̀.

Béèyàn bá ń yára sọ̀rọ̀ jù, ìyẹn pẹ̀lú lè mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣòro láti yéni. Yóò dà bí ìgbà tí a fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a ti fi kásẹ́ẹ̀tì gbà sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí kásẹ́ẹ̀tì yẹn wá ń sáré tete. Òótọ́ ni pé ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ á máa dún, ṣùgbọ́n kò ní fi bẹ́ẹ̀ ṣeni láǹfààní rárá.

Nígbà mìíràn, ohun tí kì í jẹ́ kí àwọn kan lè sọ̀rọ̀ ketekete ni pé àwọn ẹ̀yà ara wọn tó wà fún ọ̀rọ̀ sísọ ní àbùkù. Ṣùgbọ́n àwọn tó ń bá irú ìṣòro yẹn yí ṣì lè mú ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ wọn sunwọ̀n sí i nípa fífi àwọn àbá tí a dá nínú ẹ̀kọ́ yìí sílò.

Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, rírún ọ̀rọ̀ pọ̀, ìyẹn yíyára pe ọ̀rọ̀ pa pọ̀ láìdánudúró débi pé yóò ṣòro láti lóye, ni kì í jẹ́ kí ọ̀rọ̀ dún ketekete. Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni olúwarẹ̀ ń pa sílébù ọ̀rọ̀ tàbí àwọn lẹ́tà pàtàkì kan lára ọ̀rọ̀ jẹ tàbí kó tiẹ̀ máa gbé ìparí ọ̀rọ̀ mì. Béèyàn bá ní àṣà rírún ọ̀rọ̀ pọ̀ mọ́ra, àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lè máa fòye gbé díẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, àmọ́ ńṣe ni wọ́n á máa méfò nípa ohun tó dà bíi pé ìyókù ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́. Ká sòótọ́, ẹni tí kì í báá pe ọ̀rọ̀ ketekete kò ní lè kọ́ni lọ́nà tó múná dóko.

Béèyàn Ṣe Lè Sọ̀rọ̀ Ketekete. Ọ̀kan lára àwọn ohun tó lè jẹ́ kéèyàn máa sọ̀rọ̀ ketekete ni pé kéèyàn ti mọ bí ẹyọ ọ̀rọ̀ ṣe ń para pọ̀ di gbólóhùn nínú èdè ẹni. Ní ọ̀pọ̀ jù lọ èdè, àtòpọ̀ sílébù ló máa ń di gbólóhùn ọ̀rọ̀. Sílébù ni ègé ọ̀rọ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó máa ń mú ìró kan ṣoṣo jáde. Nínú irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan sílébù yẹn la máa ń pè jáde lẹ́nu bá a bá ń sọ̀rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí a ṣe ń tẹnu mọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn lè yàtọ̀ síra. Bí o bá wá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ dún ketekete, ńṣe ni wàá rọra sọ̀rọ̀, wàá sì sapá dáadáa láti rí i pé ò ń pe gbogbo sílébù inú ọ̀rọ̀ jáde. Lákọ̀ọ́kọ́, ó lè dà bíi pé ò ń yun ẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ jù, ṣùgbọ́n bí o ṣe ń gbìyànjú ẹ̀ lọ, díẹ̀díẹ̀ wàá dẹni tó ń padà sọ̀rọ̀ geerege. Kí ọ̀rọ̀ lè yọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu, ó lè gba pé kí o máa já àwọn ọ̀rọ̀ kan pọ̀ mọ́ra, ṣùgbọ́n tí ìyẹn kò bá jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ yéni, kó o dáwọ́ rẹ̀ dúró.

Ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ kan rèé o: Láti lè dẹni tó ń pe ọ̀rọ̀ ketekete, o lè máa fi yíyun ẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ dánra wò nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ tàbí tó o bá ń kàwé. Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kúkú wá di ọ̀nà tí ò ń gbà sọ̀rọ̀. Ìyẹn á mú kí o dà bí ẹni tó ń ṣakọ tàbí tó ń sínni jẹ.

Bí ó bá dà bíi pé ò ń ránu sọ̀rọ̀, fi kọ́ra láti máa gbórí sókè kí o sì ti àgbọ̀n síwájú kúrò níbi àyà rẹ. Bí o bá ń ka Bíbélì, gbé e sókè dáadáa débi pé bí o bá gbójú kúrò lọ́dọ̀ àwùjọ láti wo Bíbélì rẹ, ńṣe ni wàá kàn sáà wo ìsàlẹ̀ díẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ lè dún jáde ketekete.

Mímọ bí a ṣe ń túra ká yóò tún mú kí ọ̀rọ̀ rẹ túbọ̀ já gaara. Ohun tó dájú gbangba ni pé bí iṣan àyíká ojú tàbí àwọn tó ń darí èémí rẹ bá le tantan, yóò ṣàkóbá fún ọ̀nà tí o gbà ń sọ̀rọ̀. Àìtúraká yìí máa ń ṣèdíwọ́ fún ọ̀nà tí ọkàn ẹni, àwọn ẹ̀yà ara tó ń ṣàkóso ọ̀rọ̀ sísọ, àti èyí tó ń darí èémí ń gbà ṣiṣẹ́ pọ̀, ńṣe ló sì yẹ kí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́ láìsí ìnira kankan.

Kò yẹ kí iṣan àgbọ̀n le tantan, ó yẹ kó dẹ̀ ni kí ó lè ṣe gbogbo bí ọpọlọ bá ṣe fẹ́ kí ó ṣe. Ètè pẹ̀lú ní láti dẹ̀. Ó yẹ kí ó lè máa ràn kí ó sì máa ṣù pọ̀ kíákíá láti mú kí àwọn ìró tó ń ti ẹnu àti ọ̀nà ọ̀fun wá máa dún jáde gẹ́lẹ́ bó ṣe yẹ. Bí àgbọ̀n àti ètè ẹni bá le tantan, ẹnu ò ní là dáadáa, á wá di pé ìró ń fi ipá gba àlàfo eyín jáde. Ìyẹn máa ń mú kéèyàn máa sọ̀rọ̀ bí ẹni tó kẹhùn, tó ń ránu sọ̀rọ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò dún ketekete. Àmọ́ ṣá o, dídẹ iṣan àgbọ̀n àti ètè kò túmọ̀ sí pé kéèyàn kúkú wá dẹni tó máa ń wọ́ ọ̀rọ̀ lu ara wọn. Ńṣe ló yẹ ká jẹ́ kó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí ó bá bí ìró ọ̀rọ̀ wa ṣe ń dún mu, kí ọ̀rọ̀ wa lè dún jáde ketekete.

Láti díwọ̀n bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ń dún létí, yóò dára pé kí o kàwé sókè. Fẹ̀sọ̀ kíyè sí bí o ṣe ń lo àwọn àgbàyanu ẹ̀yà ara tó ń gbé ọ̀rọ̀ jáde. Ǹjẹ́ ò ń la ẹnu tó kí ìró ọ̀rọ̀ rẹ lè jáde dáadáa láìsí ìdíwọ́? Rántí pé ahọ́n nìkan kọ́ ni ẹ̀yà ara tí a ń lò fún ọ̀rọ̀ sísọ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ́ ọ̀kan lára èyí tí a ń lò jù lọ. Ọrùn, àgbọ̀n ìsàlẹ̀, ètè, iṣan àyíká ojú, àti iṣan ọ̀nà ọ̀fun pẹ̀lú ń kó ipa tiwọn. Bí o ṣe ń sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ ó dà bíi pé apá ibì kankan kò mì ní àyíká ojú rẹ? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ńṣe lọ̀rọ̀ rẹ kò dún ketekete.

Bí ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀ bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó rẹ, fi gbohùn ara rẹ sílẹ̀, kí o sọ̀rọ̀ bó o ṣe máa ń sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ ayé, bíi pé ò ń báni sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tó o máa sọ gùn tó ìṣẹ́jú mélòó kan. Bí o bá gbọ́ ohùn tó o gbà sílẹ̀ yìí, á jẹ́ kí o lè rí àṣìṣe tó o bá ṣe ní ti ṣíṣàìpe àwọn ọ̀rọ̀ kan ketekete. Kíyè sí àwọn ibi tó o bá ti ń rún ọ̀rọ̀ pọ̀ mọ́ra, ibi tó o ti ń ránu sọ̀rọ̀, tàbí ibi tó o ti yára sọ̀rọ̀ bíi pé ọ̀rọ̀ ń jó ọ lẹ́nu, kí o sì gbìyànjú láti ṣàwárí ohun tó fà á. Lọ́pọ̀ ìgbà, wàá borí ìṣòro yẹn bí o bá ṣiṣẹ́ lé àwọn kókó tá a jíròrò lókè yìí lórí.

Ǹjẹ́ o ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ? Ṣe ìdánrawò, kí o la ẹnu sọ̀rọ̀ ju bó o ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ lọ, kí o wá gbìyànjú láti fẹ̀sọ̀ pe ọ̀rọ̀ ketekete ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Fa atẹ́gùn kún inú ẹ̀dọ̀fóró rẹ nígbà tó o bá mí sínú, kí o wá rọra máa sọ̀rọ̀. Ṣíṣe èyí ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tó túbọ̀ ṣe ketekete. Lóòótọ́, ìṣòro rẹ lè má yanjú pátápátá o, ṣùgbọ́n má sọ̀rètí nù. Rántí pé Mósè, tó jọ pé ó ní ìṣòro ọ̀rọ̀ sísọ, ni Jèhófà yàn láti lọ jẹ́ àwọn iṣẹ́ pàtàkì kan fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Fáráò ní ilẹ̀ Íjíbítì. (Ẹ́kís. 4:10-12) Bí o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, yóò lo ìwọ náà, yóò sì bù kún iṣẹ́ ìsìn rẹ tí wàá fi ṣàṣeyọrí.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Máa sọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan kí o sì máa ka ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ketekete, máa pè é lọ́nà tó dá ṣáká lẹ́nu, gbóhùn sókè bó ṣe yẹ, má ṣe yára jù má sì fa ọ̀rọ̀ nílẹ̀ jù. Rí i dájú pé o kò gbé ìparí ọ̀rọ̀ mì.

  • Má ṣe rún ọ̀rọ̀ pọ̀ tàbí kó o wọ́ ọ̀rọ̀ lura tí yóò fi di pé àwọn olùgbọ́ rẹ kò gbọ́ ẹ yé.

  • Gbórí sókè, kí o sì la ẹnu dáadáa tó o bá ń sọ̀rọ̀.

  • Kọ́ bí a ṣe ń dẹ ọrùn, àgbọ̀n, ètè, iṣan àyíká ojú àti ti ọ̀nà ọ̀fun.

ÌDÁNRAWÒ: Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀ lójoojúmọ́ ayé. Báwo lo ṣe la ẹnu tó? Ṣé ó yẹ kó o túbọ̀ là á díẹ̀ sí i kí o sì túbọ̀ lo iṣan àyíká ojú sí i? Gbìyànjú láti ṣe ìyẹn bí o ṣe ń ka Mátíù 8:23-27 sókè. Rí i dájú pé o gbórí sókè, kí o sì gbìyànjú láti dẹ iṣan àgbọ̀n rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́