ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 143
  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣe Bíbélì sọ ohunkóhun nípa mímu igbó àbí àwọn oògùn olóró míì?
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
    Jí!—1996
  • Àwọn Ewu Wo Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Sìgá Mímu?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Tí mo bá ń mu sìgá tàbí àwọn nǹkan tí wọ́n fi tábà ṣe ǹjẹ́ ó tiẹ̀ kan Ọlọ́run?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 143
Ẹnì kan ń mu sìgá

Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa sìgá mímua kò sì mẹ́nu kan àwọn nǹkan míì táwọn èèyàn máa ń mu lónìí. Àmọ́ àwọn ìlànà kan wà nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀ṣẹ̀ ni tẹ́nì kan bá ń mu sìgá, Ọlọ́run ò fọwọ́ sí i, àṣà tí kò dáa ni, ó sì máa ń sọ èèyàn di ẹlẹ́gbin.

  • Ọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí. “Ọlọ́run . . . fún gbogbo ènìyàn ní ìyè àti èémí.” (Ìṣe 17:24, 25) Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀mí, torí náà kò yẹ ká ṣe ohun tó máa pa ẹ̀mí yẹn lára, irú bí i ká máa mu sìgá. Ká sọ pé àwọn èèyàn lè jáwọ́ nínú sìgá mímu ni, àwọn èèyàn tó ń kú níbi gbogbo láyé máa dín kù.

  • Ìfẹ́ aládùúgbò. “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Ẹni tó bá ń mu sìgá níbi táwọn míì wà ò fìfẹ́ hàn. Àwọn tó máa ń fa èéfín sìgá símú níbi tẹ́nì kan ti ń mu sìgá máa ń ní àwọn àìsàn kan náà tí ẹni tó máa ń mu sìgá máa ń ní.

  • Ìdí tó fi yẹ ká jẹ́ mímọ́. “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà.” (Róòmù 12:1) “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí, kí a máa sọ ìjẹ́mímọ́ di pípé nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run.” (2 Kọ́ríńtì 7:1) Sìgá ò dáa fún ara, ẹni tó bá sì ń mu ú ò lè jẹ́ mímọ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ máa di ẹlẹ́gbin, torí pé ńṣe làwọn tó ń fa sìgá ń mọ̀ọ́mọ̀ fa àwọn nǹkan tó máa ṣe ìpalára fún wọn sínú ara wọn.

Ṣe Bíbélì sọ ohunkóhun nípa mímu igbó àbí àwọn oògùn olóró míì?

Bíbélì ò dárúkọ igbó tàbí àwọn oògùn olóró míì. Àmọ́, ó fún wa láwọn ìlànà tó jẹ́ ká mọ̀ pé kò dáa kéèyàn máa mu àwọn nǹkan tó máa ń di bárakú fún èèyàn. Yàtọ̀ sí àwọn ìlànà tá a ti mẹ́nu bà tẹ́lẹ̀, àwọn ìlànà míì wà tó kan ọ̀rọ̀ yìí:

  • Ìdí tó fi yẹ ká lo agbára ìrònú wa. “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run . . . pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37, 38) “Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́ lọ́nà pípé pérépéré.” (1 Pétérù 1:13) Èèyàn ò lè lo ọpọlọ ẹ̀ bó ṣe yẹ tó bá ń lo àwọn oògùn nílòkulò, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló sì ti di bárakú fún. Dípò kí wọ́n máa ro àwọn èrò tó máa ṣe èèyàn láǹfààní bí wọ́n ṣe máa rí oògùn tí wọ́n fẹ́ mu ló máa gbà wọ́n lọ́kàn.​—Fílípì 4:8.

  • Ìgbọràn sí òfin ìlú. “Jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ.” (Títù 3:1) Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, òfin ò gba àwọn èèyàn láyè láti lo àwọn oògùn olóró kan. Tá a bá fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn, ó yẹ ká máa ṣègbọràn sáwọn aláṣẹ.​—Róòmù 13:1.

Ìlera Rẹ

Àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìlera lágbàáyé ìyẹn World Health Organization ṣírò pé lọ́dọọdún, nǹkan bí i mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn ló ń kú lọ́dọọdún nítorí sìgá mímu, yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600,000] tí kì í mu sìgá ni èéfín sìgá ti pa. Ẹ jẹ́ ká wo bí sìgá mímu ṣe máa ń ṣèpalára fún ìlera àwọn tó ń mu ún àtàwọn tó wà láyìíká wọn.

Àrùn jẹjẹrẹ. Àwọn kẹ́míkà tó lè ṣe ìpalára tó wà nínú sìgá ju àádọ́ta [50] lọ. Encyclopædia Britannica sọ pé, “ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó ní àrùn jẹjẹrẹ inú ọ̀fun ló jẹ́ pé sìgá ló fà á.” Sìgá lè fa jẹjẹrẹ fún àwọn ibòmíì nínú ara, irú bí ẹnu, kòmóòkun, ihò ọ̀fun, ọ̀fun, gògóńgò, ẹ̀dọ̀, àmọ́ àti ilé ìtọ̀.

Ààrùn Tí Kì Í Jẹ́ Kéèyàn Mí Dáadáa. Ó máa rọrùn fún ẹni tó ń mu sìgá láti ní àwọn àìsàn bí òtútù àyà àti ọ̀fìnkìn. Táwọn ọmọdé bá sì ń fa èéfín sìgá símú déédéé, wọ́n máa ní ikọ́ fée, ikọ́ tó le gan-an, ẹ̀dọ̀fóró wọn ò sì ní ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

Àrùn Ọkàn. Àwọn tó máa ń mu sìgá máa ń tètè ní àrùn ọkàn tàbí àrùn rọpá rọsẹ̀. Afẹ́fẹ́ Carbon monoxide tó máa ń jáde nínú sìgá máa ń gba ẹ̀dọ̀ fóró wọnú ẹ̀jẹ̀, á sì rọ́pò afẹ́fẹ́ oxygen. Tí ò bá sì sí oxygen tó pọ̀ tó nínú ẹ̀jẹ̀, ọkàn máa ṣiṣẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ kí oxygen bàa lè dé ibi tó yẹ nínú ara.

Àwọn aboyún. Táwọn obìnrin bá ń mu sìgá nígbà tí wọ́n wà nínú oyún, ọmọ tí wọ́n máa bí lè jẹ́ aláàbọ̀ ara, ọmọ náà lè fúyẹ́, ètè ọmọ náà sì lè là sí méjì tàbí kí nǹkan míì ṣẹlẹ̀ sí i. Àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ lè ní àìsàn tí kò ní jẹ́ kí wọ́n lè máa mí dáadáa, ó sì lè kú ní kékeré.

a Sìgá Mímu tá à ń sọ níbí ń tọ́ka sí àwọn tó ń mu ewé tábà, sìgá, ìkòkò. Àmọ́, àwọn ìlànà Bíbélì tá a máa gbé yẹ̀ wò níbí tún kan àwọn tó máa ń mu sìgá ìgbàlódé tó ń lo bátìrì tàbí àwọn tó ń jẹ ewé tábà tàbí tó ń fín áṣáà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́