Ṣíṣèrànwọ́ Fún Olùṣètọ́jú—Bí Àwọn Ẹlòmíràn Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
“ÈMI àti Lawrie ti ṣègbéyàwó fún ọdún 55—ìgbà tí ó ti pẹ́ gan-an—ẹ wo bí àwọn ọdún wọ̀nyẹn ti kún fún ayọ̀ tó! Bí ó bá jẹ́ pé ó ṣeé ṣe fún mi láti jẹ́ kí ó wà nílé ni, ǹ bá ti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ìlera mi bẹ̀rẹ̀ sí í jó rẹ̀yìn. Lópin rẹ̀, mo ní láti ṣètò fún un láti lọ máa gbé ní ibùdó ìpèsè ìtọ́jú. Ìrora èrò ìmọ̀lára ti sísọ èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ ti pọ̀ jù fún mi. Mo nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, mo sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an, mo sì máa ń lọ bẹ̀ ẹ́ wò bí mo ti lè ṣe tó. Ní ti ara ìyára, n kò lè ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.”—Anna, obìnrin ẹni ọdún 78 kan tí ó ti ń tọ́jú ọkọ rẹ̀, tí ó ní àrùn Alzheimer fún ohun tí ó lé ní ọdún 10, tí ó tún ti ń tọ́jú ọmọbìnrin wọn, tí ó ní àrùn Down’s syndrome, fún 40 ọdún sẹ́yìn.a
Ọ̀ràn Anna kò ṣàjèjì rárá. Ìwádìí kan tí a ṣe ní àwọn Erékùṣù Britain fi hàn pé “nínú ọ̀wọ́ àwọn ọjọ́ orí kan (láàárín 40 ọdún sí ọdún 59), ó tó obìnrin kan nínú àwọn méjì tí ó jẹ́ olùṣètọ́jú.” Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jíròrò níṣàájú, pákáǹleke èrò ìmọ̀lára àti àwọn ìṣòro tí àwọn olùṣètọ́jú ń dojú kọ lè dà bí èyí tí kò ṣeé fara dà nígbà míràn.
Dókítà Fredrick Sherman, ti Ẹgbẹ́ Àwọn Onímọ̀ Nípa Ọjọ́ Ogbó àti Ìṣòro Àwọn Arúgbó ní America, sọ pé: “Mo ronú pé ó kéré tán ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn olùṣètọ́jú ní ń sorí kọ́ ní ọdún àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ṣe ìtọ́jú.” Ní ti àwọn àgbàlagbà bí Anna, okun tiwọn fúnra wọn àti ìlera wọn tí ń jó rẹ̀yìn lè mú kí ipò náà túbọ̀ ṣòro púpọ̀ láti bójú tó lọ́nà tí ó ga.
Láti ran àwọn olùṣètọ́jú lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn, a ní láti mọ àwọn ohun tí wọ́n nílò. Kí ni àwọn ohun náà tí wọ́n nílò, báwo ni a sì ṣe lè hùwà pa dà sí wọn?
Àwọn Olùṣètọ́jú Ní Láti Sọ̀rọ̀
Obìnrin kan tí ó ṣèrànwọ́ láti ṣètọ́jú ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń kú lọ sọ pé: “Mo ní láti sọ ti inú mi jáde.” Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú, ó sábà máa ń rọrùn láti kojú àwọn ìṣòro, kí a sì kápá wọn nígbà tí a bá lè jíròrò wọn, pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan tí ó lóye. Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣètọ́jú tí wọ́n nímọ̀lára bí ẹni pé ipò tí wọ́n wà nínú rẹ̀ ká wọn mọ́ rí i pé sísọ̀rọ̀ nípa ipò tí wọ́n wà ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí ìmọ̀lára wọn ṣe kedere, ó sì ń mú ìtura kúrò nínú ìmọ̀lára pákáǹleke tí ó ti pelemọ wá fún wọn.
Jeanny rántí ìgbà tí ó ń ṣètọ́jú ọkọ rẹ̀ pé: “Mo mọrírì rẹ̀ nígbà tí àwọn ará mọ̀ pé àwa méjèèjì nílò ìtìlẹ́yìn àti àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí.” Ó ṣàlàyé pé àwọn tí ń ṣètọ́jú nílò ìṣírí àti, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, alábàárò. Hjalmar, tí ó ṣèrànwọ́ láti ṣètọ́jú ọkọ arábìnrin rẹ̀, gbà pé: “Mo nílò ẹnì kan tí yóò tẹ́tí sí àwọn ìbẹ̀rù àti ìṣòro mi, tí yóò sì lóye bí ìmọ̀lára mi ṣe rí.” Hjalmar fi kún un nípa ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan pé: “Ó dára gan-an pé mo bẹ̀ ẹ́ wò, kódà fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú péré. Ó tẹ́tí sí mi. Ó bìkítà gidigidi. Ara ń tù mí lẹ́yìn ìyẹn.”
Àwọn olùṣètọ́jú lè rí ìṣírí púpọ̀ jọjọ gbà láti ọ̀dọ̀ olùtẹ́tísílẹ̀ kan tí ó lóye. Bíbélì fi ọgbọ́n gbani nímọ̀ràn pé: “Yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ.” (Jákọ́bù 1:19) Ìròyìn kan tí ó wà nínú ìwé The Journals of Gerontology ṣí i payá pé, “wíwulẹ̀ mọ̀ pé a ní ìtìlẹ́yìn sábà máa ń tó láti pèsè ìfọkànbalẹ̀ tí ó ṣe kókó.”
Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àfikún sí ẹni tí ó fetí síni àti ìtìlẹ́yìn àti àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí, kí ni àwọn olùṣètọ́jú tún nílò?
Pípèsè Ìrànlọ́wọ́ Tí Ó Wúlò
Dókítà Ernest Rosenbaum sọ pé: “Aláìsàn àti ìdílé rẹ̀ ń jàǹfààní lọ́nàkọ́nà tí a bá lè gbà fi ìfẹ́ àti ìṣírí hàn.” Lákọ̀ọ́kọ́ ná, irú “ìfẹ́ àti ìṣírí” bẹ́ẹ̀ ni a lè fi hàn nígbà ìbẹ̀wò kan, nígbà tí a bá tẹ̀ wọ́n láago, tàbí nínú lẹ́tà kékeré kan (bóyá tí a fi òdòdó tàbí àwọn ẹ̀bùn míràn pẹ̀lú rẹ̀).
Sue rántí ìtìlẹ́yìn tí ìdílé rẹ̀ rí gbà nígbà tí àrùn Hodgkin ń pa bàbá rẹ̀ lọ pé: “Ó ń tuni nínú nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ wa bá bẹ̀ wá wò fún àkókò díẹ̀.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi bá mi dáhùn tẹlifóònù, ó bá gbogbo wa fọṣọ, ó sì lọ̀ wọ́n.”
Ìtìlẹ́yìn fún àwọn olùṣètọ́jú lè ní ìrànwọ́ pàtó, tí ó sì ṣe gúnmọ́ nínú, ó sì yẹ kí ó ní in. Elsa rántí pé: “Mo rí i bí ohun tí ń ṣèrànwọ́ nígbà tí àwọn ará bá ṣèrànlọ́wọ́ tí ó gbéṣẹ́. Wọn kì í wulẹ̀ sọ pé: ‘Bí ohun tí mo lè ṣe bá wà, jẹ́ kí n gbọ́.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń wí pé: ‘Mo ń lọ sọ́jà. Kí ni kí n rà bọ̀ fún ọ?’ ‘Ṣé kí n wá bá ọ ṣàtúnṣe ọgbà rẹ?’ ‘Mo lè wá jókòó ti aláìsàn náà, kí n sì kàwé fún un.’ Ohun mìíràn tí a tún rí i pé ó gbéṣẹ́ ni ṣíṣètò kí àwọn àlejò kọ ọ̀rọ̀ ìkíni sílẹ̀ sínú ìwé kan nígbà tí ó bá rẹ ọ̀rẹ́ mi tí ara rẹ̀ kò yá tàbí tí ó bá ń sùn. Ìyẹn fún gbogbo wa ní ìtẹ́lọ́rùn gidigidi.”
Àwọn ìrànlọ́wọ́ pàtó tí a lè ṣe lè ní èyíkéyìí lára ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú. Rose ṣàlàyé pé: “Mo mọrírì ríràn mí lọ́wọ́ láti tẹ́ bẹ́ẹ̀dì, bíbá aláìsàn náà kọ lẹ́tà, ṣíṣe àwọn tí wọ́n wá bẹ aláìsàn wò lálejò, lílọ gba oògùn tí wọ́n kọ, fífọ irun àti ṣíṣe é lọ́ṣọ̀ọ́, fífọ àwo.” Ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ lè ran olùṣètọ́jú náà lọ́wọ́ nípa pípààrọ̀ ara wọn ní gbígbọ́únjẹ fún un pẹ̀lú.
Níbi tí ó bá ti yẹ, ó tún lè gbéṣẹ́ láti ṣèrànwọ́ ní àwọn ọ̀nà pàtó kan nínú ìtọ́jú ṣíṣe. Fún àpẹẹrẹ, olùṣètọ́jú náà lè nílò ìrànlọ́wọ́ nínú fífún aláìsàn náà lóúnjẹ àti wíwẹ̀ fún un.
Àwọn mẹ́ńbà ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní àníyàn lè ṣe ìrànlọ́wọ́ tí ó gbéṣẹ́ nígbà tí àìsàn náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, àmọ́ bí àìsàn náà bá ń pẹ́ ńkọ́? Bí a bá kira bọ ìtòlẹ́sẹẹsẹ tiwa fúnra wa tí ó dí, a lè tètè gbójú fo ìkìmọ́lẹ̀ tí ń lọ lọ́wọ́—tí ó sì lè máa ga pelemọ sí i—tí olùṣètọ́jú náà dojú kọ, dá. Ẹ wo bí yóò ti bani nínú jẹ́ tó bí ìtìlẹ́yìn tí a nílò lójú méjèèjì bá bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù!
Bí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, ó lè bọ́gbọ́n mu fún olùṣètọ́jú náà láti pe ìpàdé ẹbí láti jíròrò nípa ṣíṣètọ́jú aláìsàn náà. Ó sábà máa ń ṣeé ṣe láti ṣàmúlò ìrànlọ́wọ́ àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí tí wọ́n ti fi ẹ̀mí ìmúratán láti ṣèrànwọ́ hàn. Ohun tí Sue àti ìdílé rẹ̀ ṣe nìyí. Ó sọ pé: “Nígbà tí àìní wà, a rántí àwọn tí wọ́n ti gbà láti ṣèrànwọ́, a sì tẹ̀ wọ́n láago. A ronú pé a lè béèrè pé kí wọ́n ṣèrànlọ́wọ́.”
Ẹ Jẹ́ Kí Wọ́n Sinmi
Ìwé náà, The 36-Hour Day, sọ pé: “Láìsí tàbítàbí, ó pọn dandan fún ìwọ [olùṣètọ́jú] àti fún [ẹni tí o ń tọ́jú]—pé kí ẹ ní àkókò láti máa ‘sinmi’ déédéé kúrò lẹ́nu ìṣètọ́jú ẹni tí àrùn bárakú ń ṣe náà látàárọ̀ ṣúlẹ̀. . . . Sísinmi kúrò lẹ́nu ṣíṣètọ́jú [aláìsàn] náà, jẹ́ ọ̀kan lára ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ tí o lè ṣe láti mú kí ó ṣeé ṣe fún ọ láti máa bá ṣíṣètọ́jú ẹnì kan lọ.” Ǹjẹ́ àwọn olùṣètọ́jú gbà?
Maria, tí ó ṣèrànwọ́ láti tọ́jú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan tí àrùn jẹjẹrẹ ń pa lọ, dáhùn pé: “Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo nílò ‘ìsinmi’ kí ẹlòmíràn sì máa ṣe ìtọ́jú náà fún ìgbà díẹ̀.” Joan, tí ó tọ́jú ọkọ rẹ̀ tí ó ní àrùn Alzheimer, ní ojú ìwòye kan náà. Ó sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tí a nílò jù lọ ni láti máa sinmi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.”
Bí ó ti wù kí ó rí, báwo ni wọ́n ṣe lè rí ìsinmi kúrò nínú ìkìmọ́lẹ̀ tí ń wá láti inú àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn? Jennifer, tí ó ṣèrànwọ́ láti tọ́jú àwọn òbí rẹ̀ arúgbó, sọ bí ó ṣe rí ìsinmi pé: “Ọ̀rẹ́ ìdílé wa kan máa ń wá gbé màmá lọ tọ́jú fún ọjọ́ kan kí a lè sinmi díẹ̀.”
Ìwọ lè jẹ́ kí olùṣètọ́jú náà sinmi nípa yíyọ̀ọ̀da ara rẹ láti gbé aláìsàn náà jáde lọ fún ìgbà díẹ̀, bí ó bá bọ́gbọ́n mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Joan sọ pé: “Ó máa ń mára tù mí nígbà tí ẹnì kan bá wá gbé ọkọ mi jáde kí n lè ní àyè fún ara mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.” Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, o lè lo àkókò pẹ̀lú aláìsàn náà ní ilé rẹ̀. Èyíkéyìí tí ó wù kí ó jẹ́, jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún ẹni tí ń ṣètọ́jú náà láti ní ìsinmi tí ó nílò gan-an.
Bí ó ti wù kí ó rí, fi sọ́kàn pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn fún àwọn olùṣètọ́jú láti fún ara wọn ní ìsinmi. Wọ́n lè nímọ̀lára ẹ̀bi nípa ṣíṣàìsí lọ́dọ̀ olólùfẹ́ wọn. Hjalmar jẹ́wọ́ pé: “Kò rọrùn láti ṣíwọ́ nínú ipò náà fún ìgbà díẹ̀, kí o sì kó wọnú eré ìtura tàbí ìsinmi. Mo nímọ̀lára pé mo ń fẹ́ láti máa wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” Àmọ́, ó rí ìbàlẹ̀ ọkàn tí ó pọ̀ jù lọ nípa lílọ sinmi lákòókò tí ọkọ arábìnrin rẹ̀ kò nílò àfiyèsí púpọ̀. Àwọn mìíràn ti ṣètò láti jẹ́ kí a bójú tó olólùfẹ́ wọn ní ibi ìtọ́jú àgbàlagbà lójoojúmọ́ fún wákàtí bíi mélòó kan.
Òpin Gbogbo Àìsàn
Ó dájú pé, ṣíṣètọ́jú olólùfẹ́ kan tí ń ṣàìsàn gan-an jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ńlá. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ṣíṣètọ́jú olólùfẹ́ kan lè jẹ́ ohun àṣeyọrí àti ìtẹ́lọ́rùn gan-an. Àwọn olùṣèwádìí àti àwọn olùṣètọ́jú tọ́ka sí ipò ìbátan tí a fún lókun pẹ̀lú ìdílé àti àwọn ọ̀rẹ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olùṣètọ́jú ń kọ́ àwọn ànímọ́ àti agbára ìṣe tuntun. Ọ̀pọ̀ ní ń jàǹfààní tẹ̀mí bákan náà.
Ní pàtàkì jù lọ, Bíbélì tọ́ka sí i pé Jèhófà àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jésù Kristi, ni olùṣètọ́jú lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ jù lọ. Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mú un dá wa lójú pé òpin gbogbo àìsàn, ìjìyà, àti ikú ti sún mọ́lé. Láìpẹ́, Ẹlẹ́dàá ènìyàn, tí ó jẹ́ olùṣètọ́jú tí ó bìkítà, yóò san ẹ̀san ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun tí ó kún fún ìlera pípé, fún àwọn olódodo olùgbé ilẹ̀ ayé—nínú èyí tí “àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.”—Aísáyà 33:24; Ìṣípayá 21:4.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Díẹ̀ lára àwọn orúkọ tí a lò nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ní a ti yí pa dà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]
Ire aláìsàn náà sinmi lórí ire tìrẹ ní tààràtà
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Ìtìlẹ́yìn àwọn ọ̀rẹ́ rere yóò ṣe púpọ̀ láti jẹ́ kí o lè máa bá a lọ ní àwọn àkókò tí ó nira jù lọ
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]
Ṣíṣètọ́jú Lè Lérè Nínú
‘ÈRÈ kẹ̀?’ ni àwọn kan lè béèrè. ‘Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?’ Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí ohun tí àwọn olùṣètọ́jú tí ó tẹ̀ lé e yìí wí fún Jí!:
“Pípa àwọn ìlépa àti ìfẹ́ ọkàn ara ẹni tì kò túmọ̀ sí àìláyọ̀. ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírí gbà lọ.’ (Ìṣe 20:35) O lè ní ìtẹ́lọ́rùn púpọ̀ nínú ṣíṣètọ́jú ẹnì kan tí o nífẹ̀ẹ́.”—Joan.
“Mo kún fún ọpẹ́ pé mo lè ran arábìnrin mi àti ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ ní àkókò tí wọ́n nílò rẹ̀ gan-an—láìsí pé wọ́n lè san án pa dà fún mi. Ó túbọ̀ mú wa sún mọ́ra sí i. Mo nírètí pé lọ́jọ́ kan, n óò lè lo ìrírí tí mo jèrè láti ran ẹlòmíràn tí ó bá wà nínú ipò tí ó jọ ìyẹn lọ́wọ́.”—Hjalmar.
“Gẹ́gẹ́ bí mo ti máa ń sọ lọ́pọ̀ ìgbà fún ọ̀rẹ́ mi Betty, tí ara rẹ̀ kò yá, mo jèrè gan-an ju ohun tí mo fún un lọ. Mo kẹ́kọ̀ọ́ ìfọ̀rànrora-ẹni-wò àti sùúrù. Mo kọ́ pé ó ṣeé ṣe láti máa ní ẹ̀mí ìrònú wíwà déédéé nìṣó lábẹ́ àwọn àyíká ipò tí ó ṣòro jù lọ.”—Elsa.
“Mo túbọ̀ lókun sí i. Mo wá mọ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sí i, ohun tí ó jẹ́ láti máa gbára lé Jèhófà Ọlọ́run lójoojúmọ́, kí n sì jẹ́ kí ó máa kúnjú àwọn àìní mi.”—Jeanny.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Nígbà Tí O Bá Ń Bẹ Olùṣètọ́jú Kan Wò
• Fi ìgbatẹnirò tẹ́tí sílẹ̀
• Gbóríyìn fún un látọkànwá
• Ṣe ìrànlọ́wọ́ pàtó fún un
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ṣètìlẹ́yìn fún àwọn olùṣètọ́jú nípa lílọ bá wọn rajà àti gbígbọ́únjẹ fún wọn, tàbí nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti tọ́jú aláìsàn náà