Pawel Gluza/500Px Plus/Getty Images
Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!
Ìdá Mẹ́ta Nínú Mẹ́rin Àwọn Ẹranko Inú Igbó Ló Ti Kú Láàárín Àádọ́ta (50) Ọdún—Kí Ni Bíbélì Sọ?
Ní October 9, 2024, àjọ kan tó ń jẹ́ World Wildlife Fund sọ ìròyìn kan tó bani nínú jẹ́ gan-an, ìyẹn nípa bí àwọn ẹranko inú igbó ṣe ń dín kù torí nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe. Wọ́n sọ pé “láàárín àádọ́ta (50) ọdún, ìyẹn láti 1970-2020, nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin àwọn ẹranko inú igbó ló ti kú.” Wọ́n tún sọ pé: “Kò sí àní-àní pé táwa èèyàn ò bá ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ní ọdún márùn-ún sí i, ayé lè bà jẹ́ débi pé kò ní ṣeé gbé mọ́.”
Kò yani lẹ́nu pé ọ̀rọ̀ yìí kó àwọn èèyàn lọ́kàn sókè. Ká sòótọ́, ayé yìí rẹwà gan-an, a ò sì fẹ́ kó bà jẹ́. Bákan náà, a nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹranko inú igbó, a ò sì fẹ́ kí wọ́n máa jìyà. Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa tójú àwọn ẹranko.—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Òwe 12:10.
Torí náà, o lè máa rò ó pé, ‘Ṣé àwa èèyàn lè dáàbò bo àwọn ẹranko inú igbó? Kí ni Bíbélì sọ?’
Ọjọ́ ọ̀la ń bọ̀ wá dáa
Kò sí báwa èèyàn ṣe lè gbìyànjú tó, Ọlọ́run nìkan ló lè dáàbò bo àwọn ẹranko inú igbó lọ́wọ́ gbogbo ewu. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nínú Ìfihàn 11:18 pé, Ọlọ́run máa “run àwọn tó ń run ayé.” Ẹsẹ Bíbélì yẹn jẹ́ ká mọ ohun méjì:
1. Ọlọ́run ò ní jẹ́ káwọn èèyàn ba ayé yìí jẹ́ pátápátá.
2. Ọlọ́run máa yanjú ìṣòro yìí láìpẹ́. Kí ló mú kéyìí dá wa lójú? Ìdí ni pé tí nǹkan ò bá tètè yí pa dà, àwọn èèyàn máa pa gbogbo àwọn ẹranko inú igbó tán.
Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa yanjú ìṣòro yìí? Ó máa lo Ìjọba kan tó gbé kalẹ̀ ní ọ̀run láti ṣàkóso gbogbo ayé. (Mátíù 6:10) Àwọn tó máa wà láyé nígbà yẹn máa jẹ́ onígbọràn, ìjọba yẹn sì máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa bójú tó àwọn ẹranko inú igbó.—Àìsáyà 11:9.