ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 10/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kò Sí Egbòogi “Àjídèwe”
  • Àkọ́kọ́ Ẹranko Afọ́mọlọ́mú Alájọpín Ànímọ́ Jíjọra
  • Ṣọ́ra fún Másùnmáwo!
  • Òròmọdìyẹ Orí Kọ̀ǹpútà
  • Kíkó Ọmọdé Nífà
  • A Ṣàwárí Ìrútúú Ohun Tí Ń Gbógun Ti Nǹkan Mìíràn
  • Ohun Tí Ń Lé Erin Sá
  • Fífimú-Kéèéfín Lè Pani
  • Irúgbìn Ọjọ́ Iwájú Kẹ̀?
  • A Di Ẹ̀bi Ikọ́ Fée Ọmọdé Ru Aáyán
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Eyín Erin—Báwo Ló Ṣe Níye Lórí Tó?
    Jí!—1998
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 10/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Kò Sí Egbòogi “Àjídèwe”

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ipò ọjọ́ ogbó náà, Andréa Prates, ṣe wí, lílo àwọn egbòogi àṣà tó lòde kí a lè máa wà ní ọ̀dọ́ nìṣó, bíi lílo àwọn èròjà omi ìsúnniṣe àtọwọ́dá kan, lè “ṣàǹfààní kan tàbí òmíràn, ṣùgbọ́n ó tún lè ṣe ìpalára púpọ̀ fún ìlera rẹ.” Dókítà Prates dámọ̀ràn pé “àwọn àṣà ìhùwà tuntun gbéṣẹ́ ju àwọn egbòogi tuntun lọ” nínú ìgbógunti-dídarúgbó. Ìwé ìròyìn Superinteressante ti Brazil sọ pé, lára àwọn àṣà rere tí ó lè ṣàlékún ẹ̀mí gígùn ni sísun oorun púpọ̀ tó, níní ìfọkànbalẹ̀, nínà àti ṣíṣe eré ìmárale níwọ̀ntúnwọ̀nsì, lílo ara ẹni dé góńgó ní ti èrò orí, àti yíyẹra fún ọ̀rá. Ó tún ṣe pàtàkì láti máa jẹ àwọn fítámì àti àwọn èròjà mineral tí a ń rí nínú àwọn èso àti ewébẹ̀. Gbogbo sẹ́ẹ̀lì inú ara ni dídarúgbó ń kàn, lílo èròjà kan ṣoṣo kò sì lè ṣàǹfààní fún gbogbo ẹ̀yà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ inú ara lẹ́ẹ̀kan náà.

Àkọ́kọ́ Ẹranko Afọ́mọlọ́mú Alájọpín Ànímọ́ Jíjọra

Àwọn olùwádìí ní Scotland mi ayé jìgì ní apá ìparí oṣù February, nígbà tí wọ́n kéde pé àwọn ti mú ọ̀dọ́ àgùntàn alájọpín ànímọ́ jíjọra kan jáde láti inú ásíìdì DNA àgbà àgùntàn kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti ń mú àwọn sẹ́ẹ̀lì ọlẹ̀ alájọpín ànímọ́ jíjọra jáde láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, títí di báyìí, ọ̀pọ̀ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti rò pé mímú ìbejì apilẹ̀ àbùdá àgbà ẹranko afọ́mọlọ́mú jáde kò lè ṣeé ṣe. Àwọn olùwádìí náà sọ pé, ní ti àbá tí a kò ì fi dánra wò, a lè lo ọ̀nà kan náà fún ẹ̀dá ènìyàn—pé a lè fi ásíìdì DNA tí a mú láti ara àgbàlagbà ènìyàn kan ṣèmújáde ìbejì kan tí ó jọra ní ti apilẹ̀ àbùdá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò dàgbà bákan náà. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde International Herald Tribune ṣe sọ, Ian Wilmut, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó jẹ́ aṣáájú fún ìdáwọ́lé náà, ka èrò náà sí ohun tí kò ṣètẹ́wọ́gbà ní ti ìlànà ìwà híhù. Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association ròyìn pé Àjọ Ìlera Àgbáyé fara mọ́ ọn, ní kíkẹ̀yìn sí ṣíṣe ẹ̀dà ènìyàn alájọpín ànímọ́ jíjọra gẹ́gẹ́ bí ‘oríṣi àṣejù àṣedánrawò’ kan.

Ṣọ́ra fún Másùnmáwo!

Ìwé ìròyìn Veja sọ pé: “Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ará Brazil ń fojoojúmọ́ ayé kojú másùnmáwo.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn wọ̀nyí lè rò pé ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára fún àkókò gígùn jẹ́ àfihàn ìjáfáfá àwọn, ṣùgbọ́n ìhùwàsí yìí lè léwu. Ọ̀mọ̀wé Marilda Lipp ti Yunifásítì Pontifical Catholic ṣàlàyé pé: “Òṣìṣẹ́ kan ń ṣe dáradára gan-an nígbà tí másùnmáwo rẹ̀ bá mọ ní ìwọ̀n tó bọ́gbọ́n mu, ṣùgbọ́n ó ń dé ògógóró ohun tí ó lè ṣe nígbà tí ó bá ré kọjá ààlà rẹ̀ láìmọ̀. Lábẹ́ pákáǹleke gidi, ẹ̀dá ènìyàn ń ṣiṣẹ́ dáradára gan-an fún àkókò díẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wulẹ̀ ń wó ni.” Ìròyìn náà sọ pé, àwọn tí ń ṣòro fún láti pínṣẹ́ fúnni ń kojú másùnmáwo púpọ̀ jù. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀mọ̀wé Lipp ṣe sọ ọ́, másùnmáwo tó pọ̀ jù lọ ń wà fún àwọn tí “ó ṣòro fún láti sọ ìmọ̀lára wọn jáde, tí wọ́n lè bú nígbà tí wọ́n bá ní pákáǹleke, kí wọ́n sì wá máa sapá láti máa ṣe jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, kí wọ́n sì máa hùwà dáadáa, lẹ́yìn náà.”

Òròmọdìyẹ Orí Kọ̀ǹpútà

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, ìwé agbéròyìnjáde Asahi Evening News ròyìn pé, àwọn òròmọdìyẹ orí kọ̀ǹpútà ti di àṣà tó lòde ní orílẹ̀-èdè Japan. Ohun ìṣiré tó ní ìrísí ẹyin náà máa ń fi òròmọdìyẹ kan hàn ní ìpele ìdàgbàsókè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lójú gọgọwú. Tẹ bọ́tìnnì kan, òròmọdìyẹ kan yóò sì jáde láti inú ẹyin rẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ́jú márùn-ún. “Òròmọdìyẹ” náà yóò wá dún ìdún ìkìlọ̀ kan kí ẹni tó ni ín náà lè “bọ́” ọ, kí ó sì bójú tó àwọn àìní rẹ̀ míràn nípa títẹ onírúurú bọ́tìnnì. Ó lè dún ìdún ìkìlọ̀ nígbàkigbà, kódà, lóru pàápàá. Ìkùnà láti dáhùn pa dà lè yọrí sí “ikú” òròmọdiyẹ náà láìtọ́jọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan, òròmọdìyẹ náà á kú. O lè wá tún ìgbékalẹ̀ ohun ìṣiré náà ṣe sípò, kí ó lè “bí” òròmọdìyẹ mìíràn, tí ànímọ́ ìwà rẹ̀ yàtọ̀. Ìròyìn sọ pé àwọn kan ní ìmọ̀lára ìsúnmọ́ra tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òròmọdìyẹ orí ẹ̀rọ wọn bí wọ́n ti ní in pẹ̀lú ọmọ kan. Dókítà kan tilẹ̀ sọ nípa òròmọdìyẹ rẹ̀ pé: “Mo banú jẹ́ nígbà tí ó kú ju bí mo ti banú jẹ́ tó nígbà tí aláìsàn kan tí mo ń tọ́jú kú lọ.”

Kíkó Ọmọdé Nífà

Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin sọ pé: “Nǹkan bíi mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọdé kárí ayé ni a gbà gbọ́ pé wọ́n jẹ́ òjìyà òwò ìbálòpọ̀.” Oríṣi bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe tí ẹgbẹ́ ń ṣètò bẹ́ẹ̀, tí ó ti gbilẹ̀ ní àwọn apá kan ilẹ̀ Éṣíà, ti ń pọ̀ sí i nísinsìnyí ní America. Rodrigo Quintana, ògbóǹtagí kan tí ń bá Àjọ Inter-American Institute of the Child ṣiṣẹ́, sọ pé, ìṣòro yìí ti gbilẹ̀ gidigidi ní Latin America láàárín ẹ̀wádún tó kọjá yìí. Àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò tí Quintana tọ́ka sí fi hàn pé ẹgbẹẹgbàárùn-ún àwọn ọmọdé aláìtójúú-bọ́ jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè Latin America ní ń ṣe aṣẹ́wó báyìí.

A Ṣàwárí Ìrútúú Ohun Tí Ń Gbógun Ti Nǹkan Mìíràn

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times ròyìn pé láìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ ìrísí àti ohun tó para pọ̀ di ẹ̀dá ojú sánmà ṣàwárí ìrútúú ohun tí ń gbógun ti nǹkan mìíràn tó gùn tó 3,500 ọdún ìmọ́lẹ̀, tí ń tú jáde láti àárín gbùngbùn ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wa, Milky Way. Ohun tí ń gbógun ti nǹkan mìíràn máa ń ní àwọn pátíkù tí ó rí bí nǹkan gidi fúnra rẹ̀, àfi ti pé wọ́n ní agbára ìmúnáwá òdì. Bí wọ́n bá fara kanra pẹ̀lú nǹkan náà lásán, yóò yọrí sí ìparun tọ̀túntòsì, ó sì ń tú ìtànṣán gamma lílágbára dà sílẹ̀, tí ó ní agbára pàtó kan. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ pé ìrútúú eléèéfín gígùn gbọọrọ náà jẹ́ ohun tí ń gbógun ti nǹkan mìíràn nípa yíyí sátẹ́láìtì Ìwòtànṣán-Gamma ti Compton bá ìpele agbára yẹn mu. Ní ti ipa tí ìrútúú eléèéfín gígùn gbọọrọ náà ní, “àwọn onímọ̀ ìrísí àti ohun tó para pọ̀ di ẹ̀dá ojú sánmà náà sọ pé kò wu Ilẹ̀ Ayé léwu, ìrísí ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí wọ́n ní lọ́wọ́ nìkan ló kàn.”

Ohun Tí Ń Lé Erin Sá

Loki Osborn, onímọ̀ nípa ẹranko ní Yunifásítì Cambridge, sọ pe: “Ní Éṣíà, àwọn erin ń ba irè oko tí owó rẹ̀ to ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là jẹ́ lọ́dọọdún.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn New Scientist ṣe sọ, àwọn erin ilẹ̀ Áfíríkà pẹ̀lú ń fà mọ́ orísun oúnjẹ yìí síwájú sí i. Látayébáyé, àwọn àgbẹ̀ ti gbìyànjú láti lé àwọn ẹranko náà sá nípa lílu ìlù tàbí jíju òkò. Osborn sọ pé wọ́n ti yìnbọn pa ọ̀pọ̀ erin, “ṣùgbọ́n èyí kò ṣèdíwọ́ púpọ̀ fún bíba irè oko jẹ́ náà.” Osborn àti olùhùmọ̀ kan gbà gbọ́ pé àwọn ti rí ojútùú kan tó sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ: agolo ìfúnǹkan tí ó ní nǹkan bíi kìlógíráàmù kan ata òun òróró tí ó ṣeé fún sítòsí ibi tí erin náà bá wà. Ó sọ pé imú gígùn tí erin ní jẹ́ ọ̀kan lára àwọn imú tí ń yára gbóòórùn jù lọ láwùjọ ẹranko. Nígbà ìfidánrawò ní Zimbabwe, “àwọn erin náà yóò kọ́kọ́ séra ró, lẹ́yìn náà ni wọn yóò fun imú wọn kí wọ́n tó yára kúrò níbẹ̀.” Ìròyìn náà sọ pé ata náà kì í fa ìpalára wíwàpẹ́títí kankan.

Fífimú-Kéèéfín Lè Pani

Ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Good Housekeeping ti United States sọ pé: “Fífimú-kéèéfín,” èéfín tí ń wá láti inú sìgá tí àwọn mìíràn ń mu, “ló ń fa ikú ènìyàn tí ó lé ní 50,000 tí àrùn ọkàn àyà àti àrùn òpójẹ̀ àlọ ń pa lọ́dọọdún.” Ní àfikún sí i, àwọn tí kì í mu sìgá, tí wọ́n ń fìgbà púpọ̀ wà ní àyíká tí àwọn mìíràn ti ń mu ún ń wà nínú ewu níní àrùn gbọ̀fungbọ̀fun àti òtútù àyà gan-an, wọ́n sì ń wà nínú ewu níní onírúurú àrùn jẹjẹrẹ gan-an. A kì í ka òórùn tí kò bára dé tí ń wà nínú iyàrá kan fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ lẹ́yìn tí ẹnì kan ti mu sìgá níbẹ̀ sí ewu. Bí ó ti wù kí ó rí, àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Àwọn iyàrá tó kún fún èéfín lè ní ìbafẹ́fẹ́jẹ́ tí ó fi ìlọ́po mẹ́fà pọ̀ ju ti òpópó tí ọkọ̀ ti ń lọ tí ó sì ń bọ̀ nígbà gbogbo lọ. Ó tún sọ pé “ìdámẹ́jọ gbogbo àwọn tí sìgá mímu ń pa ló jẹ́ àbáyọrí fífimú-kéèéfín.”

Irúgbìn Ọjọ́ Iwájú Kẹ̀?

Ìwé ìròyìn The UNESCO Courier sọ pé ọparun pọ̀ kítikìti ní àyíká agbedeméjì ayé kí àwọn agbókèèrè-ṣàkóso tó gé e lulẹ̀ láti rí ilẹ̀ fi dáko. Ní Áfíríkà nìkan, 1,500 oríṣiríṣi ọparun ló wà. Irúgbìn náà ní onírúurú ìlò tó yàtọ̀ síra. Nítorí tí ó ní agbára láti lẹ̀ ju irin lọ, ó dára ta yọ gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìkọ́lé. Àwọn ilé alájà-mẹ́ta kan tí a fi ọparun kọ́ ní Colombia ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún, a sì ń lò wọ́n síbẹ̀. Ọparun tún wúlò fún fífi rọ nǹkan olómi, fífidáná, àti ọ̀pọ̀ ìwúlò míràn. Ọ̀mùnú ọparun sábà máa ń wà nínú àwọn oúnjẹ àwọn ará China àti àwọn ará Japan. A lè ti fojú tín-ínrín àwọn ànímọ́ rere tí ọparun ní látijọ́. Ṣùgbọ́n àwọn ànímọ́ rẹ̀ wíwúlò àti ìyáradàgbà rẹ̀—ó máa ń gbó láàárín ọdún márùn-ún péré—ń mú kí àwọn kan máa fi ojú ọ̀tun wò ó bí “irúgbìn tí ó ṣeé sọ dọ̀tun fún ọjọ́ iwájú.”

A Di Ẹ̀bi Ikọ́ Fée Ọmọdé Ru Aáyán

Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde New York Daily News ṣe sọ, ìwádìí ọlọ́dún márùn-ún kan tí Ibùdó Ìlera Orílẹ̀-Èdè United States ṣe ń di ẹ̀bi ikọ́ fée ọmọdé tí ń pọ̀ sí i láàárín àwọn ọmọdé tí ń gbé àárín gbùngbùn ìlú ńlá ọlọ́pọ̀ èrò ru aáyán. Lára 1,528 ọmọdé oníkọ́-fée tí a fi ṣèwádìí náà ní ìlú ńlá méje, ìpín 37 nínú ọgọ́rùn-ún ni aáyán jẹ́ èèwọ̀ ara wọn. Ó ṣeé ṣe kí àkókò tí àwọn tó ní èèwọ̀ ara náà, tí wọ́n sì ní ọ̀pọ̀ aáyán níyàrá tí wọ́n ń sùn, yóò fi gbé ilé ìwòsàn fi ìlọ́po mẹ́ta ju ti àwọn ọmọdé oníkọ́-fée míràn lọ. Dókítà David Rosenstreich, olórí iṣẹ́ ìwádìí náà, fún gbígbógunti-aáyán nípa lílo ìkẹ́kùn, oògùn apakòkòrò, ásíìdì boric, àti ìmọ́tónítóní níṣìírí. Ó wí pé fífi ẹ̀rọ afafẹ́fẹ́-fàdọ̀tí fa ìdọ̀tí kúrò nínú ilé pátápátá lè palẹ̀ gbogbo ìyàgbẹ́ aáyán tó wà nínú erukuru mọ́. Dókítà Rosenstreich ṣàfikún pé: “O ní láti palẹ̀ gbogbo orísun oúnjẹ àti omi mọ́, ní pàtàkì, àwọn ibi tí omi ti ń jò tàbí tí ó ti ń kán. Àwọn aáyán gbọ́dọ̀ mumi kí wọ́n lè wà láàyè.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́