ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 8/8 ojú ìwé 21-23
  • Àárẹ̀—Ìdẹkùn Àìrí fún Àwọn Awakọ̀ Akẹ́rù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àárẹ̀—Ìdẹkùn Àìrí fún Àwọn Awakọ̀ Akẹ́rù
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ohun Tí Ń Fa Àárẹ̀
  • Mímọ Ewu Náà
  • Ṣíṣẹ́pá Ewu Náà
  • Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?
    Jí!—2002
  • Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà—Báwo Lo Ṣe Lè Kojú Rẹ̀?
    Jí!—1997
  • Ohun Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Nígbà Táa Bá Ṣe Ohun Tó Pọ̀ Jù
    Jí!—2001
Jí!—1997
g97 8/8 ojú ìwé 21-23

Àárẹ̀—Ìdẹkùn Àìrí fún Àwọn Awakọ̀ Akẹ́rù

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ GERMANY

BÍ WÁKÀTÍ ti ń gorí wákàtí, ìró gooro ẹ́ńjìnì alágbára náà àti ariwo tí ẹsẹ̀ 14 tí ó wà lórí títì náà ń pa, para pọ̀ mú kí ìjàkadì tí awakọ̀ akẹ́rù náà ń bá àárẹ̀ jà ṣòro. Pẹ̀lú iná mọ́tò ní títàn sílẹ̀, a ń rí bí a ṣe ń kọjá àwọn ilà ojú títì wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Lójijì, ibi ìkẹ́rù eléjò ẹ̀yìn rẹ̀ ń fì láti ìhà kan sí ìhà kejì; ó ti ń lọ kúrò lójú títì.

Ní fífi gbogbo ìsapá yí ìtọ́kọ̀ náà, awakọ̀ náà darí ọkọ̀ rẹ̀ oníwọ̀n ẹrù 40 tọ́ọ̀nù pa dà sójú ọ̀nà. Nígbà tí ojú rẹ̀ dá pátápátá, ó wá mọ̀ pé òun kò rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìṣẹ́jú àáyá bíi mélòó kan ṣẹ́yìn. Àárẹ̀ ń mú un.

Ó rọrùn gan-an fún ẹnikẹ́ni tó bá ń bá àárẹ̀ jà nígbà tí ó ń wakọ̀ láti tòògbé fún ìgbà díẹ̀. Ní gbígbé àwọn ọ̀nà tó kún fọ́fọ́ lónìí yẹ̀ wò, ìyẹn lè léwu kọjá ààlà—kódà fún àwọn awakọ̀ míràn. Fún àpẹẹrẹ, ní Gúúsù Áfíríkà, lára gbogbo ìjàǹbá ọkọ̀ akẹ́rù ńláńlá tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín January 1989 sí March 1994, èyí tí àwọn awakọ̀ tí ń sùn nígbà tí wọ́n ń wakọ̀ fà lé ní ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún.

Ọ̀jọ̀gbọ́n G. Stöcker, olùṣèwádìí nípa ìhùwàsí àwọn awakọ̀, sọ nínú ìwé ìròyìn èdè German náà, Fahrschule, pé, àárẹ̀ tí ń pọ̀ sí i ń fa oorun kíkunni, ó sì ń pani bí ọtí. Dájúdájú, àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ kan àwọn tí ń wa oríṣiríṣi ọkọ̀, kì í ṣe àwọn tí ń wa ọkọ̀ akẹ́rù nìkan.

Àwọn Ohun Tí Ń Fa Àárẹ̀

Èé ṣe tí àwọn ìjàǹbá tí ó tan mọ́ àárẹ̀ fi máa ń ṣẹlẹ̀ léraléra tó bẹ́ẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, òfin dámọ̀ràn iye wákàtí tí awakọ̀ akẹ́rù kan ní láti pẹ́ tó nídìí ọkọ̀ wíwà, tàbí kí ó tilẹ̀ là á sílẹ̀ ní pàtó? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a gbọ́dọ̀ wo àròpọ̀ wákàtí tí àwọn awakọ̀ akẹ́rù fi ń ṣiṣẹ́, títí kan àkókò tí wọ́n ń lò láti ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn pẹ̀lú. Àwọn wákàtí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ yìí sábà máa ń gùn, kò sì wà déédéé.

Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn awakọ̀ akẹ́rù máa ń gbádùn rírí i pé àwọn parí iṣẹ́ kan pátápátá, èyí tí ó túmọ̀ sí kíkó àwọn ẹrù lọ sọ́dọ̀ oníbàárà kan nínú irú ipò ojú ọjọ́ èyíkéyìí. Wọ́n ń fi bí ibi tí a dé ti jìnnà tó àti bí ẹrù tí a kó ti pọ̀ tó díwọ̀n bí a ṣe ṣiṣẹ́ tó. Wákàtí iṣẹ́ lè pọ̀ gan-an ju ìpíndọ́gba lọ. Ní Germany, iye àkókò tí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn fi ń ṣiṣẹ́ kò pọ̀ tó 40 wákàtí lọ́sẹ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn awakọ̀ akẹ́rù fi ìlọ́po méjì ìyẹn ṣiṣẹ́.

Ní àwọn ilẹ̀ míràn, ipò nǹkan kò yàtọ̀ sí èyí. Ní Gúúsù Áfíríkà, owó ọ̀yà kéré gan-an, nítorí náà àwọn awakọ̀ ń gbìyànjú láti mú kí owó iṣẹ́ wọn pọ̀ sí i nípa wíwakọ̀ fún wákàtí tí ó túbọ̀ gùn. Àwọn ìròyìn tí ń wá láti Íńdíà fi hàn pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé iṣẹ́ olóhun ìrìnnà ń fún àwọn awakọ̀ ní àkókò tí ó pọ̀ tó láti parí ìrìn àjò wọn, ọ̀pọ̀ lára àwọn awakọ̀ akẹ́rù ń mú kí owó iṣẹ́ wọn pọ̀ sí i nípa kíkó kún ẹrù lọ sí àwọn ibi púpọ̀ sí i, tí èyí sì ń gba àkókò púpọ̀ sí i nídìí ọkọ̀ wíwà. Nígbà náà, wọ́n wá ní láti dín àkókò tí wọ́n fi ń sùn kù, kí wọ́n baà lè pa dà dé ilé iṣẹ́ lásìkò.

Láàárín Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe, nípa lílo iye wákàtí púpọ̀ jù lọ tí òfin fàyè gbà, awakọ̀ akẹ́rù kan lè lo wákàtí 56 nídìí ọkọ̀ wíwà lọ́sẹ̀ kan. Ṣùgbọ́n ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, a dín iye wákàtí púpọ̀ jù lọ tí ó ní láti fi wakọ̀ kù sí 34. Àwọn wákàtí tí ó fi ń ṣiṣẹ́, títí kan àkókò tó lò láti di ẹrù àti láti já a, ni ẹ̀rọ kan tí ń jẹ́ tachograph, tí ń wòṣe ẹni ń ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀. Àkọsílẹ̀ yí ń mú kí ó ṣeé ṣe láti ṣàyẹ̀wò bóyá awakọ̀ kọ̀ọ̀kan ń pa àwọn ìlànà mọ́.

Kókó abájọ mìíràn tí ń nípa lórí iye àkókò tí a ń lò nídìí ọkọ̀ wíwà ni ojú ìwòye ọlọ́kọ̀. Ọkọ̀ akẹ́rù rẹ̀ jẹ́ ìdókòwò olówó ńlá kan tí a ní láti lò lọ́nà tí ń mérè wá, bí ó bá ṣeé ṣe ní wákàtí 24 lóòjọ́ láìsí pé ó rìnrìn àjò kan láìkẹ́rù. Ìbáradíje láàárín àwọn ilé iṣẹ́ olóhun ìrìnnà ń pọ̀ sí i, àwọn alábòójútó ilé iṣẹ́ sì ń da àwọn awakọ̀ láàmú láti fínnúfíndọ̀ ṣiṣẹ́ fún wákàtí púpọ̀ sí i.

Àárẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí iye wákàtí tí a fi ń ṣiṣẹ́ bá gùn àti tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ní àkókò tí kò yẹ. Fún àpẹẹrẹ, ó wọ́pọ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láàárín agogo kan oru sí mẹ́rin ìdájí. Àkókò yẹn ni ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀ wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ lókun tó, tí ìpọkànpọ̀ wọn sì máa ń jẹ́ ahẹrẹpẹ jù lọ. Ìdààmú máa ń pọ̀ sí i bí àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n ń kó ẹrù lọ bá ń gba ẹrù ní ìwọ̀nba kíkéré jù lọ, tí wọ́n sì ń béèrè fún jíjá ẹrù ‘lákòókò gẹ́lẹ́.’ Èyí túmọ̀ sí pé awakọ̀ náà ní láti kó ẹrù dé ibi tí oníbàárà wà lákòókò gẹ́lẹ́ tí wọ́n fohùn ṣọ̀kan sí. Ọkọ̀ púpọ̀ jabíjabí lójú ọ̀nà, ipò ojú ọjọ́ tí kò dára, àti àtúnṣe ọ̀nà lè fa ìdádúró tí awakọ̀ náà ní láti fi àkókò dí.

Lójú àwọn ìkálọ́wọ́kò lórí iye wákàtí tí a fàyè gbà pé kí ẹnì kan fi wakọ̀, àyẹ̀wò tí àwọn ọlọ́pàá ń ṣe láìròtẹ́lẹ̀ tún fi rírú òfin náà hàn. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà, Polizei Verkehr & Technik, ṣe sọ, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ awakọ̀ 1 lára àwọn 8 tí ń wa ọkọ̀ akẹ́rù, bọ́ọ̀sì, àti àwọn tí ń kó ẹrù tí ó léwu ni kì í pa iye wákàtí tí a là sílẹ̀ fún wíwakọ̀ àti sísinmi mọ́.” Nígbà àyẹ̀wò àwọn mọ́tò kan tí a ṣe ní Hamburg, àwọn ọlọ́pàá rí awakọ̀ akẹ́rù kan tí ó ti fi wákàtí 32 wa ọkọ̀ láìsinmi.

Mímọ Ewu Náà

A bi awakọ̀ kan tí ń wakọ̀ ọ̀nà jíjìn tí ó ti lo 30 ọdún ní kíkó àwọn ẹrù láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn léèrè nípa ìṣòro àárẹ̀. Ó wí pé: “Ìgbéraga àti ìjọra-ẹni-lójú jù lè sún awakọ̀ kan láti ṣàìfiyèsí àárẹ̀. Bí ìjàǹbá ṣe ń ṣẹlẹ̀ nìyẹn.” A to àwọn àmì tí ń fi àárẹ̀ hàn sínú àpótí tí ó wà lójú ewé 22.

Mímọ àwọn àmì ìkìlọ̀ tí ó kọ́kọ́ máa ń yọjú lè gba ẹ̀mí là. Ìwádìí kan tí Àjọ Ààbò Ohun Ìrìnnà ti Orílẹ̀-Èdè ṣe ní United States fi àkọsílẹ̀ oníṣirò kan tí ń dáni níjì hàn: Lára ìjàǹbá 107 tí kò kan sísọlu ọkọ̀ míràn, 62 lára wọn tan mọ́ àárẹ̀. Nítorí náà, ilé iṣẹ́ náà so ìjẹ́pàtàkì púpọ̀ mọ́ ṣíṣe àwọn èlò ẹ̀rọ tí ń fúnni ní ìkìlọ̀ nígbàkígbà tí awakọ̀ bá ń sùn.

Ilé iṣẹ́ kan ní ilẹ̀ Japan ń ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ ohun abánáṣiṣẹ́ kan tí ń lo kámẹ́rà fídíò kan tí ń kíyè sí bí awakọ̀ náà ṣe ń ṣẹ́jú lemọ́lemọ́ tó. Tí ojú bá ń pa dé pẹ́ jù lọ́pọ̀ ìgbà, ohùn kan tí a ti gbà sílẹ̀ yóò kìlọ̀ fún un nípa ipò eléwu tí ó wà. Ilé iṣẹ́ kan ní Europe ń ṣiṣẹ́ lórí ẹ̀rọ kan tí ń ṣírò bí a ṣe ń darí ọkọ̀ kan lọ́nà gígúnrégé tó. Bí ọkọ̀ akẹ́rù náà bá fì, ìró kìlọ̀kìlọ̀ kan yóò dún níbi tí wọ́n jókòó sí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, yóò pẹ́ díẹ̀ kí a tó ṣe àwọn ẹ̀rọ tí ó gbéṣẹ́ jáde.

Ṣíṣẹ́pá Ewu Náà

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo ọkọ̀ ni àárẹ̀ ti jẹ́ èrò ọkọ̀ tí a kò ké sí, tí a kò sì fẹ́. Ìbéèrè náà ni bí a ṣe lè lé e jáde. Àwọn awakọ̀ kan máa ń mu ọ̀pọ̀ lítà ohun mímu oníkaféènì, kìkì láti rí i pé àárẹ̀ ṣì ń dà wọ́n láàmú láìdábọ̀. Àwọn mìíràn yíjú sí àwọn ohun arùmọ̀lára-sókè míràn. A kò tún ní láti máa sọ ọ́, ìwọ̀nyí ń wu ìlera léwu. Ní Mexico, àwọn awakọ̀ kan ń jẹ ata rodo (ata títa yoyo) kí wọ́n má baà sùn.

Ó dára láti sun oorun tí ó pọ̀ tó kí a tó jáde bọ́ sọ́nà. Bákan náà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ìpinnu ṣíṣe ohun tó tọ́, ẹnì kan gbọ́dọ̀ pa iye wákàtí tí a là sílẹ̀ fúnni láti fi wakọ̀ mọ́. Ní Gúúsù Áfíríkà, àwọn ògbógi dámọ̀ràn sísinmi lẹ́yìn wákàtí márùn-ún tí a ti ń wakọ̀. Bí awakọ̀ bá ń wakọ̀ lọ láwọn títì gbọnrangandan tí ń súni, ó yẹ kí ó mú kí iyè rẹ̀ wà lójúfò, kí ó sì pọkàn pọ̀. Àwọn awakọ̀ kan máa ń gbọ́ rédíò tàbí kí wọ́n máa bá àwọn awakọ̀ míràn sọ̀rọ̀ lórí rédíò CB. Awakọ̀ kan, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, máa ń gbọ́ àwọn kásẹ́ẹ̀tì tí ó ní àwọn kókó ọ̀rọ̀ Bíbélì, bí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àti àwọn ẹsẹ Bíbélì (Gẹ̀ẹ́sì). A lè rí àwọn àbá mìíràn nínú àpótí tí ó wà lójú ewé yìí.

Gbígba owó tí ó pọ̀ tó láti lè kájú ìgbọ́bùkátà túbọ̀ ń le koko sí i, nítorí náà wíwà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì kò rọrùn. Àwọn ilé iṣẹ́ kan tàbí àwọn alábòójútó ilé iṣẹ́ kan fojú kéré ewu tí ìdẹkùn àárẹ̀ gbé síwájú àwọn awakọ̀. Nígbà náà, olúkúlùkù ẹni tó ń ṣe òwò ohun ìrìnnà yóò ṣe dáradára láti fi àwọn ohun tí a kà nípa àárẹ̀ wọ̀nyí sọ́kàn. Ní àfikún, àwọn awakọ̀ sábà máa ń ní àwọn àbá wíwúlò láti inú ìrírí tiwọn fúnra wọn tí ó lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti bá oorun jà.

Dájúdájú, ọ̀nà dídára jù lọ láti wà lójúfò jẹ́ láti fún ara ní ẹ̀tọ́ tí ó ń béèrè fún: Bí o bá rí àwọn àmì ìkìlọ̀ èyíkéyìí, dúró ní ibi tí o ti lè sinmi, tí ó sún mọ́ ọ, kí o sì sùn díẹ̀. Lẹ́yìn náà, tún tẹ́rí gbé ìpèníjà wíwakọ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Má ṣe kó sínú ìdẹkùn àìrí tí àárẹ̀ ń mú wá náà!

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn Àmì Ìkìlọ̀ Tí Ń Béèrè fún Ìgbésẹ̀ Ojú Ẹsẹ̀

• Ojú ha ń gún ọ́ tàbí ìpéǹpéjú rẹ ha ń pa dé bí?

• O ha ń finú wòye àwọn nǹkan tàbí o ha rí araà rẹ tí o ń lálàá ọ̀sán gangan bí?

• Ó ha ń jọ pé títì ń kéré sí i, tí ó ń mú kí o máa wakọ̀ láàárín ọ̀nà bí?

• O ha ń gbàgbé àwọn apá ibì kan tí o ti kọjá nínú ìrìn àjò náà bí?

• Bí o ṣe ń lo ìtọ́kọ̀ àti bí o ṣe ń tẹ bíréèkì ha ń ṣe jìgìjìgì ju bí ó ti sábà máa ń rí lọ bí?

Dídáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sí ọ̀kan péré lára àwọn ìbéèrè òkè yí túmọ̀ sí pé o nílò ìsinmi lójú ẹsẹ̀

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 23]

Nígbà Ìrìn Àjò Jíjìn

• Sun oorun tí ó pọ̀ tó

• Má ṣe gbọ́kàn lé àwọn ohun arùmọ̀lára-sókè

• Máa dúró sinmi déédéé, kí o sì máa ṣeré ìmárale kí ara rẹ lè máa ta kébékébé

• Fi sọ́kàn pé àwọn ọ̀nà gígùn gbọnrangandan tí ń súni léwu ní pàtàkì

• Má ṣe fi ebi bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò kan. Fi àṣà jíjẹun dáradára kọ́ra: oúnjẹ tó fúyẹ́, tí ó sì ń ṣara lóore

• Mu ohun mímu tó pọ̀, àmọ́ yẹra fún ọtí líle

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́