ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 21-23
  • Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà—Báwo Lo Ṣe Lè Kojú Rẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà—Báwo Lo Ṣe Lè Kojú Rẹ̀?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Okùnfà àti Ìyọrísí
  • Yẹra fún Ríru Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà Sókè
  • Òjìyà Ni Ọ́ Bí
  • Kí Ló Ń Mú Kí Ìbínú Máa Ru Bo Àwọn Èèyàn Lójú Tó Bẹ́ẹ̀?
    Jí!—2002
  • Àárẹ̀—Ìdẹkùn Àìrí fún Àwọn Awakọ̀ Akẹ́rù
    Jí!—1997
  • Jàǹbá Ọkọ̀—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣẹlẹ̀ Sí Ọ?
    Jí!—2002
  • Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 21-23

Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà—Báwo Lo Ṣe Lè Kojú Rẹ̀?

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ILẸ̀ BRITAIN

ÌBÍNÚ àti ìwà ipá túbọ̀ ń yọjú nínú àwọn ìròyìn kárí ayé. Láfikún sí ìbínú nídìí kẹ̀kẹ́ ìkẹ́rù (tí ń mú kí àwọn oníbàárà tí ń ti kẹ̀kẹ́ ìkẹ́rù tàbí kẹ̀kẹ́ ìkóúnjẹ máa kanra mọ́ ara wọn nílé ìtajà ńlá) àti ìbínú nídìí tẹlifóònù (tí ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ń fàyè gba ẹni tí o tẹ̀ láago láti dá ọ dúró sórí ẹ̀rọ kí ó sì tún máa tẹ ẹlòmíràn láago ní tirẹ̀ ń fà), ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà ló tún ń gbàfiyèsí àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ Britain.

Ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà ti gbilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ìròyìn kan ní 1996 nípa àṣà ìwakọ̀ fi sọ pé ní ilẹ̀ Britain, ó ti “di àjàkálẹ̀, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì lára àwọn awakọ̀ ń fojú winá oríṣi ìkọlù tàbí àṣìlò kan láàárín ọdún tó kọjá”! Ìwádìí tí Ẹgbẹ́ Onímọ́tò kan ṣe tilẹ̀ sọ pé ó gbòòrò jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó sì ròyìn pé “onímọ́tò mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá ló sọ pé àwọn ti jìyà ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà.” Lọ́nà tó gbàfiyèsí, ìwádìí kan náà sọ pé “mẹ́fà péré nínú [àwọn onímọ́tò] mẹ́wàá ló jẹ́wọ́ pé àwọn fúnra àwọn bínú nígbà tí àwọn ń wakọ̀ lọ́wọ́.”

Kí ló ń fa ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà? Bí ìyà rẹ̀ bá ń jẹ ọ́, kí ni o lè ṣe láti dáàbò bo ara rẹ? Bí ọ̀nà tí ẹlòmíràn gbà ń wakọ̀ bá ń mú ọ bínú, kí ló yẹ kí o ṣe? Ní gidi, bí ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà ṣe ń gbilẹ̀ kárí ayé, báwo ni o ṣe lè kojú rẹ̀?

Okùnfà àti Ìyọrísí

Àwọn awakọ̀ tí ń bínú kì í ṣe ohun tuntun. Ọ̀kan lára àwọn tó ti kọ́kọ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni akéwì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà, Lord Byron. Ní 1817, ó kọ lẹ́tà kan nínú èyí tí ó ti sọ nípa awuyewuye kan tí ó ṣe lójú títì. Bí a ti gbọ́, ẹlòmíràn tí ó tún ń lo títì “ṣàfojúdi” sí ẹṣin Byron. Nítorí náà, akéwì náà sọ ẹ̀ṣẹ́ sí onítọ̀hún létí.

Ní ọ̀pọ̀ jù lọ orílẹ̀-èdè, bí iye àwọn ohun ìrìnnà ṣe ń pọ̀ sí i, ni ìjákulẹ̀ àwọn awakọ̀ ń pọ̀ sí i. Ní àwọn ọdún 1980 ni àwọn ìwé agbéròyìnjáde ilẹ̀ United States ṣàpèjúwe ohun tí ń fa ìwà ipá nígbà tí a bá ń wakọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ọ̀ràn òfin, lọ́nà yíyẹ wẹ́kú, ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà ṣàpèjúwe ìmọ̀lára tí ń fa ọ̀pọ̀ ìwà ipá tí àwọn ọlọ́kọ̀ tí ọ̀nà tí àwọn awakọ̀ míràn ń gbà wakọ̀ ń bí nínú ń hù.

Ìṣarasíhùwà tèmi-làkọ́kọ́ náà ń gba àwọn ojú títí wa kan nísinsìnyí. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London ṣe wí, àwọn tí ń wádìí nípa àṣà ìwakọ̀ parí èrò sí pé “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ nígbà gbogbo ni àwọn tí ń dá ìwà ipá tàbí ìwà ìkóguntini náà sílẹ̀ máa ń gbà pé òjìyà ìwà tí kò dára tí àwọn ẹlòmíràn ń hù ni àwọn.” Láìka bí awakọ̀ kan ṣe ń fi jàgídíjàgan darí ọkọ̀ rẹ̀ tó sí, ó gbà pé ẹ̀tọ́ òun ni. Ṣùgbọ́n nígbà tí awakọ̀ míràn bá hùwà àìlọ́wọ̀ kékeré kan lójú títì, ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà á ru sókè.

Àṣà ìjoògùnyó tí ń pọ̀ sí i, tí ó gbilẹ̀ rẹpẹtẹ láàárín àwọn ọ̀dọ́, tún ń dá kún ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà. Gẹ́gẹ́ bí oníṣègùn kan ṣe sọ, jíjẹ kokéènì yó “ṣeé fi wé mímutíyó nígbà tí a ń wakọ̀.” Àwọn awakọ̀ tí ń joògùn yó sábà máa ń ronú nípa ohun tí àwọn lè ṣe ju bó ṣe yẹ lọ. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, àwọn kan ń fi ọkọ̀ wọn sáré de ìwọ̀n tí ó léwu. Àwọn mìíràn ń wakọ̀ lọ́nà tí kò gún régé, níwọ̀n bí agbára wọn láti ṣèpinnu ti lábùkù.

Tún ronú lórí ipa tí másùnmáwo ń ní lórí awakọ̀ kan. Ọ̀jọ̀gbọ́n Cary Cooper ti Yunifásítì Manchester di ẹ̀bi bí ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà ṣe pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ru àwọn másùnmáwo àti àìdánilójú inú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ láàárín àwọn ọdún 1990. Agbẹnusọ Ẹgbẹ́ Ọlọ́kọ̀ Tí Ìjọba Fọwọ́ Sí kan sọ pé: “Àwọn awakọ̀ túbọ̀ ń ní másùnmáwo, ìkọlù oníwà ipá sì ń pọ̀ sí i.” Ọ̀gá àgbà kan tí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí gan-an ní ilé iṣẹ́ àjọṣe ará ìlú, tí ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti wakọ̀ lọ síbi iṣẹ́ kí ó sì wakọ̀ bọ̀ nísinsìnyí, jẹ́wọ́ pé òun kì í rára gba nǹkan nísinsìnyí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ròyìn pé ó wí pé: “Nísinsìnyí, mo ń yára sọ̀rọ̀ ìbínú, mo sì tètè ń bínú fùfù nítorí àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ tí kì í dà mí láàmú tẹ́lẹ̀.” Bóyá o ń nímọ̀lára kan náà. Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí ni o lè ṣe?

Yẹra fún Ríru Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà Sókè

Mọ̀ pé àwọn awakọ̀ tó kù kì í ṣe ẹni pípé. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọn yóò máa rúfin. Máa fi èyí sọ́kàn nígbà tí o bá ń wakọ̀. Máa ronú síwájú. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé o ń wakọ̀ ní ẹ̀gbẹ́ pátápátá, tàbí lọ́nà ẹni tí kò kánjú, níbi tí a ti pín ọ̀nà ojú òpópó. Àmọ́ nígbà náà ni o dé ibi tí ọ̀nà ti jára wọn, tàbí ibi ti ọ̀nà àbáwọlé tó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ti gba àwọn ọkọ̀ míràn láyè láti wọ ojú ọ̀nà ńlá. Bí o ti ń wo iwájú, o rí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan tí ń gba ibi tí ọ̀nà ti jára wọn bọ̀ wá sí ojú ọ̀nà ńlá. O ha ń ronú pé o ti wà níbẹ̀ ṣáájú, pé o ní ẹ̀tọ́ láti máa gba ọ̀nà rẹ lọ bí? Èé ṣe tí ó fi yẹ kí o fún ọkọ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ náà láyè? Èé ṣe tí o fi ní láti yíwọ́ sí ọ̀nà kejì, bí kò bá dí, láti yọ̀ǹda fún awakọ̀ tí ń bọ̀ náà kí ó lè já ojú ọ̀nà ńlá? Ṣùgbọ́n rò ó wò ná, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí o bá ranrí mọ́ ọ̀nà rẹ, tí o sì ń bá eré rẹ bọ̀ bẹ́ẹ̀? Bóyá awakọ̀ tí ń bọ̀ wá já ojú ọ̀nà ńlá náà yóò ronú bákan náà. Ó ṣe kedere pé ẹnì kan gbọ́dọ̀ fún èkejì lọ́nà; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìjàǹbá yóò ṣẹlẹ̀.

Lọ́nà ọlọ́gbọ́n, awakọ̀ tí ń fẹ́ yẹra fún ṣíṣokùnfà ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà máa ń wo iwájú, ó sì ń gba tẹlòmíràn rò bó ṣe ń wakọ̀. Ó ń fi ọ̀nà sílẹ̀ nígbà tí ó bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í bínú nígbà tí awakọ̀ míràn bá kùnà láti mọrírì ọ̀wọ̀ onínúure tí òun bù fún un. Ẹnì kan tó jẹ́ aṣojú Àjọ Àwọn Àgbà Onímọ́tò ilẹ̀ Britain fojú díwọ̀n rẹ̀ pé 1 lára àwọn awakọ̀ 3 ní ìṣòro ìṣarasíhùwà eléwu. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn awakọ̀ wọ̀nyí lè lo òye iṣẹ́ nínú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà wakọ̀, wọn kò ní ọ̀wọ̀ onínúure. Ó pè wọ́n ní “àgbà awakọ̀ tó jẹ́ onímọ́tò tí kò ní láárí.”

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ọ̀pọ̀ jù lọ awakọ̀ kì í ka àwọn mìíràn tí ń lo ojúu títì sí. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò dá ọ láre láti hùwà bẹ́ẹ̀. Ronú nípa àwọn ohun tí ó lè jẹ́ àbájáde rẹ̀. Dájúdájú, o kò ní fẹ́ kí agídí tí ìwọ bá ṣe dá ìforígbárí ọkọ̀ kankan sílẹ̀. Má ṣe jẹ́ kí ìmọ̀lára rẹ ṣàkóso rẹ. Ògbógi kan nídìí ọkọ̀ wíwà dámọ̀ràn pé: “Má ṣe hùwà pa dà tàbí dáhùn pa dà sí ìfínràn lójú títì.” Má ṣe wọ ẹgbẹ́ àwọn tí ń bínú nídìí ọkọ̀ wíwà!

Òjìyà Ni Ọ́ Bí

Ó ṣe kedere pé gbogbo awakọ̀ ló ti jìyà ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà nígbà kan. Ọwọ́ ìbínú tí a gbé sókè, èébú tí a búni, wíwọlé lọ́nà ìfínràn, gbogbo wọn ló lè dẹ́rù bani, tí wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ààbò tó dára jù lọ ni yíyẹra fún ìforígbárí. Ẹnì kan tó jìyà ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà rò pé a ń dẹ́rù ba òun ni, nígbà tí awakọ̀ míràn fẹ́ yà á sílẹ̀. Níkẹyìn, awakọ̀ tí inú ń bí náà yà á sílẹ̀, ó yíwọ́ wọlé síwájú rẹ̀, ó sì dẹ̀rìn tó bẹ́ẹ̀ tí òjìyà náà fi rò pé àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn yóò kọ lu ara wọn. Èyí ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀nà jíjìn kan, ìgbà tí òjìyà náà sì bọ́ sí ìlà títì míràn ni ó tó dópin.

Bí o bá rí i pé àwọn awakọ̀ míràn ń fẹ́ yà ọ́ sílẹ̀, ṣe gbogbo ohun tí o bá lè ṣe láti fún wọn láyè. Yẹra fún gígùnlé ẹ̀tọ́ rẹ láti wà níbi tí o wà lójú títì. Bí o bá ti mọ̀ọ́mọ̀ mú àwọn mìíràn bínú, tọrọ àforíjì. Fara ṣàpèjúwe láti fi hàn pé o kábàámọ̀ fún fífa ìmúnibínú láìmọ̀ọ́mọ̀ pàápàá. Rántí pé ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ lè tú ìbínú ká.

Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a fìyà ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà jẹ ọ́ fún ìdí èyíkéyìí, má ṣe gbẹ̀san. Ìwé ìròyìn Focus dámọ̀ràn pé: “Má gbẹ̀san. Má ṣe máa di àwọn nǹkan tí o lè lò bí ohun ìjà kiri nínú ọkọ̀ rẹ.” Àwọn ìsọfúnni mìíràn ni pé: Máa ti ilẹ̀kùn àti fèrèsé ọkọ̀ rẹ. Yẹra fún wíwo ojú òfínràn kan.

Àwọn àbá tí ó wà lókè nípa bí o ṣe lè kojú ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà kì í ṣe tuntun. Wọ́n bá ìmọ̀ràn tí Ọba Dáfídì ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti fúnni tipẹ́tipẹ́ dọ́gba pé: “Má ṣe ìkanra nítorí àwọn olùṣebúburú, kí ìwọ kí ó má ṣe ìlara àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Dákẹ́ inú bíbí, kí o sì kọ ìkannú sílẹ̀.”—Orin Dáfídì 37:1, 8.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà ń gbilẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó ráyè lọ́dọ̀ rẹ!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Kíkápá Ìbínú Nídìí Ọkọ̀ Wíwà

Ẹgbẹ́ Onímọ́tò sọ pé ní ti mímú ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà kúrò, “yíyí ìṣarasíhùwà ẹni pa dà ṣe pàtàkì gan-an bí àwọn ìgbésẹ̀ adènà ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà ṣe ṣe pàtàkì.” Níní èrò tó jẹ́ ojúlówó nípa òye iṣẹ́ ọkọ̀ wíwà tìrẹ fúnra rẹ àti ti àwọn ẹlòmíràn tí ń lo ojú títì ṣe pàtàkì fún kíkápá ìbínú nídìí ọkọ̀ wíwà. Bí o tilẹ̀ jẹ́ pé àṣìṣe tí àwọn mìíràn bá ṣe máa ń hàn kedere sí ọ, má ṣe gbójú fo àwọn àbùkù ọkọ̀ wíwà tìrẹ fúnra rẹ dá. Tẹ́wọ́ gba òtítọ́ náà pé àwọn awakọ̀ kan máa ń tẹ òfin títì lójú. Nígbà tí o bá ń wakọ̀, rí i dájú pé o wà lójúfò pátápátá. Àárẹ̀ ń dá kún másùnmáwo. Àìpọkànpọ̀ fúngbà díẹ̀ lè ní ìyọrísí aṣekúpani.

Tún ronú lórí ìmọ̀ràn tó tẹ̀ lé e yìí, kí o sì kíyè sí bí ó ṣe tan mọ́ àwọn òwe ọlọgbọ́n Ọba Sólómọ́nì.

• Àwọn èrò ọkọ̀ rẹ ha kíyè sí i pé o ń bínú bí? Bóyá wọ́n dámọ̀ràn pé kí o fọkàn balẹ̀. Má wulẹ̀ ṣá ìmọ̀ràn wọn tì, kí o sì sọ pé àwọn kọ́ ní ń wakọ̀. Rántí pé ìṣarasíhùwà onífọkànbalẹ̀ bá ìlera mu, ó sì lè ṣèrànwọ́ fún pípẹ́ láyé ni gidi! “Àyà tí ó yè korokoro ni ìyè ara.”—Òwe 14:30.

• Ronú nípa awakọ̀ kejì, kí o sì yẹra fún àwọn ìṣòro. “Ọlọgbọ́n ènìyàn bẹ̀rù, ó sì kúrò nínú ibi; ṣùgbọ́n aṣiwèrè gbéra ga, ó sì dá ara rẹ̀ lójú.”—Òwe 14:16.

• Fi ìfara-ṣàpèjúwe tàbí ọ̀rọ̀ ìtúúbá tú ìbínú ká. “Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ yí ìbínú pa dà.”—Òwe 15:1.

• Àwọn mìíràn lè ní ìtẹ̀sí láti máa bínú nídìí ọkọ̀ wíwà, ṣùgbọ́n o kò ní láti fara wé wọn. “Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́.”—Òwe 22:24.

• Yẹra fún dídá sí awuyewuye àwọn ẹlòmíràn. “Fi ìjà sílẹ̀ kí ó tó di ńlá.”—Òwe 17:14.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́