ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 12/22 ojú ìwé 8-9
  • Ojútùú Tó Kárí Ayé—Ó Ha Ṣeé Ṣe Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojútùú Tó Kárí Ayé—Ó Ha Ṣeé Ṣe Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìjagunmólú Tí Ń Bọ̀
  • Ọ̀nà Tuntun Tí A Ń Gbà Bá Ikọ́ Ẹ̀gbẹ Jà
    Jí!—1999
  • Ìjagunmólú àti Ọ̀ràn Ìbànújẹ́
    Jí!—1997
  • Ikọ́ Fée Jà Padà!
    Jí!—1996
  • Ọ̀rẹ́ Rẹ́rùnrẹ́rùn
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 12/22 ojú ìwé 8-9

Ojútùú Tó Kárí Ayé—Ó Ha Ṣeé Ṣe Bí?

ÀWỌN ògbóǹkangí gbà pé ikọ́ ẹ̀gbẹ (TB) jẹ́ ìṣòro tí ó kárí ayé tí ó béèrè fún ojútùú tó kárí ayé. Kò sí orílẹ̀-èdè tí ó lè dá káwọ́ ikọ́ ẹ̀gbẹ, níwọ̀n bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti ń sọdá àwọn ààlà orílẹ̀-èdè lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn gbà gbọ́ pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ jákèjádò ayé ń béèrè pé kí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ́rọ̀ ran àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò lọ́rọ̀, tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ti ń ṣèpalára jù lọ, lọ́wọ́. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Arata Kochi ti sọ, “ire àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ́rọ̀ ló jẹ́ láti ran àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà lọ́wọ́ láti bá ikọ́ ẹ̀gbẹ jà, kí ó tó wá sọ orílẹ̀-èdè tiwọn pẹ̀lú di pápá ogun.”

Ṣùgbọ́n nítorí pé àwọn ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ́rọ̀ kà sí àkọ́múṣe àti ìṣòro kánjúkánjú ń dà wọ́n láàmú, wọn kò tètè gbégbèésẹ̀ láti ṣèrànwọ́. Àwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọn kò lọ́rọ̀ pẹ̀lú sábà máa ń pa àbójútó ìlera tì, tí wọ́n sì ń náwó gọbọi sórí ohun ìjà ogun wọn dípò rẹ̀. Nígbà tí ó fi di àárín 1996, kìkì ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ikọ́ ẹ̀gbẹ ń ṣe lágbàáyé ni a ti fi ìlànà ètò DOTS tọ́jú, iye náà kéré jù débi tí kò lè ṣèdíwọ́ fún àjàkálẹ̀ àrùn náà láti má ṣe burú sí i.

Àjọ WHO sọ pé: “Ìmọ̀ àti àwọn egbòogi tí kò wọ́n tí yóò wo ikọ́ ẹ̀gbẹ sàn ti wà fún ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún. Ohun tí ayé nílò nísinsìnyí ni ìgbésẹ̀ takuntakun láti ọ̀dọ̀ àwọn tí wọ́n ní agbára, ipá ìdarí àti ìyọ́nú tí wọn óò rí sí i pé a lo àwọn egbòogi wọ̀nyí bí ó ṣe yẹ jákèjádò ayé.”

Ìjagunmólú Tí Ń Bọ̀

A ha lè fi ìgbọ́kànlé wo àwọn ènìyàn tí wọ́n ní agbára àti ipá ìdarí fún ìrànlọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro náà bí? Onísáàmù tí a mí sí náà kọ̀wé nínú Bíbélì pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọmọ aládé, àní lé ọmọ ènìyàn, lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.” Ta ni a wá lè gbẹ́kẹ̀ lé nígbà náà? Ìwé Mímọ́ sọ síwájú sí i pé: “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jákọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ìrètí ẹni tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀: Ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé, òkun àti ohun tí ó wà nínú wọn.”—Orin Dáfídì 146:3, 5, 6.

Gẹ́gẹ́ bí Olùṣàgbékalẹ̀ àti Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé, Jèhófà Ọlọ́run ní agbára àti ọgbọ́n tí yóò lò láti fòpin sí àrùn. Òun ha ní ìyọ́nú bí? Jèhófà ṣèlérí láti ẹnu wòlíì rẹ̀ tí ó mí sí pé: “Èmi yóò sì fi ìyọ́nú hàn sí wọn, gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń fi ìyọ́nú hàn sí ọmọ rẹ̀ tí ń sìn ín.”—Málákì 3:17, NW.

Orí tí ó kẹ́yìn Bíbélì ṣàpèjúwe ìran kan tí a fi han àpọ́sítélì Jòhánù. Ó rí “àwọn igi ìyè . . . tí ń mú irè oko méjìlá ti èso jáde, tí ń so àwọn èso wọn ní oṣooṣù.” Àwọn igi ìṣàpẹẹrẹ wọ̀nyí àti èso tí wọ́n ń so dúró fún àwọn ìpèsè àtọ̀runwá tí yóò jẹ́ kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn lè gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 22:2.

Ní títẹ̀síwájú, Jòhánù kọ̀wé pé: “Ewé àwọn igi náà . . . wà fún wíwo àwọn orílẹ̀-èdè sàn.” Àwọn ewé ìṣàpẹẹrẹ náà dúró fún àwọn ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí yóò yọrí sí ìwòsàn aráyé, nípa tí ẹ̀mí àti nípa ti ara. Nípa bẹ́ẹ̀, ó lè dá wa lójú pé nínú ayé tuntun òdodo náà, lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, a óò ṣẹ́gun ikọ́ ẹ̀gbẹ pátápátá àti títí ayérayé.—Ìṣípayá 21:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Ọlọ́run ṣèlérí ìwòsàn pátápátá fún aráyé

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́