Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe
Eeṣe ti Noa fi ran ẹyẹ ìwo ati lẹhin naa oriri kan jade ninu aaki?
Bibeli kò funni ni kulẹkulẹ alaye. Bi o ti wu ki o ri, ó jọ bii pe ọgbọ́n wà ninu igbesẹ Noa.
Fun 40 ọsan ati 40 oru, ilẹ-aye niriiri ojo rirọ ti ń bonimọlẹ, eyi ti ó ṣokunfa àkúnya ti ó bo ori awọn oke ńlá paapaa fun oṣu marun-un. Lẹhin naa “ọkọ sì kanlẹ . . . lori oke Ararati.” (Jẹnẹsisi 7:6–8:4) Ọpọlọpọ oṣu lẹhin naa, lẹhin ti “ori awọn oke nla han,” Noa “rán ìwo kan jade, ti o fò jade lọ kaakiri.”—Jẹnẹsisi 8:5, 7.
Eeṣe ti o fi jẹ ìwo? Ẹyẹ yii jẹ ẹyẹ ti ó lè fò daradara, ó sì lè wà laaye niṣo pẹlu ọgọọrọ oniruuru ohun jijẹ, ti ó ni ẹran-ara òkú ninu. Noa lè ti rán ìwo jade lati rí yala yoo pada wá tabi yoo lọ jinna si aaki naa, boya ni jíjẹ lara iyooku ẹ̀kùrẹ̀ ti o ṣí sí gbangba gẹgẹ bi omi naa ti fà ti ilẹ sì farahan. Bi o ti wu ki o ri, ìwo naa kò duro sọhun-un. Bibeli wi pe ó pada, ṣugbọn kò sọ pe ó pada tọ Noa lọ. Boya ó pada lati sinmi lori aaki naa laaarin akoko fífò lati wá ounjẹ ti ń léfòó loju omi ti ó ṣì gbalẹ̀ sibẹ.
Lẹhin naa, Noa yàn lati ran oriri kan jade. A kà pe: “Ṣugbọn oriri kò ri ibi isinmi fun atẹlẹsẹ rẹ̀, o si pada tọ̀ ọ́ lọ ninu ọkọ̀.” (Jẹnẹsisi 8:9) Eyi damọran pe ni ọna tirẹ, oriri naa lè ṣiṣẹsin ni pipinnu yala àkúnya-omi naa ti fà. Awọn oriri fi igbẹkẹle pupọ han ninu eniyan. Noa lè reti pe oriri yoo pada, kii ṣe kiki lati sinmi lori aaki naa nikan, ṣugbọn wá sọdọ Noa funraarẹ.
A sọ pe awọn oriri ń bà sori ilẹ gbigbẹ nikan, a sì mọ wọn fun fífò rẹlẹ ni awọn afonifoji, wọn sì ń jẹ awọn eweko. (Esikiẹli 7:16) Grzimek’s Animal Life Encyclopedia ṣakiyesi pe: “Gẹgẹ bi o ti jẹ́ otitọ nipa gbogbo ẹyẹle ati oriri ti ń jẹ eso ati ẹ̀pà, iṣoro jijẹ wà nigba ti ojo dídì [tabi omi] bá bolẹ ti ó sì wà titi ju ọjọ kan lọ, ọpọjulọ ounjẹ wọn ti ó ṣeeṣe jẹ́ eyi ti ó wà lori ilẹ.” Nitori naa oriri lè mu ẹ̀rí diẹ wá fun Noa pe oun ti rí ilẹ gbigbẹ tabi awọn eweko ti ń rú. Ìgbà akọkọ ti Noa rán an jade, oriri naa wulẹ pada tọ̀ ọ́ wa ninu aaki naa. Ìgbà keji, oriri naa pada pẹlu ewe olifi kan. Ìgbà kẹta, kò pada, ni fifi ẹ̀rí han pe kò séwu fun Noa ó si ṣeeṣe fun un lati fi aaki naa silẹ.—Jẹnẹsisi 8:8-12.
Nigba ti awọn kan lè ka iwọnyi si kulẹkulẹ ṣiṣe kòńgẹ́, otitọ naa pe akọsilẹ naa ṣe pàtó gan-an, laisi ìlàkàkà lati funni ni awọn alaye pipe perepere, fi ìṣeegbagbọ Bibeli han. Ó fun wa ni afikun idi lati gba akọsilẹ naa pe, kii ṣe eyi ti a humọ tabi dọgbọn gbekalẹ, ṣugbọn eyi ti ó péye lọna ailabosi. Aisi awọn kulẹkulẹ okodoro ati alaye tun damọran awọn ohun gbigbadunmọni ti awọn Kristẹni oluṣotitọ lè fojusọna fun lati beere lọwọ Noa nigba ti a bá jí i dide ti o sì lè ṣalaye kulẹkulẹ igbesẹ rẹ̀ funraarẹ.—Heberu 11:7, 39.