ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Ìpèníjà Ṣíṣètọ́jú
    Jí!—1997
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • “Jókòó Jẹ́ẹ́, Kí O Sì Fetí Sílẹ̀!”
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ṣíṣètọ́jú—Kíkojú Ìpèníjà Náà Àgbàyanu ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí (February 8, 1997) fún mi níṣìírí gidigidi. Ọmọ ọdún 17 ni mí, mo sì ń ṣètọ́jú bàbá mi àgbà tó ní àrùn ẹ̀gbà àti ìyá mi tí ó ní ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ àti ìmọ̀lára. O tù mí lára láti kà pé ó bá ìwà ẹ̀dá mu láti bínú sí àwọn olùgbàtọ́jú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí a sì béèrè pé, ‘Èé ṣe tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?’ Mo tún mọyì àpilẹ̀kọ tó sọ nípa ìrànwọ́ wíwúlò tí a lè ṣe fún olùṣètọ́jú.

P. T., Ítálì

Bí ẹ ṣe ṣàpèjúwe ìmọ̀lára àwọn tí ń ṣètọ́jú àwọn olólùfẹ́ tí ń ṣàìsàn jẹ́ òtítọ́, ó sì kún fún ìmòye. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ru yín sókè láti kọ àwọn àpilẹ̀kọ arùmọ̀lára-sókè wọ̀nyí. Ó dá mi lójú pé wọn yóò ran gbogbo àwa tí a wà nínú ipò yí lọ́wọ́ láti mú ara wa bá a mu, kí a sì máa bá a nìṣó ní fífi ìdùnnú àti ìtara ṣiṣẹ́ sin Jèhófà.

B. V., Orílẹ̀-èdè Olómìnira Czech

Mo jẹ́ ìyá àwọn ọ̀dọ́langba méjì, mò ṣe ìkọ̀sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, ọmọkùnrin mi sì ní àrùn ADHD (Àrùn Araàbalẹ̀ Tí Ń Fa Àìlèpọkànpọ̀) lílekoko. Másùnmáwo tí ẹrù ìnira yìí ní nínú kàmàmà. Nípasẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí nípa ṣíṣètọ́jú, mo ti wá lóye àwọn ìmọ̀lára ìkójútìbáni, ìbínú, ìsoríkọ́, àti àìlólùrànlọ́wọ́ tí mo ní. Ohun kan tó fún mi níṣìírí ni pé, àwọn arákùnrin àgbàlagbà nínú ìjọ ti ṣèrànwọ́ nínú bíbójútó ọmọkùnrin mi. Ẹ wo bí ó ti dùn mọ́ mi nínú tó láti rí bí a ṣe ń lo ìfẹ́ nípa gbígbégbèésẹ̀!

C. C., United States

Ọkọ mi ní àrùn ọpọlọ, mo sì ní láti ṣàbójútó rẹ̀. Ẹ̀rù ń bà mí pé n kò ní lè ṣe é. Jeanny, tí ẹ mẹ́nu bà nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà, fún mi níṣìírí nígbà tí ó gbani nímọ̀ràn pé: “Ìbẹ̀rù ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sábà máa ń burú ju ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní gidi lọ.”

A. P., Slovakia

Nígbà kan, mo jẹ́ olùṣètọ́jú, mo sì ní ọ̀pọ̀ lára àwọn ìmọ̀lára tí ẹ ṣàpèjúwe nínú àwọn àpilẹ̀kọ náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, n kì í lè bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìjákulẹ̀ àti ẹ̀bi mi. Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí ti ràn mí lọ́wọ́ láti jíròrò àwọn ìmọ̀lára mi.

F. F., Nàìjíríà

N kò fìgbà kankan ronú pé a óò tẹ irú àpilẹ̀kọ àrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀ jáde. Ìyá mi ti wà láìlèdìde-lórí-ibùsùn láti 1989. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ ọmọkùnrin kan ṣoṣo náà láìsí àwọn iyèkan tàbí bàbá, mo tẹ́rí gba ẹrù iṣẹ́ ṣíṣètọ́jú rẹ̀. Mo fara mọ́ ìpínrọ̀ tó kẹ́yìn àwọn àpilẹ̀kọ náà—pé Jèhófà àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, ni olùṣètọ́jú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ jù lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà tí ipò náà bá polúkúrúmuṣu, tí mo sì rò pé n kò lè kojú rẹ̀ mọ́, mo máa ń yíjú sí Jèhófà nínú àdúrà, mo sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ràn mí lọ́wọ́. Nípa wíwulẹ̀ mọ̀ pé ó ń gbọ́, mo lè nímọ̀lára pé mo ń ní okun pa dà.

M. A. M., Peru

Ọkọ mi ń ṣàìsàn, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tí ìwé ìròyìn náà mẹ́nu bà ni mo ti nírìírí rẹ̀. Mo rántí ọ̀pọ̀ ìgbà tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń béèrè nípa ọkọ mi. Nígbà míràn, inú máa ń bí mi, mo sì ń ṣe kàyéfì pé, ‘Èé ṣe tí wọ́n sábà máa ń béèrè nípa rẹ̀? Èmi ńkọ́?’ Mo wá mọrírì rẹ̀ nísinsìnyí pé irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ wulẹ̀ bá ìwà ẹ̀dá mu ni.

M. A. I. I., Sípéènì

Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́ Mo jẹ́ òbí ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́wàá kan tí ó ní àrùn ADHD lílekoko. Mo láyọ̀ láti sọ fún yín pé láti ìgbà tí ẹ ti tẹ ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ìrànwọ́ fún Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Ní Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́” (February 22, 1997), jáde, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ti sọ fún mi pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ti gbìyànjú láti lóye ìṣiṣẹ́gbòdì náà kí àwọn sì ràn mí lọ́wọ́, àwọn kò fìgbà kankan lóye ìmọ̀lára èmi àti ọmọkùnrin mi ní kíkún. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn sọ pé àwọn yóò túbọ̀ ṣe tán láti ṣèrànwọ́ nísinsìnyí. Arábìnrin kan nínú ìjọ lo àkókò díẹ̀ pẹ̀lú ọmọkùnrin mi láti ṣàyẹ̀wò àpilẹ̀kọ náà, kí ó sì fún un níṣìírí. Lẹ́yìn náà, ọmọkùnrin mi wá bá mi, ó sì béèrè pé kí a tún ka ìwé ìròyìn náà.

L. A. D., United States

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́