ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 9/8 ojú ìwé 27
  • Ètò Ààbò Ojúu Títì fún Àwọn Ẹranko Igbó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ètò Ààbò Ojúu Títì fún Àwọn Ẹranko Igbó
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdá Mẹ́ta Nínú Mẹ́rin Àwọn Ẹranko Inú Igbó Ló Ti Kú Láàárín Àádọ́ta (50) Ọdún—Kí Ni Bíbélì Sọ?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà—Báwo Lo Ṣe Lè Kojú Rẹ̀?
    Jí!—1997
  • Àárẹ̀—Ìdẹkùn Àìrí fún Àwọn Awakọ̀ Akẹ́rù
    Jí!—1997
  • Ọ̀nà Àwọn Ará Róòmù Ohun Tó Ń ránni Létí Iṣẹ́ Àwọn Onímọ̀ Ẹ̀rọ Ayé Àtijọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 9/8 ojú ìwé 27

Ètò Ààbò Ojúu Títì fún Àwọn Ẹranko Igbó

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ BRITAIN

Ọ̀KẸ́ márùn-ún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti àwọn ọ̀yà àti òkété tí ó pọ̀ ní ń kú ní àwọn títì ilẹ̀ Britain lọ́dọọdún, gan-an bí 40,000 gara, 5,000 òwìwí barn, àti àwọn ọ̀pọ̀lọ́ tí iye wọn lé ní mílíọ̀nù kan ṣe ń kú. Àwọn ìkùukùu ìgbà òtútù àti òkùnkùn ń dá kún pípa tí àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ń sáré ní àwọn títì ń pa àwọn ẹranko igbó. Àwọn awakọ̀ sábà máa ń yíwọ́ kí wọ́n ma baà pa ẹranko kan, àmọ́ wọ́n ń ba ọkọ̀ wọn jẹ́ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ forí sọ àwọn ọkọ̀ tí ń bọ̀ níwájú wọn. Nígbà míràn, èyí máa ń yọrí sí pípàdánù ẹ̀mí. Lẹ́yìn ìjàǹbá kan tí ẹranko kan fà, ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀ ni hílàhílo bá, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn àwọn ọlọ́pàá sì ṣe sọ, ọgọ́rọ̀ọ̀rún lára wọn ni kò lè lọ síbi tí wọ́n ń lọ mọ́.

Ní àwọn títì kan ní Britain, àwọn aláṣẹ ti ṣàgbékalẹ̀ àwọn ìhùmọ̀ kan tí ń fi òjìji ìmọ́lẹ̀ hàn kí wọ́n baà lè máa lé àwọn ìgalà jìnnà sí ojúu títì. Bí ìmọ́lẹ̀ ọkọ̀ kan bá dé ara àwọn ìhùmọ̀ tí ń fi òjìji ìmọ́lẹ̀ hàn náà, wọ́n ń gbé ìrísí tí ó jọ ojú ìkookò jáde! Níbòmíràn, a ti gbin àwọn igi sí ibi tí ó jìnnà gan-an sí ẹ̀gbẹ́ títì ju bí ó ṣe máa ń rí tẹ́lẹ̀ lọ, kí ó lè jẹ́ kí àwọn awakọ̀ rí ẹranko igbó èyíkéyìí tí ó bá wà níwájú dáradára. Ní United States, àwọn awakọ̀ kan ti ṣe àwọn fèrè tí ìwọ̀n ìgbì ariwo wọn máa ń pọ̀ bí ọkọ̀ bá ń rìn ju 55 kìlómítà ní wákàtí kan lọ sára ọkọ̀ wọn. Afẹ́fẹ́ tí ń gba inú fèrè náà kọjá ń mú ìró tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 60 decibel jáde ní ìwọ̀n ìgbì tí etí ènìyàn kò lè gbọ́ àmọ́ tí àwọn ẹranko igbó ń gbọ́ ketekete. Ìhùmọ̀ náà wúlò jù lọ nínú ọ̀ràn àwọn ẹranko tí etí wọn kọjú síwájú. Àwọn ọlọ́pàá ròyìn pé ìwọ̀n ìforígbárí pẹ̀lú àwọn ìgalà fi ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún dín kù nínú ìfidánrawò kan tí a ti lo fèrè náà.

Báwo ni ìwọ ṣe lè yẹra fún ìjàǹbá àti pípa àwọn ẹranko igbó run lójú títì láìnídìí? Bí o bá ń wakọ̀, ní pàtàkì nígbà òtútù tàbí lọ́wọ́ alẹ́, má ṣe sáré, sì tẹ̀ lé àwọn àmì ẹ̀gbẹ́ títì tí ń ta ọ́ lólobó nípa àwọn ẹranko tí ó wà nítòsí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́