ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/8 ojú ìwé 26
  • “Ìbáramu Ìṣètò Àkókò Lọ́nà Kíkọyọyọ”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ìbáramu Ìṣètò Àkókò Lọ́nà Kíkọyọyọ”
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sísọ̀rọ̀ Ketekete
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ṣé Ọ̀rọ̀ Ẹnu Ẹ Máa Ń Tu Àwọn Èèyàn Lára?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 9/8 ojú ìwé 26

“Ìbáramu Ìṣètò Àkókò Lọ́nà Kíkọyọyọ”

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GÚÚSÙ ÁFÍRÍKÀ

ÌṢÈTÒ ìsọ̀rọ̀ ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ àgbàyanu. Nǹkan bí 100 iṣan àyà, ọ̀fun, párì, ahọ́n, àti ti ètè ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láti gbé onírúurú ìró tí kò níye jáde. Iṣan kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìdìpọ̀ ọgọ́rọ̀ọ̀rún sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún fọ́nrán. Àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ tí ń ṣàkóso àwọn fọ́nrán iṣan wọ̀nyí pọ̀ ju iye tí eléré ìdárayá kan nílò láti gbé àwọn iṣan ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ. Sẹ́ẹ̀lì iṣan ìmọ̀lára kan tó láti gbé gbogbo 2,000 fọ́nrán iṣan iṣu ẹsẹ̀. Ní ìyàtọ̀ ìfiwéra, àwọn sẹ́ẹ̀lì iṣan ìmọ̀lára tí ń darí àpò ohùn, tàbí gògóńgò, lè máa gbé ìwọ̀nba fọ́nrán iṣan tí kò ju méjì tàbí mẹ́ta lọ.

Ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tàbí ìwọ̀nba àpólà ọ̀rọ̀ kékeré tí o sọ ní bátànì bí iṣan tirẹ̀ ṣe ń yíra pa dà. Gbogbo ìsọfúnni tí a nílò láti sọ àpólà ọ̀rọ̀ kan bíi “Kí ni nǹkan?” wà ní apá ibi tí ń darí ọ̀rọ̀ sísọ nínú ọpọlọ rẹ. Èyí ha túmọ̀ sí pé ọpọlọ rẹ ń lo ìṣètò iṣan aláìlẹ́gbẹ́, oníṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, tí kì í ṣeé tẹ̀ síhìn-ín sọ́hùn-ún láti sọ ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan bí? Rárá. Àwọn agbára ìsọ̀rọ̀ jẹ́ àgbàyanu gan-an ju ìyẹn lọ. Fún àpẹẹrẹ, egbò kan lè wà ní ẹnu rẹ tí ń mú kí ó ṣòro fún ọ láti pe àwọn ọ̀rọ̀ bí o ti ṣe máa ń pè wọ́n tẹ́lẹ̀. Láìròtẹ́lẹ̀, ọpọlọ mú bí àwọn iṣan ìsọ̀rọ̀ ṣe ń yíra pa dà bá ipò náà mu, èyí sì mú kí o lè pe àwọn ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí ó sún mọ́ bí o ti ṣe máa ń sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ bí ó ti lè ṣeé ṣe tó. Èyí ń tọ́ka sí àgbàyanu òtítọ́ mìíràn.

Ìkíni ọlọ́rọ̀ ẹnu lásán kan bí “Ẹ ǹlẹ́” lè ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtumọ̀ nínú. Ìró ohùn lè fi hàn nípa ẹni tó sọ̀rọ̀ náà bóyá inú rẹ̀ dùn, orí rẹ̀ yá, nǹkan sú u, ó ń kánjú, inú ń bí i, inú rẹ̀ bà jẹ́, tàbí bóyá ẹ̀rù ń bà á, ó sì lè fi bí oríṣiríṣi irú ipò ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ ṣe le tó hàn. Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo túmọ̀ sí lè yí pa dà látàrí ìṣesí àti ìwọ̀n ìṣiṣẹ́ àkókò láàárín ìpín ìṣẹ́jú àáyá ọ̀pọ̀ onírúurú iṣan.

Dókítà William H. Perkins ṣàlàyé nínú ìwé rẹ̀ Stuttering Prevented pé: “Ní ìwọ̀n fàájì, a ń gbé ìró tí ó tó 14 jáde láàárín ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan. Ìyẹn fi ìlọ́po méjì ju bí a ṣe lè darí ahọ́n, ètè, párì tàbí àwọn ẹ̀yà ìsọ̀rọ̀ wa mìíràn lọ bí a bá ń gbé wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ṣùgbọ́n bí a bá pa wọ́n pọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà láti sọ̀rọ̀, wọn óò ṣiṣẹ́ bí àwọn ìka ògbógi atẹ̀wé kan àti ti atẹdùrù fún ẹgbẹ́ akọrin kan ṣe ń ṣiṣẹ́. Wọ́n ń yíra pa dà láìfàkókò ṣòfò nínú ìbáramu ìṣètò àkókò lọ́nà kíkọyọyọ.”

Dé ìwọ̀n àyè tí ó láàlà, àwọn ẹyẹ kan lè sín ìró ọ̀rọ̀ ènìyàn jẹ. Ṣùgbọ́n kò sí ẹranko tí a ṣètò ọpọlọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ láti sọ ọ̀rọ̀ bí ènìyàn ṣe ń ṣe. Abájọ tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò fi tí ì ṣàṣeyọrí nínú ìgbìyànjú wọn láti mú kí àwọn ìnàkí lè gbé ìró ọ̀rọ̀ tí ó ṣe ketekete jáde. Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ètò iṣan ara ẹ̀dá náà, Ronald Netsell, ti sọ, a lè fi agbára òye tí a nílò láti sọ̀rọ̀ wé ti “ènìyàn aláìlẹ́gbẹ́ kan tí ń tẹ dùrù ‘láìlo ìwé atọ́nà ohùn orin’ rárá.” Tàbí gẹ́gẹ́ bí òǹṣèwé ìtumọ̀ èdè náà, Ludwig Koehler, ti parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Àṣírí kan ni ìṣètò ìsọ̀rọ̀ ènìyàn jẹ́; ẹ̀bùn àtọ̀runwá ni, iṣẹ́ ìyanu ni.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́