Wíwo Ayé
Ikọ́ Ẹ̀gbẹ—“Hílàhílo Kárí Ayé”
Lọ́dọọdún ni àwọn àgbàlagbà tí ikọ́ ẹ̀gbẹ (TB) ń pa ń pọ̀ ju àwọn tí àrun AIDS, ibà, àti àpapọ̀ àwọn àrùn ilẹ̀ olóoru ń pa, ni Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé (WHO) sọ. Ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan ni ẹnì kan ń kó àrun TB ní ibì kan. Ikọ́ tàbí sísín lè ta àtaré bakitéríà àrun TB. Àjọ WHO retí pé láàárín ọdún mẹ́wàá tí ń bọ̀, 300 mílíọ̀nù ènìyàn yóò ti kó àrun TB, tí yóò sì pa 30 mílíọ̀nù ènìyàn. Èyí tí ó tún burú jù, yíyọjú tí oríṣiríṣi àrun TB tí kò gbóògùn ń yọjú ń halẹ̀ láti mú kí àrùn náà má ṣeé wò sàn. Gẹ́gẹ́ bí àjọ WHO ṣe sọ, “kìkì ìpín 5 sí 10 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ènìyàn tí wọ́n kó àrun TB ni wọ́n ń ṣàìsàn tàbí ní àkóràn náà fúnra wọn, nítorí pé ìgbékalẹ̀ ìdènà àrùn ‘ń ṣèdíwọ́ fún’ àwọn kòkòrò àrùn TB.” Bí ó ti wù kí ó rí, àjàkáyé náà le koko gan-an débi pé àjọ WHO polongo pé ó jẹ́ “hílàhílo kárí ayé”—àkọ́kọ́ irú ìpolongo bẹ́ẹ̀ nínú ìtàn àjọ WHO.
Wíwalẹ̀ Wá Sódómù àti Gòmórà
Àwọn awalẹ̀pìtàn ará Sweden kan sọ pé àwọ́n ti ṣàwárí Sódómù àti Gòmórà ìgbàanì. Ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Ohun Ìṣẹ̀m̀báyé ní Amman, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà ṣe àwárí wọn ní El Lisan, ní ìhà ìlà oòrùn Òkun Òkú, ní Jọ́dánì. Ìwé agbéròyìnjáde lédè Swedish náà Östgöta-Correspondenten, ṣàlàyé pé rírí àfọ́kù ilé tí a pa run ní nǹkan bí 1,900 ọdún ṣááju Kristi jẹ́ ohun àgbàyanu. Ó dá àwọn awalẹ̀pìtàn náà lójú pé àwọ́n ti ṣàwárí Sódómù àti Gòmórà. Lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa iṣẹ́ amọ̀, ògiri, àwọn sàréè, àti òkúta ìfiṣáná, ìparí èro wọn ni pé ìjábá àdánidá kan ló pa àwọn ìlú ńlá náà run. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló mú ìparun náà wá nítorí ìwà pálapàla bíburú jáì tí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ìlú ńlá náà.
Ewu Orin Tí Ohùn Rẹ̀ Ròkè
Ìwé ìròyin New Scientist sọ pé àwọn agbo ijó rọ́ọ̀kì lè fa etí dídi. Ògbóǹtagí nípa ìgbọ́rọ̀, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Faransé, Christian Meyer-Bisch, ṣàyẹ̀wo 1,364 ènìyàn tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún 14 sí 40, ó sì ṣàwárí pé ìpín púpọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ń lọ sí agbo rọ́ọ̀kì déédéé ń ní ìṣòro àìlègbọ́rọ̀ fún ìgbà díẹ̀. Meyer-Bisch kìlọ̀ pé nítorí òkìkí tí agbo rọ́ọ̀kì ní, àwọn ipa aṣèpalára yìí “kì í tún ṣe ìṣòro mọ́ fún ẹni náà, àmọ́, ó jẹ́ ìṣòro fún ìlera ará ìlú.”
Ìwà Burúkú Ń Pọ̀ sí I Láàárín Àwọn Obìnrin
• Ìwé agbéròyìnjáde Sunday Mail ti Brisbane ròyìn pé iye tí ń pọ̀ sí i lára àwọn ọ̀dọ́bìnrin ní Australia ní ń lo ọ̀rọ̀ àlùfààṣá. Ọ̀jọ̀gbọ́n Max Brandle, olùdarí Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Èdè Òde Òní ti Australia, ṣàlàyé pé: “A ń rí i pé ní báyìí ọtí mímu ń pọ̀ sí i láàárín àwọn obìnrin, wọ́n ń mu sìgá gan-an ju bí wọ́n ti ń ṣe tẹ́lẹ̀ rí ní ìfiwéra pẹ̀lú àwọn ọkùnrin. Wọ́n tún ń lo ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ lọ́nà púpọ̀ sí i. Ó dunni pé ìyọrísí kan ni pé díẹ̀ lára àwọn àṣà ìwà ọmọlúwàbí láàárín àwọn ọkùnrin àti obìnrin ti ń lọ sílẹ̀. Bí àwọn ẹ̀yà méjèèjì bá lo ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́, ẹ̀mí òòfà ìfẹ́ tí ó wà tẹ́lẹ̀ rí yóò pòórá kíákíá. Ọ̀rọ̀ tí ń mú òòfà ìfẹ́ wá tí àwọn ìran ìṣáájú ń lò kò ríbi gbé nínú àwùjọ ní báyìí. Mo wá rí i pé ọ̀rọ̀ rírùn wọ́pọ̀ gan-an láàárín àwọn ọ̀dọ́ lónìí.”
• Ìwọ̀n ìwà ọ̀daràn tí àwọn obìnrin ń hù ní Brazil di ìlọ́po méjì láàárín 1995. Ìwé agbéròyìnjáde O Estado de S. Paulo ròyìn ohun tí ọlọ́pàá kan, Francisco Basile, sọ pé, àwọn obìnrin púpọ̀ sí i ń lọ́wọ́ nínú ìfipá kọluni, olè jíjà, kódà nínú òwò oògùn líle pàápàá. Ọ̀pọ̀ obìnrín bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ọ̀daràn wọn nípa mímu oògùn líle crack ní àwọn ibi àríyá tí àwọn oníṣòwò oògùn líle ti ń pín oògùn líle crack lọ́fẹ̀ẹ́. Kì í ṣe pé àwọn obìnrin náà mú ìgbáralé oògùn líle dàgbà nìkan ni, ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn fúnra wọ́n máa ń di oníṣòwò oògùn líle. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde náà ṣe sọ, ọ̀gá ọlọ́pàá, Antônio Vilela, ṣàlàyé pé: “Bí iye àwọn obìnrin tí ń ta oògùn líle ti ṣe pọ̀ sí i jẹ́ ìyàlẹ́nu gbáà . . . , kò sì mọ sọ́dọ̀ àwọn ìṣọ̀wọ́ ọjọ́ orí kan pàtó.” Ọ̀pọ̀ lára wọn ló jẹ́ ọ̀dọ́bìnrin tí wọ́n lé ní 20 ọdún, àmọ́ àwọn kan ti lé ní 50 ọdún.
Àwọn Kan Tí Kì í Re Ṣọ́ọ̀ṣì Ṣì Ń Dá Gbàdúrà
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé agbéròyìnjáde The Sydney Morning Herald sọ, níbi gbogbo ni a ti ka Australia sí àwùjọ tí kì í ṣe onísìn nítorí bí iye àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì níbẹ̀ ṣe ń lọ sílẹ̀ lọ́dọọdún ju àwọn ti ibòmíràn lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ kan fi hàn pé àwọn ará Australia kan ṣì ń gbàdúrà déédéé. Ìwádìí náà fi hàn pé 1 nínú àwọn àgbàlagbà 5 ló ń gbàdúrà, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́ àti, síwájú sí i, pé ìpín 11 nínú ọgọ́rùn-ún ń gbàdúrà, ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan lọ́sẹ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Herald sọ pé, nínú ìròyìn tí Ẹgbẹ́ Ìṣèwádìí Nípa Ìsin Kristẹni ṣe lórí ìsìn ní àwọn ọdún 1990, ó ṣàlàyé pé níwọ̀n bí iye àwọn tí ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ti ń lọ sílẹ̀ lọ́nà gbígbàfiyèsí, “ọ̀pọ̀ ènìyán ní ojú ìwòye tẹ̀mí tí ń tẹ̀ síwájú nínú ìgbésí ayé wọn.”
“Ilé Iṣẹ́” Tí Ó Tóbi Ṣìkejì Lágbàáyé
Ìwé ìròyin World Health tí Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé ń ṣe jáde sọ pé, òwo fàyàwọ́ oògùn líle ń gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ pẹ̀lú iye ọjà tí ó lé ní 400 bílíọ̀nù dọ́là (U.S.) tí a ń tà lọ́dọọdún. Èyí ló mú kí ó jẹ́ “ilé iṣẹ́” tí ń yára gbèrú jù lọ lágbàáyé. Òun tún ni ilé iṣẹ́ tí ó tóbi ṣìkejì lágbàáyé—tí ó tẹ̀ lé òwò ohun ìjà, àmọ́ tí ó ṣáájú òwò epo rọ̀bì. Láàárín 30 ọdún tó kọjá, wíwà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn oògùn aláìbófinmu ti pọ̀ sí i ní ìlọ́po mẹ́fà. Ìlòkulò àwọn èròjà bíbófinmu, bíi àwọn ohun olómi, egbòogi tí a júwe, àti ọtí líle, ń pọ̀ sí i ní ìwọ̀n kan náà.
Ìbatisí fún Títà
Ṣọ́ọ̀ṣi Lutheran ti Sweden ti gbádùn ipò ìbátan Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba pẹ̀lú àkóso ìjọba fún ohun tí ó lé ní 300 ọdún. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, láìpẹ́ yìí, àwọn òṣìṣẹ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì kéde pé tí ó bá fi máa di January 1, 2000, ipò ìbátan Ṣọ́ọ̀ṣì òun Ìjọba yìí ni a óò fẹ́rẹ̀ẹ́ fòpin sí. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, gbogbo àwọn ará Sweden ń di mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì náà láti ìgbà ìbí wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, láti ìbẹ̀rẹ 1996, wọ́n ti gbé jíjẹ́ mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì karí ìbatisí. Ìwé agbéròyìnjáde Dagens Industri sọ pé bíṣọ́ọ̀bù àgbà ń kéde ètò ìtajà líle koko kan, tí yóò kan kí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa ṣe ìkésíni ní ilé ní ‘pípolówó ìbatisí.’ Ìròyín sọ pé àlùfáà obìnrin kan ní Stockholm ń ṣe “ìgbétáásì ìpolówó oníjàgídíjàgan kan” nínú èyí tí “ìbatisí ti jẹ́ ọ̀kan lára ọjà rẹ̀ tí ó tà jù lọ.” Ìwé ìròyin Må Bra sọ pé ṣọ́ọ̀ṣì àdúgbò kan yóò fún ọmọ ọwọ́ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá gbé wá fún ìbatisí ní ìwé ìsanwó-gbowó ní báǹkì pẹ̀lú àsansílẹ̀ 100 kronor (dọ́là 15, ti U.S.) owó Sweden tí a ti fi sínú rẹ̀.
Dídi Ìyá Ní Kògbókògbó
Àjọ Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Nípa Ilẹ̀ Ayé òun Ìwàláàyè Inú Rẹ̀ àti Àkójọ Ìsọfúnni Oníṣirò sọ pé ní 1994, ní Brazil, àwọn 11,457 ọmọdébìnrin tí wọn kò tí ì pé ọdún 15 ló bímọ. Irú dídi ìyá ní kògbókògbó bẹ́ẹ̀ ti fi ìpín 391 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i ní ọdún 18 tí ó kọjá, nígbà tí ìgasókè iye ènìyàn ibẹ̀ fi kìkì ìpín 42.5 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín àkókò kan náà. Iye àwọn ọmọdébìnrin tí ọjọ́ orí wọ́n wà láàárín ọdún 15 sí 19 tí wọ́n bímọ fi ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Ìwé ìròyin Veja sọ pé, Dókítà Ricardo Rego Barros ti Yunifásítì Àpapọ̀ ní Rio de Janeiro ṣàlàyé pé, “ipò àyíká, tẹlifíṣọ̀n, àwọn ìwé, àti ìwé ìròyìn ló máa ń fún ìbálòpọ̀ níṣìírí láàárín àwọn tí wọn kò tí ì gbó.” Ògbógi mìíràn sọ pé ó ṣì ṣòro fún àwọn òbí àti ilé ẹ̀kọ́ láti dá àwọn ọmọdé lẹ́kọ̀ọ́ nípa irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Tẹlifíṣọ̀n Ń Jó Rẹ̀yìn
Ìwé agbéròyìnjáde Independent ti London sọ pé, àwọn tí ń wo tẹlifíṣọ̀n máa ń fàyè gba wíwo ìbálòpọ̀ àti àwòrán ìhòòhò orí tẹlifíṣọ̀n ju bí wọ́n ti ṣe ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ṣe fún Àjọ Rédíò Ilẹ̀ Britain ṣe sọ, bí àwọn obìnrin tí wọ́n ti lé ní 40 ọdún ṣe ń fàyè gba wíwo ìbálòpọ̀ àti àwòrán ìhòhò orí tẹlifíṣọ̀n ti pọ̀ sí i. Nǹkan bí ìpín 41 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn obìnrin tí wọ́n dàgbà jù bẹ́ẹ̀ lọ ni àwọn pẹ̀lú ti wá rí irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí lórí tẹlifíṣọ̀n gẹ́gẹ́ bí èyí tí a kò jẹ́ lòdì sí. Láàárín àwọn ọ̀dọ́, nǹkan bí ìpín 75 nínú ọgọ́rùn-ún wọn ló ń fàyè gba ọ̀rọ̀ àlùfààṣá ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 69 nínú ọgọ́rùn-ún ní ẹ̀wádún kan sẹ́yìn. Ìyípadà gíga jù lọ nínú ẹ̀mí ìrònú ti jẹ́ sípa ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀. Ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin tí wọ́n ti lé ní ẹni ọdún 55, ìpín 56 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 35 sí ọdún 55, àti ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọdún 18 sí 34 ti wá ń rí àfihàn ọ̀nà ìgbésí ayé ìbẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò ṣèpalára—tí ó fi ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i láàárín ọdún mẹ́wàá tí ó kọjá.
Bíṣọ́ọ̀bú Ṣiyè Méjì Nípa Ọgbọ́n Inú Bíbélì
Nígbà tí bíṣọ́ọ̀bù ẹlẹ́kọ̀ọ́ Nestorius náà, Poulose Mar Poulose, ń sọ̀rọ̀ níbi ìpàdé àpérò kan ní India lórí “Àwọn Òfin Tí Ń Ṣàkóso Ìgbéyàwó àti Ìkọ̀sílẹ̀ Láàárín Àwọn Kristẹni,” ó sọ pé ènìyàn kò lè yíjú sí Bíbélì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ìlànà ìwà híhù. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Indian Express ṣe ròyìn ọ̀rọ rẹ̀, ó wí pé ó jẹ́ mímú ìtẹ̀síwájú tí ènìyàn òde òní ti ní nínú òye rẹ̀ nípa ipò ìbátan láàárín ọkọ àti aya lékèé bí a bá ń rin kinkin pé ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa ìkọ̀sílẹ̀ kò ṣeé yí padà. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Express ti sọ, bíṣọ́ọ̀bù náà fa ọ̀rọ̀ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsin Hindu kan yọ tí ó sọ pé gbogbo ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ ló ní ìhà méjì, ọ̀kan jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, ó sì lè dópin, tí ó jẹ́ ti èrò àwọn ènìyàn àkókò náà àti orílẹ̀-èdè tí a ti kọ wọ́n, èkejì jẹ́ èyí tí ó wà títí ayérayé, kò sì lè dópin, ó sì wúlò fún gbogbo àkókò àti orílẹ̀-èdè. Bíṣọ́ọ̀bu náà sọ pé: “Nínú Bíbélì, a gbọ́dọ̀ fìyàtọ̀ sí apá tí ó jẹ́ lájorí tí ó sì ṣe pàtàkì jù lọ. Ó yẹ kí a mọ òtítọ́ tí ó wà pẹ́ títí àti ẹ̀tanú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ . . . kí a sì pinnu ibi tí ìgbésí ayé tiwa yóò dórí kọ.”