ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 3/8 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 3/8 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ohun Àṣenajú Gbígbámúṣé Mo ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti di ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, n óò sì fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún títẹ̀ tí ẹ tẹ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Wíwá Ohun Àṣenajú Gbígbámúṣé” (May 22, 1997), jáde. Àwọn ètò gbígbámúṣé ṣọ̀wọ́n lórí tẹlifíṣọ̀n, ẹ sì fún gbogbo wa—lọ́mọdé lágbà—ní ìmọ̀ràn rere. Mo nírètí pé ẹ óò máa fún wa ní ìsọfúnni lórí àwọn kókó bí èyí nìṣó.

D. W., United States

Ọlọ́run Yóò Ha Máa Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Mi Nìṣó Bí? Mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wa onínúure fún àpilẹ̀kọ dáradára náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ọlọ́run Yóò Ha Máa Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Mi Nìṣó Bí?” (May 22, 1997) Láìpẹ́ yìí, mo kọ ọ̀rọ̀ kún ìwé ìbéèrè kan nípa iye ọ̀rẹ́ tí mo lè ní, àbájáde rẹ̀ níkẹyìn sì mú un dá mi lójú pé n óò máa ní àwọn ọ̀rẹ́ láyìíká mi nígbà gbogbo. Ó bani nínú jẹ́ pé ìdánilójú yìí ti já sí èké pátápátá. Síbẹ̀, mo wá mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ni Ọ̀rẹ́ wa dídára jù lọ. Òtítọ́ ni pé, bí a kò bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, a jẹ́ pé ohun gbogbo já sí òfìfo.

A. T. M., Mexico

Ẹ ṣeun fún ọkàn ìfẹ́ tí ẹ ń fi hàn sí àwọn ọ̀dọ́. Mo gba àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ọlọ́run Yóò Ha Máa Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Mi Nìṣó Bí?” ní àkókò tí mo nílò rẹ̀ jù lọ gan-an. A ti yọ mí lẹ́gbẹ́ tẹ́lẹ̀, a sì ti gbà mí padà láìpẹ́ yìí. Nígbà mìíràn, mo ti lérò pé mo nìkan wà, mo sì kojú ọ̀pọ̀ iyèméjì—ọ̀kan nínú wọn ni pé, Ǹjẹ́ Ọlọ́run ń fetí sí mi? Lẹ́yìn tí mo ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ̀gún Kan Nínú Ẹran Ara,” mo pinnu láti wá ìbùkún kan láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé àti àdúrà aláìlẹ́tàn. Ní kedere, a ti dáhùn ìbéèrè náà, Jèhófà yóò ha máa jẹ́ ọ̀rẹ́ mi nìṣó bí?

J. C. A., Ajẹntínà

Sísin Kòkòrò Oyin Mo ń kọ̀wé nípa àpilẹ̀kọ náà, “Sísin Kòkòrò Oyin—Ìtàn ‘Aládùn’ Kan” (May 22, 1997), nínú èyí tí ẹ ti pèsè ìsọfúnni títọ̀nà nípa kòkòrò oyin ní ṣókí. Mo fẹ́ràn àkànpọ̀ àlàyé, àwòrán, àti èrò yíyẹ náà—láìsí àwọn àṣìṣe. Òṣìṣẹ́ oyin sísìn kan sábà máa ń kíyè sí ìsọfúnni tí kò ṣe pàtó tàbí tí kò jẹ́ òtítọ́ délẹ̀délẹ̀ nínú àwọn ìròyìn tí ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde ń ṣe, àmọ́ kò sí irú ìyẹn nínú àpilẹ̀kọ yín. Mo jẹ́ ẹni tí ń sin oyin tìtaratìtara, mo sì sábà máa ń rí ‘ògidì ọgbọ́n’ lára àwọn kòkòrò wọ̀nyí jú bí mo ṣe ń rí i lára ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ. Nítorí náà, mo rò pé ó yẹ fún mi láti sọ pé, lọ́nà tí ẹ gbà sọ nípa kókó yìí, ẹ gbóríyìn fún ẹwà ìwàláàyè, ní pàtàkì, bí ó ṣe hàn gbangba nínú irú àwọn ẹ̀dá kékeré bẹ́ẹ̀.

P. G. M., Ítálì

Ṣíṣètọ́jú Ẹ ṣeun fún títẹ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ṣíṣètọ́jú—Kíkojú Ìpèníjà Náà” (February 8, 1997), jáde. Màmá mi ní àrùn jẹjẹrẹ, ṣíṣètọ́jú rẹ̀ ní ìpele gíga jù lọ àrùn náà ti tán mi lókun. Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ṣàpèjúwe ìmọ̀lára ẹni tí n ṣètọ́jú náà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, ó sì fi bí àwọn ẹlòmíràn ṣe lè gba ti àwa tí a wà ní ipò yẹn rò hàn wọ́n. A kì í sábà rí irú àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀.

F. T., Taiwan

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ọmọ ọdún 12 ni mí. Mo ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́, mo sì gbádùn kíka àwọn ìwé ìròyìn yín gan-an. Kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kà wọ́n, ó ṣòro fún mi láti máa bá àwọn tó dàgbà jù mí lọ kẹ́gbẹ́. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí mo ka àwọn àpilẹ̀kọ Jí! ní ẹ̀ka “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ,” ó ti rọrùn fún mi gan-an. Ẹ ṣeun!

N. T., Rọ́ṣíà

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa Láti ọdún 26 wá ni mo ti ń ka Jí! déédéé, mo sì ń gbádùn ìwé ìròyìn náà síbẹ̀ bíi ti tẹ́lẹ̀. N kò kùnà láti ka ẹ̀ka “Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa” rí, nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ máa ń mú kí n tún àpilẹ̀kọ náà kà. Ẹ ṣeun fún àwọn ìwé ìròyìn títayọlọ́lá wọ̀nyí.

M. B., ilẹ̀ Faransé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́