Ọ̀nà Tuntun Tí A Ń Gbà Bá Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Jà
IKỌ́ Ẹ̀GBẸ (TB) ni àrùn tó tíì pẹ́ jù lọ tó ń gbẹ̀mí ènìyàn, ó ṣì jẹ́ àrùn tó léwu gan-an débi pé Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) fi í wé bọ́ǹbù tí a kẹ́. Ìròyìn àjọ WHO kan nípa ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “A kò ní àkókò tó pọ̀ tó.” Bí ìran ènìyàn bá kùnà láti paná bọ́ǹbù yìí, lọ́jọ́ kan ó lè di àrùn tí kò gbóògùn mọ́, “tó ń ràn ká inú afẹ́fẹ́, tó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ má ṣeé wò sàn bí àrùn AIDS.” Àjọ WHO sọ pé, ó ti tó àkókò láti mọ bí ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣe lè ṣèbàjẹ́ tó. “Olúkúlùkù ẹni tó ń mí afẹ́fẹ́ sínú jákèjádò ayé . . . , ní láti dààmú nípa ewu yìí.”
Ṣé àsọdùn ni ọ̀rọ̀ yìí ni? Rárá o. Ṣáà ronú nípa bí gbogbo aráyé yóò ṣe wà lójúfò tó bí àrùn kan bá ń fi ojú àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè kan rí màbo, tí ó sì fẹ́ pa gbogbo olùgbé orílẹ̀-èdè tó tóbi tó Kánádà run láàárín ọdún mẹ́wàá! Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí dà bí ìtàn àròsọ, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ gan-an ni. Jákèjádò ayé, àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń pa ju àwọn tí àrùn AIDS, ibà, àti àpapọ̀ àwọn àrùn ilẹ̀ olóoru ń pa lọ: ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ènìyàn lójoojúmọ́. Nǹkan bí ogún mílíọ̀nù ènìyàn ni ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe ní báyìí, ó sì lè pa nǹkan bí ọgbọ̀n mílíọ̀nù ènìyàn lọ́dún mẹ́wàá sí i—iye náà ju iye gbogbo olùgbé Kánádà lọ.—Wo àpótí náà, “Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Ń Dalẹ̀ Rú Jákèjádò Ayé,” lójú ìwé 24.
Ìròyìn Rere Wọlé Dé
Bí ó ti wù kí ó rí, ìrètí ti wà báyìí. Lẹ́yìn tí àwọn olùwádìí ti fi ọdún mẹ́wàá ṣàyẹ̀wò, wọ́n rí ìlànà kan tó lè dí ikọ́ ẹ̀gbẹ lọ́wọ́ kó má bàa di gbẹ̀mígbẹ̀mí tí apá ò ká ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ọ̀daràn tí a ká lọ́wọ́ kò. Dókítà Hiroshi Nakajima, olùdarí àgbà àjọ WHO tẹ́lẹ̀ rí, pe ìlànà tuntun yìí ní “ọ̀kan lára àṣeyọrí pàtàkì jù lọ nínú ọ̀ràn ìlera ará ìlú ní ọ̀rúndún yìí.” Dókítà Arata Kochi, olùdarí Ètò Àbójútó Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Kárí Ayé ti Àjọ WHO, sọ pé, èyí fún wa ní àǹfààní láti “ṣẹ́pá àjàkálẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ” fún ìgbà àkọ́kọ́. Kí ló wá fa gbogbo ìdùnnú yìí? Ìlànà ìtọ́jú kan tó ń jẹ́ DOTS ni.
DOTS jẹ́ ìkékúrú ìtọ́jú lò-ó-lójú-mi ní tààràtà fún ìgbà díẹ̀ [Directly Observed Treatment, Short-Course]. Ó jẹ́ ìlànà ìtọ́jú kan tí a lè fi wo ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe sàn láàárín oṣù mẹ́fà sí mẹ́jọ láìsí pé wọ́n lo ọjọ́ kan péré ní ilé ìwòsàn. Ohun márùn-ún ni ìlànà DOTS nílò láti ṣàṣeyọrí. Àjọ WHO sọ pé, bí èyíkéyìí lára ìgbésẹ̀ ìtọ́jú yìí kò bá sí níbẹ̀, “a kò ní lè” wo àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe sàn. Kí ni àwọn ìgbésẹ̀ náà?
● 1. Ní Tààràtà: Irú ikọ́ ẹ̀gbẹ tó léwu jù lọ ni èyí tí a kò mọ̀ pé ó wà lára. Àjọ WHO wá tipa bẹ́ẹ̀ tẹnu mọ́ ọn pé lákọ̀ọ́kọ́, ó yẹ kí àwọn olùtọ́jú aláìsàn darí àfiyèsí wọn sí mímọ àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe ní àdúgbò wọn.
● 2. Lò Ó-Lójú-Mi: Ìgbésẹ̀ kejì nínú ìlànà DOTS sọ ọ́ di iṣẹ́ fún ètò ìlera—dípò aláìsàn náà—láti rí i pé ìwòsàn ṣeé ṣe. Àwọn olùtọ́jú aláìsàn tàbí àwọn olùyọ̀ǹda-ara-ẹni tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́, bí àwọn tí ń tajà, àwọn olùkọ́, tàbí àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ti ṣe rí, yóò máa wo aláìsàn bó ti ń lo àwọn oògùn ikọ́ ẹ̀gbẹ náà. “Àwọn tí ń wo aláìsàn” ṣe pàtàkì tí a bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nítorí pé ìdí pàtàkì tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣì fi ń jà títí di òní ni pé àwọn aláìsàn máa ń tètè ṣíwọ́ lílo oògùn wọn. (Wo àpótí náà, “Èé Ṣe Tí Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Fi Tún Ń Pọ̀ Sí I?” lójú ìwé 24.) Tí wọ́n bá ti lo oògùn náà fún ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré, ara wọn á bẹ̀rẹ̀ sí í yá, wọn ò wá ní lo oògùn wọn mọ́. Àmọ́, ó yẹ kí wọ́n lo oògùn náà fún oṣù mẹ́fà sí mẹ́jọ kí gbogbo bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ náà lè tán lára wọn.
● 3. Ìtọ́jú: Láàárín oṣù mẹ́fà sí mẹ́jọ yìí, àwọn olùtọ́jú aláìsàn yóò máa ṣàkíyèsí àbájáde ìtọ́jú náà, wọn á sì máa ṣàkọsílẹ̀ bí ara aláìsàn náà ṣe ń yá sí. Lọ́nà yìí, wọ́n ń rí i dájú pé ara àwọn aláìsàn yá dáadáa àti pé wọn kò lè kó àrùn náà ran àwọn ẹlòmíràn.
● 4. Fún Ìgbà Díẹ̀: Lílo àkànpọ̀ oògùn ikọ́ ẹ̀gbẹ tó yẹ àti ìwọ̀n tó yẹ, tí a mọ̀ sí fífi kẹ́míkà ṣètọ́jú fún ìgbà díẹ̀, fún àkókò tó yẹ ni ìgbésẹ̀ tó ṣìkẹrin nínú ìlànà DOTS. Àwọn àkànpọ̀ oògùn yìí lágbára tó láti pa àwọn bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ.a Àwọn oògùn náà gbọ́dọ̀ wà lórí àtẹ kí ìtọ́jú náà má bàa ní ìdíwọ́.
● 5. !: Àjọ WHO lo àmì ìyanu fún ìgbésẹ̀ ìlànà DOTS karùn-ún yìí lẹ́yìn ọ̀rọ̀ náà, DOTS! Ó dúró fún owó tí a ó lò àti àwọn ìlànà àbójútó tó gbéṣẹ́. Àjọ WHO rọ àwọn àjọ elétò ìlera láti bá àwọn ìjọba àti àjọ tí kì í ṣe tìjọba ṣàdéhùn lórí owó àti láti jẹ́ kí ìtọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ jẹ́ apá kan ètò ìlera tó wà ní orílẹ̀-èdè náà.
Ní ti rírí owó lò, ìlànà DOTS wu àwọn elétò ìlànà àbójútó tí ń pinnu owó tí a óò ná. Báńkì Àgbáyé ti ka ìlànà DOTS mọ́ “ọ̀kan lára ohun tí a ní láti fi bá . . . àrùn jà, tí kò wọ́n.” Àròpọ̀ iye tí àjọ WHO ṣírò pé a óò ná tí a bá lo ìlànà náà ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún dọ́là lórí aláìsàn kọ̀ọ̀kan. “Èyí kì í fìgbà gbogbo ju sẹ́ǹtì mẹ́wàá owó Amẹ́ríkà lọ ní ìpíndọ́gba fún ẹnì kọ̀ọ̀kan ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, tí àwọn ènìyàn lè rí san kódà bí ipò ọrọ̀ ajé wọn bá ti bàjẹ́ bàlùmọ̀ pàápàá.” Ṣùgbọ́n àìwọ́n rẹ̀ kò dín àǹfààní rẹ̀ kù.
Báwo Ló Ṣe Gbéṣẹ́ Tó?
Àwọn aṣojú àjọ WHO kéde ní March 1997, pé, lílo ìlànà DOTS lọ́nà tí a là sílẹ̀ náà títí di ìsinsìnyí, “ti ń mú kí bí ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣe ń jà rànyìn nílẹ̀ máa dín kù sí i fún ìgbà àkọ́kọ́ láàárín ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.” “Ní àwọn ibi tí a ti lo ìlànà DOTS, àwọn tó ti wò sàn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì ti tẹ́lẹ̀.” Àwọn ètò ìtọ́jú tí a fi ìlànà DOTS ṣe ní àwọn àgbègbè tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ti ń jà gan-an ti ń fi hàn pé ìlànà náà ń ṣiṣẹ́. Gbé àwọn ọ̀ràn díẹ̀ tí àjọ WHO tọ́ka sí pé ó ti ṣàṣeyọrí yẹ̀ wò.
Ní Íńdíà, “a ti lo ìlànà DOTS ní àwọn àgbègbè kan tí iye àwọn tí ń gbé ibẹ̀ lé ní mílíọ̀nù méjìlá. . . . Nísinsìnyí, mẹ́rin lára àwọn márùn-ún tó ní ikọ́ ẹ̀gbẹ ni a ń wò sàn.” Nínú ètò kan tí a ṣe fún mílíọ̀nù kan ènìyàn ní Bangladesh, “ìpín mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún [àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe] ni a wò sàn.” Ní erékùṣù kan ní Indonesia, lílo ìlànà DOTS “ń wo ẹni mẹ́sàn-án lára àwọn mẹ́wàá tó kó àrùn náà sàn.” Ní China, àwọn ètò tí a ṣe “kẹ́sẹ járí gan-an,” níbi tí àwọn tí a wò sàn ti jẹ́ ìpín mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún nínú ìpín ọgọ́rùn-ún. Ní ìlú kan ní Gúúsù Áfíríkà, “ó lé ní ìpín ọgọ́rin nínú ìpín ọgọ́rùn-ún [àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe] tí a wò sàn.” Láìpẹ́ yìí, a tún ṣètò lílo ìlànà DOTS ní Ìlú Ńlá New York, àbájáde rẹ̀ sì mú inú dùn.
Dókítà Kochi sọ pé, àwọn àbájáde dídán tí a dán ìlànà náà wò ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè fi hàn pé ìlànà náà “ṣeé lò níbikíbi, ó sì lè wo ìpín márùnlélọ́gọ́rin nínú ìpín ọgọ́rùn-ún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn tí àrùn náà ń ṣe sàn.”
Kò Búrẹ́kẹ́—Ṣùgbọ́n Ó Ń Tẹ̀ Síwájú
Nítorí pé ìlànà DOTS lágbára láti fìrọ̀rùn ṣẹ́gun ọ̀kan lára àrùn tí ń gbẹ̀mí aráyé jù lọ, tí kò sì wọ́n, a lè retí pé kí ó máa búrẹ́kẹ́. Òṣìṣẹ́ àjọ WHO kan sọ pé: “Síbẹ̀, ó yani lẹ́nu pé ìwọ̀nba orílẹ̀-èdè díẹ̀ péré ló ń lo ìlànà tí àjọ WHO fẹ̀rí hàn pé ó dára tí kò sì wọ́n tí a fi ń ṣẹ́pá ikọ́ ẹ̀gbẹ náà.” Ní gidi, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1996, orílẹ̀-èdè mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n péré ló tíì dán ìlànà ìtọ́jú náà wò káàkiri ilẹ̀ wọn.
Bí ó ti wù kí ó rí, ìtẹ̀síwájú wà. Kó tó di ọdún 1993, nígbà tí àjọ WHO polongo pé ọwọ́ ò ká ikọ́ ẹ̀gbẹ mọ́, ẹnì kan péré lára àádọ́ta ènìyàn tó ní ikọ́ ẹ̀gbẹ ló ń gba ìtọ́jú DOTS. Lónìí, ìṣirò ìfiwéra náà ti di ẹyọ kan lára àwọn mẹ́wàá. Ìròyìn sọ pé ní ọdún 1998, nǹkan bí orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ló ti ń fi ìlànà DOTS ṣètọ́jú. Bí àwọn orílẹ̀-èdè púpọ̀ sí i bá bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìlànà DOTS, iye àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe lọ́dọọdún ‘yóò fi ìdajì dín kù láàárín ẹ̀wádún kan péré.’ Dókítà Kochi sọ pé: “Ó jẹ́ ìlànà ìtọ́jú aláìsàn tí ẹ̀rí fi hàn pé ó gbéṣẹ́, kí a ṣáà ti lò ó níbi púpọ̀ gan-an ló kù.”
Níwọ̀n bí ènìyàn ti ní ìmọ̀ àti irin iṣẹ́ tó máa fi bá ikọ́ ẹ̀gbẹ jà lọ́nà tó kẹ́sẹ járí, ohun kan ṣoṣo tó ṣàìní ni ‘àwọn ènìyàn tí yóò rí i dájú pé a lo àwọn oògùn wọ̀nyí jákèjádò ayé.’ Abájọ tí àjọ WHO fi béèrè nínú ìwé kan tí a darí sí àwọn oníṣègùn àti àwọn olùṣètọ́jú aláìsàn mìíràn jákèjádò ayé pé: “Kí la tún ń dúró ṣe?”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Egbòogi isoniazid, rifampin, pyrazinamide, streptomycin, àti ethambutol wà lára àwọn oògùn náà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
Ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan ni ẹnì kan ń kó ikọ́ ẹ̀gbẹ láyé
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
‘Oògùn agbẹ̀mílà wà lórí àtẹ nígbà tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ń kú.’ Dókítà Arata Kochi
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]
“Ìlànà DOTS yóò jẹ́ àṣeyọrí pàtàkì jù lọ nínú ọ̀ràn rírí sí ìlera ará ìlú ní ẹ̀wádún yìí.” Ìròyìn tí àjọ WHO gbé jáde
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Èé Ṣe Tí Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Fi Tún Ń Pọ̀ Sí I?
Ó lé ní ẹ̀wádún mẹ́rin sẹ́yìn tí a ṣàwárí oògùn ikọ́ ẹ̀gbẹ. Láti ìgbà yẹn, ó ti lé ní ọgọ́fà mílíọ̀nù ènìyàn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ti pa, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́ta mìíràn yóò kú lọ́dún yìí. Kí ló dé tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣì ń pa àwọn ènìyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nígbà tí oògùn kan wà fún un? Ohun mẹ́ta tó fà á ni: àìbìkítà, fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn AIDS, àti ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ọ̀pọ̀ oògùn kì í ràn.
Àìbìkítà. Àwọn àrùn àkóràn bí AIDS àti Ebola ni gbogbo ayé ń gbájú mọ́. Àmọ́, ní ọdún 1995, pé bí àrùn Ebola bá pa ẹnì kan, ẹgbẹ̀rún méjìlá ènìyàn ni ikọ́ ẹ̀gbẹ ti pa. Ká sọ tòótọ́, ikọ́ ẹ̀gbẹ ń jà gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà débi pé àwọn ará ibẹ̀ ti wá ka àrùn náà sí apá kan ìgbésí ayé wọn. Lákòókò kan náà, a ti gba ikọ́ ẹ̀gbẹ láyè láti máa ràn kálẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oògùn tó gbéṣẹ́ láti fi wò ó sàn wà lórí àtẹ. Àìbìkítà tí ń ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé yìí ti jẹ́ àṣìṣe tí ń ṣekú pani. Níwọ̀n bí àníyàn tí ayé ń ṣe nípa ikọ́ ẹ̀gbẹ ti ń dín kù, àwọn bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ ń pọ̀ sí i ni. Lónìí, wọ́n ń dá ènìyàn púpọ̀ sí i gúnlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè púpọ̀ sí i ju ti ìgbàkígbà rí lọ nínú ìtàn aráyé.
Fáírọ́ọ̀sì HIV àti Àrùn AIDS. Ikọ́ ẹ̀gbẹ àti fáírọ́ọ̀sì HIV àti àrùn AIDS jọ ń rìn ni. Bí àwọn ènìyàn bá ní fáírọ́ọ̀sì HIV—tí ń dín agbára ìgbóguntàrùn wọn kù—ṣíṣeéṣe náà pé kí wọ́n ní ikọ́ ẹ̀gbẹ jẹ́ ìlọ́po ọgbọ̀n. Abájọ tí àjàkálẹ̀ fáírọ́ọ̀sì HIV tí ń jà jákèjádò ayé ní lọ́ọ́lọ́ọ́ ti mú kí iye àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe pọ̀ sí i pẹ̀lú! A fojú díwọ̀n pé ọ̀kẹ́ mẹ́tàlá ó lé ẹgbàáta [266,000] àwọn tí àyẹ̀wò fi hàn pé wọ́n ti kó fáírọ́ọ̀sì HIV ni ikọ́ ẹ̀gbẹ pa lọ́dún 1997. Peter Piot, olùdarí Àjọ Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Fáírọ́ọ̀sì HIV àti Àrùn AIDS ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, sọ pé: “Àwọn ọkùnrin àti obìnrin wọ̀nyí kò jàǹfààní oògùn tí kò wọ́n, tí ń bá ikọ́ ẹ̀gbẹ jà, tí wọ́n nílò láti wo ikọ́ ẹ̀gbẹ tó ń ṣe wọ́n sàn.”
Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Tí Ọ̀pọ̀ Oògùn Kì Í Ràn. “Àwọn adárútúrútú tíntìntín,” tí oògùn apakòkòrò tí aráyé kó jọ pelemọ kò ràn, dà bí ìtàn àròsọ sáyẹ́ǹsì, ṣùgbọ́n ní ti ikọ́ ẹ̀gbẹ, kì í ṣe ìtàn àròsọ. Àwọn tó ti kó ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ọ̀pọ̀ oògùn kì í ràn (MDR) lè ti lé ní àádọ́ta mílíọ̀nù. Àwọn tí ń gbàtọ́jú, tí wọ́n wá dáwọ́ lílo àwọn oògùn wọn dúró lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré nítorí pé ara wọ́n ti yá díẹ̀, nítorí pé oògùn náà ti tán, tàbí nítorí pé àrùn náà ń dójú tini láwùjọ kì í pa gbogbo àwọn bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ tó wà lára wọn tán. Fún àpẹẹrẹ, ní orílẹ̀-èdè kan ní Éṣíà, méjì lára àwọn mẹ́ta tó ní ikọ́ ẹ̀gbẹ ni kì í lo oògùn wọn tán. Bí àrùn náà bá tún padà wá, ó lè ṣòro gan-an láti wò sàn nítorí pé àwọn bakitéríà tí kò kú tán lákọ̀ọ́kọ́ ń jà padà, wọ́n sì ń borí gbogbo oògùn ikọ́ ẹ̀gbẹ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Ní àbájáde rẹ̀, àwọn aláìsàn á wá ní oríṣi ikọ́ ẹ̀gbẹ kan tí kì í ṣeé wò sàn—lára wọn àti lára ẹni yòówù tó bá kó o lára wọn. Bí àwọn adárútúrútú tí ọ̀pọ̀ oògùn kì í ràn yìí bá sì ti wà nínú afẹ́fẹ́, ìbéèrè adáyàfoni tí a óò máa béèrè ni pé, Ǹjẹ́ ènìyàn yóò tún lè ṣẹ́pá rẹ̀ bí?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Ń Dalẹ̀ Rú Jákèjádò Ayé
Àjàkálẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ (TB) ń pọ̀ sí i, ó túbọ̀ ń náni lówó gan-an, ó sì ń pa ènìyàn púpọ̀ sí i lọ́dọọdún. Ìròyìn tí Àjọ Ìlera Àgbáyé kó jọ tọpa bí àrùn ayọ́kẹ́lẹ́pani yìí ṣe ń ràn kálẹ̀. Àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nìyí: “Ikọ́ ẹ̀gbẹ ti ń fojú wọn rí màbo ní Pakistan.” “Ikọ́ ẹ̀gbẹ tún ti padà dé sí Thailand pẹ̀lú ìkanragógó.” “Ní báyìí, ikọ́ ẹ̀gbẹ wà lára ohun tí ń fa àìsàn àti ikú jù lọ ní Brazil.” “Gírígírí ni ikọ́ ẹ̀gbẹ gbá àwọn ará Mexico mú.” “Ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ ń pọ̀ lọ́nà lílékenkà” ní Rọ́ṣíà. Ní Etiópíà, “ikọ́ ẹ̀gbẹ ń jà káàkiri ni orílẹ̀-èdè náà.” “Gúúsù Áfíríkà ní ọ̀kan lára àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ tó ga jù lọ lágbàáyé.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún ènìyàn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe ló ń gbé ní àwọn orílẹ̀-èdè tó tòṣì jù lọ lágbàáyé, àrùn náà ti ń ràn káàkiri ní àwọn orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ pẹ̀lú. Iye ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ tí a ròyìn pọ̀ sí i ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990. Oníròyìn Valery Gartseff tó jẹ́ ọmọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà sọ pé ikọ́ ẹ̀gbẹ “tún ti padà wá láti ṣe àwọn ará Amẹ́ríkà lọ́ṣẹ́.” Bákan náà, Dókítà Jaap Broekmans, olùdarí Àjọ Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Ikọ́ Ẹ̀gbẹ ti Ìjọba Àpapọ̀ Netherlands, sọ láìpẹ́ yìí pé, àjàkálẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ ti “bẹ̀rẹ̀ sí í burú sí i ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti àwọn apá ibì kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù.” Kò yani lẹ́nu nígbà tí ìwé àtìgbàdégbà Science, ti August 22, 1997, sọ pé, “ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣì jẹ́ ewu ńlá kan fún ìlera.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
A Ṣàwárí Àpadé-Àludé Ikọ́ Ẹ̀gbẹ
Àwọn olùwádìí ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàṣeyọrí láti ṣàkọsílẹ̀ àpadé-àludé gbogbo àbùdá bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ ni. Dókítà Douglas Young, láti Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Ìṣègùn ti Kọ́lẹ́ẹ̀jì Ìjọba ní London, sọ pé, ìgbésẹ̀ yìí sàmì sí “apá tuntun kan nínú ogun tí a ń bá ọ̀kan lára àwọn ohun tí ń gbẹ̀mí aráyé jù lọ jà.” Àjọ Ìlera Àgbáyé ròyìn pé àwárí yìí “lè wúlò gan-an láti mú lò nínú àwọn ìwádìí tí a ó ṣe nípa àwọn oògùn àti abẹ́rẹ́ àjẹsára fún ikọ́ ẹ̀gbẹ lọ́jọ́ iwájú.”—The TB Treatment Observer, September 15, 1998.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn àkànpọ̀ oògùn yìí lè pa àwọn bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò tí àjọ WHO, Geneva, fún wa
Fọ́tò: WHO/Thierry Falise
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ọgọ́rùn-ún dọ́là ni yóò náni láti wo aláìsàn kan sàn
[Àwọn Credit Line]
Fọ́tò: WHO⁄Thierry Falise
Fọ́tò tí àjọ WHO, Geneva, fún wa
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Fọ́tò: WHO/Thierry Falise
Fọ́tò tí àjọ WHO, Geneva, fún wa
Fọ́tò: WHO/Thierry Falise