ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/22 ojú ìwé 21-24
  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Gbé Ìkálọ́wọ́kò Lé E
  • Àwọn Ọmọdé—Àwọn Òjìyà Tí Kò Láàbò
  • Ojú Ìwòye Tí Ó Yí Padà
  • Títà Á Sílẹ̀ Òkèèrè
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Láti Jáwọ́ Nínú Sìgá Mímu?
    Jí!—2000
  • Ṣé Ẹ̀ṣẹ̀ Ni Kí Èèyàn Mu Sìgá tàbí Igbó?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ojú Wo ni Ọlọ́run fi Ń Wo Sìgá Mímu?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • “Àwa Jáwọ́ Ńbẹ̀—Ìwọ náà Lè Ṣe Bẹ́ẹ̀!”
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 10/22 ojú ìwé 21-24

Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?

Orílẹ̀-èdè kan tí ó ṣèrànwọ́ láti gbé tábà jáde fún aráyé ń múpò iwájú ní kíkìlọ̀ nípa àwọn ewu rẹ̀.

ÒPÌTÀN kan kọ̀wé pé: “Tábà kò sí nínú àkọsílẹ̀ ìtàn kankan ṣáájú ìgbà tí a ṣàwárí ilẹ̀ America.” Àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Caribbean ló fi í fún Columbus. Kíkó o ránṣẹ́ sí ilẹ̀ òkèèrè ló fẹsẹ̀ ìlú Jamestown, ibùdó wíwà pẹ́ títí àkọ́kọ́ fún àwọn ará Britain ní Àríwá America, múlẹ̀. Títà á ló pèsè owó fún Ìyípadà Tegbòtigaga Ilẹ̀ America. Ọ̀gbìn rẹ̀ ni iṣẹ́ àwọn ààrẹ United States àkọ́kọ́ gan-an, George Washington àti Thomas Jefferson.

Ní àwọn àkókò lọ́ọ́lọ́ọ́, Hollywood ń fi sìgá hàn bí àmì òòfà ìfẹ́, ìfani lọ́kàn mọ́ra, àti ànímọ́ àwọn ọkùnrin. Àwọn jagunjagun ilẹ̀ America fi wọ́n fún àwọn ènìyàn tí wọ́n bá pàdé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti jagun. A sì ti gbọ́ pé, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, sìgá ni wọ́n lò bí owó ìná “láti Paris dé Peking.”

Ṣùgbọ́n ipò náà yí padà. Ní January 11, 1964, ọ̀gá àgbà oníṣègùn ilẹ̀ United States gbé ìròyìn olójú ìwé 387 kan jáde, tí ó so sìgá mímu pọ̀ mọ́ àrùn ìwúlé ẹran ara, jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró, àti àwọn àrùn eléwu mìíràn. Láìpẹ́ òfin ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ pé kí a máa kọ ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ náà, “Ìṣọ́ra: Sìgá Mímu Lè Jẹ́ Orísun Ewu fún Ìlera Rẹ,” sára gbogbo páálí sìgá tí a ń tà ní United States. Ní báyìí, a gbọ́ pé sìgá mímu ní ń fa ikú iye ènìyàn tí a fojú díwọ̀n sí 434,000 lọ́dọọdún ní United States. Iye yẹn pọ̀ ju àròpọ̀ iye àwọn ará America tí ó kú lójú ogun láàárín ọ̀rúndún tí ó kọjá lọ!

A Gbé Ìkálọ́wọ́kò Lé E

Ní èyí tí ó lé ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, Aspen, Colorado, ibi ìlògbà òtútù kan tí ó lókìkí, fi òfin de mímu sìgá ní àwọn ilé àrójẹ rẹ̀. Láti ìgbà náà wá, àwọn agbègbè tí a kì í ti í mu sìgá ti wọ́pọ̀ gan-an ní àwọn ilé àrójẹ, ibi iṣẹ́, àti àwọn ibi tí èrò ń pọ̀ sí mìíràn. Ní ọdún pípẹ́ sẹ́yìn, ará California kan béèrè àgbègbè tí a kì í ti í mu sìgá lọ́wọ́ ọmọbìnrin rẹ̀ ní ilé àrójẹ kan ní Virginia. Ó dáhùn pé: “Dádì, ẹkùn ilẹ̀ tábà ni èyí!” Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó fi tún ṣèbẹ̀wò tẹ̀ lé e, a ti ya ìlàjì àyè ilé àrójẹ yẹn sọ́tọ̀ fún àwọn tí kì í mu sìgá. Láìpẹ́ yìí, kò rí ẹnikẹ́ni tí ń mu sìgá níbẹ̀.

Ṣùgbọ́n yíya àyè kan sọ́tọ̀ fún àwọn tí kì í mu sìgá kò tán ìṣòro náà. Àwọn pátákó ìpolówó ńláńlá tí ìjọba gbé kalẹ̀ ní àwọn òpópónà pàtàkì-pàtàkì ní California ń béèrè pé: “Ǹjẹ́ o rò pé èéfín sìgá mọ ààlà agbègbè tí a ti ń mu sìgá bí?”

Nígbà tí New York City fòfin de mímu sìgá ní àwọn ilé àrójẹ rẹ̀ ńlá-ńlá, àwọn onílé àrójẹ fẹ̀hónú hàn pé èyí yóò lé àwọn arìnrìn àjò afẹ́ láti Europe sẹ́yìn, níbi tí wọ́n sọ pé, ìwọ̀n òfin kéréje ní ń ṣàkóso sìgá mímu. Síbẹ̀, ìwádìí kan tí a ṣe ṣáájú ti fi hàn pé ó túbọ̀ ṣeé ṣe kí ìpín 56 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará America lọ sí ilé àrójẹ tí a kì í ti í mu sìgá, nígbà tí kìkì ìpín 26 nínú ọgọ́rùn-ún kì yóò fi taratara fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Pákó ìsọfúnni kan nínú àwọn ọkọ̀ ojú irin abẹ́lẹ̀ New York City kà pé: “Ní èdè èyíkéyìí, ìsọfúnni náà kò yàtọ̀: Má ṣe mu sìgá nígbàkúùgbà, níbikíbi, ní ibùdókọ̀ wa tàbí nínú ọkọ̀ wa. Ẹ ṣeun.” Kì í ṣe ní èdè Gẹ̀ẹ́sì nìkan ni pákó ìsọfúnni náà ti gbé ìsọfúnni yìí jáde, ṣùgbọ́n ní èdè 15 mìíràn pẹ̀lú.

Ọ̀ràn náà ha le tó bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. Bí 300 ènìyàn bá kú nínú ìjábá ńlá kan, yóò máa wà nínú ìròyìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, bóyá ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ pàápàá. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé, a ti fojú díwọ̀n pé 53,000 ará America ń kú lọ́dọọdún nítorí àbájáde ẹ̀yìn-ọ̀-rẹyìn ti fífa èéfín sìgá àwọn ẹlòmíràn símú. Ó sọ pé, ìyẹn ni yóò mú kí fífa èéfín tábà símú láìṣe tààrà, tàbí láti inú afẹ́fẹ́ àyíká jẹ́ “okùnfà ikú tí ó ṣeé dènà tí ó gbapò kẹta, tẹ̀ lé mímu sìgá gan-an àti ọtí líle.”

Àwọn Ọmọdé—Àwọn Òjìyà Tí Kò Láàbò

Ṣùgbọ́n, mímu sìgá nínú ilé ńkọ́? Ìwé Healthy People 2000, ìtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ ìjọba United States tí ń gbé góńgó dídín “ikú àìtọ́jọ́ àti àrùn òun àbùkù ara tí kò pọn dandan” kù kalẹ̀, sọ pé: “Lílo tábà ló ń pa èyí tí ó lé ní ọ̀kan lára ènìyàn mẹ́fà tí ń kú ní United States, òun sì ni okùnfà kan ṣoṣo, tí ó ṣe pàtàkì jù lọ, tí a lè dènà, tí ń fa ikú àti àrùn láwùjọ wa.”

Ó fi kún un pé: “Mímu sìgá pẹ̀lú oyún nínú ti jẹ́ okùnfà ìpín 20 sí 30 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí kò wọ̀n tó bí ó ṣe yẹ nígbà ìbí, iye tí ó pọ̀ tó ìpín 14 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọ tí oṣù wọn kò pé, àti nǹkan bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ikú ọmọ ọwọ́.” Ó sọ pé àwọn ìyá tí ń mu sìgá lè tàtaré àwọn èròjà èéfín tábà, kì í ṣe kìkì nípa fífi ọmú bọ́ ọmọ ọwọ́ náà tàbí nípa mímu sìgá láyìíká ọmọ ọwọ́ náà, ṣùgbọ́n nípa “gbígbé ọmọ ọwọ́ náà sínú iyàrá tí ẹnì kan ti ṣẹ̀ṣẹ̀ mu sìgá tán.”

Ó kan àwọn bàbá pẹ̀lú. Ìtẹ̀jáde kan náà dámọ̀ràn pé: “Bí àwọn ènìyàn tí ń fara kanra pẹ̀lú àwọn ọmọdé bá ní láti mu sìgá, kí wọ́n bọ́ síta tàbí kí wọ́n lọ sí àwọn agbègbè tí afẹ́fẹ́ kò ti lè fẹ́ dé ibi tí ọmọ náà bá wà.” Ewu náà ń pọ̀ sí i bí iye àwọn àgbàlagbà tí ń mu sìgá nínú iyàrá kan náà àti iye sìgá tí a mu ṣe ń pọ̀ sí i. Nítorí èyí ni Joycelyn Elders, ọ̀gá àgbà oníṣègùn ilẹ̀ United States nígbà kan rí, fi sọ pé: “Àwọn ọmọ rẹ ni òjìyà aláìmọwọ́mẹsẹ̀ jù lọ nítorí àwọn ohun tí o sọ di bárakú.”

Àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú wà nínú ewu. Ìpolówó ọjà kan tí ìjọba ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀ lórí tẹlifíṣọ̀n ní California fi ọkùnrin arúgbó kan tí ó dá jókòó hàn. Ó sọ pé ìyàwó òun ‘ń tojú bọ’ ọ̀ràn sìgá mímu ‘òun.’ “Ó tilẹ̀ halẹ̀ pé òun kò níí fẹnu kò mí lẹ́nu mọ́, bí n kò bá ṣíwọ́. Mo sọ pé ẹ̀dọ̀fóró mi ni, ẹ̀mí mi sì ni. Ṣùgbọ́n n kò tọ̀nà. N kò ṣíwọ́. N kò mọ̀ pé ẹ̀mí tí n óò pàdánù kì í ṣe tèmi . . . Tirẹ̀ ni.” Bí ọkùnrin arúgbó náà ṣe ń wo àwòrán ìyàwó náà pẹ̀lú ìbànújẹ́, ó fi kún un pé: “Ìyàwó mi ni ẹ̀mí mi.”

Ojú Ìwòye Tí Ó Yí Padà

Irú àwọn ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ ti mú kí sìgá mímu dín kù gan-an ní United States. Lọ́nà yíyani lẹ́nu, a fojú díwọ̀n pé mílíọ̀nù 46 ará America—ìpín 49.6 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tó ti mu sìgá rí—ti ṣíwọ́!

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ilé iṣẹ́ tábà ní ìwéwèé ìṣúnná owó púpọ̀ fún ìpolówó ọjà wọn, wọ́n sì ti ń jà padà. Àbájáde rẹ̀ ni pé, bí sìgá mímu ṣe ń dín kù ti ń falẹ̀. Joseph A. Califano Kékeré, ti Ibùdó Ìsọdibárakú àti Àwọn Èròjà Àsọdibárakú ní Yunifásítì Columbia ti New York, sọ pé: “Ìpalára títóbi jù lọ tí ilé iṣẹ́ tábà ń ṣe fún ìlera ará ìlú [ni] lílò tí ó ń lo ìpolówó ọjà àti ọjà títà tí ń fojú sun àwọn ọmọdé àti àwọn ọ̀dọ́langba tí wọ́n jẹ́ àwùjọ tuntun tí ń sọ nǹkan di bárakú ní ti àwọn ohun àṣejáde aṣekúpani rẹ̀.”

Ìwé ìròyìn The Journal of the American Medical Association sọ pé: “A fojú bù ú pé 3000 ọ̀dọ́ ènìyàn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn jẹ́ ọmọdé àti aṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà ń di amusìgá déédéé lójoojúmọ́. Èyí jẹ́ nǹkan bíi mílíọ̀nù 1 amusìgá tuntun lọ́dọọdún tí ń rọ́pò nǹkan bíi mílíọ́nù 2 amusìgá tí ń fi sìgá mímu sílẹ̀ tàbí tí ń kú lọ́dọọdún lápá kan.”

Ó lé ní ìdajì lára gbogbo amusìgá ní United States tí ń bẹ̀rẹ̀ láti bí ọmọ ọdún 14. David Kessler, kọmíṣánnà Àjọ Abójútó Oúnjẹ àti Oògùn ní United States, sọ pé, lára àwọn 3,000 ọmọdé to ṣẹ̀ṣẹ̀ ń di amusìgá lójoojúmọ́, àwọn àìlera tí ó tan mọ́ sìgá mímu ni yóò pa iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 1,000 lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.

Bí iye ìṣirò yẹn bá dà ọ́ láàmú, ì bá dára kí a rántí pé àwọn ọmọ wa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wa. Bí a kò bá fẹ́ kí wọ́n máa mu sìgá, àwa pẹ̀lú kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

Títà Á Sílẹ̀ Òkèèrè

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí ń mu sìgá ní United States ti dín kù, ọjà náà ń tà sí i nílẹ̀ òkèèrè. Ìwé agbéròyìnjáde Los Angeles Times ròyìn pé, “àwọn tí a ń kó ránṣẹ́ sílẹ̀ òkèèrè ti lé ní ìlọ́po mẹ́ta, iye tí ilé iṣẹ́ tábà United States sì ń tà sílẹ̀ òkèèrè ti pọ̀ sí i gan-an.” Ìwé ìròyìn The New England Journal of Medicine sọ pé ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, “ìtẹnumọ́ tí a gbé karí ìjàm̀bá tí sìgá mímu ń ṣe kò tó nǹkan,” ó sì fàyè gba àwọn ilé iṣẹ́ tábà “láti kó wọnú ọjà ilẹ̀ òkèèrè ní kánmọ́kánmọ́.”

Síbẹ̀síbẹ̀, Patrick Reynolds, ọmọkùnrin R. J. Reynolds Kékeré, tí ó sì jẹ́ àtọmọdọ́mọ olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ tí ń ṣe sìgá Camel àti Winston, sọ pé sìgá mímu ló ń pa 1 nínú ènìyàn 5 tí ń kú ní United States. A tún gbọ́ pé Reynolds sọ pé mímu sìgá ń fa ọ̀pọ̀ ikú lọ́dọọdún ju àròpọ̀ èyí tí kokéènì, ọtí líle, heroin, iná, fífi ọwọ́ ẹni pa ara ẹni, ìpànìyàn, àrùn AIDS, àti ìjàm̀bá ohun ìrìnnà ń fà lọ, àti pé òun ni okùnfà kan ṣoṣo tí a lè dènà jù lọ, tí ń fa ikú, àrùn, àti ìsọdi bárakú nínú sànmánì wa.

Ó ha dà bí ohun àjèjì pé orílẹ̀-èdè kan náà tí ó kọ́ ayé láti mu sìgá ti ń gbé àtakò tí ń gbilẹ̀ sí i dìde sí tábà bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá dára kí a bi ara wa léèrè pé, ‘Ta ni ì bá tún mọ ìdáhùn dídára jù lọ?’

Ìwé ìròyìn Modern Maturity sọ nípa obìnrin kan tí ó ti ń mu sìgá fún èyí tí ó lé ní 50 ọdún. Obìnrin náà wí pé: “Bí ó bá fi lè wọ̀ ọ́ lára, o wọ gàù.” Ṣùgbọ́n ó mú èrò pé sìgá mímu jẹ́ nǹkan ìṣefàájì tí ó mú kí ó bẹ̀rẹ̀ gan-an kúrò lọ́kàn, ó ṣe àtúpalẹ̀ àwọn àwáwí tí ó lè mú kí ó máa bá a nìṣó, ó sì ṣíwọ́.

Ó kọ̀wé pé: “Gbìyànjú fífi sìgá mímu sílẹ̀ wò. Ó kàmàmà.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

A ti “díye lé e pé láàárín àwọn ọdún 1990, ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà, tábà yóò ṣokùnfà ikú nǹkan bí ìpín 30 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín àwọn ẹni ọdún 35 sí ọdún 69, èyí tí yóò mú kí ó jẹ́ ohun kan ṣoṣo tí ń fa ikú àìtọ́jọ́ jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà.”—NEW ENGLAND JOURNAL OF MEDICINE

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

ÀWỌN ÌKÌLỌ̀ NÍPA ÀRÙN JẸJẸRẸ

Àwọn ìkìlọ̀ wọ̀nyí ni a fà yọ láti inú àwọn ìwé pẹlẹbẹ Facts on Lung Cancer àti Cancer Facts & Figures—1995 tí Ẹgbẹ́ Tí Ń Gbógun Ti Àrùn Jẹjẹrẹ ní America ṣe jáde:

• “Àwọn ìyàwó tí kì í mu sìgá wà nínú ewu níní àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró tí ó fi ìpín 35 nínú ọgọ́rùn-ún peléke bí ọkọ wọn bá ń mu sìgá.”

• “A fojú bù ú pé sìgá mímu ló ń fa ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró láàárín àwọn ọkùnrin àti ìpín 79 nínú ọgọ́rùn-ún láàárín àwọn obìnrin.”

• “Fún ẹni tí ó bá ń mu páálí sìgá méjì lóòjọ́ fún 40 ọdún, ó ṣeé ṣe kí àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró pa á ní ìlọ́po 22 ju ẹni tí kì í mu sìgá lọ.”

• “Ọ̀nà dídára jù lọ láti dáàbò bo ara ẹni lọ́wọ́ àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró ni láti má ṣe dáwọ́ lé mímu sìgá, tàbí láti ṣíwọ́ rẹ̀ lọ́gán.”

• “Kò sí ohunkóhun tí ń jẹ́ sìgá tí kò léwu.”

• “Lílo tábà jíjẹ tàbí áṣáà ń mú kí ewu jẹjẹrẹ ẹnu, ti gògóńgò, ti ọ̀nà ọ̀fun, àti ti ihò ọ̀fun pọ̀ sí i, ó sì jẹ́ àṣà tí ń di bárakú gan-an.”

• “Àfikún ewu àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀rẹ̀kẹ́ àti ti ẹran ìdí eyín lè fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po àádọ́ta láàárín àwọn tí wọ́n bá lo áṣáà fún ìgbà gígùn.”

• “Àwọn ènìyàn tí ń ṣíwọ́ mímu sìgá, láìka ọjọ́ orí wọn sí, ń pẹ́ láyé ju àwọn tí ń mu sìgá nìṣó lọ. Àwọn amusìgá tí ń ṣíwọ́ mímu sìgá kí wọ́n tóó pé 50 ọdún ní ìdajì ewu kíkú láàárín ọdún 15 tí ó tẹ̀ lé e ní ìfiwéra pẹ̀lú èyí tí àwọn tí ń mu sìgá nìṣó ní.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

ẸTÌ ÀWỌN ÀGBẸ̀

Látọdúnmọ́dún, gbígbin tábà ti pèsè owó ìgbọ́bùkátà fún àwọn ìdílé tí ilẹ̀ oko wọn kéré ju bí ohun ọ̀gbìn èyíkéyìí mìíràn ti lè ṣe lọ. Kókó yìí ti dá ìṣòro ẹ̀rí ọkàn sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Stanley Hauerwas, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìhùwà tí ó bá ìmọ̀ ẹ̀sìn mu ní Yunifásítì Duke, ilé ẹ̀kọ́ kan tí ògbóǹtarìgì onítábà kan dá sílẹ̀, sọ pé: “Mo rò pé ìdààmú èrò inú tí àwọn tí ń gbin tábà ní ni pé . . . nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbìn ín, wọn kò mọ̀ pé yóò pa ẹnikẹ́ni.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èéfín kì í dúró sí kìkì ààlà agbègbè tí a ti ń mu sìgá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Mímu sìgá pẹ̀lú oyún nínú ni okùnfà nǹkan bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún nínú gbogbo ikú ọmọ ọwọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́