Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìráragbaǹkan Ẹni ọdún 22 ni mí, mo sì fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Ìráragbaǹkan—Ayé Ha Ti Tàṣejù Bọ̀ Ọ́ Bí?” (January 22, 1997) Àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni ní láti kojú ọ̀pọ̀ ipò tí ó ṣòro. Àwọn àpilẹ̀kọ wọ̀nyí fún mi níṣìírí láti má ṣe máa ṣàṣejù, ó sì fún ìpinnu mi láti sin Jèhófà lókun lójú àwọn pákáǹleke ayé.
M. B., Ítálì
Ẹyẹ Ìwò Mo fẹ́ràn àpilẹ̀kọ tó kún fún ẹ̀kọ́ náà, “Ẹyẹ Ìwò—Kí Ló Mú Un Yàtọ̀?” (January 8, 1997) Ọmọ ọdún 18 ni mí, wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà mí síṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ aláàbọ̀ àkókò nínú ìmọ̀ nípa ohun alààyè ní ibùdó ìṣèwádìí nípa irúgbìn àti ẹranko igbó ni. Àwọn ẹyẹ ìwò méjì tí wọ́n rẹwà wà lára àwọn ohun alààyè tí a ń tọjú. Mo rí i pé bí àpilẹ̀kọ yín ṣe ṣàpèjúwe wọn gẹ́lẹ́ ni wọ́n rí—wọ́n ní làákàyè gan-an. Mo ń wéwèé láti fún àwọn alájọṣiṣẹ́ mi ní àpilẹ̀kọ náà kà.
J. C., United States
Òtítọ́ ni àwọn ìsọfúnni tí ẹ pèsè, wọ́n sì dùn mọ́ni. Níhìn-ín ní ọgbà yunifásítì tí mo wà ní Gánà, a mọ̀ dájú pé àwọn ẹyẹ ìdílé adìyẹ jẹ́ olè. A ní àkọsílẹ̀ pé àwọn adìyẹ tí wọ́n wà níhìn-ín lè jí ohunkóhun—láti orí ẹja sí ọṣẹ. A tilẹ̀ ti ròyìn pé àwọn adìyẹ kan ṣí páànù ìsebẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan, wọ́n sì fi oúnjẹ wọn jẹ!
F. A. A., Gánà
Adùn Ilé Ìgbọ́únjẹ Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Ilé Ìgbọ́únjẹ Lè Gbádùn Mọ́ni.” (January 8, 1997) Èmi pẹ̀lú ti jàǹfààní láti inú àwọn ìjíròrò tó ń wáyé nínú ilé ìgbọ́únjẹ. Nígbà tí a bá ń bó àlùbọ́sà àti ọ̀dùnkún, màmá mi máa ń kọ́ mi láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì máa ń fún mi níṣìírí láti sìn ín ní kíkún. Àwọn ìjíròrò yìí nínú ilé ìgbọ́únjẹ ti ṣàǹfààní ní pàtàkì lákòókò ìṣòro kan tí bàbá mi lòdì sí wa ní ti ìsìn. Nísinsìnyí, èmi àti màmá mi ní ayọ̀ ti rírí i tí bàbá mi di ìránṣẹ́ Jèhófà. Bákan náà, mo ti kọ́ bí a ṣe ń se onírúurú oúnjẹ aládùn!
A. M. M., Ítálì
Mo ń ṣiṣẹ́ agbọ́únjẹ fún ọ̀gá mi tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ ìferédáni-lárayá. Mo ti tipa bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní púpọ̀ láti ṣàjọpín oúnjẹ tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn àlejò—títí kan àwọn gbajúgbajà ènìyàn—nígbà tí mo bá ń ṣiṣẹ́ nínú ilé ìgbọ́únjẹ. Mo kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì díẹ̀ sínú àpótí tí a ń fà jáde lára tábìlì ilé ìgbọ́únjẹ. Ní ìgbà kan, mo bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò Bíbélì pẹ̀lú àlejò kan. Ó pa dà wá sínú ilé ìgbọ́únjẹ fún ìjíròrò síwájú sí i. Nígbà tí èmi ń yan adìyẹ kan, òun ń ka ẹ̀dà ìwé náà, Revelation—Its Grand Climax At Hand!, mi sókè. Bẹ́ẹ̀ ni, òtítọ́ lẹ sọ. Ilé ìgbọ́únjẹ lè gbádùn mọ́ni!
A. R., United States
Jíjẹ́wọ́ Àwọn Ẹ̀ṣẹ̀ Mo ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ìjọ, mo sì fẹ́ láti fi ìmọrírì mi hàn fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ó Ha Yẹ Kí N Jẹ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Mi Bí?” (January 22, 1997) Àpilẹ̀kọ yìí sún àwọn èwe mélòó kan láti jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan tí wọ́n ti dá ní àwọn ìgbà kan sẹ́yìn. Ohun ayọ̀ ló jẹ́ láti rí i pé lẹ́yìn rírí ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ gbà, àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí tún ipò ìbátan wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣe. Wọ́n pinnu láti máa wà ní mímọ́ tónítóní.
O. B., Ítálì
Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti mọ̀ pé dídákẹ́ lè pani lára. Jíjẹ́wọ́ lè fa ìtìjú, kí ara sì tini, àmọ́ tí o bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ fún Jèhófà àti fún àwọn òbí rẹ, ìwọ yóò ní ipò ìbátan pẹ́kípẹ́kí, tí ó lágbára, pẹ̀lú wọn.
B. K., Guyana
Àpilẹ̀kọ náà dé nígbà tí mo nílò rẹ̀ gẹ́lẹ́. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé mo ní láti sọ ohun tí mo ti ṣe fún àwọn òbí mi àti àwọn alàgbà ìjọ. Mo nímọ̀lára bíi pé èmi ni wọ́n kọ àpilẹ̀kọ náà fún. Nígbà tí mo wá sọ nípa àwọn ìṣòro mi fún wọn níkẹyìn, ara tù mí gidigidi!
A. A., United States