Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ẹ̀bùn Agbára Ìgbọ́ròó Mo fẹ́ fi ìmọrírì mi hàn fún àpilẹ̀kọ “Agbára Ìgbọ́ròó Rẹ—Ẹ̀bùn Tí Ó Yẹ Kí O Ṣìkẹ́.” (September 22, 1997) Kí n tó ka àpilẹ̀kọ náà, mo rò pé mo mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú apá kọ̀ọ̀kan etí àti bí a ṣe ń gbọ́ròó dunjú ni. Àmọ́, n kò mọ bí mo ti jẹ́ òpè tó. Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23 kọyọyọ! Bí ìrònú àti ìsapá tí ẹ lò láti gbé àwòrán etí yẹn jáde ṣe pọ̀ tó jọ mí lójú gidigidi. Èyí tó wá jọ mí lójú jù ni bí a ṣe ṣẹ̀dá etí náà gan-an fúnra rẹ̀!
A. S., United States
Èmi àti ọ̀rẹ́ mi jẹ́ oníṣègùn, ó sì dá wa lójú láìṣẹ̀tàn pé, ní gbogbo ọ̀pọ̀ ọdún tí a ti fi kẹ́kọ̀ọ́, a kò tíì ka àpilẹ̀kọ kankan tó ṣàpèjúwe etí lọ́nà tó rọrùn, tó sì péye bẹ́ẹ̀ rí. Àpilẹ̀kọ yìí mú kí a fara mọ́ ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 139:14 pé: “Lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.”
M. B. àti Z. B., Venezuela
Ọ̀mùtí awakọ̀ kan ló kó bá mi. Lẹ́yìn odindi oṣù kan tí mo fi dákú, mo jí, n kò sì gbọ́ròó mọ́. Lẹ́yìn ọdún 18, n kò tíì lè gbọ́ròó dáradára, àmọ́ bí mo bá lo àwọn ohun èlò àfigbọ́ròó, mo lè gbọ́ròó dé ìwọ̀n kékeré kan. Àpilẹ̀kọ tó bọ́ sákòókò yìí ṣèrànwọ́ gidigidi fún àwọn tí ń gbọ́ròó dáadáa láti máa fi ọ̀ràn àwọn tí kò lè gbọ́ròó dáadáa ro ara wọn wò.
K. C., United States
Kilimanjaro Mo gbádùn àpilẹ̀kọ náà, “Kilimanjaro—Ibi Gíga Jù Lọ ní Áfíríkà.” (September 8, 1997) Mo rí Òkè Kilimanjaro ní January 1994, nígbà tí mo lọ sí àpéjọpọ̀ àgbáyé ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Kẹ́ńyà. Ìran náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìṣẹ̀dá àgbàyanu tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́.
E. J., United States
Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé Mo fẹ́ràn àpilẹ̀kọ náà, “Ojú Ìwòye Bíbélì: ‘Kì Í Ṣe Apá Kan Ayé’—Kí Ló Túmọ̀ Sí?” (September 8, 1997) Lẹ́yìn tí mo baralẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, mo pinnu láti ṣíwọ́ pípe àwọn tí kì í ṣe Kristẹni ní “ẹni ayé.” Ṣebí ní 30 ọdún sẹ́yìn, èmi náà kò ì di Kristẹni. Ká ní ẹni tó kọ́kọ́ kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ní ìṣarasíhùwà onígbèéraga ni, ó ṣeé ṣe kí n má ti fẹ́ láti bá Ẹlẹ́rìí kankan sọ̀rọ̀ mọ́ lẹ́yìn náà!
B. G., United States
Àwọn Gbájú-Ẹ̀ Nígbà tí mo kọ́kọ́ gba ìtẹ̀jáde September 22, 1997, n kò wá àyè láti ka ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ṣọ́ra fún àwọn Gbájú-Ẹ̀!” Lọ́jọ́ kejì, awakọ̀ takisí kan tó jọ pé ó níwà bí ọ̀rẹ́ gbájú àwa mẹ́rin nígbà tó rí i pé a kò mọ ìlú náà dunjú. Owó tó gbà lọ́wọ́ wa pọ̀, ibi tó sì já wa sí jìnnà gan-an sí ibi tí a ń lọ. Ì bá dára gan-an ká ní a ti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ inú Òwe 14:15, tí ẹ fà yọ ní ìparí àwọn àpilẹ̀kọ náà pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀”!
J. P., Philippines
Àwọn Ogun Ìsìn Mo ń ṣe àwọn ìwádìí kan lọ́wọ́ nípa Àwọn Ogun Ìsìn nígbà tí mo rí ìtẹ̀jáde October 8, 1997, gbà, tó ní àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ogun Ìsìn—‘Ẹ̀tàn Ọlọ́rọ̀ Ìbànújẹ́’” nínú. A ń gba ìsọfúnni ní àkókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu ní tòótọ́! Ó mú mi rántí bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé kí a máa ka ìwé ìròyìn náà ní kété tí a bá ti gbà á.
T. K., Finland
Párádísè Kan Láìsí Wàhálà Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án ni mí, mo sì fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Párádísè Kan Láìsí Wàhálà—Yóò Dé Láìpẹ́.” (October 8, 1997) Àpilẹ̀kọ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an nítorí pé baba mi ti lọ sí àjò, ẹ̀rù sì máa ń ba èmi àti màmá mi láti ṣí fèrèsé sílẹ̀ lóru, nítorí ẹnì kan lè já wọlé wa. Nítorí náà, nígbà tí mo kà nípa bí Jèhófà ṣe ṣèlérí láti mú gbogbo ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá kúrò, ara tù mí.
D. M., United States