ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/22 ojú ìwé 4-9
  • Ìjagunmólú àti Ọ̀ràn Ìbànújẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjagunmólú àti Ọ̀ràn Ìbànújẹ́
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìwòsàn Kan Dé Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!
  • Ó Tún Pa Dà Wá Lọ́nà Aṣekúpani
  • Kí Ló Dé Tó Pa Dà Wá Lọ́nà Aṣekúpani?
  • Fáírọ́ọ̀sì HIV àti Ikọ́ Ẹ̀gbẹ —Ìṣòro Alápá Méjì
  • Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Tí Ọ̀pọ̀ Egbòogi Kò Ràn
  • Ìdènà àti Ìwòsàn
  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ń Gbà Bá Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Jà
    Jí!—1999
  • Ọ̀rẹ́ Rẹ́rùnrẹ́rùn
    Jí!—1998
  • Iye Ènìyàn Tí Ó Ń Pa Bá Ti Ogun Dọ́gba
    Jí!—1997
  • Ikọ́ Fée Jà Padà!
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/22 ojú ìwé 4-9

Ìjagunmólú àti Ọ̀ràn Ìbànújẹ́

“Ìtàn nípa ikọ́ ẹ̀gbẹ láàárín 30 ọdún tó kọjá ti jẹ́ ọ̀ràn ìjagunmólú àti ti ìbànújẹ́—ìjagunmólú àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n pèsè ọ̀nà tí a lè gbà káwọ́ àrùn náà àti ọ̀nà tí a lè gbà mú un kúrò pátápátá, ìkùnà wọn láti ṣàmúlò àwọn àwárí wọn tí a ń rí níbi gbogbo sì jẹ́ ọ̀ràn ìbànújẹ́.”—J. R. Bignall, 1982.

IKỌ́ Ẹ̀GBẸ (TB) ti ń pànìyàn tipẹ́tipẹ́. Ó pọ́n àwọn ará Inca ti Peru lójú tipẹ́tipẹ́ kí àwọn ará Yúróòpù tó tẹkọ̀ létí lọ sí Gúúsù Amẹ́ríkà. Ó kọ lu àwọn ara Íjíbítì nígbà tí àwọn fáráò ń ṣàkóso nínú ọlá ńlá. Àwọn ìwé tí a kọ nígbà láéláé fi hàn pé ikọ́ ẹ̀gbẹ fìyà jẹ àwọn sàràkísàràkí ènìyàn àti àwọn ènìyàn gbáàtúù ní Bábílónì, Gíríìsì, àti China ìgbàanì.

Láti ọ̀rúndún kejìdínlógún títí di ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ikọ́ ẹ̀gbẹ ló ń pa ènìyàn jù lọ ní ìhà Ìwọ̀ Oòrùn ayé. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ní 1882, dókítà ọmọ ilẹ̀ Germany náà, Robert Koch, kéde pé òun ṣàwárí bacillus tí ń fa àrùn náà níkẹyìn. Ní ọdún 13 lẹ́yìn náà, Wilhelm Röntgen ṣàwárí àwọn ìyàwòrán X ray, èyí sì ń mú kí ó rọrùn láti ṣàyẹ̀wò ẹ̀dọ̀fóró àwọn alààyè ènìyàn kínníkínní láti rí àwọn àmì tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ikọ́ ẹ̀gbẹ. Lẹ́yìn náà, ní 1921, àwọn ọmọ ilẹ̀ Faransé tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣẹ̀dá abẹ́rẹ́ àjẹsára kan tí yóò bá ikọ́ ẹ̀gbẹ jà. Wọ́n sọ ọ́ ní BCG (Bacillus Calmette-Guérin), orúkọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀, òun ló sì wá jẹ́ abẹ́rẹ́ àjẹsára kan ṣoṣo tí ń bá àrùn náà jà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ikọ́ ẹ̀gbẹ ń bá a lọ ní pípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.

Ìwòsàn Kan Dé Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!

Àwọn oníṣègùn kó àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe lọ sí àwọn ibùdó ìkọ́fẹpadà. A sábà máa ń kọ́ àwọn ilé ìwòsàn wọ̀nyí sórí àwọn òkè ńlá, níbi tí àwọn aláìsàn ti lè sinmi, kí wọ́n sì fa afẹ́fẹ́ mímọ́tónítóní sínú. Lẹ́yìn náà, ní 1944, àwọn dókítà ní United States ṣàwárí egbòogi streptomycin, oògùn agbógunti kòkòrò àrùn tí wọ́n kọ́kọ́ ṣàwárí pé ó gbéṣẹ́ láti fi gbógun ti ikọ́ ẹ̀gbẹ. Ìgbéjáde àwọn egbòogi agbógunti ikọ́ ẹ̀gbẹ mìíràn tẹ̀ lé e láìpẹ́-láìjìnnà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, a lè wo àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe sàn, kódà nínú ilé wọn.

Bí ìwọ̀n tí ó fi ń ran àwọn ènìyàn ṣe ń lọ sílẹ̀ gan-an, ó jọ pé ọjọ́ ọ̀la yóò mìnrìngìndìn. Àwọn ibùdó ìkọ́fẹpadà kógbá sílé, ìkówójọ fún ìwádìí nípa ikọ́ ẹ̀gbẹ sì pòórá. Àwọn ètò fún ṣíṣèdíwọ́ fún un di èyí tí a pa tì, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àti àwọn dókítà sì wá àwọn ìṣòro tuntun nínú ìṣègùn lọ.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikọ́ ẹ̀gbẹ ṣì ń pa ènìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, dájúdájú ipò nǹkan yóò sunwọ̀n. Ikọ́ ẹ̀gbẹ ti di ọ̀rọ̀ ìtàn tẹ́lẹ̀ rí. Ohun tí àwọn ènìyàn rò nìyẹn, àmọ́ wọn kò tọ̀nà.

Ó Tún Pa Dà Wá Lọ́nà Aṣekúpani

Láàárín àwọn ọdún 1980, ikọ́ ẹ̀gbẹ bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà wá lọ́nà tí ń múni fòyà, tí ó sì ń ṣekú pani. Lẹ́yìn náà, ní April 1993, Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) polongo ikọ́ ẹ̀gbẹ bí “ọ̀ràn ìṣòro jákèjádò àgbáyé,” ó fi kún un pé, “àrùn náà yóò gba ẹ̀mí àwọn tí iye wọn lé ní 30 mílíọ̀nù ní ẹ̀wádún tí ń bọ̀ àyàfi bí a bá gbé ìgbésẹ̀ ojú ẹsẹ̀ láti ṣẹ́pá ìrànkálẹ̀ rẹ̀.” Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí àjọ WHO ṣe irú ìpolongo bẹ́ẹ̀.

Láti ìgbà náà wá, kò sí “ìgbésẹ̀ ojú ẹsẹ̀” tí ó tí ì ṣẹ́pá ìrànkálẹ̀ àrùn náà. Ó dájú pé ipò ọ̀ràn náà ti bàlùmọ̀. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àjọ WHO ròyìn pé àwọn ènìyàn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ pa ní 1995 pọ̀ gan-an ju àwọn tí ó tí ì pa ní ọdún èyíkéyìí nínú ìtàn lọ. Àjọ WHO tún kìlọ̀ pé ó lè tó ìdajì bílíọ̀nù ènìyàn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ yóò ṣe láàárín 50 ọdún tí ń bọ̀. Lọ́nà tí ń pọ̀ sí i, àwọn ènìyàn yóò máa ní ikọ́ ẹ̀gbẹ tí kì í sábà ṣeé wò sàn, tí ọ̀pọ̀ egbòogi kò ràn.

Kí Ló Dé Tó Pa Dà Wá Lọ́nà Aṣekúpani?

Ìdí kan ni pé láàárín 20 ọdún tó kọjá, àwọn ètò ìṣàkóso ikọ́ ẹ̀gbẹ ti jó rẹ̀yìn tàbí kí wọ́n ti pòórá ní apá ibi púpọ̀ lágbàáyé. Èyí ti ṣamọ̀nà sí ìjáfara nínú dídá àrùn náà mọ̀ àti títọ́jú àwọn tí wọ́n ní in. Ìyẹn ti wá yọrí sí ikú àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i àti ìrànkálẹ̀ àrùn náà.

Ìdí mìíràn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ fi pa dà wá jẹ́ nítorí pípọ̀ tí àwọn òtòṣì, tí wọn kò jẹun-unre kánú tí ń gbé àárín àwọn ìlú ńlá kíkúnfọ́fọ́ ń pọ̀ sí i, ní pàtàkì àwọn ìlú ńlá ọlọ́pọ̀ èrò ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikọ́ ẹ̀gbẹ kò mọ sọ́dọ̀ àwọn òtòṣì nìkan—ẹnikẹ́ni ni ikọ́ ẹ̀gbẹ lè ṣe—àìmọ́tótó àti gbígbé ní àyíká híhá gádígádí ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún àkóràn àrùn láti ràn láti ọ̀dọ̀ ẹnì kan sí ẹlòmíràn. Wọ́n tún ń mú kí ó túbọ̀ ṣeé ṣe pé kí ìgbékalẹ̀ adènà àrùn àwọn ènìyàn máà lókun tó láti dènà àrùn náà.

Fáírọ́ọ̀sì HIV àti Ikọ́ Ẹ̀gbẹ —Ìṣòro Alápá Méjì

Lájorí ìṣòro kan ni pé ikọ́ ẹ̀gbẹ ti mú àjọṣepọ̀ oníkúpani dàgbà pẹ̀lú fáírọ́ọ̀sì HIV, fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìdá kan nínú mẹ́ta lára àwọn ènìyàn tí a fojú díwọ̀n sí àádọ́ta ọ̀kẹ́ tí àwọn ohun tó tan mọ́ àrùn AIDS pa ní 1995, ni ikọ́ ẹ̀gbẹ pa. Èyí jẹ́ nítorí pé fáírọ́ọ̀sì HIV ń sọ ara di aláìlágbára tó láti dènà ikọ́ ẹ̀gbẹ.

Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn, níní ikọ́ ẹ̀gbẹ kò lágbára débi tí yóò fi fa àìsàn. Èé ṣe? Nítorí pé ńṣe ni a sé àwọn bakitéríà bacillus mọ́ sínú àwọn sẹ́ẹ̀lì tí a ń pè ní macrophages. Ìgbékalẹ̀ adènà àrùn ẹni náà ló sé wọn mọ́ síbẹ̀, ní pàtàkì àwọn sẹ́ẹ̀lì T lymphocyte, tàbí àwọn sẹ́ẹ̀lì T.

Ńṣe ni àwọn bakitéríà bacillus ikọ́ ẹ̀gbẹ dà bí àwọn ṣèbé tí a tọ́jú pa mọ́ sínú àwọn apẹ̀rẹ̀ tí a fi ìdérí dé pinpin. Àwọn apẹ̀rẹ̀ náà dúró fún àwọn sẹ́ẹ̀lì macrophage, àwọn ìdérí náà sì dúró fún àwọn sẹ́ẹ̀lì T. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí fáírọ́ọ̀sì AIDS bá dé ibẹ̀, yóò fìpá ṣí ìdérí kúrò lórí apẹ̀rẹ̀ náà. Tí ìyẹn bá ṣẹlẹ̀, àwọn bacillus náà yóò ráyè jáde, wọn óò sì lómìnira láti ba ẹ̀yà èyíkéyìí nínú ara jẹ́.

Nítorí náà, ó ṣeé ṣe gan-an kí ikọ́ ẹ̀gbẹ máa ṣe àwọn alárùn AIDS lójú méjèèjì ju àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìgbékalẹ̀ adènà àrùn tó lera lọ. Ògbóǹtagí kan nínú ìtọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ ní Scotland sọ pé: “Àwọn ènìyàn tí wọ́n ní fáírọ́ọ̀sì HIV ni ó lè tètè ràn. Àwọn méjì kan tí wọ́n ní fáírọ́ọ̀sì HIV tí wọ́n wà ní ilé ìwòsàn kan ní London kó ikọ́ ẹ̀gbẹ nígbà tí a ti ẹnì kan tí ó ń ṣe kọjá níwájú wọn ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọ́n jókòó sí.”

Nítorí náà, àrùn AIDS ti lọ́wọ́ nínú mímú kí àjàkálẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ máa pọ̀ sí i. Gẹ́gẹ́ bí ìfojúdíwọ̀n kan tí a ṣe ti sọ, tí ó bá fi máa di ọdún 2000, àjàkálẹ̀ àrùn AIDS yóò fa mílíọ̀nù 1.4 ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ì bá tí ṣẹlẹ̀. Kì í ṣe pé àwọn tí wọ́n ti kó àrùn AIDS lè tètè kó ikọ́ ẹ̀gbẹ gan-an nìkan ni kókó pàtàkì kan tí ń mú kí ìṣẹ̀lẹ̀ ikọ́ ẹ̀gbẹ pọ̀ sí i, àmọ́ pé wọ́n tún lè kó ikọ́ ẹ̀gbẹ ran àwọn ẹlòmíràn, títí kan àwọn tí kò ní àrùn AIDS.

Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Tí Ọ̀pọ̀ Egbòogi Kò Ràn

Kókó abájọ tí ó kẹ́yìn tí ń mú kí ìjà tí a ń bá ikọ́ ẹ̀gbẹ jà túbọ̀ le koko ni ti àwọn oríṣi ikọ́ ẹ̀gbẹ tó tún ń yọjú tí egbòogi kò ràn. Àwọn oríṣi eléwèlè yí ń halẹ̀ láti mú kí àrùn náà máà tún ṣeé wò sàn, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní sànmánì tí ó ṣáájú kí a tó gbé àwọn oògùn agbógunti kòkòrò àrùn jáde.

Lọ́nà títakora, lílo àwọn egbòogi agbógunti ikọ́ ẹ̀gbẹ lọ́nà tí kò yẹ ni lájorí okùnfà ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ọ̀pọ̀ egbòogi kì í ràn. Títọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ lọ́nà tí ó yẹ ń gba oṣù mẹ́fà, ó kéré tán, ó sì ń béèrè pé kí aláìsàn náà máa lo egbòogi mẹ́rin déédéé láìdáwọ́dúró. Aláìsàn náà lè ní láti lo àwọn egbòogi oníhóró tó pọ̀ tó dọ́sìnì kan lóòjọ́. Bí àwọn aláìsàn kò bá lo àwọn egbòogi náà déédéé tàbí tí wọn kò bá gba ìtọ́jú tán, àwọn oríṣi ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ó ṣòro láti pa tàbí tí a kò ní lè pa máa ń jẹyọ. Nǹkan bí oríṣi méje egbòogi ikọ́ ẹ̀gbẹ tí àwọn ènìyàn máa ń lò gan-an kò ran àwọn oríṣi ikọ́ ẹ̀gbẹ kan.

Kì í ṣe pé títọ́jú àwọn aláìsàn tí wọ́n ní ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ọ̀pọ̀ egbòogi kò ràn wulẹ̀ ṣòro ni, ó tún gbówó lórí. Iye rẹ̀ lè fẹ́rẹ̀ẹ́ fi ìlọ́po 100 pọ̀ ju iye tí a fi ń tọ́jú àwọn mìíràn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe lọ. Fún àpẹẹrẹ, ní United States, iye owó tí a ń gbà láti tọ́jú ìṣẹ̀lẹ̀ oríṣi rẹ̀ kan ṣoṣo lè lé ní 250,000 dọ́là!

Àjọ WHO fojú díwọ̀n pé ó lè tó 100 mílíọ̀nù ènìyàn jákèjádò ayé tí yóò kó oríṣi ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ọ̀pọ̀ egbòogi kì í ràn, irú àwọn tí egbòogi agbógunti ikọ́ ẹ̀gbẹ èyíkéyìí tí a tí ì mọ̀ kò lè wò sàn. Àwọn oríṣi aṣekúpani wọ̀nyí máa ń gbèèràn gan-an bí àwọn oríṣi tí ó wọ́pọ̀.

Ìdènà àti Ìwòsàn

Kí ni a ti ṣe láti gbéjà ko ọ̀ràn ìṣòro tó kárí ayé yìí? Ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti ṣàkóso àrùn náà jẹ́ láti ṣàwárí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń gbèèràn, kí a sì tètè wò wọ́n sàn kí wọ́n tó di ńlá. Kì í ṣe pé èyí yóò ran àwọn tí wọ́n ti ní àìsàn náà lọ́wọ́ nìkan ni, àmọ́ yóò tún dá kíkó àrùn náà ran àwọn ẹlòmíràn dúró.

Bí a kò bá ṣe nǹkan kan sí ikọ́ ẹ̀gbẹ, ó máa ń pa ju ìdajì àwọn tó ń ṣe lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, bí a bá tọ́jú ikọ́ ẹ̀gbẹ dáadáa, gbogbo irú rẹ̀ tí ń ṣeni fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣeé wò sàn bí kì í bá ṣe oríṣi kan tí ọ̀pọ̀ egbòogi kì í ràn ló fà á.

Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, ìtọ́jú tí ó yẹ béèrè pé kí aláìsàn náà lo gbogbo egbòogi tí wọ́n kọ fún un tán. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kì í lò ó tán. Kí ló fà á? Bí ó ti máa ń rí, ikọ́, ibà, àti àwọn àmì àrùn míràn máa ń lọ ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn tí a bẹ̀rẹ̀ sí í gba ìtọ́jú. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn ń parí èrò sí pé ara àwọn ti yá, àwọn kò sì ní lo àwọn egbòogi náà mọ́.

Láti gbéjà ko ìṣòro yìí, àjọ WHO ṣonígbọ̀wọ́ ètò kan tí a pè ní DOTS, tí ó dúró fún “ìtọ́jú lò-ó-lójú-mi, fún ìgbà díẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí orúkọ náà ti fi hàn, àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ń fojú sí àwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú láti rí i pé wọ́n ń lo egbòogi náà bí a ti kọ ọ́ pé kí wọ́n lò ó, ó kéré tán, fún oṣù méjì lára àsìkò tí wọ́n fi ń gbàtọ́jú. Síbẹ̀, èyí kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti ṣe nítorí pé púpọ̀ lára àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń yọ lẹ́nu jẹ́ òtòṣì láwùjọ. Níwọ̀n bí ìgbésí ayé wọn ti máa ń kún fún pákáǹleke àti ìṣòro lọ́pọ̀ ìgbà—àwọn kan kò tilẹ̀ nílé—ìṣòro rírí sí i pé wọ́n ń lo egbòogi wọn déédéé lè le koko.

Nítorí náà, ìfojúsọ́nà kankan ha wà fún ṣíṣẹ́gun àjàkálẹ̀ àrùn yí tó dé sọ́rùn ìràn aráyé pátápátá bí?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Òkodoro Ọ̀rọ̀ Nípa Ikọ́ Ẹ̀gbẹ

Àpèjúwe: Ikọ́ ẹ̀gbẹ jẹ́ àrùn kan tí ó sábà máa ń kọ lu àwọn ẹ̀dọ̀fóró, ó sì máa ń bà á jẹ́ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ó lè ràn dé àwọn ibòmíràn nínú ara, pàápàá jù lọ ọpọlọ, àwọn kíndìnrín, àti àwọn egungun.

Àwọn àmì àrùn: Ikọ́ ẹ̀gbẹ inú ẹ̀dọ̀fóró lè fa híhúkọ́, rírù àti àìní ìyánnú fún oúnjẹ, lílàágùn lákọlákọ lóru, àárẹ̀, àìlèmídélẹ̀, àti àyà ríro.

Bí a ṣe ń ṣàwárí àrùn náà: Fífi omi tuberculin ṣàyẹ̀wò awọ ara lè fi hàn bí ẹnì kan bá ní bakitéríà bacillus lára. Àwòrán X ray igbáàyà lè fi ìpalára tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹ̀dọ̀fóró hàn, tí ó lè fi àkóràn ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ń ṣeni lójú méjèèjì hàn. Ṣíṣàyẹ̀wò kẹ̀lẹ̀bẹ̀ aláìsàn kan ní ibi ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ni ọ̀nà tí ó nígbọ̀ọ́kànlé jù lọ láti ṣàwárí àwọn bakitéríà bacillus tí ń fa ikọ́ ẹ̀gbẹ.

Ta ló yẹ láti yẹ̀ wò? Àwọn tí wọ́n ń rí yálà àwọn àmì ikọ́ ẹ̀gbẹ tàbí tí wọ́n ti sún mọ́ ẹni tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe gan-an léraléra—ní pàtàkì nínú àwọn iyàrá tí atẹ́gùn kì í rọ́nà gbà wọlé dáadáa.

Abẹ́rẹ́ àjẹsára: Abẹ́rẹ́ àjẹsára kan ṣoṣo ló wà—tí a mọ̀ sí BCG. Ó ń dènà ikọ́ ẹ̀gbẹ lílekoko nínú àwọn ọmọdé àmọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà àti àwọn àgbàlagbà. Lábẹ́ ipò dídára jù lọ, abẹ́rẹ́ àjẹsára náà ń dáàbò boni fún nǹkan bí ọdún 15. Abẹ́rẹ́ àjẹsára BCG wulẹ̀ ń dáàbò bo àwọn tí wọn kò tí ì kó àrùn náà; kì í ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn tí wọ́n ti kó o.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]

Ikọ́ Ẹ̀gbẹ àti Àṣà Tó Lòde

Ó lè ṣàjèjì létí pé àwọn ènìyàn mú ikọ́ ẹ̀gbẹ bí ọ̀pá ìdiwọ̀n ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, níwọ̀n bí wọ́n ti gbà gbọ́ pé àwọn àmì àrùn náà ń fún ìfùsì onímọ̀lára ẹlẹgẹ́, tí ń fi ọgbọ́n ọnà hàn lókun.

Ọmọ ilẹ̀ Faransé tí ó jẹ́ òǹkọ̀wé eré onítàn àti ti ìwé ìtàn náà, Alexandre Dumas, kọ nípa bí nǹkan ṣe rí ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1820 nínú ìwé rẹ̀, Mémoires, pé: “Ó bá àṣà tó lòde mu láti ní ìṣòro àyà ríro; gbogbo ènìyàn ní ń rù hangogo nítorí ìjoro ẹ̀dọ̀fóró, pàápàá jù lọ àwọn akéwì; wọ́n kà á sí àṣà tó lòde láti kú láìpé ẹni ọgbọ̀n ọdún.”

A gbọ́ pé akéwì ọmọ ilẹ̀ England náà, Lord Byron, sọ pé: “Inú mi yóò dùn tí ó bá jẹ́ ìṣòro rírù hangogo nítorí ìjoro ẹ̀dọ̀fóró [ikọ́ ẹ̀gbẹ] ló pa mí . . . nítorí gbogbo àwọn ọmọge ni yóò máa sọ pé, ‘Ẹ wo Byron, ẹ wo bí ìrísí rẹ̀ ti jojú ní gbèsè tó nígbà tó ń kú lọ!’”

Òǹkọ̀wé tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà, Henry David Thoreau, tí ó hàn gbangba pé ikọ́ ẹ̀gbẹ ló pa á, kọ̀wé pé: “Ìjoro àti àrùn sábà máa ń jojú ní gbèsè, bíi ti . . . ìwúrí aláìnírònú ti ìṣòro rírù hangogo nítorí ìjoro ẹ̀dọ̀fóró.”

Nígbà tí àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association ń sọ̀rọ̀ nípa ìwúrí tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń fà níbi gbogbo yìí, ó sọ pé: “Ìkúndùn tí kò bá ìwà ẹ̀dá mu tí àwọn ènìyàn ń ní fún àrùn yí ń hàn nínú gbogbo ohun tí a nífẹ̀ẹ́ sí ní ti àṣà ìṣoge; àwọn obìnrin ń lépa ìrísí ara ṣíṣì, tí ó ṣẹlẹgẹ́, wọ́n ń lo èròjà ìṣaralóge funfun báláwú, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ sí àwọn aṣọ tí a fi oríṣi òwú muslin hun, tí ó gbẹ lára—bíi ti èyí tí àwọn afìmúra-polówó-ọjà òde òní, tí wọ́n ní ìrísí oníṣòro àìjẹunkánú, ń wá.”

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Ó Ha Rọrùn Láti Kó Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Bí?

Dókítà Arata Kochi, olùdarí Ètò Àbójútó Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Kárí Ayé ti Àjọ WHO, kìlọ̀ pé: “Kò sí ibi tí a lè sá sí kúrò lọ́wọ́ bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ. Ẹnikẹ́ni lè kó ikọ́ ẹ̀gbẹ nípa wíwulẹ̀ fa kòkòrò-àrùn ikọ́ ẹ̀gbẹ tí ẹnì kan hú níkọ́ tàbí tí ó sín sínú afẹ́fẹ́. Àwọn kòkòrò-àrùn wọ̀nyí lè wà nínú afẹ́fẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí; kódà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún pàápàá. Gbogbo wa la wà nínú ewu.”

Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kí ẹnì kan tó ní ikọ́ ẹ̀gbẹ, ohun méjì ní láti ṣẹlẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó ní láti kó bakitéríà ikọ́ ẹ̀gbẹ. Lẹ́yìn náà, àkóràn náà ní láti di àrùn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí a kó ikọ́ ẹ̀gbẹ nípa rírọra sún mọ́ ẹnì kan tí ó ní in lára gan-an, ó ṣeé ṣe gan-an pé kí a kó o nípa sísúnmọ́ ẹni náà léraléra, bí irú èyí tí ń ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn mẹ́ńbà ìdílé nínú àwọn ipò àyíká tí ó há gádígádí.

Àwọn bakitéríà bacillus tí ẹni tí ó kó o fà sínú ń di púpọ̀ nínú àyà rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ènìyàn 9 lára ènìyàn 10 ni ìgbékalẹ̀ adènà àrùn wọn máa dá ìrànkálẹ̀ àkóràn náà dúró, tí kò sì ní di àìsàn sí ẹni tí ó kó o náà lára. Àmọ́ nígbà míràn, àwọn bakitéríà bacillus tí wọn kò lágbára lè gba agbára bí fáírọ́ọ̀sì HIV, àrùn àtọ̀gbẹ, àwọn ìtọ́jú oníkẹ́míkà fún àrùn jẹjẹrẹ, tàbí àwọn okùnfà míràn bá sọ ìgbékalẹ̀ adènà àrùn di aláìlera gan-an.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

New Jersey Medical School—National Tuberculosis Center

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ńṣe ni àwọn bakitéríà bacillus tí ń fa ikọ́ ẹ̀gbẹ tí fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS ń tú sílẹ̀ dà bí àwọn ṣèbé tí a tú sílẹ̀ kúrò nínú àwọn apẹ̀rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́