Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìbunijẹ Ejò Gẹ́gẹ́ bí amọṣẹ́dunjú onímọ̀ nípa ẹ̀dá afàyàfà àti jomijòkè, mo ń bójú tó àwọn ejò, mo sì ń gba oró lẹ́nu wọn. Gbogbo àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Láti Wo Ṣèbé?” (March 22, 1996), “Habu—Àkòtagìrì Ejò” (July 8, 1996), àti “Ewu! Olóró Ni Mí” (August 22, 1996) fi èrò títọ̀nà hàn nípa ìṣẹ̀dá Jèhófà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, n óò fẹ́ láti sọ pé, a kò dámọ̀ràn dídi ibi tí ejò ti buni jẹ. Ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn ni kò lè ṣe é bí ó ti yẹ, àwọn kan sì ti pàdánù ẹsẹ̀ wọn ní àbájáde rẹ̀. Mo gbẹnu sọ gidigidi fún fífi báńdéèjì tí ń fún nǹkan pinpin wé odindi ẹsẹ̀ náà gan-an kí ó lè tò, bí a ṣe fi ń wé kókósẹ̀ tàbí ọrùn ọwọ́ tí a fi ṣẹ́. Níwọ̀n bí oró náà ti wà ní sàkáání ẹsẹ̀ tí ejò bù jẹ náà, ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ tí ń wá kì í yí pa dà, tí èyí sì ń mú kí ẹsẹ̀ náà “máà kú.”
P. R., England
Àwọn ìwé ìmọ̀ ìṣègùn bíi mélòó kan tí ó dé lẹ́nu àìpẹ́ yìí gbà pẹ̀lú kókó yìí, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ òǹkàwé wa fún àlàyé yìí.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ẹyẹ Ìwò Ara mi kò yá nígbà tí àpilẹ̀kọ náà, “Ẹyẹ Ìwò—Kí Ló Mú Un Yàtọ̀?” jáde. (January 8, 1997) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ohun tí ì bá mú mi láyọ̀. Àmọ́, ọgbọ́n féfé tí ẹyẹ ìwò ní pa mí lẹ́rìn-ín. Lẹ́yìn náà, mo kọ ohun kan nípa àwọn ẹyẹ láti lò ní ilé ẹ̀kọ́, mo sì lo àwọn ìsọfúnni tí ó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ inú Jí! Mo gba máàkì tó pọ̀ nínú rẹ̀!
J. B., Slovakia
Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́ Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ìrànwọ́ fún Àwọn Ọmọ Tí Wọ́n Ní Ìṣòro Àìlèkẹ́kọ̀ọ́.” (February 22, 1997) Mo dá ilé ẹ̀kọ́ àdáni kan sílẹ̀, mo sì ti ṣe àwọn ẹ̀dà rẹ̀ fún àwọn olùkọ́ tí ń ṣiṣẹ́ fún mi. Mo tún ti gbé àwọn lẹ́tà ìròyìn karí àwọn ìsọfúnni inú ìwé ìròyìn yín. Ẹ ṣeun fún ọ̀nà wíwàdéédéé tí ẹ gbà jíròrò àwọn kókó ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.
E. G., Honduras
Èmi ni olùdarí àgbà fún ilé iṣẹ́ títóbi jù lọ ti orílẹ̀-èdè, tí kì í ṣe fún òwò èrè jíjẹ, tí ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ọmọdé àti àgbàlagbà tí wọ́n ní àrùn ADD. A ní láti gbóríyìn fún yín nípa àpilẹ̀kọ tí ó kún fún ìrònú náà lórí Àrùn Araàbalẹ̀ Tí Ń Fa Àìlèpọkànpọ̀ (ADHD) àti Àrùn Àìlèpọkànpọ̀ (ADD). Àwọn àrùn wọ̀nyí jẹ́ èyí tí kì í jẹ́ kí a kún ojú ìwọ̀n, tí a sì sábà máa ń ṣì lóye. A mọrírì sísọ tí ẹ sọ pé ọ̀nà dídá àrùn mọ̀ àti ìtọ́jú títọ́ kan ti ń ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n wá ìrànlọ́wọ́. Ìtẹnumọ́ tí ẹ ṣe lórí ìfẹ́ àti òye láti ọ̀dọ̀ òbí tún gbé ìsọfúnni pàtàkì kan jáde.
L. R., United States
Mo ní ọmọkùnrin kan tí ó ní àrùn ADHD, ó sì ti ṣòro gan-an fún mi láti gba òkodoro òtítọ́ náà pé kì í wulẹ̀ ṣe pé ó jẹ́ oníjàngbọ̀n ọmọ. Àwọn ènìyàn ti sọ ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé, bíi, “Wọn kò ṣe ń bá a wí?” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí máa ń dùn mí gan-an nítorí pé mo ti lo ọ̀pọ̀ àkókò ní gbígbìyànjú láti bá a wí. Mo lérò pé àlàyé tí ẹ ṣe nípa àrùn yí yóò ràn àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé ìṣòro kan wà ní gidi àti pé àwọn ẹlòmíràn lè túbọ̀ fúnni ní ìṣírí.
M. T., United States
Ẹ wulẹ̀ lè wòye bí àwa, gẹ́gẹ́ bí òbí ọmọ tí ó ní ìṣòro àìlèkẹ́kọ̀ọ́, ṣe gbádùn ẹ̀dà yí ni. Ní pàtàkì, a mọrírì bí ẹ ṣe mẹ́nu kan ọ̀nà tí èyí gbà kan àwọn òbí àti pé a ní ẹrù ìnira tí ó pọ̀ tó láti gbé láìjẹ́ pé a ní láti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé tí àwọn ẹlòmíràn ń sọ.
J. C. àti B. C., Kánádà
Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Ẹ ṣeun gan-an fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?” (February 22, 1997) Ó ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Nísinsìnyí, mo ní ìtẹ́lọ́rùn, nítorí pé mo ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé Jèhófà jẹ́ ọ̀rẹ́ mi! Ojú mi wà lọ́nà fún àpilẹ̀kọ tí ó sọ nípa bí mo ṣe lè mú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yìí máa wà nìṣó.a
T. E., Ítálì
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí!, May 22, 1997.