Wíwo Ayé
Àwọn Àṣìlóye Líléwu
Ìwé agbéròyìnjáde The European sọ pé, ní 1977, àṣìlóye kan tí ó jẹ mọ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ṣákálá kan wà lára ohun tó fa ìjábá ọkọ̀ òfuurufú tí ó burú jù lọ lágbàáyé. Awakọ̀ òfuurufú 747 náà, tí ó jẹ́ ọmọ Dutch, fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lórí rédíò alátagbà pé òun “wà ní ojú ibi àtigbéra,” tí olùdarí ọkọ̀ òfuurufú ní Tenerife, Canary Islands, lóye sí pé ojú kan ni ọkọ̀ òfuurufú náà wà. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí awakọ̀ òfuurufú náà ní lọ́kàn ni pé ọkọ̀ òfuurufú òun ń sáré lọ lójú ibi ìgbéra tí ìkùukùu bò, ó sì ti fẹ́ gbéra. Ní àbáyọrí rẹ̀, ọkọ̀ òfuurufú náà forí sọ ọkọ̀ òfuurufú 747 míràn, ó sì pa ènìyàn 583. Bákan náà, òye èdè ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ tí kò kún tó jẹ́ ọ̀kan lára okùnfà ìforígbárí tó ṣẹlẹ̀ ní agbedeméjì òfuurufú ní 1996 nítòsí Delhi, Íńdíà, nínú èyí tí àwọn ènìyàn 349 ti kú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àṣìṣe tí ó burú jáì kò wọ́pọ̀ àti pé àwọn agbo òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó múná nínú ojúlówó Gẹ̀ẹ́sì tí a ń lò ní ẹ̀ka iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú, àwọn èdè àkànṣe tí a ń lò ní ẹ̀ka iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú nìkan ni àwọn agbo òṣìṣẹ́ kan mọ̀. Nígbà tí ọ̀ràn ìṣòro kan bá ṣẹlẹ̀, òye èdè tí wọ́n ní lè fò lọ lórí wọn. Àwọn ògbógi dámọ̀ràn ṣíṣàfikún ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà sí àyè àwọn agbo òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú láti mú ìfìsọfúnni-ránṣẹ́ tí ó tọ́ dájú ní ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú.
Ilé Gogoro Pisa Tí Ó Dẹ̀gbẹ́ Ti Nàró Kẹ̀?
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí Ilé Gogoro Pisa ti dẹ̀gbẹ́ lọ́nà tí ó fi jọ pé yóò wó lulẹ̀, ó ti wá hàn gbangba pé Ilé Gogoro Pisa tí ó dẹ̀gbẹ́ náà ti wá nàró—ọpẹ́lọpẹ́ àwọn òjé rírọ oníwọ̀n mílíọ̀nù kan kìlógíráàmù tí ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀ tí ó sún un sípò. Ọ̀jọ̀gbọ́n Michele Jamialcowsky, ààrẹ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe àgbáyé tí ń rí sí ààbò ilé gogoro náà ló kéde èyí. Ìwé agbéròyìnjáde La Stampa ti Ítálì sọ pé: “Síbẹ̀síbẹ̀, ìṣòro gidi ṣì ni ọ̀ràn ti fífìdímúlẹ̀ jẹ́ níwọ̀n bí ìtẹ̀sẹ́gbẹ̀ẹ́ onímítà márùn-ún [ẹsẹ̀ bàtà 16] tí ó ti lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọdún náà ti dé òtéńté tí ó ṣe kókó gan-an.”
Lílò Oògùn Líle Tí Kò Bófin Mu Jákèjádò Ayé
Ìròyìn àjọ UN kan sọ pé, àwọn oògùn líle tí kò bófin mu ló dúró fún ìpín 8 nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo òwò àgbáyé, ó sì ń mú èrè wá tí ó tó 400 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún. Ìròyìn olójú ìwé 332 náà ni ìwádìí àkọ́kọ́ tí a ṣe lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ lórí ipa tí oògùn líle tí kò bófin mu ń ní jákèjádò ayé. Ó fi hàn pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 2.5 nínú ọgọ́rùn-ún lára iye gbogbo olùgbé ayé—nǹkan bí 140 mílíọ̀nù ènìyàn—tí ń mu marijuana tàbí àwọn ohun tí a fi ṣe. Ọgbọ̀n mílíọ̀nù ènìyàn ní ń lo àwọn èròjà arùmọ̀lára-sókè tí ó jẹ́ oríṣi amphetamine, mílíọ̀nù 13 ń lo àwọn oríṣi kokéènì, mílíọ̀nù 8 sì ń lo oògùn líle heroin. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀ka agbófinró ti gbẹ́sẹ̀ lé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ kìlógíráàmù marijuana, kokéènì, oògùn líle heroin, àti oògùn aleṣan morphine, èyí tí a kò rí tú fó pọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìròyìn náà sọ pé, a ń mú nǹkan bí ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ń gbé kokéènì àti kìkì ìpín 10 sí ìpín 15 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ń gbé oògùn líle heroin. Òwò oògùn líle jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè díjú pọ̀ gan-an. Giorgio Giacomelli, olùdarí àgbà ètò ìgbógunti oògùn líle ti àjọ UN, sọ pé: “Ìṣòro náà ti gbilẹ̀ kárí ayé débi pé orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan kò lè dá yanjú rẹ̀.”
Àwọn Àrùn Àkóràn Ń Pọ̀ Sí I
Ìwé agbéròyìnjáde Nassauische Neue Presse sọ pé: “Láàárín 20 ọdún tó kọjá, àwọn àrùn alákòóràn lílekoko, tí wọ́n jẹ́ tuntun pátápátá, tí iye wọn jẹ́ 30 ti yọjú.” Fún ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn àrùn wọ̀nyí—bí àrùn Ebola, àrùn AIDS, àti àrùn mẹ́dọ̀wú ìpele C—kò sí ìwòsàn. Síwájú sí i, àwọn àrùn àkóràn bí ibà, kọ́lẹ́rà, àti ikọ́ ẹ̀gbẹ pẹ̀lú ń pọ̀ sí i. Èé ṣe? Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) ti sọ, “àìsàn púpọ̀ tún ti ń pa dà wá nítorí pé púpọ̀ púpọ̀ sí i àwọn fáírọ́ọ̀sì ni onírúurú àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn kò ràn mọ́. Ìwọ̀nba àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn tuntun ni a ń ṣe jáde nítorí pé ìlànà ìṣejáde wọn gbówó lórí gan-an.” Nínú ìsapá láti yí ìtẹ̀sí yìí pa dà, àjọ WHO ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba àti àwọn ilé iṣẹ́ apoògùn láti “kó owó púpọ̀ sí i sórí ṣíṣe àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn tuntun, kí wọ́n sì mú àwọn ìlànà ṣíṣàwárí àwọn àkóràn àrùn sunwọ̀n sí i.” Iye ènìyàn tí àkóràn àrùn pa lágbàáyé ní 1996 fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù 55.
“Ìlànà Ìkọluni”
Lábẹ́ àkọlé yìí, Haim Shapiro, ọ̀kan lára àwọn olóòtú ìwé agbéròyìnjáde The Jerusalem Post, ròyìn nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ ní oṣù March tó kọjá nínú èyí tí àwọn ènìyàn ti sọ òkúta àti bíríkì lu Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n fọ́ gbọ̀ngàn wọn, wọ́n sì bà á jẹ́, wọ́n sì sun àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn. Ó sọ pé: “Nígbà tí àwọn ènìyàn lọ kógun ti Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan ní Jaffa lọ́dún tó kọjá, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀—àti lọ́nà ẹ̀tọ́—onírúurú ìfẹ̀hónúhàn ló ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì àti nílẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí àwọn ènìyàn lọ ba gbọ̀ngàn tí ó wà ní Lod náà jẹ́, a kò fi bẹ́ẹ̀ rí ohunkóhun gbọ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Shapiro fúnra rẹ̀ ‘kò fẹ́ràn wọn, kò sì gba’ ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó rántí pé wọ́n “jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àwùjọ tí a ṣe inúnibíni sí, tí a sì kó lọ sí àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní àgọ́ Nazi ti Germany.” Ó kọ̀wé pé: “Láti finú wòye pé ẹnikẹ́ni lè kọ lu irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kí ó ba ibi ìjọsìn wọn jẹ́, kí ó sì sun àwọn ìwé wọn láìsí pé a fìyà jẹ ẹni náà, ń dẹ́rù bani gan-an, ó sì ń múni rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ jíjọra tí kò bójú mu nínú ìtàn.”
Ìfọkànsìn Tí Ń Dín Kù ní “Ìlú Ńlá Mímọ́” Kan
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pè é ní ìlú ńlá mímọ́ tí ó sì jẹ́ pé olórí Ìjọ Kátólíìkì ni bíṣọ́ọ̀bù rẹ̀, Róòmù kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́mìí ìsìn tó bí àwọn kan ti lè rò. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí Yunifásítì Third ti Róòmù ṣe jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ti fi hàn, nǹkan bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ará Ítálì sọ pé àwọn kò nífẹ̀ẹ́ nínú ìsìn Kristẹni “páàpáà,” àmọ́ ní Róòmù, iye yìí lọ sókè sí ìpín 19 nínú ọgọ́rùn-ún. Ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica sọ pé, ìpín 21 nínú ọgọ́rùn-ún mìíràn lára àwọn ará Róòmù ní ìfẹ́ ọkàn “tí kò tó nǹkan” nínú Ìjọ Kátólíìkì. Yàtọ̀ sí ìyẹn, kìkì ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára wọn ló lọ́kàn ìfẹ́ gan-an nínú ìsìn. Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá náà, Roberto Cipriani, ti sọ, kìkì ẹnì kan lára àwọn 4 ní Róòmù ló ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ṣọ́ọ̀ṣì náà tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí ìrònú àti ìhùwàsí dáradára.
Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Bẹ́ Sílẹ̀ ní Íńdíà
Láìka àwọn ìsapá takuntakun tí a ṣe láti mú bakitéríà tí ń fa ikọ́ ẹ̀gbẹ (TB) wá sábẹ́ àkóso sí, Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) sọ pé, àgbàlagbà kan nínú àwọn 2 ní Íńdíà ló ní in. Ìwé agbéròyìnjáde The Asian Age sọ pé, lára àwọn ará Íńdíà tí iye wọn lé ní 900 mílíọ̀nù, ó lé ní mílíọ̀nù 2 tó ń ní irú ikọ́ ẹ̀gbẹ kólekóle lọ́dọọdún, ó sì ń pa tó 500,000. Gẹ́gẹ́ bí àjọ WHO ti sọ, iye àwọn tí àrùn náà ti ràn àti ewu tí ń tìdí ríranni rẹ̀ wá pọ̀ lápọ̀jù. Kì í ṣe pé àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ràn ń dojú kọ ìṣòro ti kíkojú àrùn tí ó ń ṣokùnfà nìkan ni; wọ́n tún ní láti máa mú ìtìjú tí ó sábà máa ń so mọ́ àrùn náà mọ́ra. Èyí lè mú kí àwọn aládùúgbò, àwọn agbanisíṣẹ́, àti àwọn alájọṣiṣẹ́ ta wọ́n nù. Àwọn ìyàwó kéékèèké tí a rí i pé wọ́n ní ikọ́ ẹ̀gbẹ ni a sábà máa ń dá pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn bí ẹni tí kò tóótun láti bímọ.
Eku Tó Dára Kẹ̀?
Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn eku ni a kì í sọ ohun dáadáa nípa wọn. Wọn kì í dúró tini nígbà ìṣòro, wọ́n jẹ́ olùgbé inú galagálá tí a dà jọ—ajẹlójú-onílé pàápàá ni wọ́n.” Kò rí bẹ́ẹ̀ ní ti Rattie, eku kan tí ó wà nínú ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó jẹ́ ti onímọ̀ nípa ohun àfojúrí òun ohun alààyè náà, Judy Reavis. Rattie ti ṣèrànwọ́ láti so ọgọ́rọ̀ọ̀rún mítà wáyà kọ̀ǹpútà pọ̀ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ kí a baà lè gbé ìsokọ́ra kọ̀ǹpútà kalẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde Journal náà ṣàlàyé pé: “Pẹ̀lú okùn tí ó fi eyín gbá mú ṣinṣin, Ratie yóò rún ara mọ́ àárín àwọn òpó àti ihò inú ògiri, lábẹ́ ilẹ̀ àti igi àjà. Àwọn ìró ìgbáǹkanpẹ́pẹ́ àti àwo oúnjẹ aládùn kan máa ń tàn án lọ sí ọ̀nà àbájáde kan. Tí ó bá jáde síta, okùn tí ó fà náà ni a óò fi fa wáyà kọ̀ǹpútà jáde gba ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ rẹ̀.” Rattie ti wà dà bíi gbajúgbajà kan, ó sì ní àyè kan àti orin “láti ọwọ́” rẹ̀ lórí ìsokọ́ra alátagbà Internet. Ọ̀mọ̀wé Reavis sọ pé, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ó kú láìtọ́jọ́, “a óò kọ́ òmíràn. Ó ṣe tán eku lásán ni.”
Àwọn Ọ̀dọ́bìnrin Tí A Dá Abẹ́ fún, Ìbímọ Àwọn Ọ̀dọ́langba
Ìwé The Progress of Nations, ìtẹ̀jáde tí Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé ṣe jáde, tí ó dá lórí ìlera, ìjẹunrekánú, àti ẹ̀kọ́ àwọn ọmọdé, ẹ̀dà ti 1996, sọ pé: “Ó tó mílíọ̀nù 2 ọ̀dọ́bìnrin tí a ń dá abẹ́ fún lọ́dọọdún. Íjíbítì, Etiópíà, Kẹ́ńyà, Nàìjíríà, Somalia, àti Sudan ni a ti ń rí ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ní Djibouti àti Somalia, ìpín 98 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọbìnrin ni wọ́n ń dá abẹ́ fún.” Yàtọ̀ sí ìrora ibẹ̀, bí wọ́n ṣe ń ṣe é lè fa àrùn, àìtètèdáwọ́-dúró ẹ̀jẹ̀, àìlèbímọ, àti ikú. Ìròyìn náà sọ pé: “Kò sí ìsìn kankan tí ó béèrè fún dídá abẹ́. Ó jẹ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí a pète láti dáàbò bo ipò wúńdíá, láti mú un dájú pé a jẹ́ ẹni tí a lè gbé níyàwó, àti láti ṣèdíwọ́ fún àṣà ìbálòpọ̀.” Àwọn àwùjọ ènìyàn àti ètò àjọ tí ń rí sí ọ̀ràn ẹ̀tọ́ obìnrin àti ire ọmọdé ń da àwọn ìjọba láàmú láti fòfin de àṣà náà.
Ìròyìn kejì fi hàn pé ìbímọ àwọn ọ̀dọ́langba jẹ́ ìṣòro tí kò dáwọ́ dúró ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Fún àpẹẹrẹ, United States ní ó ti pọ̀ jù lọ lára àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ńláńlá lágbàáyé: 1,000 ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 15 sí 19 ń bímọ 64 lọ́dọọdún. Japan ló ní ìwọ̀n kíkéré jù lọ tí ó jẹ́ bíbímọ mẹ́rin lọ́dún. Kì í ṣe pé ìbímọ àwọn ọ̀dọ́langba ń nípa lórí ìdàgbàsókè, ẹ̀kọ́, àti àwọn àǹfààní ìtẹ̀síwájú ọ̀dọ́bìnrin kan nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún lè fa ìṣòro fún ìkókó náà, irú bí àìrítọ̀ọ́jú-tó, ipò àìní, àti ipò ìdílé tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀.