Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Àìsàn Àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kojú Ṣíṣàìsàn Tó Báyìí?” (June 22, 1997), wọ̀ mí lọ́kàn. Mo kan sáárá sí Jason, Ashley, àti Carmen nítorí bí wọ́n ṣe kojú àìsàn wọn lọ́nà dáradára bẹ́ẹ̀.
R. D., ilẹ̀ Faransé
Àmọ̀ràn tí ẹ fúnni wúlò, ó ń gbéni ró, ó sì gbéṣẹ́ ní tòótọ́. Ní pàtàkì ni ìrírí Ashley fún mi níṣìírí. Òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Èrò náà pé àwọn ènìyàn kan wà tí wọ́n ń fẹ́ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, àmọ́ tí wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí àìlera wọn, ti fún mi níṣìírí láti máa bá a lọ láìka àwọn ìṣòro tí mo ní sí.
D. I., Albania
Láti ìgbà tí mo ti mọ̀ pé àrùn Crohn ló ń ṣe mí, ó ti lé ní ẹ̀ẹ̀mẹwàá tí wọ́n ti dá mi dúró sí ilé ìwòsàn, tí mo sì ti nílò iṣẹ́ abẹ méjì. Àmọ́, fún ọdún mẹ́rin tí ó kọjá, mo ti ń sìn ní ìpínlẹ̀ àdádó níhìn-ín ní ilẹ̀ àjèjì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara mi kò tíì yá dáradára, ó ti ṣẹ́ pẹ́rẹ́ gan-an. Àwọn àpilẹ̀kọ náà fún mi níṣìírí gan-an.
G. H., Ecuador
Àwọn Ẹranko Ìgbẹ́ Tí Ń Pòórá Mo ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹranko, àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ta Ni Yóò Dáàbò Bo Àwọn Ẹranko Wa?” wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. (July 8, 1997) Mo lérò pé àwọn tí ń ka àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí yóò mọ ohun tí ìwọra àti ìwà òǹrorò ti ṣe fún ọ̀pọ̀ ọ̀wọ́ ẹranko.
G. H., United States
Gẹ́gẹ́ bí akíyànyán kan nípa àwọn ẹranko ìgbẹ́, inú mi dùn láti ka àwọn àpilẹ̀kọ yín. Àwọn ọgbà ẹranko ń ṣe ohun púpọ̀ láti ran àwọn ọ̀wọ́ ẹranko tí a wu léwu lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ọgbà ẹranko ni yóò gba àwọn ẹranko ìgbẹ́ sílẹ̀, ó dájú pé àwọn ẹranko wọ gàù. Kíkó àwọn ẹranko kúrò ní ibùgbé àdánidá wọn, kí a sì máa sìn wọ́n ní ọgbà ẹranko àárín ìlú, kọ́ ni yóò yanjú ọ̀ràn.
M. T., Kánádà
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè gbóríyìn fún irú ìsapá bẹ́ẹ̀ láti pèsè ààbò, a gbà gbọ́ pé ojútùú tí yóò wà pẹ́ títí kan ṣoṣo ni lílo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ayé lọ́nà tó bójú mu nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run. (Aísáyà 11:9)—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ààbò Ohun Ọ̀sìn Mo fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọmọdé Ha Wà Láìséwu Lọ́dọ̀ Ajá Rẹ Bí?” (July 8, 1997) Mo ti jẹ́ amọṣẹ́dunjú olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún 18, mo sì ń fìgbà gbogbo tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì kíkọ́ ajá lẹ́kọ̀ọ́ àti ẹrù iṣẹ́ ara ẹni. Ó yà mí lẹ́nu gan-an láti ka àpilẹ̀kọ tí ó kún fún ìsọfúnni yìí, inú mi sì dùn láti rí i pé olùkọ́-ajá-lẹ́kọ̀ọ́ tí ẹ fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ń lo irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí a ń lò. Mo lérò pé gbogbo àwọn tí wọ́n ní ajá yóò ka ìmọ̀ràn náà, wọn óò sì fi sílò.
B. C., United States
N óò fẹ́ láti fi kókó kan kún un pé: Lọ́nà àdánidá, àwọn ajá máa ń bẹ́ mọ́ oúnjẹ. Ajá kan lè dájú sọ ọmọdé kan tí ó gbé ẹran lílọ̀ tí wọ́n sè tàbí midinmí-ìndìn dáni gẹngẹ nígbà tí ó ń kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ajá náà kò ní in lọ́kàn láti rorò, àmọ́ ó lè bẹ́ mọ́ oúnjẹ náà, bí ó sì ti fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè gé ọmọ náà lọ́wọ́ jẹ. A gba àwọn òbí nímọ̀ràn dáradára láti gbé ẹrù iṣẹ́ wọn nínú ọ̀ràn yìí.
K. S., United States
A mọrírì àwọn àlàyé tí ẹ ṣàfikún wọn yìí.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Eléwu Mo mọrírì àpilẹ̀kọ náà, “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Eléwu—Báwo Ni Ohun Tí Ń Náni Ṣe Pọ̀ Tó?” (July 22, 1997) Gẹ́gẹ́ bí Kristẹni èwe kan, ọ̀pọ̀ ìdánwò ni mo ń dojú kọ. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ kí n rí i ní ti gidi pé a ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn àrùn àti ìpalára bí a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì.
R. K., United States
Àwọn Ìlù Tí Ń Sọ̀rọ̀ Lẹ́yìn tí mo ka àpilẹ̀kọ àgbàyanu náà, “Àwọn Ìlù Áfíríkà Ha Ń Sọ̀rọ̀ Ní Gidi Bí?” (July 22, 1997), mo tọ bàbá-bàbá mi, ẹni 100 ọdún lọ láti wádìí ìjótìítọ́ ìtàn náà. Ó sọ pé òtítọ́ ni gbogbo rẹ̀ látòkèdélẹ̀, ó sì wú mi lórí!
G. M. O., Nàìjíríà