ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 2/8 ojú ìwé 3-6
  • Ìpèníjà Ṣíṣètọ́jú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpèníjà Ṣíṣètọ́jú
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ó Ń Mára Tì Mí Gan-an”
  • “Mo Ń Fòyà Pé Bí A Kò Bá Ṣọ́ra . . .”
  • “Bí Ipò Wọn Ṣe Rí Sí Ti Tẹ́lẹ̀ Lè Bà Ọ́ Nínú Jẹ́”
  • “Mo Nímọ̀lára Ìpatì, Ìbínú”
  • “Mo Nímọ̀lára Ẹ̀bi”
  • Ṣíṣèrànwọ́ Fún Olùṣètọ́jú—Bí Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
    Jí!—1997
  • Bí A Ṣe Lè Kojú Ìmọ̀lára
    Jí!—1997
  • Tí Àìsàn Gbẹ̀mí-Gbẹ̀mí Bá Ń Ṣe Ẹni Tá A Nífẹ̀ẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 2/8 ojú ìwé 3-6

Ìpèníjà Ṣíṣètọ́jú

“NÍGBÀ míràn, mo máa ń dàníyàn pé kí n lè bọ́ nínú ipò náà. Àmọ́, mo wúlò fún un ju ti ìgbàkigbà rí lọ. Nígbà míràn, mo máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà gan-an.”—Jeanny, ẹni tí ó fi oṣù 18 tọ́jú ọkọ rẹ̀, ọlọ́dún 29, kí ìwúlé inú ọpọlọ tóó pa á.a

“Àwọn ìgbà kan wà tí ara máa ń kan mí sí Mọ́mì, nígbà náà, n óò wá kórìíra ara mi. Mo máa ń nímọ̀lára bí ẹni tí kò tóótun nígbà tí n kò bá lè kojú ipò náà dáradára.”—Rose, ẹni ọdún 59, tí ó tọ́jú ìyá rẹ̀ tí ó jẹ́ ẹni 90 ọdún, tí ó wà ní ipò ẹlẹgẹ́, tí kò lè kúrò lórí ibùsùn.

Ìròyìn nípa àìsàn tí ń la ikú lọ tàbí èyí tí ó ti di bárakú lè ba ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ nínú jẹ́. Jeanne Munn Bracken sọ nínú ìwé Children With Cancer pé: “Nígbà tí a bá ṣàwárí àrùn, gbogbo ìdílé máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà. Wọ́n lè má mọ ẹlòmíràn tí ó ti ní ìṣòro yìí rí.” Ó sábà máa “ń yà wọ́n lẹ́nu, wọn kì í sì í gbà gbọ́,” bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Elsa nígbà tí ó gbọ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, Betty, ẹni ọdún 36, ní àrùn jẹjẹrẹ. Sue, tí bàbá rẹ̀ ń ṣàìsàn, ní “ìmọ̀lára àìjámọ́ǹkan, amúniṣàárẹ̀-ọkàn” nínú ikùn rẹ̀ nígbà tí ó mọ̀ níkẹyìn pé àrùn jẹjẹrẹ ní ń pa bàbá rẹ̀ lọ.

Àwọn mẹ́ńbà ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ lè rí ara wọn bí olùṣètọ́jú lójijì—ní pípèsè àwọn ohun tí aláìsàn náà nílò nípa tí ara àti ti èrò ìmọ̀lára. Wọ́n lè ní láti gbọ́únjẹ aṣaralóore, kí wọ́n bójú tó lílo oògùn, kí wọ́n ṣètò fún ọkọ̀ tí yóò gbé e lọ sọ́dọ̀ dókítà, kí wọ́n ṣe àwọn tí wọ́n wá bẹ aláìsàn náà wò lálejò, kí wọ́n bá aláìsàn náà kọ lẹ́tà, àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan mìíràn. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ ni a máa ń rún mọ́ àárín ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó ti há tẹ́lẹ̀.

Bí ó ti wù kí ó rí, bí ipò aláìsàn náà ṣe ń burú sí i, iṣẹ́ ṣíṣètọ́jú ń gbàfiyèsí sí i. Kí ni èyí lè ní nínú? “Ohun gbogbo!” bí Elsa ṣe sọ nípa ọ̀rẹ́ rẹ̀ Betty tí kò lè kúrò lórí ibùsùn. “Wíwẹ̀ fún un àti fífi oúnjẹ nù ún, kíkó èébì rẹ̀, dída ìtọ̀ inú rọ́bà ìfàtọ̀sí rẹ̀ nù.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí Kathy ń ṣe jẹ́ alákòókò kíkún, ó ní láti ṣètọ́jú ìyá rẹ̀ tí ń ṣàìsàn. Sue, tí a mẹ́nu kan níṣàájú, sọ nípa “yíyẹ ìdíwọ̀n ooru ara [bàbá rẹ̀] wò, tí ó sì ń ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní ọgbọọgbọ̀n ìṣẹ́jú, fífi omi bà á lára nígbà tí ìwọ̀n ooru ara rẹ̀ bá ń ròkè, àti pípààrọ̀ aṣọ rẹ̀ àti aṣọ bẹ́ẹ̀dì rẹ̀ láàárín wákàtí díẹ̀díẹ̀ síra.”

Ìjójúlówó ìtọ́jú tí aláìsàn ń rí gbà yóò sinmi, lọ́nà púpọ̀, lórí ìlera àwọn tí ń ṣètọ́jú náà. Síbẹ̀, àwọn ìmọ̀lára àti àìní àwọn tí ń ṣètọ́jú aláìsàn náà ni a sábà máa ń gbójú fò dá. Bí ìṣètọ́jú bá yọrí sí ẹ̀yìn dídùn àti èjìká ríro lásán, yóò jẹ́ ohun tí ó ṣòro gan-an. Àmọ́, bí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn olùṣètọ́jú yóò ti jẹ́rìí sí i, ìṣètọ́jú náà ń náni ní èrò ìmọ̀lára púpọ̀ jọjọ.

“Ó Ń Mára Tì Mí Gan-an”

Ìwé The Journals of Gerontology ròyìn pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ìwádìí ń ṣàpèjúwe wàhálà tí ń jẹ́ àbájáde ìhùwà àìmèrò, tí ń mára tini, àti ìsọ̀rọ̀ jàùjàù [ti aláìsàn] náà.” Fún àpẹẹrẹ, Gillian ṣàpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ní ìpàdé Kristẹni ní òun fẹ́ láti kí ìyá rẹ̀, tí ó jẹ́ arúgbó. Gillian rántí tìbànújẹ́tìbànújẹ́ pé: “Ìyá mi kàn ń wò suu ni, kò sì fèsì. Ó ń mára tì mí gan-an, ó sì pa mí lẹ́kún.”

Joan, tí ọkọ rẹ̀ ní àrùn ọpọlọ, sọ pé: “Ó jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí ó ṣòro jù lọ láti fara dà.” Ó ṣàlàyé pé: “Ó jẹ́ kí ó jọ ẹni tí kò lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà tí a bá ń jẹun pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ní ilé àrójẹ, “nígbà míràn, ó máa ń lọ sí ìdí àwọn tábìlì míràn nínú ilé ìjẹun náà, yóò tọ́ àpòpọ̀ èso àti ṣúgà wò, yóò sì dá ṣíbí tí ó lò náà pa dà sínú àwo àpòpọ̀ èso àti ṣúgà náà. Nígbà tí a bá lọ kí àwọn aládùúgbò, ó lè bẹ́tọ́ sójú ọ̀nà ọgbà wọn. Ó ṣòro gidigidi fún mi láti gbé èrò pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹlòmíràn máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìwà wọ̀nyẹn àti bóyá kí wọ́n kà á sí ẹni tí kò ní ìwà rere, kúrò lọ́kàn mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í súnra kì.”

“Mo Ń Fòyà Pé Bí A Kò Bá Ṣọ́ra . . .”

Ṣíṣètọ́jú olólùfẹ́ kan tí ń ṣàìsàn gan-an lè jẹ́ ìrírí tí ń dáyà foni. Olùṣètọ́jú náà lè bẹ̀rù nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ bí àìsàn náà ṣe ń burú sí i—bóyá kí ó tilẹ̀ bẹ̀rù pé olólùfẹ́ rẹ̀ yóò kú. Ó tún lè bẹ̀rù pé òun kò ní lókun tàbí pé òun kò lè tóótun láti pèsè àwọn ohun tí aláìsàn náà nílò.

Elsa ṣàpèjúwe ìdí tí ó fi ń bẹ̀rù lọ́nà yí pé: “Mo fòyà pé mo lè pa Betty lára, kí n sì tipa bẹ́ẹ̀ dá kún ìjìyà rẹ̀, tàbí pé n óò ṣe ohun kan tí ó lè gé ìwàláàyè rẹ̀ kúrú.”

Nígbà míràn, ìbẹ̀rù tí ó jẹ́ ti aláìsàn náà yóò di ti olùṣètọ́jú. Sue sọ láṣìírí pé: “Bàbá mi bẹ̀rù dídi ẹni tí nǹkan fún lọ́rùn pa, ìpáyà sì ń bá a lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Mo fòyà pé bí a kò bá ṣọ́ra, nǹkan yóò fún un lọ́rùn pa, ohun tí ó bẹ̀rù jù lọ yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí i.”

“Bí Ipò Wọn Ṣe Rí Sí Ti Tẹ́lẹ̀ Lè Bà Ọ́ Nínú Jẹ́”

Ìwé Caring for the Person With Dementia sọ pé: “Ìbànújẹ́ jẹ́ ohun tí ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ń ṣètọ́jú olólùfẹ́ kan tí ó ní àrùn bárakú. Bí àìsàn ẹni náà ṣe ń burú sí i, o lè pàdánù alájọṣepọ̀ kan àti ipò ìbátan kan tí ó ṣe pàtàkì sí ọ. Bí ipò wọn ṣe rí sí ti tẹ́lẹ̀ lè bà ọ́ nínú jẹ́.”

Jennifer ṣàpèjúwe bí ìlera ìyá rẹ̀ tí ń burú sí i láìdábọ̀ ṣe nípa lórí ìdílé rẹ̀ pé: “Ó dùn wá. A pàdánù ìjíròrò rẹ̀ tí ń dáni lára yá. Inú wa bà jẹ́ gan-an.” Gillian ṣàlàyé pé: “N kò fẹ́ kí ìyá mi kú, n kò sì fẹ́ kí ó jìyà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń sunkún.”

“Mo Nímọ̀lára Ìpatì, Ìbínú”

Olùṣètọ́jú kan lè ṣe kàyéfì pé: ‘Èé ṣe tí èyí fi ní láti ṣẹlẹ̀ sí mi? Kí ló dé tí àwọn ẹlòmíràn kò ṣèrànlọ́wọ́? Ṣe wọn kò rí i pé n kò lè kojú rẹ̀ dáradára ni? Aláìsàn náà kò ha lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ sí i bí?’ Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, inú lè bí olùṣètọ́jú náà gan-an nípa ohun tí ó jọ pé ó ń pọ̀ sí i àti àwọn ohun tí kò bọ́gbọ́n mu tí aláìsàn àti àwọn mìíràn lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé ń ní kí ó ṣe. Rose, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bínú sí ara mi—nínú èrò orí mi. Àmọ́, Mọ́mì sọ pé ó ń hàn ní ojú mi.”

Ẹni tí ń ṣètọ́jú náà lè gbé ìdààmú nípa àwọn ìjákulẹ̀ àti ìbínú aláìsàn náà sọ́kàn. Nínú ìwé náà, Living With Cancer, Dókítà Ernest Rosenbaum ṣàlàyé pé àwọn aláìsàn kan “lè máa nírìírí ìrunú àti ìsoríkọ́, tí yóò máa wá ẹni tí ó bá wà lárọ̀ọ́wọ́tó jù lọ láti fìkanra mọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan . . . Ìbínú yìí sábà máa ń fara hàn bí ìkanra nípa àwọn ọ̀ràn tí kò tó nǹkan, tí ó jẹ́ pé nígbà tí nǹkan bá wà déédéé, aláìsàn náà kò tilẹ̀ ní bìkítà nípa rẹ̀.” Ó yé ni pé, èyí lè dá kún ìrora gógó àwọn olólùfẹ́ tí inú ti ń bí tẹ́lẹ̀, tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti ṣètọ́jú aláìsàn náà.

Fún àpẹẹrẹ, Maria ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ fún oríyìn ní títọ́jú ọ̀rẹ́ kan tí ń kú lọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, inú tètè máa ń bí ọ̀rẹ́ rẹ̀ jù, ó sì máa ń fò fẹ̀rẹ̀ dórí àwọn ìpinnu tí kò tọ́. Maria ṣàlàyé pé: “Ó tètè máa ń pa ìmọ̀lára àwọn ènìyàn lára, kò sì lọ́wọ̀, ó sì ń mára ti àwọn olólùfẹ́.” Ipa wo ni èyí ní lórí Maria? “Lákòókò náà, ó jọ pé ẹnì kan ‘lóye’ aláìsàn náà. Àmọ́, bí mo bá rò ó wò lẹ́yìn náà, mo máa ń nímọ̀lára ìpatì, ìbínú, àìdánilójú—n kì í sì í ní ìtẹ̀sí láti fi ìfẹ́ tí ó nílò hàn.”

Ìwádìí kan tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé The Journals of Gerontology parí ọ̀rọ̀ pé: “Ìbínú lágbára láti lọ dé ìpele gíga nínú àwọn ipò ìṣètọ́jú [àti] lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń yọrí sí ìwà ipá gidi tàbí èyí tí a ń finú rò.” Àwọn olùṣèwádìí náà ṣàwárí pé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ 1 lára olùṣètọ́jú 5 ní ń bẹ̀rù pé òun lè di oníwà ipá. Ó sì lé ní 1 nínú 20 lára wọn tí ń hùwà ipá sí aláìsàn tí ó ń tọ́jú.

“Mo Nímọ̀lára Ẹ̀bi”

Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣètọ́jú ni ìmọ̀lára ẹ̀bi ń yọ lẹ́nu. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ̀bi náà máa ń tẹ̀ lé ìbínú—ìyẹn ni pé, wọ́n ń nímọ̀lára ẹ̀bi nítorí pé wọ́n máa ń bínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Irú èrò ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ lè gba gbogbo èrò ìmọ̀lára wọn tán débi tí wọn óò fi ronú pé àwọn kò lè máa bá ṣíṣètọ́jú náà lọ mọ́.

Nínú àwọn ipò kan, kò sí ohun mìíràn tí wọ́n lè ṣe àyàfi kí wọ́n gbé aláìsàn náà lọ fún ìtọ́jú ní ibi ìṣètọ́jú tàbí ilé ìwòsàn. Èyí lè jẹ́ ìpinnu kan tí ń dáni lóró, tí ó lè da èrò ìmọ̀lára olùṣètọ́jú kan láàmú gidigidi. Jeanne sọ pé: “Nígbẹ̀yìngbẹ́yín tí ó di ọ̀ràn-anyàn láti gbé Màmá lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó kan, mo nímọ̀lára pé mo ń dà á ni, pé mo ń ta á nù ni.”

Yálà aláìsàn náà wà nílé ìwòsàn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lè nímọ̀lára ẹ̀bi pé àwọn kò ṣe tó fún un. Elsa sọ pé: “Ó sábà máa ń dùn mí pé n kò ní àkókò tí ó pọ̀ tó. Nígbà míràn, ọ̀rẹ́ mi kò wulẹ̀ ní í jẹ́ kí n lọ.” Àníyàn tún lè wà nípa pípa àwọn ẹrù iṣẹ́ ìdílé mìíràn tì, ní pàtàkì bí olùṣètọ́jú náà bá ń lo àkókò púpọ̀ ní ilé ìwòsàn tàbí tí ó bá gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ fún wákàtí púpọ̀ láti lè san owó tí ń ga pelemọ. Ìyá kan dárò pé: “Mo ní láti ṣiṣẹ́ láti lè ṣèrànwọ́ nínú àwọn ìnáwó, síbẹ̀ mo nímọ̀lára ẹ̀bi nítorí pé n kò lè máa wà nílé láti mójú tó àwọn ọmọ mi.”

Ní kedere, àwọn olùṣètọ́jú nílò ìrànlọ́wọ́ gidigidi, ní pàtàkì lẹ́yìn ikú ẹni tí wọ́n ń tọ́jú. Dókítà Fredrick Sherman, láti Huntington, New York, sọ pé: “Ẹrù iṣẹ́ mi tí ó le koko jù lọ [lẹ́yìn ikú aláìsàn kan] . . . jẹ́ láti mú kí ìmọ̀lára ẹ̀bi tí àwọn olùṣètọ́jú ń ní dín kù, èyí tí wọn kì í sábà mẹ́nu kàn.”

Bí wọn kò bá mẹ́nu kan àwọn ìmọ̀lára yìí, wọ́n lè ṣèpalára fún olùṣètọ́jú àti aláìsàn náà. Nígbà náà, kí ni àwọn tí ń ṣètọ́jú lè ṣe láti lè kápá àwọn ìmọ̀lára yìí? Kí sì ni àwọn ẹlòmíràn—àwọn mẹ́ńbà ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́—lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí díẹ̀ lára àwọn orúkọ náà pa dà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Má Ṣe Fojú Yẹpẹrẹ Wò Wọ́n!

MYRNA I. LEWIS, igbákejì ọ̀jọ̀gbọ́n ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìṣègùn àdúgbò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn Mount Sinai, New York, sọ pé: “A mọ̀ pé àwọn obìnrin ní ń ṣe ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára ìtọ́jú tí a ń ṣe fún àwọn arúgbó nínú ilé.”

Ìwádìí kan tí a ṣe láàárín àwọn obìnrin tí ń ṣètọ́jú, tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé The Journals of Gerontology,b fi hàn pé ìpín 61 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn obìnrin náà ni wọ́n ròyìn pé yálà àwọn ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ kò ran àwọn lọ́wọ́. Àwọn tí iye wọn sì lé ní ìdajì (ìpín 57.6 nínú ọgọ́rùn-ún) sọ pé àwọn kò rí ìtìlẹ́yìn ní ti èrò ìmọ̀lára tí ó tó gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkọ àwọn. Nínú ìwé Children With Cancer, Jeanne Munn Bracken tọ́ka pé, bí ìyá ti ń gbé ẹrù èyí tí ó pọ̀ jù nínú ṣíṣètọ́jú náà, “bàbá lè máa fà sẹ́yìn, kí ó sì máa gbájú mọ́ iṣẹ́ rẹ̀.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Dókítà Lewis sọ pé, ìwọ̀n ìṣètọ́jú kan tí ó ṣe pàtàkì wà tí àwọn ọkùnrin máa ń bójú tó. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọkọ tí wọ́n ní àwọn aya alárùn Alzheimer pọ̀ díẹ̀. Ó sì dájú pé wọn kò ní àjẹsára lòdì sí másùnmáwo ti ṣíṣètọ́jú olólùfẹ́ kan tí ń ṣàìsàn. Lewis ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ó lè jẹ́ pé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni wọ́n lè tètè ní ìpalára jù lọ, nítorí pé wọ́n sábà máa ń dàgbà ju àwọn aya wọn lọ, àwọn alára sì lè ṣàìní ìlera pípé. . . . Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni a kò dá lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà ti ṣíṣètọ́jú ní ti gidi.”

Àwọn ìdílé ní láti ṣọ́ra fún ìtẹ̀sí láti dẹ́rù pa mẹ́ńbà ìdílé wọn kan tí ó jọ pé ó ń kojú ìpèníjà náà dáradára. Ìwé náà, Care for the Carer, sọ pé: “Lọ́pọ̀ ìgbà, mẹ́ńbà ìdílé kan ní pàtó ni ó wá máa ń di olùṣètọ́jú onírúurú àwọn olólùfẹ́. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló jẹ́ obìnrin tí àwọn fúnra wọn ti ń di àgbàlagbà. . . . A tún rí àwọn obìnrin gẹ́gẹ́ bí olùṣètọ́jú ‘lọ́nà àdánidá’ . . . , àmọ́ àwọn ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú èyí.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b A túmọ̀ gerontology sí “ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ọjọ́ ogbó àti ìṣòro àwọn arúgbó.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwọn olùṣètọ́jú nílò ìtìlẹ́yìn láti lè kojú ìmọ̀lára ẹ̀bi àti ìbínú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́