Ẹyẹ Ìwò—Kí Ló Mú Un Yàtọ̀?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ KÁNÁDÀ
“‘Abanilẹ́rù, ògbólógbòó ẹyẹ Ìwò tí ń ríni lára, tí ń rìn kiri láti etíkun Lóròòru . . . , gbé àgógó rẹ kúrò lọ́kàn àyà mi, kí o sì jáde kúrò níyàrá mi! Ẹyẹ Ìwò dáhùn pé, ‘Láéláé pọngbá.’”—Edgar Allan Poe, “The Raven.”
TA LÓ lè retí ohun àrà ọ̀tọ̀ kankan lọ́dọ̀ ẹyẹ aláwọ̀ ràkọ̀ràkọ̀, tí ń dún bí ẹni tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ yí? Họ́wù, lójú ẹni tí kò mọ̀kan nípa àwọn ẹyẹ, adìyẹ kan tí ó tóbi ju bí ó ti sábà máa ń rí lọ lásán ló kọ́kọ́ ń jọ. Ẹyẹ ìwò kì í yára gbàfiyèsí bíi blue jay, ìbátan rẹ̀ aláwọ̀ búlúù, tó jojú ní gbèsè. Ṣàṣà ènìyàn ló sì lè ka ìró ẹyẹ ìwò sí orin, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kà á mọ́ àwọn ẹyẹ passerine, tàbí àwọn ẹyẹ kọrinkọrin. Bí ó ti wù kí ó rí, má ṣe fojú kéré ẹyẹ yìí. Ní àwọn ọ̀nà míràn, ó ní àfidípò púpọ̀ fún àìlóhùn orin dídùn àti àìnírìísí tí ó jojú ní gbèsè rẹ̀. Ẹyẹ ìwò ní ẹwà àti àmì ànímọ́ láyè ọ̀tọ̀. Ní gidi, ọ̀pọ̀ àwọn ògbòǹtarìgì nípa ẹyẹ to ẹyẹ ìwò sí àyè ọ̀tọ̀ fúnra rẹ̀.
Àwọn Àbùdá Àrà Ọ̀tọ̀
Ẹyẹ ìwò wíwọ́pọ̀ (Corvus corax) ni ó tóbi jù lọ, tí a sì buyì fún jù lọ láàárín àwọn ẹyẹ ìdílé adìyẹ (Corvidae) lódindi. Ó lè tóbi ju ìlọ́po méjì ìwọ̀n ìtóbi adìyẹ tí ó wọ́pọ̀ lọ, ó sì ń gùn tó 60 sẹ̀ǹtímítà, tí ìnà apá rẹ̀ sì ń gùn tó mítà kan. Ó yàtọ̀ sí adìyẹ tí ó wọ́pọ̀ ní ti pé, ó ní àgógó tí ó túbọ̀ tóbi àti ìrù gígùn, tí ó rí bí àáké. Àyẹ̀wò fínnífínní tún fi hàn pé ó ní àwọn ìyẹ́ ṣágiṣàgi lọ́rùn. Nígbà tí ó bá ń fò, ó lókìkí fún fífò láìlo ìyẹ́, nígbà tí àwọn adìyẹ ní ìtẹ̀sí láti lo ìyẹ́, kí wọ́n sì lu apá.
Ẹyẹ ìwò ni a kà sí ẹyẹ tí ó tóbi jù lọ tí ń bà. Bí o bá ń wo ẹyẹ ńlá yìí bí ó ṣe bà sórí igi, tí ó ń sinmi, bí kò ṣe já bọ́ yóò yà ọ́ lẹ́nu. Ó ní ọ̀gàn lílágbára kan lẹ́yìn ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan láti fi di ẹ̀ka igi tàbí èèhù ẹ̀ka mú; bí ó ti wù kí ó rí, àṣírí dídìrọ̀ pinpin mọ́ nǹkan bẹ́ẹ̀ wà nínú ìhùmọ̀ ìdèmọ́ nǹkan tí a dá mọ́ inú rẹ̀. Àwọn ẹran ara àti iṣan máa ń di àwọn ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ pọ̀ di ìkúùkù nígbà tí ẹyẹ náà bá ba mọ́lẹ̀. Ẹsẹ̀ lílágbára, tí ó sì wúlò fún gbogbo nǹkan, tí ẹyẹ ìwò ní tún bá rírìn àti híha nǹkan mu, tí ó tipa bẹ́ẹ̀ mú un gbára dì dáadáa fún ṣíṣa oúnjẹ kiri ní onírúurú ibi ìwáúnjẹ.
Àgbègbè Ibùgbé Àdánidá Ẹyẹ “Black Thunderbolt” àti Bí Ó Ṣe Ń Fò
Ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn ẹyẹ tí ó ní àgbègbè ibùgbé fífẹ̀ bíi ti ẹyẹ ìwò. Alárìnká ni ní tòótọ́. A lè rí i ní apá ibi púpọ̀ ní Àríwá Ìlàjì ayé. Ó ń gbé ní àwọn ibi tí kò jọra bí àgbègbè aṣálẹ̀; àwọn ẹgàn onígi tí kì í gbọnwé ní Kánádà àti Siberia, níbi tí ó máa ń fi àwọn èéṣẹ́ igi àti àwọn ohun mìíràn ṣe ìtẹ́ lílọ́júpọ̀ sórí àwọn igi gíga fíofío; àwọn ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkun ní Àríwá America àti Scandinavia; àti ní àgbègbè tí kò sí igi àti àwọn erékùṣù Òkun Ńlá Arctic. Ó jọ pé aginjù ni àgbègbè ibùgbé rẹ̀ tí ó wọ́pọ̀ jù lọ nítorí pé a sábà máa ń rí ẹyẹ ìwò nínú aginjù.
A lè rí àwọn àpẹẹrẹ onírúurú ibùgbé rẹ̀ ní ilẹ̀ Bíbélì, níbi tí oríṣi méjì ẹyẹ ìwò dúdú bàgùjẹ̀ ń gbé. Ọ̀kan fi gbalasa ilẹ̀ aṣálẹ̀ ìhà gúúsù ṣe ibùgbé, nígbà tí èkejì ń gbé ìhà àríwá. Àwọn ẹyẹ ìwò dúdú máa ń ṣe ìtẹ́ wọn sí àwọn ibi fífarasin inú àwọn àpáta àfonífojì tóóró tí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ dà gẹ̀ẹ̀rẹ̀. Jèhófà lo àwọn ẹyẹ ìwò láti bọ́ Èlíjà nígbà tí ó fi ara rẹ̀ pa mọ́ síbi àfonífojì odò Kẹ́rítì. (Àwọn Ọba Kìíní 17:3-6) Àkọsílẹ̀ Aísáyà nípa àwọn ẹyẹ ìwò tí ń gbé inú ‘okùn ìparun àti òkúta òfo’ Édómù tún ṣàpèjúwe irú ibi tí wọ́n ń gbé.—Aísáyà 34:11.
Àwọn ẹyẹ ìwò máa ń fò lọ́nà àgbàyanu. Ìran wọn dùn-ún wò bí wọ́n ti ń lọ sókè láìlo ìyẹ́ ní ṣíṣe ìyípo fífẹ̀, tí wọ́n ń fojú wá oúnjẹ ní àgbègbè tí ó wà nísàlẹ̀. Lọ́nà rírọrùn, wọ́n máa ń dárà lófuurufú—títàkìtì àti fífò nídoríkodò fún ìgbà díẹ̀—ní pàtàkì, nígbà eré ìfẹ́sọ́nà àti, nígbà míràn, ó lè jọ pé wọ́n ń ṣe é fún ìdárayá lásán. Bernd Heinrich ṣàpèjúwe bí ẹyẹ ìwò ṣe ń fò dáradára nínú ìwé Ravens in Winter pé: “Ó ń rà bàbà, ó sì ń yí bìrìpó bí ẹdùn ààrá dúdú kan tí ń já bọ́ láti òfuurufú, tàbí ó máa ń yára fò ṣòòròṣò láìlu apá.” Ó fi kún un pé ó jẹ́ “àfiṣàpẹẹrẹ ìṣẹ̀dá pípé nínú afẹ́fẹ́, ó sì tún ní agbára ìṣe púpọ̀ sí i.” A ti gbọ́ pé agbára tí ẹyẹ ìwò ní láti fò ni ìdí tí Nóà fi yàn án bí ẹ̀dá tí a kọ́kọ́ rán jáde láti inú ọkọ̀ áàkì nígbà Ìkún Omi náà.—Jẹ́nẹ́sísì 8:6, 7.
Olè Amárabápòmu àti Onídàánúṣe
Àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí ohun alààyè nínú ibùgbé àdánidá rẹ̀ ka ẹyẹ ìwò sí ọ̀kan lára àwọn ẹyẹ tí ń mú ara wọn bá ipò mu jù lọ, tí wọ́n sì ń lo ìdánúṣe jù lọ. Gẹ́gẹ́ bí orísun kan ṣe sọ ọ́, “ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀ lókìkí.” Ipò tó wù kí ẹyẹ ìwò bá ara rẹ̀, ó lè kojú ìpèníjà mímú ara bá ipò tí ó yí i ká mu, ní pàtàkì, bí ó bá kan ọ̀ràn oúnjẹ. Dájúdájú, àìmáa ṣàṣàyàn oúnjẹ ń ṣèrànwọ́ fún un! Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ohunkóhun tí ẹyẹ ìwò bá ti lè fèékánná mú—èso, hóró èso, kóró èso, ẹja, òkú ẹran, àwọn ẹran kéékèèké, pàǹtírí, ni yóò jẹ. Kò sì sí ohun tó gbún un nípa ibi tí ó ti rí oúnjẹ rẹ̀, kódà, ó ń gbẹ́ òjò dídì láti hú àwọn ọ̀rá àjẹkù oúnjẹ jáde nínú ipò ojú ọjọ́ tí ó tutù ju ìwọ̀n òfo lọ níhà àríwá àgbègbè ibùgbé rẹ̀. Àwọn ẹyẹ ìwò yóò tún tẹ̀ lé àwọn ọdẹ àti àwọn apẹja fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, pẹ̀lú èrò pé, àwọn yóò rí oúnjẹ jẹ́ lásìkò lọ́dọ̀ wọn lọ́nà kan ṣáá.
Àwọn ẹyẹ ìdílé Corvidae, tàbí ìdílé adìyẹ, jẹ́ ògbójú olè, kò sì yọ àwọn ẹyẹ ìwò sílẹ̀. Kò lọ́ wọn lára láti jí oúnjẹ àwọn ẹyẹ mìíràn àti ti àwọn ẹranko jẹ, a sì ti rí i pé wọ́n máa ń fẹ̀tàn jí oúnjẹ àwọn ajá jẹ. Àwọn méjì yóò máa gba ẹ̀tàn náà ṣe—ọ̀kan yóò máa pín ọkàn ajá náà níyà nígbà tí èkejì yóò máa jẹ oúnjẹ rẹ̀. Àwòrán kan tí àwọn Eskimo ilẹ̀ America yà fi ẹyẹ ìwò kan hàn, níbi tí ó ti ń jí ẹja apẹja inú omi dídì kan gbé.
Àwọn ẹyẹ ìwò ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn ìkookò, wọ́n máa ń tẹ̀ lé agbo àwọn ìkookò. Wọ́n máa ń jẹ lára ẹran tí àwọn ìkookò bá pa, ṣùgbọ́n níhìn-ín pẹ̀lú, ó jọ pé wọ́n máa ń gbádùn ìwà ìdẹ́rìn-ínpani bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìkookò, L. David Mech, ṣe àkọsílẹ̀ pé òun rí àwọn ẹyẹ ìwò tí ń tan àwọn ìkookò jẹ. Ó sọ ìtàn ẹyẹ ìwò kan tó rìn tìreratìrera lọ sọ́dọ̀ ìkookò kan tí ń sinmi, ó sọ ọ́ nírù, ó sì fò sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nígbà tí ìyẹn yánnu sí i. Nígbà tí ìkookò náà ń yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ tọ ẹyẹ ìwò ọ̀hún, ẹyẹ náà yóò jẹ́ kí ó sún mọ́ òun tó bí ẹsẹ̀ bàtà kan, kí ó tóó fò lọ. Lẹ́yìn náà, yóò tún balẹ̀ sí nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mélòó kan síwájú ìkookò náà, yóò sì tún ṣe bákan náà. Ìròyìn míràn sọ nípa ẹyẹ ìwò kan tí ń bá àwọn ọmọ ìkookò ṣeré ẹkùnmẹ́ran. Nígbà tí eré náà sú àwọn ọmọ ìkookò, ẹyẹ ìwò náà dúró, ó ń kébòòsí títí wọ́n fi tún bẹ̀rẹ̀ eré náà.
Ìwé ìròyìn Canadian Geographic ń tọ́ka sí ètò orí rédíò kan láti Yellowknife, Àwọn Àgbègbè Ìpínlẹ̀ Àríwá Ìlà Oòrùn, tí ó sọ pé àwọn ẹyẹ ìwò máa ń bà sórí páànù òrùlé dídagun ní àwọn ilé iṣẹ́ ìṣòwò, tí ó ṣe kedere pé wọ́n ń dúró níbẹ̀ láti gbọn òjò dídì sórí àwọn tí ń fẹsẹ̀ rìn kọjá lọ nísàlẹ̀ láìfura. Abájọ tí àwọn ẹ̀yà Haida ní ìwọ̀ oòrùn Kánádà fi máa ń pe ẹyẹ ìwò ní ẹlẹ́tàn!
Ọ̀rọ̀ Sísọ àti Agbára Ìkẹ́kọ̀ọ́
“Ọ̀rọ̀ èdè” ẹyẹ ìwò pọ̀ lọ́nà àràmàǹdà, ó sì jẹ́ onírúurú. Láfikún sí híhan rẹ̀ tí ń wọni lára, tí ó jinlẹ̀, tí a sì lè tètè mọ̀ jù lọ—tí a lóye pé ó jẹ́ àmì pé ìrúkèrúdò kan ń bọ̀—a ti gbọ́ pé àwọn ìró tí ó ń mú jáde ń fi jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ayọ̀, ìyanu, ìdùnnú, àti ìbínú hàn. Àwọn ẹyẹ ìwò tún lè sín àwọn ẹyẹ mìíràn, tí ohùn wọn gbà wọ́n láyè láti sín jẹ, jẹ, ní pàtàkì, wọ́n ń kọ bí àkùkọ láìsí àṣìmú.
Bí a ṣe lè kọ́ àwọn ẹyẹ ìwò lẹ́kọ̀ọ́ láti sọ̀rọ̀ tó ti jẹ́ ọ̀ràn àríyànjiyàn díẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, Candace Savage ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìròyìn nípa àwọn ẹyẹ ìwò tí a mú sìn, tí a sì kọ́ láti máa sín ìró ọ̀rọ̀ ènìyàn jẹ, nínú ìwé rẹ̀, Bird Brains. Ìtàn àtẹnudẹ́nu sọ pé akéwì náà, Edgar Allan Poe, ra ẹyẹ ìwò kan, ó sì fi sùúrù dá a lẹ́kọ̀ọ́ láti máa fi híhan onírẹ̀wẹ̀sì rẹ̀ sọ pé “láéláé pọngbá,” tí ó sún un kọ ewì rẹ̀ lílókìkí náà, The Raven, tí ó sọ nípa “ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń ṣọ̀fọ̀ ikú olólùfẹ́ rẹ̀.”
Kò sí awuyewuye rẹpẹtẹ lórí agbára ìṣe ẹyẹ ìwò láti kẹ́kọ̀ọ́. Bí a bá lè to àwọn ẹyẹ bí wọ́n ṣe ní làákàyè tó, ó jọ pé ẹyẹ ìwò ni yóò gbapò kíní. Onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè ní ibùgbé àdánidá wọn, Bernd Heinrich, sọ pé, ẹyẹ ìwò “ni a kà sí onílàákàyè jù lọ láwùjọ ẹyẹ.” Ó sọ pé “lábẹ́ àdánwò, àwọn ẹyẹ ìwò ń lo ìfòyemọ̀.” Nínú àṣedánrawò kan, ẹyẹ ìwò kan ṣàwárí bí ó ṣe lè dé ibi tí ègé ẹran kan tí a so rọ̀ gbé wà láàárín wákàtí mẹ́fà, nígbà tí àwọn ẹyẹ ìdílé adìyẹ sì ń wá ojútùú náà fún 30 ọjọ́ lẹ́yìn náà. A ti kọ́ àwọn ẹyẹ ìwò láti ka iye nǹkan. Ó ṣeé ṣe kí ìwòyemọ̀ wọn dídára jẹ́ àlékún sí ẹ̀mí gígùn wọn, nítorí pé àwọn ẹyẹ ìwò ń gbé ju 40 ọdún lọ nínú ìgbẹ́, wọ́n sì ń gbé tó 70 ọdún bí a bá fi wọ́n dọ́sìn. Dájúdájú, agbára ìṣe èyíkéyìí tí ẹyẹ ìwò bá ní ni a gbọ́dọ̀ gbóríyìn rẹ̀ fún ọgbọ́n tí Ẹlẹ́dàá rẹ̀ ní.
A mọ ẹyẹ yìí káàkiri, àwọn tí ó sì mọ àwọn ànímọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí ó ní ń bọ̀wọ̀ fún un. A lè rí i nínú àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu àwọn ènìyàn jákèjádò ayé. Àwọn òǹkọ̀wé látijọ́ àti nísinsìnyí ti mú kí ó lókìkí. (Wo àpótí, ojú ìwé 24.) Bẹ́ẹ̀ ni, ẹyẹ ìwò jẹ́ ẹyẹ kan tí ó gbàfiyèsí jù lọ. Ṣùgbọ́n nípa ẹwà rẹ̀ ńkọ́?
Ẹwà Kan Láyè Ọ̀tọ̀
Tóò, ǹjẹ́ o kò ti gbọ́ nípa ‘irun dúdú bí ẹyẹ ìwò’ rí bí? (Orin Sólómọ́nì 5:11) Ẹ̀yìn dúdú tí ń dán gbinrin pẹ̀lú àwọn ìyẹ́ elésè àlùkò òun àwọ̀ búlúù eléérú tí ń bì—wọ́n máa ń ní àwọ̀ ewé nísàlẹ̀ nígbà míràn—ni ó fi ìtúmọ̀ gidi fún orúkọ náà, “ìwò.” Fojú inú wo ẹyẹ ìwò bí ó ti ń fò sókè láìlo ìyẹ́ pẹ̀lú bí ó ti tóbi lọ́nà kíkàmàmà àti adúmáadán ìyẹ́ ara rẹ̀, tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ibùgbé àdánidá rẹ̀ ní aṣálẹ̀ tí kò lè méso jáde. Tàbí kí o finú wòye ìyàtọ̀ àárín ẹyẹ adúmáadán tí ń kọ mànà yí àti òjò dídì funfun pìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já bọ́. Àwọn ayàwòrán ti yàwòrán ẹwà ẹyẹ ìwò. Ayàwòrán Robert Bateman rántí pé: “Àgbàyanu gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ olójò dídì ní Ọgbà Yellowstone fà mí mọ́ra, ìrísí ojú ilẹ̀ tí ó dúró déédéé, tí ń mọ́kàn yọ̀, tí ó pa pọ̀ pẹ̀lú ìrísí ẹyẹ ìwò lọ́nà tí ó wọni lọ́kàn dáradára.”
Ní tòótọ́, a lè sọ pé ẹyẹ ìwò jẹ́ ẹyẹ títayọlọ́lá ní ti ẹwà, ìtàn, àgbègbè ibùgbé, fífò, ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àti àìkáàárẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]
Ẹyẹ Ìwò Nínú Ìtàn Àtẹnudẹ́nu àti Ìtàn Alákọsílẹ̀
ÌTÀN ÀTẸNUDẸ́NU:
Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu ti China, Gíríìkì, Íjíbítì, àwọn Júù, àti Siberia ń fi ẹyẹ ìwò hàn bí alásọtẹ́lẹ̀ ìjì tàbí ojú ọjọ́ tí kò dára. Bóyá irú àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu bẹ́ẹ̀ pilẹ̀ ní ìgbà Nóà àti Ìkún Omi náà.
Ẹyẹ ìwò ń ṣàpẹẹrẹ ìwàláàyè àti ìṣẹ̀dá nínú àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu ti Siberia, òun sì ni òrìṣà ìṣẹ̀dá lọ́dọ̀ àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ ní Àríwá America.
Nínú àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà, àti Europe, ẹyẹ ìwò ń ṣojú fún ikú.
ÌTÀN ALÁKỌSÍLẸ̀:
Nínú Bíbélì, ẹyẹ ìwò ní ìtayọlọ́lá ti pé òun ni ẹyẹ tí a kọ́kọ́ dárúkọ ní pàtó.—Jẹ́nẹ́sísì 8:7.
Nínú àwọn ìwé Shakespeare, ó sábà máa ń lo ẹyẹ ìwò fún títọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ ibi àti fún ohun burúkú (Julius Caesar, Macbeth, Othello), ṣùgbọ́n ó tún ń lò ó bí aṣeni-láǹfààní fún àwọn ọmọdé tí a pa tì.—Titus Andronicus, The Winter’s Tale.
Charles Dickens fi ẹyẹ ìwò hàn bí ohun apanilẹ́rìn-ín nínú Barnaby Rudge.
Nínú ewì rẹ̀, The Raven, Edgar Allan Poe so ẹyẹ ìwò pọ̀ mọ́ ìfẹ́ tí a pàdánù àti àìnírètí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
A ní ẹ̀kọ́ púpọ̀ láti kọ́ nípa ẹyẹ ìwò. Ọmọkùnrin Ọlọ́run ni ó sọ pé: “Ẹ ṣàkíyèsí dáadáa pé àwọn ẹyẹ ìwò kì í fún irúgbìn tàbí kárúgbìn, wọn kò sì ní yálà abà tàbí ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́, síbẹ̀ Ọlọ́run sì ń bọ́ wọn.” (Lúùkù 12:24) Níwọ̀n bí ibùgbé àdánidá rẹ̀ ti sábà máa ń jẹ́ ní ibi àdádó, ó ní láti máa wá oúnjẹ ní àgbègbè tí ó fẹ̀. Àwọn ìwò máa ń yan ẹ̀yà òdì kejì kan ṣoṣo jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn, wọ́n sì jẹ́ òbí tí ń fara jìn. Nígbà tí wọ́n bá ń tọ́mọ lọ́wọ́, wọ́n ní láti máa pèsè oúnjẹ déédéé kí àwọn ọmọ má baà máa kígbe nítorí ebi. Nígbà tí Jèhófà ń kọ́ Jóòbù lẹ́kọ̀ọ́ nípa ọgbọ́n tí ó wà nínú ìṣẹ̀dá, ó fi ẹyẹ ìwò kún àwọn àpẹẹrẹ tí ó lò. (Jóòbù 38:41) Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti ń pèsè fún ẹyẹ ìwò, tí Òfin Mósè kà sí aláìmọ́, ó lè dá wa lójú pé òun kì yóò kọ àwọn ènìyàn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé e sílẹ̀.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Àwọn ẹyẹ ìwò ní ojú ìwé 23 sí 25: © 1996 Justin Moore