Bí A Ṣe Lè Kojú Ìmọ̀lára
ÌWỌ ha ń tọ́jú olólùfẹ́ kan tí ń ṣàìsàn gan-an lọ́wọ́lọ́wọ́ bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o lè ti máa nírìírí àwọn èrò ìmọ̀lára tí ń dà ọ́ lọ́kàn rú, tí ó sì ń kó jìnnìjìnnì bá ọ. Kí ni o lè ṣe? Ronú nípa àwọn ìmọ̀lára tí àwọn olùṣètọ́jú kan ń bá jà àti àwọn àbá wíwúlò tí ó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀.
Ìkótìjúbáni. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìwà ẹnì kan tí ń ṣàìsàn lè kótìjú bá ọ lójú àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́, ṣíṣàlàyé irú àìsàn tí ń ṣe olólùfẹ́ rẹ fún àwọn ọ̀rẹ́ àti aládùúgbò lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye, ó sì tún lè sún wọn láti fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” àti sùúrù hàn. (Pétérù Kíní 3:8) Bí ó bá ṣeé ṣe, bá àwọn ìdílé mìíràn tí wọ́n wà nínú irú ipò tí ó jọra pẹ̀lú tìrẹ sọ̀rọ̀. O lè nímọ̀lára bí ẹni tí a kò kótìjú bá bí ẹ ti ń ṣe pàṣípààrọ̀ ìrírí. Sue ṣàlàyé ohun tí ó ràn án lọ́wọ́ pé: “Àánú bàbá mi ṣe mí gan-an—ìyẹn kò jẹ́ kí ìmọ̀lára ìkótìjúbáni èyíkéyìí já mọ́ nǹkan kan. Ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani rẹ̀ tún ràn mí lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni, ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani—ní ìhà ọ̀dọ̀ aláìsàn àti àwọn tí ń ṣètọ́jú rẹ̀—jẹ́ ohun èèlò àgbàyanu tí ń mú ìtura bá iṣan tí ìdààmú ti pá lórí.—Fi wé Oníwàásù 3:4.
Ìbẹ̀rù. Àìmọ̀kan nípa àìsàn náà lè jẹ́ ohun akójìnnìjìnnì-báni gan-an. Bí ó bá ṣeé ṣe, wá àmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn amọṣẹ́dunjú lórí ohun tí ó yẹ kí o retí bí àìsàn náà ṣe ń le sí i. Kọ́ bí a ṣe ń ṣètọ́jú lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀. Ní ti Elsa, ọ̀kan lára àwọn kókó ṣíṣe pàtàkì jù lọ ní kíkojú àwọn ohun tí ń bà ọ́ lẹ́rù ni bíbá àwọn olùṣètọ́jú mìíràn àti àwọn nọ́ọ̀sì tí ń ṣiṣẹ́ ní ibùdó ìpèsè ìtọ́jú sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó yẹ kí o retí bí ipò aláìsàn náà ṣe ń burú sí i. Jeanny dámọ̀ràn pé: “Ko àwọn ohun tí ń bà ọ́ lẹ́rù lójú, kí o sì ṣàkóso wọn. Ìbẹ̀rù ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sábà máa ń burú ju ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní gidi lọ.” Dókítà Ernest Rosenbaum dámọ̀ràn pé, ohun yòó wù kí ó máa ṣokùnfà àwọn ìbẹ̀rù rẹ, ó yẹ kí o “máa sọ̀rọ̀ nípa” àwọn ohun tí ń bà ọ́ lẹ́rù “bí wọ́n bá ṣe ń yọjú.”—Fi wé Òwe 15:22.
Ìbànújẹ́. Kò rọrùn láti kojú ìbànújẹ́, ní pàtàkì nínú ipò ṣíṣètọ́jú. O lè banú jẹ́ lórí pípàdánù ìbákẹ́gbẹ́pọ̀, ní pàtàkì bí olólùfẹ́ rẹ tí ń ṣàìsàn kò bá lè sọ̀rọ̀, tí kò lè lóye dáradára, tàbí tí kò lè dá ọ mọ̀ mọ́. Àwọn ẹlòmíràn lè ṣàìlóye irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀. Bíbá ọ̀rẹ́ kan tí ó lóye, tí yóò fi sùúrù àti ìgbatẹnirò tẹ́tí sílẹ̀, sọ̀rọ̀ lè mú ìtura tí a nílò gan-an wá.—Òwe 17:17.
Ìbínú àti Ìjákulẹ̀. Wọ́n jẹ́ ìhùwàpadà tí ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ṣíṣètọ́jú ẹni tí ń ṣàìsàn gan-an, tí ìhùwà rẹ̀ lè ṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Fi wé Éfésù 4:26.) Mọ̀ pé àrùn náà ló sábà máa ń fa ìhùwà onírora ọkàn, kì í ṣe aláìsàn náà. Lucy rántí pé: “Nígbà tí inú bá ń bí mi gan-an, ẹkún ló máa ń gbẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà náà, n óò gbìyànjú láti rán ara mi létí nípa ipò aláìsàn náà àti àìsàn rẹ̀. Mo mọ̀ pé aláìsàn náà nílò ìrànlọ́wọ́ mi. Ìyẹn yóò ràn mí lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú.” Irú ìfòyemọ̀ bẹ́ẹ̀ lè ṣèrànwọ́ láti ‘mú ọ lọ́ra láti bínú.’—Òwe 14:29; 19:11.
Ẹ̀bi. Ìmọ̀lára ẹ̀bi wọ́pọ̀ láàárín àwọn olùṣètọ́jú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé iṣẹ́ pàtàkì kan, tí ó sì ṣòro gan-an ni o ń ṣe. Gba òkodoro òtítọ́ náà pé o kò ní máa fìgbà gbogbo hùwà pa dà lọ́nà pípé nínú ìsọ̀rọ̀ tàbí ìṣesí. Bíbélì rán wa létí pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2; Róòmù 3:23) Má ṣe jẹ́ kí ìmọ̀lára ẹ̀bi dí ọ lọ́wọ́ láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ títọ́ nísinsìnyí. Bí ohun kan tí o sọ tàbí tí o ṣe bá mú ọkàn rẹ gbọgbẹ́, o lè rí i pé sísọ pé “Máà bínú” yóò mú kí ara ìwọ àti ẹni tí o ń tọ́jú balẹ̀. Ọkùnrin kan tí ó tọ́jú ẹbí rẹ̀ kan tí ń ṣàìsàn dámọ̀ràn pé: “Sa gbogbo ipá rẹ lábẹ́ àwọn ipò náà.”
Ìsoríkọ́. Ìsoríkọ́ wọ́pọ̀ gan-an—ó sì ṣeé lóye—nínú àwọn ìdílé tí ń kojú àìsàn líle koko. (Fi wé Tẹsalóníkà Kíní 5:14.) Olùṣètọ́jú kan tí ń jìyà ìsoríkọ́ ṣàlàyé ohun tí ó ràn án lọ́wọ́ pé: “Àwọn púpọ̀ máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa fún ṣíṣètọ́jú wọn. Ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ ìṣírí díẹ̀ lè fún ọ níṣìírí láti máa bá a lọ nígbà tí ó bá rẹ̀ ọ́ gan-an tàbí tí o ní ìsoríkọ́.” Bíbélì sọ pé: “Ìbànújẹ́ ní àyà ènìyàn ní í dorí rẹ̀ kọ odò; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní í mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Àwọn mìíràn lè má fìgbà gbogbo ṣàkíyèsí pé o nílò ìṣírí. Nítorí náà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè kọ́kọ́ ní láti ṣàlàyé “ìbànújẹ́” tí ó wà ní àyà rẹ ní gbangba, kí o baà lè rí “ọ̀rọ̀ rere” tí ń ṣíni lórí gbọ́ láti ẹnu àwọn ẹlòmíràn. Bí ó ti wù kí ó rí, bí ìmọ̀lára ìsoríkọ́ bá ń bá a lọ láìdábọ̀ tàbí tí ó ń le koko sí i, ó lè bọ́gbọ́n mu láti lọ rí dókítà.
Àìlólùrànlọ́wọ́. O lè nímọ̀lára àìlólùrànlọ́wọ́ lójú àìsàn tí ń sọni di hẹ́gẹhẹ̀gẹ. Fara mọ́ òkodoro òtítọ́ nípa ipò tí o wà. Mọ àwọn ààlà rẹ ní àmọ̀dunjú—ìwọ kọ́ ni yóò ṣàkóso ìlera aláìsàn náà, àmọ́ o lè fún un ní ìtọ́jú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Má ṣe retí ìjẹ́pípé lọ́dọ̀ ara rẹ, ẹni tí o ń tọ́jú, tàbí àwọn tí ń ṣètìlẹ́yìn fún ọ. Kì í ṣe pé ìyọsíǹkan níwọ̀ntúnwọ̀nsì ń mú kí ìmọ̀lára àìlólùrànlọ́wọ́ rọlẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ó tún ń mú kí iṣẹ́ náà dín kù. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti ṣètọ́jú olólùfẹ́ kan dámọ̀ràn pé: Kọ́ láti kojú ọjọ́ kan lẹ́ẹ̀kan.—Mátíù 6:34.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
“Ko àwọn ohun tí ń bà ọ́ lẹ́rù lójú, kí o sì ṣàkóso wọn. Ìbẹ̀rù ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sábà máa ń burú ju ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní gidi lọ”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ọ̀rọ̀ Afúnni-Níṣìírí Láti Ẹnu Àwọn Olùṣètọ́jú
“MÁ ṢE jẹ́ kí àwọn èrò òdì nípa ara rẹ dààmú rẹ. Wọ́n kò burú lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, kò yẹ kí o bo ìmọ̀lára rẹ mọ́ra. Finú han ẹnì kan nípa bí ìmọ̀lára rẹ ṣe rí, bí o bá sì lè ṣe é, lọ fún ìsinmi—kúrò níbẹ̀ fún àkókò díẹ̀—kí ara baà lè tù ọ́.”—Lucy, tí iṣẹ́ rẹ̀ ní ilé ìwòsàn wé mọ́ ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn olùṣètọ́jú àti àwọn aláìsàn mélòó kan.
“Bí àwọn mẹ́ńbà ìdílé tàbí àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó, tí wọ́n sì ń fẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́ bá wà, jẹ́ kí wọ́n ṣèrànlọ́wọ́. Ó ṣe pàtàkì pé kí o ṣàjọpín ẹrù náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.”—Sue, tí ń tọ́jú bàbá rẹ̀, kí àrùn Hodgkin tóó pa bàbá náà.
“Kọ́ láti mú ànímọ́ ìdẹ́rìn-ínpani dàgbà.”—Maria, tí ó ṣèrànwọ́ láti ṣètọ́jú ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan tí àrùn jẹjẹrẹ pa.
“Jẹ́ olókun nípa tẹ̀mí. Fà sún mọ́ Jèhófà, sì máa gbàdúrà láìdábọ̀. (Tẹsalóníkà Kíní 5:17; Jákọ́bù 4:8) Ó ń pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, àti àwọn ìlérí rẹ̀. Gbìyànjú láti wà létòlétò bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. Fún àpẹẹrẹ, ṣíṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún àwọn oògùn àti àkọsílẹ̀ àwọn olùrànlọ́wọ́ máa ń ṣèrànwọ́.”—Hjalmar, tí ó tọ́jú ọkọ arábìnrin rẹ̀ kí ìyẹn tóó kú.
“Mọ gbogbo ohun tí o bá lè mọ̀ nípa irú àrùn tí ń ṣe ẹni tí o ń tọ́jú. Bí ó ti yẹ, ìyẹn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ ohun tí ó yẹ kí o retí pé kí agbàtọ́jú náà àti ìwọ fúnra rẹ máa ṣe àti bí o ṣe lè tọ́jú ẹni tí o ń tọ́jú.”—Joan, tí ọkọ rẹ̀ ní àrùn Alzheimer.
“Mọ̀ pé àwọn mìíràn ti kojú rẹ̀ ṣáájú rẹ, àti pé Jèhófà lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ohun yòó wù kí ó ṣẹlẹ̀.”—Jeanny, tí ó tọ́jú ọkọ rẹ̀ kí ìyẹn tóó kú.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Láti mú ìbẹ̀rù rẹ rọlẹ̀, wádìí ohun tí o bá lè wádìí nípa àìsàn náà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Bíbá ọ̀rẹ́ kan tí ó lóye sọ̀rọ̀ lè mú ìtura wá